106 - Suuratu Quraesh
Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.  
(1) (Ìkẹ́ ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu) fún ìdílé Ƙuraeṣ láti wà papọ̀ nínú ààbò.
(2) (Ìkẹ́ ni sẹ́ láti ọ̀dọ̀ Allāhu) fún wọn láti wà papọ̀ nínú ààbò lórí ìrìn-àjò ní ìgbà òtútù àti ní ìgbà ooru.
(3) Nítorí náà, kí wọ́n jọ́sìn fún Olúwa Ilé (Ka‘bah) yìí.
(4) Ẹni tí Ó fún wọn ní jíjẹ (ní àsìkò) ebi. Ó sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ nínú ìpáyà.