|
| 36 - Suuratu Yaasiin | |
| | كاتب الموضوع | رسالة |
---|
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: 36 - Suuratu Yaasiin الأحد 23 يوليو 2023, 6:21 pm | |
| 36 - Suuratu Yaasiin Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run. (1) Yā sīn (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)¹ 1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1. (2) (Allāhu) fi Al-Ƙur’ān tí ó kún fún ọgbọ́n búra.¹ 1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Yūnus; 10:1 (3) Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn Òjíṣẹ́. (4) (O) wà lórí ọ̀nà tààrà (’Islām). (5) (Al-Ƙur’ān jẹ́) ìmísí tó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run (6) nítorí kí o lè ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn kan, (àwọn) tí wọn kò ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn bàbá wọn rí. Nítorí náà, afọ́núfọ́ra sì ni wọ́n (nípa ìmọ̀nà).¹ 1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Ƙọsọs; 28:46. (7) Dájúdájú ọ̀rọ̀ náà ti kò lé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn lórí; wọn kò sì níí gbàgbọ́. (8) Dájúdájú Àwa ti kó ẹ̀wọ̀n sí wọn lọ́rùn (mọ́ ọwọ́ wọn). Ó sì ga dé àgbọ̀n (wọn). Wọ́n sì gà wọ́n lọ́rùn sókè. (9) Àti pé Àwa fi gàgá kan síwájú wọn, gàgá kan sẹ́yìn wọn; A bò wọ́n lójú, wọn kò sì ríran. (10) Bákan náà ni fún wọn, yálà o kìlọ̀ fún wọn tàbí o kò kìlọ̀ fún wọn; wọn kò níí gbàgbọ́.¹ 1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:6. (11) Ẹni tí ìkìlọ̀ rẹ (máa wúlò fún) ni ẹni tí ó tẹ̀lé Ìrántí (al-Ƙur’ān), tí ó sì páyà Àjọkẹ́-ayé ní ìkọ̀kọ̀. Nítorí náà, fún un ní ìró ìdùnnú nípa àforíjìn àti ẹ̀san alápọ̀n-ọ́nlé. (12) Dájúdájú Àwa, Àwa l’À ń sọ àwọn òkú di alàyè. A sì ń ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n tì síwájú àti orípa (iṣẹ́ ọwọ́) wọn. Gbogbo n̄ǹkan ni A ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú tírà kan tó yanjú. (13) Fi àpèjúwe kan lélẹ̀ fún wọn nípa àwọn ará ìlú kan nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ wá bá wọn. (14) (Rántí) nígbà tí A rán Òjíṣẹ́ méjì níṣẹ́ sí wọn. Wọ́n pe àwọn méjèèjì ní òpùrọ́. A sì fi ẹnì kẹta ró àwọn méjèèjì lágbára. Wọ́n sì sọ pé: “Dájúdájú àwa ni Òjíṣẹ́ tí Wọ́n rán níṣẹ́ si yín.”¹ 1. Kíyè sí i! Ìtàn kan gbajúmọ̀ nínú àwọn tírà Tafsīr pé, àwọn mẹ́ta kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - tí ó rán níṣẹ́ lọ sí ìlú Antiok ni àwọn Òjíṣẹ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà. Àmọ́ nínú Tafsīr Ibn Kathīr, ó sọ pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Nítorí náà, má ṣe gbaralé ìtàn náà. Èyí tí ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ ni pé, wọ́n jẹ́ ara àwọn Òjíṣẹ́ tí Allāhu kò dárúkọ wọn fún Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Àti pé Òjíṣẹ́ Allāhu ni wọ́n pe ara wọn, wọn kò pe ara wọn ní òjíṣẹ́ ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá wọn -. (15) Wọ́n wí pé: “Ẹ̀yin kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe abara bí irú tiwa. Àjọkẹ́-ayé kò sì sọ n̄ǹkan kan kalẹ̀. Ẹ̀yin kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe òpùrọ́.” (16) Wọ́n sọ pé: “Olúwa wa mọ̀ pé dájúdájú àwa ni Òjíṣẹ́ tí Wọ́n rán níṣẹ́ si yín. (17) Kò sì sí ojúṣe kan fún wa bí kò ṣe ìkéde (ẹ̀sìn) tó yanjú.” (18) Wọ́n wí pé: “Dájúdájú àwa rí àmì aburú lára yín. Tí ẹ kò bá jáwọ́ (níbi ìpèpè yín), dájúdájú a máa sọ yín lókò pa. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro yó sì jẹ yín láti ọ̀dọ̀ wa.” (19) Wọ́n sọ pé: “Àmì aburú yín ń bẹ pẹ̀lú yín. Ṣé nítorí pé wọ́n ṣe ìṣítí fún yín (l’ẹ fi rí àmì aburú lára wa)? Kò rí bẹ́ẹ̀! Ìjọ alákọyọ ni yín ni.” (20) Ọkùnrin kan sáré dé láti òpin ìlú náà, ó wí pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ tẹ̀lé àwọn Òjíṣẹ́ náà. (21) Ẹ tẹ̀lé ẹni tí kò bèèrè owó-ọ̀yà kan ní ọwọ́ yín. Olùmọ̀nà sì ni wọ́n. (22) Kí ni ó máa mú mi tí èmi kò fi níí jọ́sìn fún Ẹni tí Ó pilẹ̀ ẹ̀dá mi? Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí. (23) Ṣé kí èmi sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu ni? Tí Àjọkẹ́-ayé bá fẹ́ fi ìnira kàn mí, ìṣìpẹ̀ wọn kò lè rọ̀ mí lọ́rọ̀ kiní kan, wọn kò sì lè gbà mí là. (24) (Bí èmi kò bá jọ́sìn fún Allāhu) nígbà náà dájúdájú mo ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé. (25) Dájúdájú èmi gbàgbọ́ nínú Olúwa Ẹlẹ́dàá yín. Nítorí náà, ẹ gbọ́ mi.” (Àwọn aláìgbàgbọ́ sì pa onígbàgbọ́ òdodo yìí.) |
| | | أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 36 - Suuratu Yaasiin الأحد 23 يوليو 2023, 6:22 pm | |
| (26) (Àwọn mọlāika) wọ́n sọ pé: “Wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra.” Ó sọ pé: “Àwọn ènìyàn mi ìbá ní ìmọ̀ (27) nípa bí Olúwa mi ṣe foríjìn mí àti (bí) Ó ṣe fi mí sí ara àwọn alápọ̀n-ọ́nlé (wọn ìbá ronú pìwàdà).” (28) A kò sọ ọmọ ogun kan kalẹ̀ lé àwọn ènìyàn rẹ̀ lórí láti sánmọ̀ lẹ́yìn rẹ̀. A kò sì sọ (mọlāika kan) kalẹ̀ (fún ìparun wọn). (29) (Ìparun wọn) kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe igbe ẹyọ kan; nígbà náà ni wọ́n di òkú kalẹ̀. (30) Àbámọ̀ mà ni fún àwọn ẹrúsìn náà (nígbà tí wọ́n bá fojú ara wọn rí Iná); òjíṣẹ́ kan kò níí wá bá wọn àyàfi kí wọ́n máa fi ṣe yẹ̀yẹ́. (31) Ṣé wọn kò wòye pé mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn? (Ṣé wọn kò wòye pé) dájúdájú wọn kò padà sí ọ̀dọ̀ wọn mọ́ (nílé ayé) ni? (32) Dájúdájú gbogbo wọn pátápátá sì ni (àwọn mọlāika) máa kó wá sí ọ̀dọ̀ Wa. (33) Àmì ni òkú ilẹ̀¹ jẹ́ fún wọn. A sọ ọ́ di ààyè. A sì mú èso jáde láti inú rẹ̀. Wọ́n sì ń jẹ nínú rẹ̀. 1. Òkú ilẹ̀, ìyẹn ni ilẹ̀ tí ó ti di òkú tí kò lè hu irúgbìn kan kan. Kíyè sí i! Nínú ìlò èdè Yorùbá, kò sí “òkú ilẹ̀” tàbí pé “ilẹ̀ kú”. Dípò bẹ́ẹ̀, Yorùbá máa sọ pé, “Kàkà kí ilẹ̀ kú, ilẹ̀ yó yà sá ni.” Àmọ́ ìlò èdè Lárúbáwá kò tako pípe ilẹ̀ ní “òkú ilẹ̀” (34) A tún ṣe àwọn ọgbà dàbínù àti àjàrà sórí ilẹ̀. A sì mú àwọn odò ìṣẹ́lẹ̀rú ṣàn láti inú rẹ̀ (35) nítorí kí wọ́n lè jẹ nínú èso rẹ̀ àti èyí tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe!¹ Ṣé wọn kò níí dúpẹ́ ni? 1. Àwọn kan nínú àwọn onímọ̀ Tafsīr túmọ̀ “mọ̄” tó jẹyọ nínú “وَمَا عَمِلَتْهُ أَيْدِيهِمْ ۖ” yìí sí “mọ̄-maosūlah’. Ìtúmọ̀ yìí l’a lò nínú āyah yìí. Ìtúmọ̀ náà sì dúró lé iṣẹ́ àgbẹ̀. Àwọn mìíràn sì túmọ̀ “mọ̄” yìí sí “mọ̄-nnāfiyah. Nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀, gbólóhùn náà máa túmọ̀ sí pé, “nítorí kí wọ́n lè jẹ nínú èso rẹ̀, kì í sì ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Ṣé wọn kò níí dúpẹ́ ni?” Ìtúmọ̀ kejì dúró lé iṣẹ́ Allāhu lórí ìṣẹ̀dá n̄ǹkan oko. Ìyẹn ni pé, àdáyébá ni gbogbo èso. Kò sí èso kan tí ìṣẹ̀dá rẹ wá láti ọwọ́ àgbẹ̀. (36) Mímọ́ ni fún Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan ní oríṣiríṣi nínú ohun tí ilẹ̀ ń hù jáde àti nínú ẹ̀mí ara wọn àti nínú ohun tí wọn kò mọ̀.¹ 1. Àwọn nasọ̄rọ̄ sọ pé, “Ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sáẹ̀nsì tako āyah yìí nítorí pé, àìmọ̀ye n̄ǹkan l’ó wà tí kò ṣe é pín sí ìsọ̀rí akọ àti abo.” Èsì: Ní àkọ́kọ́ ná, mùsùlùmí kò gbọ́dọ̀ gbẹ̀tàn pẹ̀lú àbá tàbí irọ́. Àbá àti irọ́ ni èyíkéyìí ọ̀rọ̀ tàbí ìròrí tó bá yapa sí al-Ƙur’ān àti hadīth Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti ìpasẹ̀ ọ̀rọ̀ ìmọ̀ sáẹ̀nsì kan, tàbí ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ẹ̀rọ kan tàbí ìmọ̀ ìròrí kan tàbí èyíkéyìí ìmọ̀ kan lòdì sí āyah kan nínú al-Ƙur’ān tàbí hadīth Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀, ó ti ṣìnà ní ìṣìnà pọ́nńbélé. Ó ṣuwọ̀n kí àwọn nasọ̄rọ̄ dákẹ́ ẹnu wọn nípa ìtúmọ̀ āyah al-Ƙur’ān àti hadīth Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - nítorí pé, ńṣe ni wọ́n ń dá ọ̀ràn kún ọ̀ràn. Wọ́n sì ń fira wọn hàn gẹ́gẹ́ bí aláìmọ̀kan tó gbópọn. Nínú al-Ƙur’ān kalmọh “zaoj” jẹyọ ní àyè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí àpapọ̀ rẹ̀ lé ní ọgbọ̀n. “’Azwāj” ni ọ̀pọ̀, “zaoj” ni ẹyọ. “Zaoj” sì ń túmọ̀ sí akọ tàbí abo nígbà tí Allāhu Ẹlẹ́dàá bá ń = = sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá ènìyàn tàbí ọmọ bíbí, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah an-Najm; 53:45 àti sūrah al-Ƙiyāmọh; 75:39. Bákan náà, “zaoj” ń túmọ̀ sí ọkọ tàbí aya nígbà tí Allāhu Ẹlẹ́dàá bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó. Nínú irú sàkánì yìí ìtúmọ̀ ti “aya” l’ó sì pọ̀ jùlọ fún zaoj nínú al-Ƙur’ān. Bákan náà, “zaoj” ń túmọ̀ sí ìkíní-kejì tàbí ẹnì kejì nígbà tí Allāhu bá ń sọ̀rọ̀ nípa ènìyàn àti ẹnì kejì rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:102. Bákan náà, “zaoj” ń túmọ̀ sí èjì ọ̀kán-yà (irú kan-ùn méjì, àmọ́ tí ìkíní kejì yàtọ̀ síra wọn ní ọ̀nà kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí akọ àti abo, n̄ǹkan dídùn àti n̄ǹkan kíkorò, n̄ǹkan tútù àti n̄ǹkan gbígbóná, n̄ǹkan mímu àti n̄ǹkan jíjẹ) tàbí èjì onídàkejì (n̄ǹkan méjì tí ìkíní kejì dúró fún ọ̀rọ̀ àti ìdà kejì rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí sánmọ̀ àti ilẹ̀, ènìyàn àti àlùjọ̀nnú, ọ̀sán àti òru, ìmọ́lẹ̀ àti òòkùn, ìṣìnà àti ìmọ̀nà, òòrùn àti òṣùpá. Ìtúmọ̀ wọ̀nyí ni zaoj mú wá nínú āyah tí à ń tọsẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ àti sūrah ath-Thāriyāt; 51:49 àti nínú ar-Rahmọ̄n; 55:45. Síwájú sí i, “zaoj” tún túmọ̀ sí oníran-ànran tàbí oríṣiríṣi. Bí àpẹ̀ẹrẹ, a lè rí èso mímu tàbí èso jíjẹ kan tí ó máa jẹ́ oríṣiríṣi. Ìtúmọ̀ olóríṣiríṣi tún lọ lábẹ́ āyah tí à ń tọsẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ yìí. Nítorí náà, zaoj kò pọn dandan kí ó ní ìtúmọ̀ akọ àti abo nìkan. Oríṣiríṣi ni “zaoj”; akọ jẹ́ oríṣi kan, abo jẹ́ oríṣi kan, àwọ̀ jẹ oríṣi kan, èdè jẹ́ oríṣi kan, adùn jẹ́ oríṣi kan àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. “Zaoj” ni àwọn n̄ǹkan oríṣi méjì, “ ’azwāj” ni àwọn n̄ǹkan oríṣiríṣi. (37) Àmì kan ni òru jẹ́ fún wọn, tí À ń yọ ọ̀sán jáde láti inú rẹ̀. Nígbà náà (tí A bá yọ ọ́ tán) wọn yóò tún wà nínú òkùnkùn (alẹ́ mìíràn).¹ 1. Kókó inú āyah yìí ni pé, òru l’ó ń ṣíwájú ọ̀sán nínú ọjọ́, bí àpẹ̀ẹrẹ, òru Jímọ̀ mọ́júmọ́ ọ̀sán Jímọ̀, òru Sabt mọ́júmọ́ ọ̀sán Sabt. Nítorí náà, kò sí òru Àlàmísì mọ́júmọ́ ọ̀sán Jímọ̀. Kò sì sí òru Jímọ̀ mọ́júmọ́ Sabt. Bákan náà, wíwọ̀ òòrùn ni ìparí ọjọ́ kan àti ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ mìíràn. Ìyẹn ni pé, níkété tí òòrùn bá ti wọ̀, a ti parí ọjọ́ tí à ń lò bọ̀, a sì ti = = bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ titun. Ní ọ̀dọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́, ni ọjọ́ kan ń parí, tí ọjọ́ titun ń bẹ̀rẹ̀ ní aago méjìlá òru. Ìyẹn kì í ṣe ìlànà ti Allāhu - Ọba tó ga jùlọ -. Síwájú sí i, tí obìnrin bá bímọ, ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìparan súná ọmọ náà. Báwo ni a ó ṣe ka ọjọ́ méje náà? Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn kan lérò pé, ọjọ́ mẹ́jọ ni ọjọ́ súná ọmọ. Èyí sì tako hadīth súná ọmọ ṣíṣe tí Samrah ọmọ Jundub - kí Allāhu yọ́nú sí i - gbà wá pé, dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ pé: كُلُّ غُلاَمٍ رَهِينَةٌ بِعَقِيقَتِهِ تُذْبَحُ عَنْهُ يَوْمَ سَابِعِهِ وَيُحْلَقُ وَيُسَمَّى. Ìtúmọ̀: “Ọmọ titun kọ̀ọ̀kan ni wọ́n ti fi ẹran ‘aƙīkọh kan dógò fún tí wọ́n máa bá a pa ní ọjọ́ keje rẹ̀ (tó dáyé). Wọ́n máa fá irun orí rẹ̀. Wọ́n sì máa fún un ní orúkọ.” (Abu Dāud) Irú ẹ̀gbàwá yìí wà nínú An-Nasā’iy, Ahmad àti Baehaƙiy. Àṣìṣe tí àwọn ọlọ́jọ́ mẹ́jọ fún súná ọmọ ṣíṣe ṣe ni pé, wọn kì í ka ọjọ́ ìbímọ mọ́ ọn. Dandan sì ni kí ọjọ́ ìbímọ jẹ́ ọjọ́ àkọ́kọ́ nínú ọjọ́ méje náà, kódà kí ọjọ́ ìbímọ ku ìṣẹ́jú kan tí a ó fi bọ́ sínú ọjọ́ titun. Bí àpẹ̀ẹrẹ, tí obìnrin kan bá bímọ ní ọ̀sán Alaadi, ní àkókò kan bíi kó ku ìṣẹ́jú díẹ̀ tí òòrùn máa wọ̀ ní ọjọ́ náà, ọjọ́ Alaadi ni ọjọ́ ìbímọ̀ rẹ̀. Ọjọ́ Sabt l’ó sì máa jẹ́ ọjọ́ keje, tí ó máa jẹ́ ọjọ́ súná ọmọ náà. Ṣebí nínú ààwẹ̀ Rọmọdọ̄n, tí obìnrin kan bá rí n̄ǹkan oṣù rẹ̀ ní àkókò kan bíi kó ku ìsẹ́jú díẹ̀ tí òòrùn máa wọ̀, ọ́ máa mú ọjọ́ yẹn kà mọ́ iye òǹkà ọjọ́ tí ó máa san padà lẹ́yìn oṣù Rọmọdọ̄n. Nítorí náà, ọjọ́ keje súná ọmọ kò gbọ́dọ̀ di ọjọ́ kẹjọ mọ́ wa lọ́wọ́. Bákan náà, àdádáálẹ́ ni ṣíṣe ìjókòó aláàfáà fún súná ọmọ ṣíṣe. Súná ọmọ ṣíṣe kò tayọ bí ó ṣe wà nínú hadīth yẹn. Àti pé dandan ni fún òbí láti fá irun orí ọmọ titun náà ní ọjọ́ keje, yálà ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin. Ọmọ kó gbọ́dọ̀ di dàda nítorí pé, irun ọ̀bùn àti irun ẹbọ ni irun dàda. (38) Àti pé òòrùn yóò máa rìn lọ sí àyè rẹ̀. Ìyẹn ni ètò (ti) Alágbára, Onímọ̀. (39) Òṣùpá náà, A ti ṣe òdíwọ̀n àwọn ibùsọ̀ fún un (tí ó ti ma máa tóbi sí i) títí ó máa fi padà dà bíi àran ọ̀pẹ tó ti pẹ́ (gbígbẹ). (40) Kò yẹ fún òòrùn láti lo àsìkò òṣùpá. Kò sì yẹ fún alẹ́ láti lo àsìkò ọ̀sán. Ìkọ̀ọ̀kan wà ní òpópónà róbótó tó ń tọ̀. (41) Àmì kan tún ni fún wọn pé, dájúdájú Àwa gbé àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn gun ọkọ̀ ojú-omi tó kún kẹ́kẹ́. (42) A tún ṣẹ̀dá (òmíràn) fún wọn nínú irú rẹ̀ tí wọn yóò máa gún.¹ 1. Ìyẹn ni pé n̄ǹkan ìgùn tí Allāhu dá fún wa, kò mọ ní ẹyọ kan. Àwọn n̄ǹkan ìgùn mìíràn tún wà bí àwọn ẹṣin, ràkúnmí, ìbaaka, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ọkọ̀ inú òfurufú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (43) Tí A bá fẹ́ Àwa ìbá tẹ̀ wọ́n rì sínú omi. Kò níí sí olùrànlọ́wọ́ kan fún wọn. Wọn kò sì níí gbà wọ́n là. (44) Àfi (kí Á fi) ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa (yọ wọ́n jáde, kí A sì tún fún wọn ní) ìgbádùn ayé títí di ìgbà díẹ̀. (45) (Wọ́n máa gbúnrí) nígbà tí A bá sọ fún wọn pé: “Ẹ ṣọ́ra fún ohun tó wà níwájú yín¹ àti ohun tó wà lẹ́yìn yín² nítorí kí A lè kẹ yín.” 1. “Ẹ ṣọ́ra fún ohun tó wà níwájú yín”; ohun tí ó wà níwájú wọn ni àwọn àpẹ̀ẹrẹ irú ìyà àti ìparun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí wọ́n pé ọ̀rọ̀ Allahu - Ọba Òdodo - ní irọ́ ṣíwájú wọn. 2. “àti ohun tó wà lẹ́yìn yín”; ohun tí ó wà lẹ́yìn wọn ni ìyà ọjọ́ Àjíǹde, ìyà Iná tí ó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí wọ́n pé ọ̀rọ̀ Allahu - Ọba Òdodo - ní irọ́. (46) Àti pé āyah kan nínú àwọn āyah Olúwa wọn kò níí wá bá wọn àfi kí wọ́n máa gbúnrí kúrò níbẹ̀. (47) Nígbà tí A bá sì sọ fún wọn pé: “Ẹ ná nínú ohun tí Allāhu ṣe ní arísìkí fún yín.”, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò wí fún àwọn tó gbàgbọ́ pé: “Ṣé kí á bọ́ ẹni tí (ó jẹ́ pé) Allāhu ìbá fẹ́ ìbá bọ́ ọ (àmọ́ kò bọ́ ọ. Àwa náà kò sì níí bá A bọ́ ọ)?” Kí ni ẹ̀yin bí kò ṣe pé (ẹ wà) nínú ìṣìnà pọ́nńbélé. (48) Wọ́n ń wí pé: “Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?” (49) Wọn kò retí kiní kan bí kò ṣe igbe ẹyọ kan ṣoṣo tí ó máa gbá wọn mú nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àríyànjiyàn lọ́wọ́. (50) Nígbà náà, wọn kò níí lè sọ àsọọ́lẹ̀ kan. Wọn kò sì níí lè padà sí ọ̀dọ̀ ará ilé wọn.
|
| | | أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 36 - Suuratu Yaasiin الأحد 23 يوليو 2023, 6:22 pm | |
| (51) Wọ́n á sì fọn fèrè oníwo fún àjíǹde, nígbà náà ni wọn yóò máa sáré jáde láti inú sàréè wá sí ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. (52) Wọ́n á wí pé: “Ègbé wa ò! Ta ni ó ta wá jí láti ojú oorun wa?” Èyí ni n̄ǹkan tí Àjọkẹ́-ayé ṣe ní àdéhùn. Àwọn Òjíṣẹ́ sì ti sọ òdodo (nípa rẹ̀). (53) Kò jẹ́ kiní kan tayọ igbe ẹyọ kan ṣoṣo. Nígbà náà ni (àwọn mọlāika) yóò kó gbogbo wọn wá sí ọ̀dọ̀ Wa. (54) Nítorí náà, ní òní wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹ̀mí kan. A kò sì níí san yín ní ẹ̀san àfi ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. (55) Dájúdájú ní òní, àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra yóò kún fún ìgbádùn. (56) Àwọn àti àwọn ìyàwó wọn yóò wà lábẹ́ àwọn ibòji, wọn yó sì rọ̀gbọ̀kú sórí àwọn ibùsùn. (57) Èso wà nínú rẹ̀ fún wọn. Ohun tí wọ́n yóò máa bèèrè fún tún wà fún wọn pẹ̀lú. (58) Àlàáfíà ni ọ̀rọ̀ tí ó má máa wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa, Àṣàkẹ́-ọ̀run. (59) Ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ bọ́ sí ọ̀tọ̀ ní òní. (60) Ẹ̀yin ọmọ (Ànábì) Ādam, ṣe Èmi kò ti pa yín ní àṣẹ pé, ẹ kò gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún Èṣù? Dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fún yín. (61) Àti pé kí ẹ jọ́sìn fún Mi. Èyí ni ọ̀nà tààrà. (62) Àti pé (Èṣù) kúkú ti ṣi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ẹ̀dá lọ́nà nínú yín. Ṣé ẹ kò níí ṣe làákàyè ni? (63) Èyí ni iná Jahanamọ tí À ń ṣe ní àdéhùn fún yín. (64) Ẹ wọ inú rẹ̀ ní òní nítorí pé, ẹ̀yin jẹ́ aláìgbàgbọ́. (65) Ní òní, A máa di ẹnu wọn pa. Àwọn ọwọ́ wọn yó sì máa bá Wa sọ̀rọ̀. Àwọn ẹsẹ̀ wọn yó sì máa jẹ́rìí sí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́. (66) Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, Àwa ìbá fọ́ wọn lójú, wọn ìbá sì yára wá si ojú ọ̀nà, báwo ni wọ́n ṣe máa ríran ná? (67) Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, Àwa ìbá yí wọn padà sí ẹ̀dá mìíràn nínú ibùgbé wọn. Wọn kò sì níí lágbára láti lọ síwájú. Wọn kò sì níí padà sẹ́yìn. (68) Ẹnikẹ́ni tí A bá fún ní ẹ̀mí gígùn lò, A óò sọ ẹ̀dá rẹ̀ di ọ̀lẹ, ṣé wọn kò níí ṣe làákàyè ni! (69) A kò kọ́ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ní ewì. Kò yẹ ẹ́ (kò sì rọ̀ ọ́ lọ́rùn láti kéwì). Kí ni ohun (tí A fi ránṣẹ́ sí i) bí kò ṣe ìrántí àti al-Ƙur’ān pọ́nńbélé (70) nítorí kí ó lè ṣèkìlọ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ alààyè àti nítorí kí ọ̀rọ̀ náà lè kò lórí àwọn aláìgbàgbọ́. (71) Ṣé wọn kò wòye pé dájúdájú Àwa l’A ṣẹ̀dá nínú ohun tí A fi ọwọ́ Wa ṣe (tí ó jẹ́) àwọn ẹran-ọ̀sìn fún wọn? Wọ́n sì ní ìkápá lórí wọn. (72) A tẹ̀ wọ́n lórí ba fún wọn; wọ́n ń gùn nínú wọn, wọ́n sì ń jẹ nínú wọn. (73) Àwọn àǹfààní àti ohun mímu tún wà fún wọn nínú rẹ̀. Ṣé wọn kò níí dúpẹ́ ni? (74) Wọ́n sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu nítorí kí wọ́n lè ṣàrànṣe fún wọn! (75) Wọn kò sì lè ṣe àrànṣe fún wọn; ṣebí àwọn òrìṣà ni ọmọ ogun tí (àwọn mọlāika) máa kó wá sínú Iná fún àwọn abọ̀rìṣà (láti fi jẹ wọ́n níyà).¹ 1. Ẹ wo sūrah Mọryam; 19:82 àti sūrah al-’Anbiyā’; 21:98.
|
| | | أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 36 - Suuratu Yaasiin الأحد 23 يوليو 2023, 6:23 pm | |
| (76) Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn bà ọ́ nínú jẹ́. Dájúdájú Àwa mọ ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣàfi hàn rẹ̀. (77) Ṣé ènìyàn kò wòye pé dájúdájú Àwa l’A ṣẹ̀dá rẹ̀ láti inú àtọ̀? (Ṣebí lẹ́yìn) ìgbà náà l’ó di alátakò pọ́nńbélé. (78) Àti pé ó fi àkàwé lélẹ̀ nípa Wa.¹ Ó sì gbàgbé ìṣẹ̀dá rẹ̀. Ó wí pé: “Ta ni Ó máa sọ egungun di alààyè nígbà tí ó ti kẹfun?” 1. Ìyẹn ni pé, ènìyàn ń fi agbára ẹ̀dá tí kò lè jí òkú dìde wé agbára Allāhu tí ó lè jí òkú dìde. (79) Sọ pé: “Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ nígbà àkọ́kọ́ l’Ó máa sọ ọ́ di alààyè. Òun sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo ẹ̀dá. (80) (Òun ni) Ẹni tí Ó mú iná jáde fún yín láti ara igi tútù. Ẹ sì ń fi dáná. (81) Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò ní agbára láti dá irú wọn (mìíràn) bí? Bẹ́ẹ̀ ni (Ó ní agbára). Òun sì ni Ẹlẹ́dàá, Onímọ̀. (82) Àṣẹ Rẹ̀ nígbà tí Ó bá gbèrò kiní kan ni pé, Ó máa sọ fún un pé “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀. (83) Nítorí náà, mímọ́ ni fún Ẹni tí ìjọba gbogbo n̄ǹkan wà ní ọwọ́ Rẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí.
|
| | | | 36 - Suuratu Yaasiin | |
|
مواضيع مماثلة | |
|
| صلاحيات هذا المنتدى: | لاتستطيع الرد على المواضيع في هذا المنتدى
| |
| |
| |