95 - Suuratut-Teen
 Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
(1) Allāhu fi èso tīn àti èso zaetūn búra.
(2) Ó tún fi àpáta Sīnīn búra.
(3) Ó tún fi ìlú ìfàyàbalẹ̀ yìí búra.
(4) Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn pẹ̀lú ìrísí tó dára jùlọ.
(5) Lẹ́yìn náà, A máa dá a padà sí ìsàlẹ̀ pátápátá (nínú Iná).
(6) Àyàfi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Nítorí náà, ẹ̀san tí kò níí pin (tí kò níí pẹ̀dín) ń bẹ fún wọn.
(7) Ta l’ó tún ń pè ọ́ ní òpùrọ́ nípa Ọjọ́ ẹ̀san lẹ́yìn (ọ̀rọ̀ yìí)?
(8) Ṣé Allāhu kọ́ ni Ẹni t’Ó mọ ẹ̀jọ́ dá jùlọ nínú àwọn adájọ́ ni?