65 - Suuratut-Tolaaq
Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
(1) Ìwọ Ànábì, nígbà tí ẹ bá fẹ́ kọ àwọn obìnrin sílẹ̀, ẹ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ pẹ̀lú òǹkà ọjọ́ opó ìkọ̀sílẹ̀ tí wọ́n máa ṣe.¹ Kí ẹ sì ṣọ́ òǹkà ọjọ́ opó ìkọ̀sílẹ̀ náà. Kí ẹ bẹ̀rù Allāhu, Olúwa yín. Ẹ má ṣe mú wọn jáde kúrò nínú ilé wọn, àwọn náà kò sì gbọdọ̀ jáde àfi tí wọ́n bá lọ ṣe ìbàjẹ́ tó fojú hàn.² Ìwọ̀nyẹn sì ni àwọn ẹnu-ààlà òfin tí Allāhu gbékalẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ àwọn ẹnu-ààlà òfin tí Allāhu gbékalẹ̀, o kúkú ti ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara rẹ̀. Ìwọ kò sì mọ̀ bóyá Allāhu máa mú ọ̀rọ̀ titun kan ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn.
1. Ìyẹn ni pé, ẹ jẹ́ kí wọ́n ṣe “‘iddatu-ttọlāƙ” (opó ìkọ̀sílẹ̀) parí kí yìgì ààrin yín tó ó já. Lẹ́yìn náà, kí ó padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀. Bákan náà, a kì í sọ pé “mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀” ní àsìkò tí obìnrin bá ń ṣe héélà rẹ̀ lọ́wọ́ tàbí lẹ́yìn ìbálòpọ̀ tó wáyé lẹ́yìn ìmọ́ra níbi héélà. 2. Ìbàjẹ́ tó fojú hàn tí ó lè dínà kí obìnrin rí opó ìkọ̀sílẹ̀ rẹ̀ ṣe nínú ilé ọkọ rẹ̀ pín sí bíi oríṣi mẹ́ta nínú àwọn tírà Tafsīr: Ìbàjẹ́ kìíní: kí obìnrin ṣe zina. Ìbàjẹ́ kejì: kí ẹnu obìnrin mú fún èébú bíbú, èpè ṣíṣẹ́ àti ariwo burúkú tí ó ń fi kó ìnira bá ọkọ rẹ̀ àti ará ilé ọkọ rẹ̀. Ìbàjẹ́ kẹta: kí igun kìíní kejì wà nínú ẹ̀rù àti àìbalẹ̀-ọkàn síra wọn nípa aburú tí ó súnmọ́ kí wọ́n fi kanra wọn tàbí dúkìá wọn. Láti lè dènà irúfẹ́ ìwọ̀nyí, obìnrin máa lọ ṣe opó ìkọ̀sílẹ̀ rẹ̀ ní àyè mìíràn. Fún àlàyé yòókù lórí tọlāƙ (kíkọ ìyàwó sílẹ̀), ẹ lọ ka sūrah al-Baƙọrah; 2: 228 - 232.
(2) Nígbà tí wọ́n bá fẹ́ parí òǹkà ọjọ́ opó wọn, ẹ mú wọn mọ́ra ní ọ̀nà tó dára tàbí kí ẹ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ní ọ̀nà tó dára.¹ Ẹ fi àwọn onídéédé méjì nínú yín jẹ́rìí sí i.² Kí ẹ sì gbé ìjẹ́rìí náà dúró ní tìtorí ti Allāhu. Ìyẹn ni À ń fi ṣe wáàsí fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń bẹ̀rù Allāhu, Ó máa fún un ní ọ̀nà àbáyọ (nínú ìṣòro).
1. Ìyẹn ni pé, ẹ lè dá gbólóhùn ìkọ̀sílẹ̀ pada (ìyẹn tí ìkọ̀sílẹ̀ kò bá tí ì pé ìgbà mẹta) tàbí ẹ sì lè takú sórí gbólóhùn ìkọ̀sílẹ̀ náà títí òǹkà n̄ǹkan oṣù mẹ́ta yóò fi ko sẹ̀. 2. Ìyapa-ẹnu wà lọ́dọ̀ àwọn ààfáà ẹ̀sìn lórí kí ni ohun tí tọkọ-tìyàwó tó fẹ́ kọra wọn sílẹ̀ máa wá ẹlẹ́rìí méjì fún. Ṣé jíjẹ́rìí gbólóhùn ìkọ̀sílẹ̀ ni tàbí jíjẹ́rìí ìdápadà obìnrin náà (ìyẹn, wíwọ́gilé ìkọ̀sílẹ̀ ti ìgbà àkọ́kọ́ tàbí ti ìgbà kejì.) Kókó tí ó gbọ́dọ̀ yé wa ni pé, kíkọ obìnrin sílẹ̀ àti dídá a padà kò gbọ́dọ̀ la iyàn jíjà lọ. Ìdí nìyí tí ẹ̀sìn fi fẹ́ kí á pe ẹlẹ́rìí méjì sí àwọn ọ̀rọ̀ náà.
(3) Ó sì máa pèsè fún un ní àyè tí kò ti rokàn. Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé Allāhu, Ó máa tó o. Dájúdájú Allāhu yóò mú àṣẹ Rẹ̀ ṣẹ. Dájúdájú Allāhu ti kọ òdíwọ̀n àkókò fún gbogbo n̄ǹkan.
(4) Àwọn obìnrin tó ti sọ̀rètí nù nípa n̄ǹkan oṣù ṣíṣe nínú àwọn obìnrin yín, tí ẹ bá ṣeyèméjì, òǹkà ọjọ́ ìkọ̀sílẹ̀ wọn ni oṣù mẹ́ta. (Bẹ́ẹ̀ náà ni fún) àwọn tí kò tí ì máa ṣe n̄ǹkan oṣù. Àwọn olóyún, ìparí òǹkà ọjọ́ opó ìkọ̀sílẹ̀ tiwọn ni pé kí wọ́n bí oyún inú wọn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń bẹ̀rù Allāhu, Ó máa ṣe ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìrọ̀rùn fún un.
(5) Ìyẹn ni àṣẹ Allāhu, tí Ó sọ̀kalẹ̀ fún yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń bẹ̀rù Allāhu, Ó máa pa àwọn àṣìṣe rẹ̀ rẹ́. Ó sì máa jẹ́ kí ẹ̀san rẹ̀ tóbi.
(6) Ẹ fún wọn ní ibùgbé nínú ibùgbé yín bí àyè ṣe gbà yín mọ. Ẹ má ṣe ni wọ́n lára láti kó ìfúnpinpin bá wọn. Tí wọ́n bá jẹ́ olóyún, ẹ náwó lé wọn lórí títí wọn yóò fi bí oyún inú wọn. Tí wọ́n bá ń fún ọmọ yín ní ọyàn mu, ẹ fún wọn ní owó-ọ̀yà wọn. Ẹ dámọ̀ràn láààrin ara yín ní ọ̀nà tó dára. Tí ọ̀rọ̀ kò bá sì rọgbọ láààrin ara yín, kí ẹlòmíìràn bá ọkọ (fún ọmọ) ní ọyàn mu.
(7) Kí ọlọ́rọ̀ ná nínú ọrọ̀ rẹ̀. Ẹni tí A sì díwọ̀n arísìkí rẹ̀ fún (níwọ̀nba), kí ó ná nínú ohun tí Allāhu fún un. Allāhu kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àyàfi n̄ǹkan tí Ó fún un. Allāhu yó sì mú ìrọ̀rùn wá lẹ́yìn ìnira.
(8) Mélòó mélòó nínú àwọn ìlú tí wọ́n yapa àṣẹ Olúwa Rẹ̀ àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. A sì máa ṣírò iṣẹ́ wọn ní ìṣírò líle. Àti pé A máa jẹ wọ́n níyà tó burú gan-an.
(9) Nítorí náà, wọn máa tọ́ ìyà ọ̀ràn wọn wò. Ìkángun ọ̀rọ̀ wọn sì jẹ́ òfò.
(10) Allāhu ti pèsè ìyà líle sílẹ̀ dè wọ́n. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, ẹ̀yin onílàákàyè tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo. Allāhu kúkú ti sọ tírà ìrántí kalẹ̀ fún yín.
(11) Òjíṣẹ́ kan tí ó máa ké àwọn āyah Allāhu tó yanjú fún yín nítorí kí ó lè mú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n tún ṣe àwọn iṣẹ́ rere, kúrò nínú àwọn òkùnkùn lọ sínú ìmọ́lẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ nínú Allāhu ní òdodo, tí ó sì ń ṣe iṣẹ́ rere, Ó máa mú un wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Dájúdájú Allāhu ti ṣe arísìkí rẹ̀ (ìjẹ-ìmu àti ìgbádùn rẹ̀) ní dáadáa fún un.
(12) Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ méje àti ilẹ̀ ní (òǹkà) irú rẹ̀. Àṣẹ ń sọ̀kalẹ̀ láààrin wọn nítorí kí ẹ lè mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan. Àti pé dájúdájú Allāhu fi ìmọ̀ rọ̀gbà yí gbogbo n̄ǹkan ká.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Mujādilah 58:7.