86 - Suuratut-Taariq
Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.  
(1) (Allāhu) fi sánmọ̀ àti Tọ̄riƙ búra.
(2) Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Tọ̄riƙ?
(3) Ìràwọ̀ tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ń tàn ròrò (ní alẹ́ ni).
(4) Kò sí ẹ̀mí kan àfi kí ẹ̀ṣọ́ kan wà fún un (nínú àwọn mọlāika).
(5) Nítorí náà, kí ènìyàn wòye sí ohun tí A fi ṣẹ̀dá rẹ̀.
(6) Wọ́n ṣẹ̀dá rẹ̀ láti inú omi tó ń tú jáde kọ̀ọ́kọ̀ọ́.
(7) Ó ń jáde láti ààrin ìbàdí ọkùnrin àti àwọn ẹfọ́nhà igbá-àyà obìnrin.
(8) Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lóri ìdápadà rẹ̀
(9) ní ọjọ́ tí wọ́n máa ṣe àyẹ̀wò àwọn (iṣẹ́) àṣepamọ́.
(10) Nígbà náà, kò níí sí agbára tàbí alárànṣe kan fún un.
(11) Allāhu fi sánmọ̀ tó ń rọ òjò ní ọdọọdún búra.
(12) Ó tún fi ilẹ̀ tó ń sán kànkàn (fún híhùjáde èso) búra.
(13) Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀-ìpínyà (láààrin òdodo àti irọ́).
(14) Kì í sì ṣe àwàdà.
(15) Dájúdájú wọ́n ń déte gan-an.
(16) Èmi náà sì ń déte gan-an.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Baƙọrah; 2:15.
(17) Nítorí náà, lọ́ra fún àwọn aláìgbàgbọ́. Lọ́ wọn lára sẹ́ fún ìgbà díẹ̀.