114 - Suuratun-Naas
Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
(1) Sọ pé: “Mo sá di Olúwa àwọn ènìyàn,
(2) Ọba àwọn ènìyàn,
(3) Ọlọ́hun àwọn ènìyàn,¹
1. Ìtúmọ̀ “Ọlọ́hun àwọn ènìyàn” ni pé, Ẹni tí àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo, tí wọn kò sì gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ẹlòmíìràn lẹ́yìn Rẹ̀.
(4) níbi aburú (Èṣù) oníròyíròyí, olùsásẹ́yìn (fún ẹni tó bá ń dárúkọ Allāhu¹).
1. Ọ̀kan pàtàkì nínú àǹfààní àti oore tí ó wà nínú ath-thikār ṣíṣe ni pé, Èṣù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yóò máa sá sẹ́yìn fún ẹni tí ó bá ń ṣe ath-thikār ní gbogbo ìgbà. Kí á sì rántí wí pé, ọ̀kan pàtàkì jùlọ nínú ohun tí mùsùlùmí yóò máa fi ṣe ath-thikār ni kíké al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé ní ojoojúmọ́ ní díẹ̀ díẹ̀. Lẹ́yìn náà ni àwọn gbólóhùn ath-thikār èyí tí ó wà nínú ẹ̀gbàwá hadīth Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Kí á sì jìnnà tefétefé sí àwọn ìkàkúkà tí wọ́n ń pè ní “wiridi àti waṭḥīfah” èyí tí àwọn ààfáà ẹlẹ́bọ, àwọn ààfáà onibidiah àti àwọn ààfáà onisūfī dáálẹ̀. Bí mùsùlùmí kò bá jìnnà tefétefé sí àwọn irúfẹ́ “wiridi àti waṭḥīfah” bẹ́ẹ̀, yàtọ̀ sí pé, ó máa di kèfèrí lórí rẹ̀, àwọn èṣù yóò máa bá onítọ̀ún fínra.
(5) (Èṣù ni) ẹni tí ó ń kó ròyíròyí sínú àwọn ọkàn ènìyàn.
(6) (Èṣù náà) wà nínú àwọn àlùjànnú àti àwọn ènìyàn.”

SOURCE:
IslamHouse.com Books Quran