|
| 34 - Suuratu Saba' | |
| | كاتب الموضوع | رسالة |
---|
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: 34 - Suuratu Saba' السبت 22 يوليو 2023, 8:00 am | |
| 34 - Suuratu Saba' Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run. (1) Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ń jẹ́ tiRẹ̀. Àti pé tiRẹ̀ ni gbogbo ẹyìn ní ọ̀run. Òun sì ni Ọlọ́gbọ́n, Alámọ̀tán. (2) Ó mọ ohunkóhun tó ń wọnú ilẹ̀ àti ohunkóhun tó ń jáde látinú rẹ̀. (Ó mọ) ohunkóhun tó ń sọ̀kalẹ̀ látinú sánmọ̀ àti ohunkóhun tó ń gùnkè lọ sínú rẹ̀. Òun sì ni Àṣàkẹ́-ọ̀run, Aláforíjìn. (3) Àwọn aláìgbàgbọ́ wí pé: “Àkókò náà kò níí dé bá wa.” Sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Èmi fi Olúwa mi búra. Dájúdájú ó máa dé ba yín (láti ọ̀dọ̀) Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ (Ẹni tí) òdiwọ̀n ọmọ iná-igún kò pamọ́ fún nínú àwọn sánmọ̀ àti nínú ilẹ̀. (Kò sí n̄ǹkan tí ó) kéré sí ìyẹn tàbí tí ó tóbi (jù ú lọ) àfi kí ó wà nínú àkọsílẹ̀ tó yanjú.” (4) (Ó máa ṣẹlẹ̀) nítorí kí Allāhu lè san ẹ̀san fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n tún ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn ni àforíjìn àti èsè alápọ̀n-ọ́nlé ń bẹ fún. (5) Àwọn tó ṣe iṣẹ́ (burúkú) nípa àwọn āyah Wa, tí wọ́n ń dá àwọn ènìyàn ní agara (láti tẹ̀lé àwọn āyah Wa, tí wọ́n sì lérò pé àwọn máa mórí bọ́ lọ́dọ̀ Allāhu); àwọn wọ̀nyẹn, ìyà kan nínú ìyà ẹlẹ́ta-eléró ń bẹ fún wọn. (6) Àwọn tí A fún ní ìmọ̀ mọ̀ pé, èyí tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, òhun ni òdodo, àti pé ó ń ṣe ìtọ́sọ́nà sí ọ̀nà Alágbára, Ẹlẹ́yìn. (7) Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “Ṣé kí á tọ́ka yín sí ọkùnrin kan tí ó máa fún yín ní ìró pé nígbà tí wọ́n bá tú (ara) yín ká tán pátápátá (sínú erùpẹ̀, tí ẹ ti di erùpẹ̀), pé dájúdájú ẹ máa padà wà ní ẹ̀dá titun? (8) Ṣé ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu ni tàbí àlùjànnú ń bẹ lára rẹ̀ ni?” Rárá o! Àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́ ti wà nínú ìyà àti ìṣìnà tó jìnnà. (9) Ṣé wọn kò rí ohun tó ń bẹ níwájú wọn àti ohun tó ń bẹ lẹ́yìn wọn ní sánmọ̀ àti ilẹ̀? Tí A bá fẹ́, Àwa ìbá jẹ́ kí ilẹ̀ ri mọ́ wọn lẹ́sẹ̀, tàbí kí Á já apá kan nínú sánmọ̀ lulẹ̀ lé wọn lórí mọ́lẹ̀. Dájúdájú àmì kan wà nínú ìyẹn fún gbogbo ẹrúsìn, olùronúpìwàdà. (10) Dájúdájú A ti fún (Ànábì) Dāwūd ní oore àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Wa; Ẹ̀yin àpáta, ẹ ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú rẹ̀. (A pe) àwọn ẹyẹ náà (pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.) A sì rọ irin fún un. (11) (A sọ fún un) pé, ṣe àwọn ẹ̀wù irin tó máa bo ara dáadáa, ṣe òrùka fún ẹ̀wù irin náà níwọ̀n-níwọ̀n. Kí ẹ sì ṣe rere. Dájúdájú Èmi ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. (12) Àti pé (A tẹ) atẹ́gùn lórí bá fún (Ànábì) Sulaemọ̄n, ìrìn oṣù kan ni ìrìn òwúrọ̀ rẹ̀, ìrìn oṣù kan sì ni ìrìn ìrọ̀lẹ́ rẹ̀¹. A sì mú kí odò idẹ máa ṣàn nínú ilẹ̀ fún un. Ó sì wà nínú àwọn àlùjànnú, èyí tó ń ṣiṣẹ́ (fún un) níwájú rẹ̀ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Olúwa rẹ̀. Àti pé ẹni tí ó bá yẹ̀ kúrò níbi àṣẹ Wa nínú wọn, A máa fún un ní ìyà iná tó ń jó tọ́ wò. 1. Èyí já sí pé Ànábì Sulaemọ̄n - kí ọlà Allāhu máa bá a - ń rin ìrìn oṣù méjì ní ojúmọ́ bí ó bá fẹ́ rìn jáde pẹ̀lú atẹ́gùn. (13) Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ tí ó bá fẹ́ fún un nípa mímọ àwọn ilé (ilé ìjọ́sìn àti ilé ìgbé), àwọn ère,¹ àwọn àwo tó jìn kòtò tó fẹ̀ bí àbàtಠàti àwọn ìkòkò tó rídìí múlẹ̀.³ Ẹ̀yin ènìyàn (Ànábì) Dāwūd, ẹ ṣiṣẹ́ ìdúpẹ́ (fún Allāhu). Díẹ̀ nínú àwọn ẹrúsìn Mi sì ni olùdúpẹ́. 1. Ní àsìkò Ànábì Sulaemọ̄n - kí ọlà Allāhu máa bá a -, gbígbẹ́ ère fún fífi ṣe ọ̀ṣọ́ sínú ilé kì í ṣe èèwọ̀. Àmọ́ ní àsìkò Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ó ti di èèwọ̀, yálà ó jẹ́ ère tàbí àwòrán n̄ǹkan abẹ̀mí. Nínú hadīth Abu Tọlhah - kí Allāhu yọ́nú sí i -, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ pé, “Mọlāika (oníkẹ̀ẹ́) kò níí wọ inú ilé tí ajá àti àwòrán ère bá wà nínú rẹ̀.” Bukọ̄riy àti Muslim 2. Àpẹ̀ẹrẹ ìyẹn ni àwọn àwo tí àwọn ènìyàn máa ń ṣe sínú ilé ìwẹ̀ tí ènìyàn máa ń wẹ̀ nínú rẹ̀ “bath tub”. 3. Àpẹ̀ẹrẹ ìyẹn ni àwọn apẹ irin ìdáná ńlá ńlá. (14) Nígbà tí A pàṣẹ pé kí ikú pa (Ànábì) Sulaemọ̄n, kò sí ohun tí ó mú àwọn àlùjànnú mọ̀ pé ó ti kú bí kò ṣe kòkòrò inú ilẹ̀ kan tí ó jẹ ọ̀pá rẹ̀. Nígbà tí ó wó lulẹ̀, ó hàn kedere sí àwọn àlùjànnú pé tí ó bá jẹ́ pé àwọn ní ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ ni, àwọn ìbá tí wà nínú (iṣẹ́) ìyà tó ń yẹpẹrẹ ẹ̀dá. (15) Dájúdájú àmì kan wà fún àwọn Saba’ nínú ibùgbé wọn; (òhun ni) ọgbà oko méjì tó wà ní ọ̀tún àti ní òsì.¹ “Ẹ jẹ nínú arísìkí Olúwa yín. Kí ẹ sì dúpẹ́ fún Un.” Ìlú tó dára ni (ilẹ̀ àwọn Saba’. Allāhu sì ni) Olúwa Aláforíjìn. 1. Ìyẹn ni pé, ìlú wọn wà ní ààrin, ọgbà oko sì yí wọn po. (16) Wọ́n gbúnrí (níbi ẹ̀sìn). Nítorí náà, A rán adágún odò tí wọ́n mọ odi yíká sí wọn. A sì pààrọ̀ oko wọn méjèèjì fún wọn pẹ̀lú oko èso méjì mìíràn tí ó jẹ́ oko èso tó korò, oko igi àti kiní kan nínú igi sidir díẹ̀.¹ 1. Oríṣi igi sidr méjì ló wà. Igi sidr kan wà tí wọ́n ń jẹ èso rẹ̀, tí wọ́n ń fi ewé rẹ̀ wẹ̀. Èyí ni “nabƙ”. Igi sidr kejì ni èyí tí kò ní èso, tí wọn kì í fi ewé rẹ̀ wẹ̀. Èyí ni “dọ̄ll”. Òhun sì ni wọ́n gbàlérò nínú āyah yìí. (17) Ìyẹn ni A fi san wọ́n ní ẹ̀san nítorí pé, wọ́n ṣàì moore. Ǹjẹ́ A máa san ẹnì kan lẹ́san ìyà bí kò ṣe aláìmoore? (18) A sì fi àwọn ìlú kan tó wà ní gban̄gba sí ààrin ìlú tí A rán adágún odò sí¹ àti àwọn ìlú tí A fi ìbùkún sí. A sì ṣètò ibùsọ̀ níwọ̀n-níwọ̀n fún ìrìn-àjò ṣíṣe sínú àwọn ìlú náà.² Ẹ rìn lọ sínú wọn ní òru àti ní ojú ọjọ́ pẹ̀lú ìfàyàbalẹ̀. 1. Ìyẹn àwọn Saba’ ní ilẹ̀ Yamọn. 2. Èyí ni pé, tí onírìn-àjò bá gbéra, ó máa kan àwọn ìlú lójú-ọ̀nà. Ó sì máa ríbi sinmi láti ìlú kan sí ìlú mìíràn láààrin àwọn ìlú tí ó wà láààrin ilẹ̀ Saba’ àti ìlú tí Allāhu fi ìbùkún sí, ìyẹn ilẹ̀ Ṣām. (19) (Àwọn ará ìlú Saba’) wí pé: “Olúwa wa, mú àwọn ìrìn-àjò wa láti ìlú kan sí ìlú mìíràn jìnnà síra wọn.” Wọ́n ṣe àbòsí sí ẹ̀mí ara wọn.¹ A sì sọ wọ́n di ìtàn. A tú wọn ká pátápátá (ìlú wọn di ahoro). Dájúdájú àwọn àmì kan wà nínú ìyẹn fún gbogbo onísùúrù, olùdúpẹ́. 1. Ọ̀kan nínú oore tí Allāhu - Ọba Olóore - ṣe fún àwọn ará Saba’ ni pé, Ó fi àwọn ìlú tó já mọ́ra wọn yí wọn ká. Wọ́n sì ń rí oore púpọ̀ láti ara àwọn onírìn-àjò tó ń gba ìlú wọn kọjá. Àmọ́ wọn kò mọ ìwọ̀nyí sí oore. Wọ́n jọra wọn lójú, wọ́n sì tọrọ pé kí Allāhu taari àwọn ìlú náà kúrò nítòsí àwọn. Allāhu sì taari àwọn fúnra wọn dànù. Allāhu fi adágún odò tú ìlú wọn ká. Wọ́n sì fọ́nká káàkiri ayé. (20) Dájúdájú ’Iblīs ti sọ àbá-modá rẹ̀ di òdodo lórí wọn. Wọ́n sì tẹ̀lé e àfi igun kan nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo. (21) (’Iblīs) kò sì ní agbára kan lórí wọn bí kò ṣe pé kí A lè ṣàfi hàn ẹni tó gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́ kúrò lára ẹni tó wà nínú iyèméjì nípa rẹ̀. Olùṣọ́ sì ni Olúwa rẹ lórí gbogbo n̄ǹkan. (22) Sọ pé: “Ẹ pe àwọn tí ẹ sọ pé (wọ́n jẹ́ ọlọ́hun) lẹ́yìn Allāhu.” Wọn kò ní ìkápá òdiwọ̀n ọmọ-iná igún nínú àwọn sánmọ̀ tàbí nínú ilẹ̀. Wọn kò sì ní ìpín kan nínú méjèèjì. Àti pé kò sí olùrànlọ́wọ́ kan fún Allāhu láààrin wọn. (23) Ìṣìpẹ̀ kò sì níí ṣàǹfààní lọ́dọ̀ Allāhu àfi fún ẹni tí Ó bá yọ̀ǹda fún. (Inúfu-àyàfu ní àwọn olùṣìpẹ̀ àti àwọn olùṣìpẹ̀-fún máa wà) títí A óò fi yọ ìjáyà kúrò nínú ọkàn wọn. Wọ́n sì máa sọ (fún àwọn mọlāika) pé: “Kí ni Olúwa yín sọ (ní èsì ìṣìpẹ̀)?” Wọ́n máa sọ pé: “Òdodo l’Ó sọ (ìṣìpẹ̀ yin ti wọlé. Allāhu) Òun l’Ó ga, Ó tóbi.¹ 1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:48. (24) Sọ pé: “Ta ni Ó ń pèsè fún yín láti inú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?” Sọ pé: “Allāhu ni.” Dájúdájú àwa tàbí ẹ̀yin wà nínú ìmọ̀nà tàbí nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.¹ 1. Àwọn nasọ̄rọ̄ lérò pé Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ń ṣeyèméjì nípa ẹ̀sìn rẹ̀ ni gbólóhùn yẹn fi parí āyah yẹn. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:74. (25) Sọ pé: “Wọn kò níí bi yín léèrè nípa ẹ̀ṣẹ̀ tí a dá; wọn kò sì níí bi àwa náà nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.” |
| | | أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 34 - Suuratu Saba' السبت 22 يوليو 2023, 8:01 am | |
| (26) Sọ pé: “Olúwa wa yóò kó wa jọ papọ̀. Lẹ́yìn náà, Ó máa fi òdodo ṣèdájọ́ láààrin wa. Òun sì ni Onídàájọ́, Onímọ̀.” (27) Sọ pé: “Ẹ fi hàn mí ná àwọn òrìṣà tí ẹ dàpọ̀ mọ́ Allāhu.” Rárá (kò ní akẹgbẹ́). Rárá sẹ́, Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n. (28) A kò rán ọ níṣẹ́ àfi sí gbogbo ènìyàn pátápátá; (o jẹ́) oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀ ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀. (29) Wọ́n ń wí pé: “Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?” (30) Sọ pé: “Àdéhùn ọjọ́ kan ń bẹ fún yín, tí ẹ kò níí lè sún un ṣíwájú di àkókò kan, ẹ kò sì níí lè fà á sẹ́yìn.”¹ 1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Al-’a‘rọ̄f; 7:34. (31) Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “A kò níí ní ìgbàgbọ́ nínú al-Ƙur’ān yìí àti èyí tó wá ṣíwájú rẹ̀.” Tí ó bá jẹ́ pé o bá rí wọn ni nígbà tí wọ́n bá dá àwọn alábòsí dúró níwájú Olúwa wọn, (o máa rí wọn tí) apá kan wọn yóò dá ọ̀rọ̀ náà padà sí apá kan; àwọn tí wọ́n sọ di ọ̀lẹ (nínú wọn) yóò wí fún àwọn tó ṣègbéraga (nínú wọn) pé: “Tí kì í bá ṣe ẹ̀yin ni, àwa ìbá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.” (32) Àwọn tó ṣègbéraga yó sì wí fún àwọn tí wọ́n sọ di ọ̀lẹ pé: “Ṣé àwa l’a ṣẹ yín lórí kúrò nínú ìmọ̀nà lẹ́yìn tí ó dé ba yín? Rárá o! Ọ̀daràn ni yín ni.” (33) Àwọn tí wọ́n sọ di ọ̀lẹ yó sì wí fún àwọn tó ṣègbéraga pé: “Rárá! Ète òru àti ọ̀sán (láti ọ̀dọ̀ yín ló kóbá wa) nígbà tí ẹ̀ ń pa wá ní àṣẹ pé kí á ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu, kí á sì sọ (àwọn kan) di ẹgbẹ́ Rẹ̀.” Wọ́n fi àbámọ̀ wọn pamọ́ nígbà tí wọ́n rí ìyà. A sì kó ẹ̀wọ̀n sí ọrùn àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Ṣé A óò san wọ́n ní ẹ̀san kan bí kò ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́? (34) Àti pé A kò rán olùkìlọ̀ kan sí ìlú kan àyàfi kí àwọn onígbẹdẹmukẹ ìlú náà wí pé: “Dájúdájú àwa ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n fi ran yín níṣẹ́.” (35) Wọ́n tún wí pé: “Àwa ní dúkìá àti ọmọ jù (yín lọ); wọn kò sì níí jẹ wá níyà.” (36) Sọ pé: “Dájúdájú Olúwa mi, Ó ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn), ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀. (37) Kì í ṣe àwọn dúkìá yín, kì í sì ṣe àwọn ọmọ yín ni n̄ǹkan tí ó máa mu yín súnmọ́ Wa pẹ́kípẹ́kí àfi ẹni tí ó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn ni ẹ̀san ìlọ́po wà fún nípa ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Wọn yó sì wà nínú àwọn ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì gíga (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra) lẹ́ni ìfàyàbalẹ̀. (38) Àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ (burúkú) nípa àwọn āyah Wa, tí wọ́n ń dá àwọn ènìyàn ní agara (láti tẹ̀lé àwọn āyah Wa, tí wọ́n sì lérò pé àwọn máa mórí bọ́ lọ́dọ̀ Allāhu); àwọn wọ̀nyẹn ni (àwọn mọlāika) máa kó wá sínú Iná.” (39) Sọ pé: “Dájúdájú Olúwa mi, Ó ń tẹ́ arísìkí¹ sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ fún ẹlòmíìràn. Àti pé ohunkóhun tí ẹ bá ná, Òun l’Ó máa fi (òmíràn) rọ́pò rẹ̀. Ó sì l’óore jùlọ nínú àwọn olùpèsè.”² 1. Arísìkí ni ìjẹ-ìmu, n̄ǹkan ìgbádùn àti àwọn dúkìá mìíràn. 2. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:125. (40) Ní ọjọ́ tí Allāhu yóò kó gbogbo wọn jọ pátápátá, lẹ́yìn náà Ó máa sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ṣé ẹ̀yin ni wọ́n ń jọ́sìn fún?” (41) Wọ́n á sọ pé: “Mímọ́ ni fún Ọ! Ìwọ ni Aláàbò wa, kì í ṣe àwọn. Rárá (wọn kò jọ́sìn fún wa). Àwọn àlùjànnú ni wọ́n ń jọ́sìn fún; ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni wọ́n gbàgbọ́ nínú àwọn àlùjànnú. (42) Nítorí náà, ní òní apá kan yín kò ní ìkápá àǹfààní, kò sì ní ìkápá ìnira fún apá kan. A sì máa sọ fún àwọn tó ṣàbòsí pé: “Ẹ tọ́ ìyà Iná tí ẹ̀ ń pè ní irọ́ wò.” (43) Àti pé nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa tó yanjú fún wọn, wọ́n á wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe ọkùnrin kan tí ó fẹ́ ṣẹ yín lórí kúrò níbi n̄ǹkan tí àwọn bàbá yín ń jọ́sìn fún.” Wọ́n tún wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe àdápa irọ́.” Àti pé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí nípa òdodo nígbà tí ó dé bá wọn pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.” (44) A kò fún wọn ní àwọn tírà kan kan tí wọ́n ń kọ́ ẹ̀kọ́ nínú rẹ̀, A kò sì rán olùkìlọ̀ kan sí wọn ṣíwájú rẹ.¹ 1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Ƙọsọs; 28:46. (45) Àwọn tó ṣíwájú wọn náà pe òdodo ní irọ́. (Ọwọ́ àwọn wọ̀nyí) kò sì tí ì tẹ ìdá kan ìdá mẹ́wàá nínú ohun tí A fún (àwọn tó ṣíwájú). Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n pe àwọn Òjíṣẹ́ Mi ní òpùrọ́. Báwo sì ni bí Mo ṣe (fi ìyà) kọ (aburú fún wọn) ti rí! (46) Sọ pé: “Ohun kan ṣoṣo ni mò ń ṣe wáàsí rẹ̀ fún yín pé, ẹ dúró nítorí ti Allāhu ní méjì àti ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, kí ẹ ronú jinlẹ̀. Kò sí àlùjànnú kan lára ẹni yín. Kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀ fún yín ṣíwájú ìyà líle kan.” (47) Sọ pé: “Èmi kò bi yín léèrè owó-ọ̀yà kan, ẹ̀yin lẹ kúkú lowó yín. Kò sí owó ọ̀yà mi (lọ́dọ̀ ẹnì kan) àfi lọ́dọ̀ Allāhu. Òun sì ni Arínú-róde gbogbo n̄ǹkan.” (48) Sọ pé: “Dájúdájú Olúwa mi, Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ l’Ó ń mú òdodo náà wá.” (49) Sọ pé: “Òdodo ti dé. Irọ́ (èṣù) kò lè mú n̄ǹkan bẹ, kò sì lè dá n̄ǹkan padà (lẹ́yìn tó ti kú).” (50) Sọ pé: “Tí mo bá ṣìnà, mo ṣìnà fún ẹ̀mí ara mi ni. Tí mo bá sì mọ̀nà, nípa ohun tí Olúwa mi fi ránṣẹ́ sì mi ní ìmísí ni. Dájúdájú Òun ni Olùgbọ́, Alásùn-únmọ́ ẹ̀dá.”¹ 1. Okùnfà āyah yìí ni pé, àwọn ọ̀ṣẹbọ ìlú Mọkkah ń sọ fún Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - pé, “Tí o bá fi lè pa ẹ̀sìn ìbọ̀rìṣà àwọn bàbá rẹ tì, o ti ṣìnà nìyẹn.” Allāhu sì sọ āyah kalẹ̀ pé, kí ó fún wọn lésì pé “Tí mo bá ṣìnà gẹ́gẹ́ bí ẹ ti sọ láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́, ìyà ìṣìnà mi kò kàn yín. Àmọ́ tí mo bá mọ̀nà nípasẹ̀ bí mo ṣe ń jọ́sìn fún Allāhu nìkan ṣoṣo, mo rí ìmọ̀nà náà nípasẹ̀ ìmísí tí Allāhu fi ránṣẹ́ sí mi ni. Kì í
|
| | | أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 34 - Suuratu Saba' السبت 22 يوليو 2023, 8:01 am | |
| ṣe àdáṣe mi.” Ƙurtubiy (51) Tí ó bá jẹ́ pé o lè rí (ẹ̀sín wọn ni) nígbà tí ẹ̀rù bá dé bá wọn (ní Ọjọ́ Àjíǹde, o máa rí i pé), kò níí sí ìmóríbọ́ kan (fún wọn). A sì máa gbá wọn mú láti àyè tó súnmọ́. (52) Wọn yóò wí pé: “A gbàgbọ́ nínú (al-Ƙur’ān báyìí).” Báwo ni ọwọ́ wọn ṣe lè tẹ ìgbàgbọ́ òdodo láti àyè tó jìnnà (ìyẹn, ọ̀run).” (53) Wọ́n kúkú ti ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ ṣíwájú (nílé ayé). Wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ nípa ìkọ̀kọ̀ láti àyè tó jìnnà (ìyẹn, ilé ayé). (54) A sì fi gàgá sí ààrin àwọn àti ohun tí wọ́n ń ṣojú kòkòrò rẹ̀¹ gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe fún àwọn ẹgbẹ́ wọn ní ìṣáájú. Dájúdájú wọ́n wà nínú iyèméjì tó gbópọn (nípa Ọjọ́ Àjíǹde). 1. Àwọn aláìgbàgbọ́ yóò máa ṣojú kòkòrò sí ìronúpìwàdà àti ìpadà sí ilé ayé ní Ọjọ́ Àjíǹde nígbà tí àìgbàgbọ́ wọn bá di ìyà ńlá fún wọn. Àmọ́ Allāhu kò níí fún wọn ní àyè láti lọ ronú pìwàdà tàbí láti padà sí ilé ayé. |
| | | | 34 - Suuratu Saba' | |
|
مواضيع مماثلة | |
|
| صلاحيات هذا المنتدى: | لاتستطيع الرد على المواضيع في هذا المنتدى
| |
| |
| |