منتديات إنما المؤمنون إخوة (2024 - 2010) The Believers Are Brothers

(إسلامي.. ثقافي.. اجتماعي.. إعلامي.. علمي.. تاريخي.. دعوي.. تربوي.. طبي.. رياضي.. أدبي..)
 
الرئيسيةالأحداثأحدث الصورالتسجيل
(وما من كاتب إلا سيبلى ** ويبقى الدهر ما كتبت يداه) (فلا تكتب بكفك غير شيء ** يسرك في القيامة أن تراه)

IZHAR UL-HAQ

(Truth Revealed) By: Rahmatullah Kairanvi
قال الفيلسوف توماس كارليل في كتابه الأبطال عن رسول الله -صلى الله عليه وسلم-: "لقد أصبح من أكبر العار على أي فرد مُتمدين من أبناء هذا العصر؛ أن يُصْغِي إلى ما يظن من أنَّ دِينَ الإسلام كَذِبٌ، وأنَّ مُحَمَّداً -صلى الله عليه وسلم- خَدَّاعٌ مُزُوِّرٌ، وآنَ لنا أنْ نُحارب ما يُشَاعُ من مثل هذه الأقوال السَّخيفة المُخْجِلَةِ؛ فإنَّ الرِّسَالة التي أدَّاهَا ذلك الرَّسُولُ ما زالت السِّراج المُنير مُدَّةَ اثني عشر قرناً، لنحو مائتي مليون من الناس أمثالنا، خلقهم اللهُ الذي خلقنا، (وقت كتابة الفيلسوف توماس كارليل لهذا الكتاب)، إقرأ بقية كتاب الفيلسوف توماس كارليل عن سيدنا محمد -صلى الله عليه وسلم-، على هذا الرابط: محمد بن عبد الله -صلى الله عليه وسلم-.

يقول المستشرق الإسباني جان ليك في كتاب (العرب): "لا يمكن أن توصف حياة محمد بأحسن مما وصفها الله بقوله: (وَمَا أَرْسَلْنَاكَ إِلَّا رَحْمَةً لِّلْعَالَمِين) فكان محمدٌ رحمة حقيقية، وإني أصلي عليه بلهفة وشوق".
فَضَّلَ اللهُ مِصْرَ على سائر البُلدان، كما فَضَّلَ بعض الناس على بعض والأيام والليالي بعضها على بعض، والفضلُ على ضربين: في دِينٍ أو دُنْيَا، أو فيهما جميعاً، وقد فَضَّلَ اللهُ مِصْرَ وشَهِدَ لها في كتابهِ بالكَرَمِ وعِظَم المَنزلة وذَكَرَهَا باسمها وخَصَّهَا دُونَ غيرها، وكَرَّرَ ذِكْرَهَا، وأبَانَ فضلها في آياتٍ تُتْلَى من القرآن العظيم.
المهندس حسن فتحي فيلسوف العمارة ومهندس الفقراء: هو معماري مصري بارز، من مواليد مدينة الأسكندرية، وتخرَّجَ من المُهندس خانة بجامعة فؤاد الأول، اشْتُهِرَ بطرازهِ المعماري الفريد الذي استمَدَّ مَصَادِرَهُ مِنَ العِمَارَةِ الريفية النوبية المَبنية بالطوب اللبن، ومن البيوت والقصور بالقاهرة القديمة في العصرين المملوكي والعُثماني.
رُبَّ ضَارَّةٍ نَافِعَةٍ.. فوائدُ فيروس كورونا غير المتوقعة للبشرية أنَّه لم يكن يَخطرُ على بال أحَدِنَا منذ أن ظهر وباء فيروس كورونا المُستجد، أنْ يكونَ لهذه الجائحة فوائدُ وإيجابيات ملموسة أفادَت كوكب الأرض.. فكيف حدث ذلك؟!...
تخليص الإبريز في تلخيص باريز: هو الكتاب الذي ألّفَهُ الشيخ "رفاعة رافع الطهطاوي" رائد التنوير في العصر الحديث كما يُلَقَّب، ويُمَثِّلُ هذا الكتاب علامة بارزة من علامات التاريخ الثقافي المصري والعربي الحديث.
الشيخ علي الجرجاوي (رحمه الله) قَامَ برحلةٍ إلى اليابان العام 1906م لحُضُورِ مؤتمر الأديان بطوكيو، الذي دعا إليه الإمبراطور الياباني عُلَمَاءَ الأديان لعرض عقائد دينهم على الشعب الياباني، وقد أنفق على رحلته الشَّاقَّةِ من مَالِهِ الخاص، وكان رُكُوبُ البحر وسيلته؛ مِمَّا أتَاحَ لَهُ مُشَاهَدَةَ العَدِيدِ مِنَ المُدُنِ السَّاحِلِيَّةِ في أنحاء العالم، ويُعَدُّ أوَّلَ دَاعِيَةٍ للإسلام في بلاد اليابان في العصر الحديث.

أحْـلامٌ مِـنْ أبِـي (باراك أوباما) ***

 

 12 - Suuratu Yuusuf

اذهب الى الأسفل 
كاتب الموضوعرسالة
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn
مؤسس ومدير المنتدى
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn


عدد المساهمات : 52644
العمر : 72

12 - Suuratu Yuusuf  Empty
مُساهمةموضوع: 12 - Suuratu Yuusuf    12 - Suuratu Yuusuf  Emptyالجمعة 21 يوليو 2023, 11:10 pm

12 - Suuratu Yuusuf
Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
(1) ’Alif lām rọ̄. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)¹ Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà tó yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.
(2) Dájúdájú Àwa sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ní n̄ǹkan kíké ní èdè Lárúbáwá nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.
(3) Àwa ń sọ ìtàn tó dára jùlọ fún ọ pẹ̀lú ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ (nínú ìmísí) al-Ƙur’ān yìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíwájú ìmísí náà ìwọ wà lára àwọn tí kò nímọ̀ (nípa rẹ̀).
(4) (Rántí) nígbà tí (Ànábì) Yūsuf sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Bàbá mi, dájúdájú èmi (lálàá) rí àwọn ìràwọ̀ mọ́kànlá, òòrùn àti òṣùpá. Mo rí wọn tí wọ́n forí kanlẹ̀ fún mi.”
(5) Ó sọ pé: “Ọmọ mi, má ṣe rọ́ àlá rẹ fún àwọn ọbàkan rẹ kí wọ́n má baà déte sí ọ. Dájúdájú Èṣù ni ọ̀tá pọ́nńbélé fún ènìyàn.
(6) Báyẹn ni Olúwa rẹ yóò ṣe ṣà ọ́ lẹ́ṣà. Ó máa fi ìtúmọ̀ àlá mọ̀ ọ́. Ó sì máa pé ìdẹ̀ra Rẹ̀ fún ìwọ àti àwọn ẹbí Ya‘ƙūb, gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe pé e ṣíwájú fún àwọn bàbá rẹ méjèèjì, (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti ’Ishāƙ. Dájúdájú Olúwa rẹ ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.”
(7) Dájúdájú àwọn àmì (àríwòye) ń bẹ fún àwọn oníbèéèrè nípa (ìtàn Ànábì) Yūsuf àti àwọn ọbàkan rẹ̀.
(8) (Rántí) nígbà tí wọ́n sọ pé: “Dájúdájú Yūsuf àti ọmọ-ìyá rẹ̀ ni bàbá wa nífẹ̀ẹ́ sí ju àwa. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ni àwa. Dájúdájú bàbá wa mà ti wà nínú àṣìṣe pọ́nńbélé.
(9) Ẹ pa Yūsuf tàbí kí ẹ lọ gbé e jùnù sí ilẹ̀ kan nítorí kí bàbá yín lè rójú gbọ́ tiyín. Ẹ sì máa di ènìyàn rere lẹ́yìn rẹ̀.”
(10) Òǹsọ̀rọ̀ kan nínú wọn sọ pé: “Ẹ má ṣe pa Yūsuf. Tí ó bá jẹ́ pé ẹ ṣá fẹ́ wá n̄ǹkan ṣe (sí ọ̀rọ̀ rẹ̀), ẹ gbé e jù sínú ìsàlẹ̀ẹ̀sàlẹ̀ kànǹga nítorí kí apá kan nínú àwọn onírìn-àjò lè he é lọ.”
(11) Wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, kí ni kò mú ọ fi ọkàn tán wa lórí Yūsuf. Dájúdájú àwa yóò máa tọ́jú rẹ̀ dáadáa.
(12) Jẹ́ kí ó bá wa lọ ní ọ̀la kí ó lè dára yá, kí ó sì lè ṣeré. Àti pé dájúdájú àwa yóò máa ṣọ́ ọ.”
(13) Ó sọ pé: “Dájúdájú ó máa bà mí nínú jẹ́ pé kí ẹ mú u lọ. Mo sì ń páyà kí ìkokò má lọ pa á jẹ nígbà tí ẹ̀yin bá gbàgbé rẹ̀ (síbì kan).”
(14) Wọ́n sọ pé: “Tí ìkokò bá fi pa á jẹ, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ni wá, dájúdájú àwa nígbà náà ni ẹni òfò.”
(15) Nígbà tí wọ́n mú un lọ tán, wọ́n panupọ̀ pé kí àwọn jù ú sí ìsàlẹ̀ẹ̀sàlẹ̀ kànǹga. À si fí ìmísí ránṣẹ́ sí Yūsuf (níbẹ̀) pé: “Dájúdájú ìwọ yóò fún wọn ní ìró nípa ọ̀rọ̀ wọn yìí nígbà tí wọn kò níí fura.”
(16) Wọ́n dé bá bàbá wọn ní àṣálẹ́, tí wọ́n ń sunkún.
(17) Wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, àwa lọ díje eré sísá. A sì fi Yūsuf sílẹ̀ síbi àwọn ẹrù wa. Nígbà náà ni ìkokò pa á jẹ. Ìwọ kò sì níí gbà wá gbọ́, àwa ìbáà jẹ́ olódodo.”
(18) Wọ́n dé pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ irọ́ lára ẹ̀wù rẹ̀. (Ànábì Ya‘ƙūb) sọ pé: “Rárá o, ẹ̀mí yín ló ṣe ọ̀ràn kan lọ́ṣọ̀ọ́ fún yín. Nítorí náà, sùúrù abiyì (lọ̀rọ̀ mi kàn). Allāhu sì ni Ẹni tí à ń wá àánú Rẹ̀ lórí ohun tí ẹ̀ ń ròyìn (yìí).”
(19) Àwọn onírìn-àjò kan sì dé. Wọ́n rán apọnmi wọn (ní omi). Ó sì ju doro rẹ̀ sínú kànǹga. (Yūsuf sì dìrọ̀ mọ́ okùn doro bọ́ síta. Apọnmi sì) sọ pé: “Ire ìdùnnú rè é! Èyí ni ọmọdékùnrin.” Wọ́n sì fi pamọ́ fún títà (bí ọjà). Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
(20) Wọ́n tà á ní ẹ̀dínwó pẹ̀lú owó diriham tó níye. Wọ́n kò sì wowọ́ mọ́ ọn.¹
1. Ìyẹn ni pé, wọn kò tà á ní ọ̀wọ́n gógó.
(21) Ẹni tí ó rà á ní (ìlú) Misrọ sọ fún aya rẹ̀ pé: “Ṣàpọ́nlé ibùgbé rẹ̀. Ó súnmọ́ kí ó wúlò fún wa tàbí kí á fi ṣọmọ.” Báyẹn ni A ṣe fi àyè gba Yūsuf lórí ilẹ̀. Àti pé kí Á tún lè fi ìtúmọ̀ àlá mọ̀ ọ́n. Allāhu ni Olùborí lórí àṣẹ Rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kò mọ̀.
(22) Nígbà tí ó sì dàgbà dáadáa, A fún un ní ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ àti ìmọ̀. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san rere.
(23) Obìnrin tí Yūsuf wà nínú ilé rẹ̀ sì jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sì ti àwọn ìlẹ̀kùn pa. Ó sọ pé: “Súnmọ́ mi.” (Yūsuf) sọ pé: “Mo sádi Allāhu. Dájúdájú ọkọ rẹ ni ọ̀gá mi. Ó sì ṣe ibùgbé mi dáadáa. Dájúdájú àwọn alábòsí kò níí jèrè.”
(24) (Obìnrin náà) kúkú gbèrò eré ìfẹ́ sí i. Òun náà gbèrò rẹ̀.¹ Tí kò bá jẹ́ pé ó rí ẹ̀rí Olúwa rẹ̀ (pé harāmu ni sìná, ìbá súnmọ́ ọn). Báyẹn ni (ọ̀rọ̀ náà rí) nítorí kí Á lè ṣẹ́rí aburú àti sìná ṣíṣe kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ipò ànábì).”
1. Ànábì Yūsuf - kí ọlà Allāhu máa bá a - kò di ẹlẹ́ṣẹ̀ látara bí èròǹgbà ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ ṣe tì í sínú èròkérò ní ìbámu sí hadīth ọmọ ‘Abbās - kí Allāhu yọ́nú sí àwọn méjèèjì -, láti ọ̀dọ̀ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - nínú ohun tí ó gbà lẹ́gbàwá làti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ - tó ga jùlọ -. Ó sọ pé: “Dájúdájú Allāhu ti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn iṣẹ́ rere àti àwọn iṣẹ́ ibi sínú kádàrá. Lẹ́yìn náà, Ó ṣàlàyé èyí (fún ẹ̀dá). Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbèrò iṣẹ́ rere kan, kò sì ṣe é, Allāhu yóò kọ ọ́ sílẹ̀ fún un lọ́dọ̀ Rẹ̀ ní iṣẹ́ rere tó pé pérépéré. Tí ó bá sì gbèrò rẹ̀, tí ó sì rí i ṣe, Allāhu yóò kọ ọ́ sílẹ̀ fún un lọ́dọ̀ Rẹ̀ ní iṣẹ́ rere mẹ́wàá, títí dé ọgọ́rùn-ún méje àdìpèlé, títí dé àdìpèlé lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbèrò iṣẹ́ ibi kan, kò sì ṣe é, Allāhu yóò kọ ọ́ sílẹ̀ fún un lọ́dọ̀ Rẹ̀ ní iṣẹ́ rere tó pé pérépéré (fún gbígbé iṣẹ́ ibi jù sílẹ̀). Tí ó bá sì gbèrò rẹ̀, tí ó sì rí i ṣe, Allāhu yóò kọ ọ́ sílẹ̀ fún un lọ́dọ̀ Rẹ̀ ní iṣẹ́ ibi ẹyọ kan.” Bukāriy àti Muslim
(25) Àwọn méjèèjì sáré lọ síbi ìlẹ̀kùn. (Obìnrin yìí) sì fa ẹ̀wù (Yūsuf) ya lẹ́yìn. Àwọn méjèèjì sì bá ọ̀gá rẹ̀ lẹ́nu ọ̀nà. (Obìnrin yìí) sì sọ pé: “Kí ni ẹ̀san fún ẹni tí ó gbèrò aburú sí ará ilé rẹ bí kò ṣe pé kí wọ́n sọ ọ́ sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n tàbí ìyà ẹlẹ́ta-eléro.” 



12 - Suuratu Yuusuf  2013_110
الرجوع الى أعلى الصفحة اذهب الى الأسفل
https://almomenoon1.0wn0.com/
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn
مؤسس ومدير المنتدى
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn


عدد المساهمات : 52644
العمر : 72

12 - Suuratu Yuusuf  Empty
مُساهمةموضوع: رد: 12 - Suuratu Yuusuf    12 - Suuratu Yuusuf  Emptyالجمعة 21 يوليو 2023, 11:10 pm


(26) (Yūsuf) sọ pé: “Òun ló jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ mi.” Ẹlẹ́rìí kan nínú ará ile (obìnrin náà) sì jẹ́rìí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n fa ẹ̀wù rẹ̀ ya níwájú, (obìnrin yìí) ló sọ òdodo, (Yūsuf) sì wà nínú àwọn òpùrọ́.
(27) Tí ó bá sì jẹ́ pé wọ́n fa ẹ̀wù rẹ̀ ya lẹ́yìn, (obìnrin yìí) ló parọ́, (Yūsuf) sì wà nínú àwọn olódodo.”¹
1. Ẹlẹ́rìí yìí ni ọmọ òpóǹló tí Allāhu - Ọba mímọ́ jùlọ - fún lọ́rọ̀ sọ lórí ìtẹ́. Nítorí náà, kì í ṣe Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - nìkan ni ẹni tí ó sọ̀rọ̀ ní òpóǹló lórí ìtẹ́.
(28) Nígbà tí (ọkọ) rí ẹ̀wù rẹ̀ tí wọ́n ti fà á ya lẹ́yìn, ó sọ pé: “Dájúdájú nínú ète ẹ̀yin obìnrin ni (èyí). Dájúdájú ète yín tóbi.
(29) Yūsuf, ṣẹ́rí kúrò níbi èyí. Kí ìwọ (obìnrin yìí) sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Dájúdájú ìwọ wà lára àwọn aláṣìṣe.”
(30) Àwọn obìnrin kan nínú ìlú sọ pé: “Ayaba ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀; ìfẹ́ kúkú ti kó sí i lọ́kàn. Dájúdájú àwa ń rí òun pé ó wà nínú àṣìṣe pọ́nńbélé.”
(31) Nígbà tí (ayaba) gbọ́ ète (ọ̀rọ̀) wọn (tí wọ́n ń sọ nípa rẹ̀), ó ránṣẹ́ sí wọn. Ó sì pèsè ohun jíjẹ tí wọ́n máa rọ̀gbọ̀kú jẹ lórí tìmùtìmù àti ìrọ̀rí sílẹ̀ fún wọn. Ó fún ìkọ̀ọ̀kan wọn ní ọ̀bẹ (tí ó máa fi jẹun). Ó sì sọ pé: “Jáde sí wọn, (Yūsuf).” Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n gbé e tóbi (fún ẹwà ara rẹ̀). Wọ́n sì rẹ́ra wọn lọ́wọ́ (fún ìyanu ẹwà ara rẹ̀). Wọ́n sì wí pé: “Mímọ́ ni fún Allāhu! Èyí kì í ṣe abara. Kí ni èyí bí kò ṣe mọlāika alápọ̀n-ọ́nlé.”
(32) (Ayaba) sọ pé: “Ìyẹn ni ẹni tí ẹ bú mi fún. Dájúdájú mo jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wá ìṣọ́ra. Dájúdájú tí kò bá ṣe ohun tí mò ń pa láṣẹ fún un, wọ́n kúkú máa fi sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n ni. Dájúdájú ó sì máa wà nínú àwọn ẹni yẹpẹrẹ.”
(33) (Yūsuf) sọ pé: “Olúwa (Ẹlẹ́dàá) mi, ọgbà ẹ̀wọ̀n ni mo nífẹ̀ẹ́ sí ju ohun tí wọ́n ń pè mí sí. Tí O ò bá sì ṣẹ́rí ète wọn kúrò lọ́dọ̀ mi, èmi yóò kó sínú ète wọn, èmi yó sì wà lára àwọn aláìmọ̀kan.”
(34) Nítorí náà, Olúwa rẹ̀ jẹ́pè rẹ̀. Ó sì ṣẹ́rí ète wọn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
(35) Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti rí àwọn àmì (pé Yūsuf kò jẹ̀bi ẹ̀sùn), lẹ́yìn náà, ó hàn sí wọn pé àwọn gbọ́dọ̀ sọ ọ́ sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n títí di àsìkò kan ná.
(36) Àwọn ọ̀dọ́kùnrin méjì kan wọ inú ọgbà ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú rẹ̀. Ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì sọ pé: “Èmi lálàá rí ara mi pé mò ń fún ọtí.” Ẹnì kejì sọ pé: “Dájúdájú èmi lálàá rí ara mi pé mo gbé búrẹ́dì rù sórí mi, ẹyẹ sì ń jẹ nínú rẹ̀.” Sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún wa. Dájúdájú àwa ń rí ọ pé o wà nínú àwọn ẹni rere.
(37) Ó sọ pé: “Oúnjẹ tí wọ́n ń pèsè fún ẹ̀yin méjèèjì kò ní tí ì dé ba yín, àfi kí èmi ti sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún ẹ̀yin méjèèjì ṣíwájú kí ó tó dé ba yín. Ìyẹn wà nínú n̄ǹkan tí Olúwa mi fi mọ̀ mí. Dájúdájú èmi fi ẹ̀sìn àwọn ènìyàn tí kò gbàgbọ́ nínú Allāhu sílẹ̀. Àwọn sì ni aláìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.
(38) Mo sì tẹ̀lé ẹ̀sìn àwọn bàbá mi, (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb. Kò tọ́ sí wa pé kí á sọ n̄ǹkan kan di akẹgbẹ́ fún Allāhu. Ìyẹn wà nínú oore àjùlọ Allāhu lórí àwa àti lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kì í dúpẹ́ (fún Allāhu).
(39) Ẹ̀yin akẹgbẹ́ mi méjéèjì nínú ẹ̀wọ̀n, ṣé àwọn olúwa ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló lóore jùlọ (láti jọ́sìn fún) tàbí Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí?
(40) Kò sí ohun kan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Rẹ̀ bí kò ṣe àwọn orúkọ kan tí ẹ sọ wọ́n - ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín - Allāhu kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún un. Ìdájọ́ (ta ni a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo) kò sí fún ẹnì kan àyàfi Allāhu. Ó sì ti pàṣẹ pé ẹ má ṣe jọ́sìn fún kiní kan àyàfi Òun nìkan. Ìyẹn ni ẹ̀sìn tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.
(41) Ẹ̀yin akẹgbẹ́ mi méjéèjì nínú ẹ̀wọ̀n, ní ti ẹnì kan nínú yín, ó máa fún ọ̀gá rẹ̀ ní ọtí mu. Ní ti ẹnì kejì, wọn yóò kàn án mọ́ igi àgbélébùú, ẹyẹ yó sì máa jẹ nínú orí rẹ̀. Wọ́n ti parí ọ̀rọ̀ tí ẹ̀yin méjèèjì ń ṣe ìbéèrè nípa rẹ̀.”
(42) Ó sì sọ fún ẹni tí ó rò pé ó máa là nínú àwọn méjèèjì pé: “Rántí mi lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ.” Èṣù sì mú (Yūsuf) gbàgbé ìrántí Olúwa rẹ̀ (nípa wíwá ìrànlọ́wọ́ sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀). Nítorí náà, ó wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n fún àwọn ọdún díẹ̀.
(43) Ọbá sọ pé: “Dájúdájú èmi lálàá rí màálù méje tó sanra. Àwọn màálù méje tó rù sì ń jẹ wọ́n. (Mo tún lálàá rí) ṣiri méje tutù àti òmíràn gbígbẹ. Ẹ̀yin ìjòyè, ẹ fún mi ní àlàyé ìtúmọ̀ àlá mi tí ẹ bá jẹ́ ẹni tó máa ń túmọ̀ àlá.”
(44) Wọ́n sọ pé: “Àwọn àlá tí ó lọ́pọ̀ mọ́ra wọn tí kò ní ìtúmọ̀ (nìyí). Àti pé àwa kì í ṣe onímọ̀ nípa ìtúmọ̀ àwọn àlá.”
(45) Ẹni tí ó là nínú àwọn (ẹlẹ́wọ̀n) méjèèjì sọ pé, - ó rántí (Yūsuf) lẹ́yìn ìgbà pípẹ́ -: “Èmi yóò fún yín ní ìró nípa ìtúmọ̀ rẹ̀. Nítorí náà, ẹ fi iṣẹ́ rán mi ná (kí n̄g lọ ṣe ìwádìí rẹ̀).”
(46) Yūsuf, ìwọ olódodo, fún wa ní àlàyé ìtúmọ̀ àlá (yìí): màálù méje tó sanra. Àwọn màálù méje tó rù sì ń jẹ wọ́n. Àti ṣiri méje tutù àti òmíràn gbígbẹ. (Kí ni ìtúmọ̀ rẹ̀) nítorí kí n̄g lè fi àbọ̀ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn àti nítorí kí wọ́n lè mọ (ìtúmọ̀ rẹ̀).
(47) Ó sọ pé: “Ẹ̀yin yóò gbin n̄ǹkan ọ̀gbìn fún ọdún méje gbáko (gẹ́gẹ́ bí) ìṣe (yín). Ohunkòhun tí ẹ bá kó lérè oko, kí ẹ fi sílẹ̀ sínú ṣiri rẹ̀ àfi díẹ̀ tí ẹ máa jẹ nínú rẹ̀.
(48) Lẹ́yìn náà, ọdún méje tó le (fún ọ̀dá òjò) yóò dé lẹ́yìn ìyẹn, (àwọn ará ìlú) yó sì lè jẹ ohun tí ẹ ti (kó lérè oko) ṣíwájú àfi díẹ̀ tí ẹ máa fi pamọ́ (fún gbígbìn).
(49) Lẹ́yìn náà, ọdún kan tí Wọn yóò rọ̀jò fún àwọn ènìyàn yóò dé lẹ́yìn ìyẹn. Àwọn ènìyàn yó sì máa fún èso àti wàrà mu nínú ọdún náà.
(50) Ọba sọ pé: “Ẹ mú (Yūsuf) wá fún mi.” Nígbà tí ìránṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ rẹ. (Yūsuf) sọ pé: “Padà sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ, kí o bi í léèrè pé, kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn obìnrin tí wọ́n rẹ́ ọwọ́ ara wọn. Dájúdájú Olúwa mi ni Onímọ̀ nípa ète wọn.” 



12 - Suuratu Yuusuf  2013_110
الرجوع الى أعلى الصفحة اذهب الى الأسفل
https://almomenoon1.0wn0.com/
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn
مؤسس ومدير المنتدى
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn


عدد المساهمات : 52644
العمر : 72

12 - Suuratu Yuusuf  Empty
مُساهمةموضوع: رد: 12 - Suuratu Yuusuf    12 - Suuratu Yuusuf  Emptyالجمعة 21 يوليو 2023, 11:11 pm


(51) (Ọba) sọ pé: “Kí ni ọ̀rọ̀ tiyín ti jẹ́ tí ẹ fi jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ Yūsuf?” Wọ́n sọ pé: “Mímọ́ ni fún Allāhu. àwa kò mọ aburú kan mọ Yūsuf.” Ayaba sọ pé: “Nísinsìn yìí ni òdodo fojú hàn. Èmi ni mo jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀. Dájúdájú ó wà nínú àwọn olódodo.”
(52) (Yūsuf sọ pé): “Ìyẹn nítorí kí ọba lè mọ̀ pé dájúdájú èmi kò jàǹbá rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀. Àti pé dájúdájú Allāhu kò níí fi ìmọ̀nà síbi ète àwọn oníjàǹbá.
(53) Èmi kò sì fọra mi mọ́ (níbi èròkérò); dájúdájú ẹ̀mí kúkú ń pàṣẹ èròkérò (fún ẹ̀dá) ni àfi ẹni tí Olúwa mi bá kẹ́. Dájúdájú Olúwa mi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”
(54) Ọba sọ pé: “Ẹ mú (Yūsuf) wá fún mi. Èmi yóò ṣe é ní ẹni ẹ̀ṣà lọ́dọ̀ mi.” Nígbà tí ọba bá a sọ̀rọ̀ tán, ó sọ pé: “Lọ́dọ̀ wa ní òní dájúdájú ìwọ ni ẹni pàtàkì, olùfọkàntán.”
(55) (Yūsuf) sọ pé: “Fi mí ṣe aláṣẹ lórí àwọn ọrọ̀ ìlú, dájúdájú alámòjúútó onímọ̀ ni mí.”
(56) Báyẹn ni A ṣe fún Yūsuf ní ipò àti ibùgbé lórí ilẹ̀. Ó sì ń gbé ní ibi tí ó bá fẹ́. Àwa ń mú ìkẹ́ Wa bá ẹnikẹ́ni tí A bá fẹ́. A ò sì níí fi ẹ̀san àwọn olùṣe-rere ráre.
(57) Dájúdájú ẹ̀san ti ọ̀run lóore jùlọ fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ń bẹ̀rù (Allāhu).
(58) Àwọn ọbàkan (Ànábì) Yūsuf dé, wọ́n sì wọlé tọ̀ ọ́. Ó dá wọn mọ̀. Àwọn kò sì mọ̀ ọ́n mọ́.
(59) Nígbà tí ó sì fún wọn ní ẹrù oúnjẹ wọn tán, ó sọ pé: “Ẹ lọ mú ọbàkan yín wá láti ọ̀dọ̀ bàbá yín. Ṣé ẹ kò rí i pé dájúdájú mò ń wọn kóńgò ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ni? Èmi sì dára jùlọ nínú àwọn olùgbàlejò.
(60) Tí ẹ ò bá sì mú un wá, kò sí (ẹrù oúnjẹ) wíwọ̀n fún yín lọ́dọ̀ mi. Kí ẹ sì má ṣe súnmọ́ mi.”
(61) Wọ́n sọ pé: “A máa jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún un lọ́dọ̀ bàbá rẹ̀. Dájúdájú àwa máa ṣe bẹ́ẹ̀.”
(62) Ó sì sọ fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ fi owó-ọjà wọn sínú ẹrù (oúnjẹ) wọn nítorí kí wọ́n lè mọ̀ nígbà tí wọ́n bá padà dé ọ̀dọ̀ ará ilé wọ́n (pé a ti dá a padà fún wọn), wọn yó sì lè padà wá.”
(63) Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ bàbá wọn, wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, wọ́n kọ̀ láti wọn oúnjẹ fún wa. Nítorí náà, jẹ́ kí ọbàkan wa bá wa lọ nítorí kí á lè rí oúnjẹ wọ̀n (wálé). Dájúdájú àwa yóò máa ṣọ́ ọ.”
(64) Ó sọ pé: “Ṣé kí n̄g gbà yín gbọ́ lórí rẹ̀ bí kò ṣe bí mó ṣe gbà yín gbọ́ ní ìṣaájú lórí ọmọ-ìyá rẹ̀? Nítorí náà, Allāhu lóore jùlọ ní Olùṣọ́. Òun sì ni Aláàánú-jùlọ nínú àwọn aláàánú.”
(65) Nígbà tí wọ́n tú ẹrù oúnjẹ wọn, wọ́n rí owó-ọjà wọn tí wọ́n dá padà fún wọn (nínú rẹ̀). Wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, kí ni a tún ń fẹ́? Owó-ọjà wa nìyí tí wọ́n ti dá padà fún wa. A ó si tún fi wá oúnjẹ rà fún àwọn ẹbí wa. A ó sì dáàbò bo ọbàkan wa. A sì máa rí àlékún ẹrù oúnjẹ (tí) ràkúnmí kan lè rù sí i. Ìwọ̀n oúnjẹ kékeré sì nìyẹn (lọ́dọ̀ ọba).”
(66) Ó sọ pé: “Èmi kò níí jẹ́ kí ó ba yín lọ títí ẹ máa fi ṣe àdéhùn fún mi ní (orúkọ) Allāhu pé dájúdájú ẹ máa mú un padà wá bá mi àfi tí (àwọn ọ̀tá) bá ka yín mọ́.” Nígbà tí wọ́n fún un ní àdéhùn wọn tán, ó sọ pé: “Allāhu ni Ẹlẹ́rìí lórí ohun tí à ń sọ (yìí).”
(67) Ó tún sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe gba ẹnu ọ̀nà ẹyọ kan wọlé. Ẹ gba ẹnu ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wọlé. Èmi kò lè fí n̄ǹkan kan rọ̀ yín lọ́rọ̀ lọ́dọ̀ Allāhu. Kò sí ìdájọ́ (kan) àfi ti Allāhu. Òun ni mo gbáralé. Òun sì ni kí àwọn olùgbáralé gbáralé.”
(68) Nígbà tí wọ́n wọ (inú ìlú) ní àwọn àyè tí bàbá wọn pa láṣẹ fún wọn, kò sì rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kan kan lọ́dọ̀ Allāhu bí kò ṣe bùkátà kan nínú ẹ̀mí (Ànábì) Ya‘ƙūb tí ó múṣẹ. Dájúdájú onímọ̀ ni nípa ohun tí A fi mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.
(69) Nígbà tí wọ́n wọlé ti (Ànábì) Yūsuf, ó mú ọmọ-ìyá rẹ̀ mọ́ra sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sọ pé: “Dájúdájú èmi ni ọmọ-ìyá rẹ. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.”
(70) Nígbà tí ó sì fún wọn ní ẹrù wọn tán, ó fi ife-ìmumi sínú ẹrù ọmọ-ìyá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, olùpèpè kan kéde pé: “Ẹ̀yin èrò-ràkúnmí, dájúdájú olè mà ni yín.”
(71) Wọ́n dojú kọ wọ́n, wọ́n sọ pé: “Kí l’ẹ ṣàfẹ́kù?”
(72) Wọ́n sọ pé: “A ṣàfẹ́kù ife ọba ni. Ẹni tí ó bá sì mú un wá yóò rí ẹrù oúnjẹ ràkúnmí kan gbà. Èmi sì ni onídùróó fún ẹ̀bùn náà.”
(73) Wọ́n sọ pé: “A fi Allāhu búra, dájúdájú ẹ mọ̀ pé a kò wá láti ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀. Àti pé àwa kì í ṣe olè.”
(74) Wọ́n sọ pé: “Kí ni ẹ̀san (fún ẹni tí) ó jí i, tí (ó bá hàn pé) ẹ̀yin jẹ́ òpùrọ́?”
(75) Wọ́n sọ pé: “Ẹ̀san rẹ̀; ẹni tí wọ́n bá bá a nínú ẹrù rẹ̀, òun náà ni ẹ̀san rẹ̀. Báyẹn ni àwa ṣe ń san àwọn alábòsí ní ẹ̀san (ní ọ̀dọ̀ tiwa).”¹
1. Nínú òfin tí Allāhu gbékalẹ̀ lórí olè ní àsìkò Ànábì Ya'ƙūb - kí ọlà Allāhu máa bá a - ni pé, tí ọwọ́ bá tẹ olè, wọ́n máa fà á lé olóhun lọ́wọ́, ó sì máa sọ ọ́ di ẹrú rẹ̀. Àmọ́ ní àsìkò Ànábì tiwa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ọrùn ọwọ́ olè ni wọ́n máa gé pẹ̀lú àwọn májẹ̀mu rẹ̀. 



12 - Suuratu Yuusuf  2013_110
الرجوع الى أعلى الصفحة اذهب الى الأسفل
https://almomenoon1.0wn0.com/
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn
مؤسس ومدير المنتدى
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn


عدد المساهمات : 52644
العمر : 72

12 - Suuratu Yuusuf  Empty
مُساهمةموضوع: رد: 12 - Suuratu Yuusuf    12 - Suuratu Yuusuf  Emptyالجمعة 21 يوليو 2023, 11:11 pm


(76) Ó sì bẹ̀rẹ̀ (àyẹ̀wò) pẹ̀lú àpò wọn ṣíwájú àpò ọmọ-ìyá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó mú un jáde láti inú àpò ọmọ-ìyá rẹ̀. Báyẹn ní A ṣe fún (Ànábì) Yūsuf ní ète dá. Kò lè fi òfin ọba mú ọmọ-ìyá rẹ̀ àfi tí Allāhu bá fẹ́.¹ À ń ṣàgbéga àwọn ipò fún ẹni tí A bá fẹ́. Onímọ̀ wà lókè gbogbo onímọ̀.²
1. Kò sí òfin sísọ olè dí ẹrú olóhun nínú ìlú Misrọ. Àmọ́ Allāhu fẹ́ kí Ànábì Yūsūf - kí ọlà Allāhu máa bá a - mú ọmọ ìyá rẹ̀ mọ́lẹ̀. Allāhu sì fi ìdàjọ́ tí wọ́n máa lò fún "olè" sí ẹnu àwọn ọmọ Ànábì Ya'ƙūb - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Ohun tí Allāhu fẹ́ sì wá sí ìmúṣẹ. 2. Ìyẹn ni pé, ẹ̀dá fi ipò àti ìmọ̀ ga jura wọn títí ipò àti ìmọ̀ fi pin sí ọ̀dọ̀ Allāhu Ọba tí Ó ga jùlọ nínú ipò àti ìmọ̀.
(77) Wọ́n sọ pé: “Tí ó bá jalè, dájúdájú ọmọ-ìyá rẹ̀ kan ti jalè ṣíwájú.” (Ànábì) Yūsuf sì fi ọ̀rọ̀ náà pamọ́ sínú ẹ̀mí rẹ̀, kò sì fi hàn sí wọn pé (kò rí bẹ́ẹ̀). Ó (sì) sọ pé: “Ẹ̀yin lẹ burú jùlọ ní ipò. Allāhu l’Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ̀ ń ròyìn rẹ̀.”
(78) Wọ́n sọ pé: “Ìwọ ọba, dájúdájú ó ní bàbá arúgbó àgbàlágbà kan. Nítorí náà, mú ẹnì kan nínú wa dípò rẹ̀. Dájúdájú àwa ń rí ìwọ pé o wà nínú àwọn ẹni-rere.”
(79) Ó sọ pé: “Mo sádi Allāhu pé kí á mú ẹnì kan àfi ẹni tí a bá ẹrù wa lọ́dọ̀ rẹ. (Tí a bá mú ẹlòmíìràn) dájúdájú nígbà náà alábòsí ni wá.”
(80) Nígbà tí wọ́n sọ̀rètí nù lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n tẹ̀ sọ̀rọ̀. Àgbà (nínú) wọn sọ pé: “Ṣé ẹ kò mọ̀ pé dájúdájú bàbá yín ti gba àdéhùn yín tí (ẹ ṣe ní orúkọ) Allāhu. Àti pé ṣíwájú (èyí, ohun tí ẹ ṣe ní) àṣeètó lórí ọ̀rọ̀ (Ànábì) Yūsuf. Nítorí náà, èmi kò níí fi ilẹ̀ (Misrọ) sílẹ̀ títí bàbá mi yóò fi yọ̀ǹda fún mi tàbí (títí) Allāhu yóò fi ṣe ìdájọ́ fún mi. Ó sì lóore jùlọ nínú àwọn olùdájọ́.
(81) Ẹ padà sọ́dọ̀ bàbá yín, kí ẹ sì sọ pé: “Bàbá wa, dájúdájú ọmọ rẹ jalè. A kò sì lè jẹ́rìí (sí kiní kan) àfi ohun tí a bá nímọ̀ (nípa) rẹ̀. Àwa sì kọ́ ni à ń ṣọ ìkọ̀kọ̀ (ẹ̀dá).
(82) Kí o sì bi àwọn ará ìlú tí a wà nínú rẹ̀ àti èrò-ràkúnmí tí a jọ darí dé léèrè wò. Dájúdájú olódodo ni wá.”
(83) (Ànábì Ya‘ƙūb) sọ pé: “Rárá o, ẹ̀mí yín ló ṣe ọ̀ràn kan lọ́ṣọ̀ọ́ fún yín. Nítorí náà, sùúrù tó rẹwà (lọ̀rọ̀ mi kàn báyìí). Ó ṣeé ṣe kí Allāhu bá mi mú gbogbo wọn wá. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.”
(84) Ó pa wọ́n tì, ó sì sọ pé: “Ìbànújẹ́ ń bẹ fún mi lórí Yūsuf!” Ojú rẹ̀ méjèèjì sì funfun wá (kò ríran mọ́) látara ìbànújẹ́ náà; ó sì pa á mọ́ra.
(85) Wọ́n sọ pé: “A fi Allāhu búra, ìwọ kò yé rántí Yūsuf títí o máa fi di yánnayànna tàbí (títí) o máa fi di ara àwọn òkú.”
(86) Ó sọ pé: “Allāhu mà ni èmi ń ro ẹ̀dùn ọkàn mi àti ìbànújẹ́ mi fún. Mo sì mọ ohun tí ẹ kò mọ̀ nípa Allāhu.
(87) Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ lọ wádìí nípa Yūsuf àti ọmọ-ìyá rẹ̀. Ẹ sì má ṣe sọ̀rètí nù nínú ìkẹ́ Allāhu. Dájúdájú kò sí ẹnì kan tí ó máa sọ̀rètí nù nínú ìkẹ́ Allāhu àfi ìjọ aláìgbàgbọ́.”
(88) Nìgbà tí wọ́n wọlé tọ Yūsuf, wọ́n sọ pé: “Ìwọ ọba, ìnira (ebi) ti mú àwa àti ará ilé wa. A sì mú owó kan tí ẹ máa ta dànù lọ́wọ́.¹ Nítorí náà, wọn kóńgò (oúnjẹ) náà kún fún wa, kí ó sì ta wá lọ́rẹ. Dájúdájú Allāhu yóò san àwọn olùtọrẹ ní ẹ̀san rere.”
1. Ìyẹn ni pé, owó tí wọ́n mú dání kì í ṣe owó tí wọ́n lè gbà lọ́wọ́ wọn torí pé ó kéré púpọ̀, tàbí owó náà ti fẹ́ di kọ̀ǹdẹ̀ mọ́ wọn lọ́wọ́.
(89) Ó sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí ẹ ṣe fún Yūsuf àti ọmọ ìyá rẹ̀ nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ aláìmọ̀kan?”
(90) Wọ́n sọ pé: “Ṣé dájúdájú ìwọ ni Yūsuf?” Ó sọ pé: “Èmi ni Yūsuf. Ọmọ ìyá mi sì nìyí. Dájúdájú Allāhu ti ṣe ìdẹ̀ra fún wa. Dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá bẹ̀rù (Allāhu), tí ó sì ṣe sùúrù, dájúdájú Allāhu kò níí fi ẹ̀san àwọn olùṣe-rere ráre.”
(91) Wọ́n sọ pé: “A fi Allāhu búra! Dájúdájú Allāhu ti gbọ́lá fún ọ jù wá lọ. Àti pé dájúdájú àwa ni aláṣìṣe.”
(92) Ó sọ pé: “Kò sí ìbáwí fún yín ní òní. Allāhu yóò foríjìn yín. Òun sì ni Aláàánú-jùlọ nínú àwọn aláàánú.
(93) Ẹ mú ẹ̀wù mi yìí lọ, kí ẹ fi lé iwájú bàbá mi, ó máa padà di olùríran. Kí ẹ sì kó gbogbo ẹbí yín wá bá mi.”
(94) Nígbà tí èrò-ràkúnmí náà sí pínyà (kúrò lọ́dọ̀ Ànábì Yūsuf), bàbá wọn sọ pé: “Dájúdájú èmi ń gbọ́ òórùn Yūsuf tí ẹ kò bá níí sọ pé mò ń jarán.”
(95) Wọ́n sọ pé: “A fi Allāhu búra! Dájúdájú ìwọ sì wà nínú àṣìṣe rẹ ti àtijọ́ (nípa ìfẹ́ Yūsuf).”
(96) Nígbà tí oníròó-ìdùnnú dé, ó ju (ẹ̀wù náà) lé e níwájú, ó sì ríran padà. Ó sọ pé: “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún yín pé dájúdájú mo mọ ohun tí ẹ kò mọ̀ nípa Allāhu.”
(97) Wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, tọrọ àforíjìn ẹ̀ṣẹ̀ wa fún wa, dájúdájú àwa jẹ́ aláṣìṣe.”
(98) Ó sọ pé: “Láìpẹ́ mo máa tọrọ àforíjìn fún yín lọ́dọ̀ Olúwa mi. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”
(99) Nígbà tí wọ́n wọlé tọ (Ànábì) Yūsuf, ó kó àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì mọ́ra sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì sọ pé: “Ẹ wọ ìlú Misrọ ní olùfàyàbalẹ̀ - tí Allāhu bá fẹ́ -.”
(100) Ó gbé àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì sórí ìtẹ́. Wọ́n sì wó lulẹ̀ fún un, tí wọ́n forí kanlẹ̀ kí i.¹ Ó sọ pé: “Bàbá mi, èyí ni ìtúmọ̀ àlá mi (tí mo lá) ṣíwájú. Dájúdájú Olúwa mi ti sọ ọ́ di òdodo. Ó sì ṣe dáadáa fún mi nígbà tí Ó mú mi jáde kúrò nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ó tún mu yín wá (bá mi) láti inú oko lẹ́yìn tí Èṣù ti saburú sáààrin èmi àti àwọn ọbà-kan mi. Dájúdájú Olúwa mi ni Aláàánú fún ohun tí Ó bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
1. Ní àsìkò náà, kò lòdì sí òfin tí Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - fún Ànábì Ya'ƙūb àti àwọn ọmọ rẹ̀ - kí ọlà Allāhu máa bá wọn - láti fi ìdọ̀bálẹ̀ àti ìkúnlẹ̀ kí ẹnikẹ́ni. Àmọ́ nínú òfin tí Allāhu fún Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ó ti di èèwọ̀ láti fi ìdọ̀bálẹ̀ àti ìkúnlẹ̀ kí ẹnikẹ́ni. Ẹ wọ ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:34. 



12 - Suuratu Yuusuf  2013_110
الرجوع الى أعلى الصفحة اذهب الى الأسفل
https://almomenoon1.0wn0.com/
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn
مؤسس ومدير المنتدى
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn


عدد المساهمات : 52644
العمر : 72

12 - Suuratu Yuusuf  Empty
مُساهمةموضوع: رد: 12 - Suuratu Yuusuf    12 - Suuratu Yuusuf  Emptyالجمعة 21 يوليو 2023, 11:12 pm


(101) Olúwa mi, dájúdájú O ti fún mi nínú ìjọba. O tún fún mi nínú ìmọ̀ ìtúmọ̀ àlá. Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, Ìwọ ni Alátìlẹ́yìn mi ní ayé àti ní ọ̀run, pa mí sípò mùsùlùmí. Kí O sì fi mí pẹ̀lú àwọn ẹni rere.”
(102) Ìyẹn wà nínú ìró ìkọ̀kọ̀ tí A fi ìmísí (rẹ̀) ránṣẹ́ sí ọ. Àti pé ìwọ kò sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí wọ́n fẹnukò lórí ọ̀rọ̀ wọn, tí wọ́n ń déte.
(103) Ìwọ ìbáà ṣojú kòkòrò (ìgbàlà wọn), ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kò níí gbàgbọ́.
(104) Ìwọ kò sì bi wọ́n léèrè owó-ọ̀yà kan lórí rẹ̀. Kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.
(105) Àti pé mélòó mélòó nínú àwọn àmì tí ń bẹ ní sánmọ̀ àti ní orí ilẹ̀ tí wọ́n ń ré kọjá lórí rẹ̀, tí wọ́n sì ń gbúnrí kúrò níbẹ̀.
(106) Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni kò níí gbàgbọ́ nínú Allāhu àfi kí wọ́n tún máa ṣẹbọ.¹
1. Ìyẹn ni pé, àwọn ènìyàn kan ń bẹ láààrin àwa mùsùlùmí tí ó jẹ́ pé, tòhun ti bí wọ́n ṣe ń ṣe ’Islām, wọ́n tún ń ṣẹbọ yálà ní kọ̀rọ̀ tàbí ní gban̄gba. Àpẹ̀ẹrẹ àwọn wọ̀nyí ni àwọn ààfáà ẹlẹ́bọ, “mùsùlùmí” tó ń lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ààfáà ẹlẹ́bọ, páítọ̀ àti babaláwo, “mùsùlùmí” tí ó ń pe n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn Allāhu, “mùsùlùmí” tí ó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, “mùsùlùmí” tí ó ń bọ àwọn òrìṣà bí òrìṣà egúngún, òrìṣà ìbejì, òrìṣà Ajé àti “mùsùlùmí” tí ó ń lo ìfúnpá àti àsorọ̀ òògùn àti àsorọ̀ tíà àti “mùsùlùmí” tí ó ń gbé ẹbọ àti ètùtù. Gbogbo àwọn wọ̀nyí kì í ṣe mùsùlùmí ní ọ̀dọ̀ Allāhu - Ọba mímọ́ jùlọ.
(107) Ṣé wọ́n fàyà balẹ̀ pé ohun tí ń bo ẹ̀dá mọ́lẹ̀ nínú ìyà Allāhu kò lè dé bá àwọn ni tàbí pé Àkókò náà kò lè kò lé àwọn lórí ní òjijì, tí wọn kò sì níí fura?
(108) Sọ pé: “Èyí ni ojú ọ̀nà (ẹ̀sìn) mi, èmi àti àwọn tó tẹ̀lé mi sì ń pèpè sí (ẹ̀sìn) Allāhu pẹ̀lú ìmọ̀ àmọ̀dájú àti ẹ̀rí. Mímọ́ ni fún Allāhu. Èmi kò sì sí lára àwọn ọ̀ṣẹbọ.”
(109) A kò rán ẹnì kan ní iṣẹ́-òjíṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi àwọn ọkùnrin tí À ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí nínú àwọn ará ìlú.¹ Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe rí? Dájúdájú Ilé ìkẹ́yìn lóore jùlọ fún àwọn tó bẹ̀rù (Allāhu). Ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni?
1. Lóde òní yìí, à ń rí àwọn obìnrin kan tí wọ́n ń sọra wọn di aṣíwájú ẹlẹ́sìn nínú ìjọ ’Islām àti nínú ìjọ nasọ̄rọ̄. Wọ́n sì ń sọ pé Ọlọ́hun l’Ó fi iṣẹ́ ẹ̀sìn rán àwọn níṣẹ́. Wọ́n ń sọra wọn di ànábì Ọlọ́hun àti òjíṣẹ́ Rẹ̀. Āyah yìí ti já wọn nírọ́. Allāhu - Ọba mímọ́ - ti fi rinlẹ̀ pé, Òun kò fi iṣẹ́ ìmísí rán obìnrin kan kan níṣẹ́ rí sí ẹnikẹ́ni. Ẹ jìnnà sí irú àwọn obìnrin abẹ̀sìnjẹ́ náà. Kíyè sí i! Bí Allāhu ṣe ṣa Mọryam, ìyá Ànábì ‘Īsā lẹ́ṣà tó, kò fi iṣẹ́ ìmísí rán an níṣẹ́ sí ẹnikẹ́ni.
(110) (A kì í jẹ àwọn ènìyàn níyà) títí di ìgbà tí àwọn Òjíṣẹ́ bá tó sọ̀rètí nù (nípa ìgbàgbọ́ wọn), tí wọ́n sì mọ̀ pé wọ́n ti pe àwọn ní òpùrọ́. Àrànṣe Wa yó sì dé bá wọn. A sì máa gba ẹni tí A bá fẹ́ là. Wọn kò lè dá ìyà Wa padà lórí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀.
(111) Dájúdájú àríwòye wà nínú ìtàn wọn fún àwọn onílàákàyè. (Al-Ƙur’ān) kì í ṣe ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n ń hun, ṣùgbọ́n ó ń jẹ́rìí sí èyí tó jẹ́ òdodo nínú èyí tó ṣíwájú rẹ̀, ó ń ṣàlàyé gbogbo n̄ǹkan;¹ ó jẹ́ ìmọ̀nà àti ìkẹ́ fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Ani‘ām; 6:114. 



12 - Suuratu Yuusuf  2013_110
الرجوع الى أعلى الصفحة اذهب الى الأسفل
https://almomenoon1.0wn0.com/
 
12 - Suuratu Yuusuf
الرجوع الى أعلى الصفحة 
صفحة 1 من اصل 1
 مواضيع مماثلة
-
» QUR’AAN 12, SUURATU YUUSUF
» 19 - Suuratu Mar'yam
» QUR’AAN 43, SUURATU ZUH’RUF (B43)
» 37 - Suuratu Sooffaat
» QUR’AAN 19, SUURATU-MAR’YAM

صلاحيات هذا المنتدى:لاتستطيع الرد على المواضيع في هذا المنتدى
منتديات إنما المؤمنون إخوة (2024 - 2010) The Believers Are Brothers :: (English) :: The Holy Quran is translated :: Yoruba-
انتقل الى: