|
| 37 - Suuratu Sooffaat | |
| | كاتب الموضوع | رسالة |
---|
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: 37 - Suuratu Sooffaat الأحد 23 يوليو 2023, 6:24 pm | |
| 37 - Suuratu Sooffaat Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run. (1) Allāhu fi àwọn mọlāika tí ó ń tò ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ búra. (2) Allāhu tún fi àwọn mọlāika tó ń wọ́ ẹ̀ṣújò kiri tààrà bura. (3) Allāhu tún fi àwọn mọlāika tó ń ka ìrántí bura. (4) Dájúdájú ọ̀kan ṣoṣo ni Ọlọ́hun yín tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo. (5) Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Òun sì ni Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn. (6) Dájúdájú Àwa fi àwọn ìràwọ̀ ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́ (7) àti ìṣọ́ kúrò níbi (aburú) gbogbo èṣù olóríkunkun. (8) (Àwọn èṣù) kò sì níí lè tẹ́tí sí ìjọ (mọlāika tó wà ní) àyè gíga jùlọ (nínú sánmọ̀. Bí wọ́n bá sì gbìyànjú láti yọ́ ọ̀rọ̀ gbọ́ láti sánmọ̀, àwọn mọlāika) yó sì máa kù wọ́n lókò (ẹ̀ta ìràwọ̀) ní gbogbo agbègbè (sánmọ̀). (9) Wọ́n máa lé wọn dànù. Ìyà àìlópin sì wà fún wọn. (10) (Wọn kò níí gbọ́ ọ̀rọ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́) àyàfi ẹni tí ó bá rí ọ̀rọ̀ àjígbọ́ gbé, nígbà náà (ni mọlāika) yó sì fi ẹ̀ta ìràwọ̀ iná tó máa jó o tẹ̀lé e.¹ 1. Àwọn èṣù àlùjànnú máa ń gbé ara wọn gunra wọn láti lè súnmọ́ etí sánmọ̀ ilé ayé. Bí wọ́n bá bá àwọn mọlāika lórí àwọn ìro kan tí Allāhu fi ránṣẹ́ sí wọn, wọ́n máa jí i gbọ́. Níkété tí àwọn mọlāika bá fura sí wọn, wọ́n máa fi adó olóró ẹta ìràwọ̀ tú wọn ká. Nígbà mìíràn, àwọn èṣù àlùjànnú yìí yóò ti ṣe àtagbà ìró náà síra wọn tán ṣíwájú kí wọ́n tó tú wọn ká. Nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, ẹni tí ó wà lókè pátápátá nínú wọn, kò níí tí ì ṣe àtagbà ìró sí àwọn yòókù rẹ̀ ṣíwájú kí wọ́n tó tú wọn ká. Èyí tí wọ́n bá jàjà rí jí gbé lọ, wọ́n máa lọ kọ bí àkùkọ sínú etí àwọn ẹni wọn nínú àwọn èṣù ènìyàn tí wọ́n yẹsẹ́ wò. Wọ́n sì máa fi irọ́ ọgọ́rùn-ún kún un fúnra wọn ní ọ̀dọ̀ àwọn tó ń pawọ́ dà, tí wọ́n ń yẹsẹ́ wò. (11) Bi wọ́n léèrè wò pé, ṣé àwọn (ènìyàn) ni ìṣẹ̀dá wọn lágbára jùlọ ni tàbí àwọn (n̄ǹkan mìíràn)¹ tí A dá? Dájúdájú Àwa dá àwọn (ènìyàn) láti ara ẹrẹ̀ tó lẹ̀ mọ́ra wọn. 1. Àwọn n̄ǹkan mìíràn bíi àwọn sánmọ̀, àwọn ilẹ̀, àwọn mọlāika àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (12) Rárá (kò jọra wọn); ìwọ ṣèèmọ̀ (nípa al-Ƙur’ān), àwọn sì ń ṣe yẹ̀yẹ́. (13) Àti pé nígbà tí wọ́n bá ṣe ìrántí fún wọn, wọn kò níí lo ìrántí. (14) Nígbà tí wọ́n bá tún rí àmì kan, wọn yóò máa ṣe yẹ̀yẹ́. (15) Wọ́n sì wí pé: “Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe idán pọ́nńbélé. (16) Ṣé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò tún gbé wa dìde ni? (17) Ṣé àti àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́?” (18) Sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹ̀yin yó sì di ẹni yẹpẹrẹ.” (19) Nítorí náà, igbe ẹyọ kan mà ni. Nígbà náà ni wọn yóò máa wò sùn. (20) Wọ́n á wí pé: “Ègbé wa ò! Èyí ni Ọjọ́ ẹ̀san.” (21) Èyí ni ọjọ́ Ìdájọ́ èyí tí ẹ̀ ń pè ní irọ́. (22) Ẹ kó àwọn tó ṣàbòsí jọ, àwọn ìyàwó wọn àti ohun tí wọ́n ń jọ́sìn fún (23) lẹ́yìn Allāhu. Kí ẹ sì júwe wọn sí ojú ọ̀nà iná Jẹhīm. (24) Ẹ dá wọn dúró ná, dájúdájú wọ́n máa bi wọ́n léèrè ìbéèrè. (25) Kí ni kò jẹ́ kí ẹ ran ara yín lọ́wọ́? |
| | | أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 37 - Suuratu Sooffaat الأحد 23 يوليو 2023, 6:25 pm | |
| (26) Rárá, wọ́n ti juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ ní òní ni. (27) Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, tí wọn yóò máa bi ara wọn léèrè ìbéèrè.¹ 1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Mu’minūn; 23:101. (28) (Àwọn ènìyàn) wí pé: “Dájúdájú ẹ̀yin l’ẹ̀ ń gba ọ̀tún wọlé sí wa lára (láti ṣì wá lọ́nà).”¹ 1. Gbígba ọ̀tún wọlé sí ni lára ni pé, wọ́n ń lo orúkọ ’Islām láti fi pe àwọn ènìyàn lọ síbi ìṣẹbọ dípò mímú Allāhu ní Ọ̀kan ṣoṣo. Àpẹ̀ẹrẹ àwọn wọ̀nyí ni àwọn àáfà tí wọ́n bá àwọn àlùjọ̀nnú dòwò pọ̀ tán, tí wọ́n sọra wọn di oníṣẹ́-ìyanu àti àwọn onibidiah bí ìjọ Ahmadiyyah àti ìjọ Tijāniyyah. (29) (Àwọn àlùjànnú) wí pé: “Rárá o (àwa kọ́), ẹ̀yin ni ẹ kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. (30) Àti pé àwa kò ní agbára kan lórí yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ ìjọ olùtayọ-ẹnu ààlà. (31) Ọ̀rọ̀ Olúwa wa sì kò lé wa lórí pé dájúdájú àwa yóò tọ́ Iná wò. (32) Nítorí náà, a ṣì yín lọ́nà. Dájúdájú àwa náà sì jẹ́ olùṣìnà.” (33) Dájúdájú ní ọjọ́ yẹn, akẹgbẹ́ ni wọ́n nínú Ìyà. (Wọ́n dìjọ máa wà nínú Iná.) (34) Dájúdájú báyẹn ni Àwa yóò ti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. (35) Dájúdájú nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé “Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Allāhu.”, wọn yóò máa ṣègbéraga. (36) Wọ́n sì ń wí pé: “Ṣé a máa fi àwọn òrìṣà wa sílẹ̀ nítorí eléwì wèrè kan?” (37) Kò rí bẹ́ẹ̀. Ó mú òdodo wá ni. Ó sì ń jẹ́rìí sí òdodo àwọn Òjíṣẹ́ náà. (38) Dájúdájú ẹ máa tọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro wò. (39) A kò níí san yín ní ẹ̀san kan àfi ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. (40) Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo). (41) Ti àwọn wọ̀nyẹn sì ni arísìkí tí wọ́n ti mọ̀; (42) àwọn èso. Àwọn sì ni alápọ̀n-ọ́nlé (43) nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra. (44) Lórí àwọn ìtẹ́ ni wọn yóò ti kọjú síra wọn. (45) Wọn yóò máa gbé ife ọtí mímọ́ láti inú odò kan tó ń ṣàn káà kiri ọ̀dọ̀ wọn. (46) Funfun ni (ọtí náà). Ó ń dùn lẹ́nu àwọn tó máa mu ún. (47) Kò sí ìpalára kan fún wọn nínú rẹ̀, wọn kò sì níí hunrírà lórí rẹ̀. (48) Àwọn obìnrin tí kì í wo ẹlòmíìràn, àwọn ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ yó sì wà lọ́dọ̀ wọn. (49) Wọ́n dà bí ẹyin tí wọn kò ì bó èèpo rẹ̀ kúrò lára rẹ̀.¹ 1. Àwọn nasọ̄rọ̄, nínú ọ̀rọ̀ wọn kan tí wọ́n ń fi tàbùkù àwọn ìkẹ́ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, wọ́n sọ pé, “Nítorí ọ̀wọ́n èso ní erúkùsù ilẹ̀ Lárúbáwá ni Allāhu fi ṣàdéhùn ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èso fún àwọn mùsùlùmí nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra Rẹ̀; nítorí pé àwọn Lárúbáwá fẹ́ràn ọtí àmupara ni Allāhu fi bá wọn pèsè ọtí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ sílẹ̀ dè wọ́n nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra Rẹ̀; nítorí pé àwọn Lárúbáwá fẹ́ràn àgbèrè ṣíṣe ni Allāhu fi bá wọn pèsè obìnrin ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ sílẹ̀ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan àwọn mùsùlùmí nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra Rẹ̀!” Èsì: Ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn nasọ̄rọ̄ wọ̀nyí, yàtọ̀ sí pé ó ń fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bí aláwàdà kẹríkẹrì, ó tún jẹ́ kí á mọ̀ pé wọn kò retí ìkẹ́ kan kan lọ́run ní tiwọn. Tí ó bá jẹ́ pé, wọ́n ń retí ìkẹ́ kan ní ọ̀run, irú ìkẹ́ wo gan-an ni wọ́n ń retí nígbà náà? Síwájú sí i, kì í kúkú ṣe Lárúbáwá nìkan ni mùsùlùmí. Gbogbo àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu ni mùsùlùmí. Àwọn nasọ̄rọ̄ ṣe wá ń sọ̀rọ̀ bí ẹni pé nítorí Lárúbáwá nìkan ni Allāhu fi dá Ọgbà Ìdẹ̀ra! Ìgbádùn inú Ọgbà Ìdẹ̀ra wulẹ̀ pọ̀ tayọ èso, ọtí tí kì í pani àti obìnrin. Àmọ́ sá, kò wulẹ̀ sí ìgbádùn kan kan fún àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́run bí kò ṣe Iná gbére. (50) Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, tí wọn yóò máa bira wọn léèrè ìbéèrè.
|
| | | أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 37 - Suuratu Sooffaat الأحد 23 يوليو 2023, 6:26 pm | |
| (51) Òǹsọ̀rọ̀ kan nínú wọn yóò sọ pé: "Dájúdájú èmi ní ọ̀rẹ́ kan (52) tí ó ń wí pé, “Ṣé dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn onígbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Àjíǹde? (53) Ṣé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò san wá ní ẹ̀san ni?” (54) Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀yin yóò yọjú wo (ẹni náà tí kò gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ àjíǹde)?” (55) Ó yọjú wò ó. Ó sì rí i láààrin gbùngbùn nínú iná Jẹhīm. (56) Ó (sì) sọ pé: “Mó fi Allāhu búra, ìwọ fẹ́ẹ̀ kó ìparun bá mi tán. (57) Àti pé tí kì í bá ṣe ìdẹ̀ra Olúwa mi ni, èmi náà ìbá wà nínú ẹni tí wọ́n máa mú wá sínú Iná. (58) Àwa kò sá níí kú mọ́ báyìí? (59) Àfi ikú wa àkọ́kọ́. Wọn kò sì níí jẹ àwa níyà. (60) Dájúdájú èyí, òhun ni èrèǹjẹ ńlá.” (61) Nítorí irú èyí, kí àwọn olùṣẹ̀sìn máa ṣẹ̀sìn lọ. (62) Ǹjẹ́ ìyẹn l’ó lóore jùlọ ní ibùdésí ni tàbí igi zaƙūm (igi ẹlẹ́gùn-ún)? (63) Dájúdájú Àwa ṣe é ní àdánwò fún àwọn alábòsí. (64) Dájúdájú òhun ni igi kan tí ó máa hù jáde láti ìdí iná Jẹhīm. (65) Èso rẹ̀ dà bí orí àwọn èṣù. (66) Dájúdájú wọn yóò máa jẹ nínú rẹ̀. Wọ́n sì máa jẹ ẹ́ ní àjẹyo bámúbámú. (67) Lẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò mu àwọnúwẹ̀jẹ̀ olómi gbígbóná tó gbóná parí lé e lórí. (68) Lẹ́yìn náà, dájúdájú ibùpadàsí wọn ni iná Jẹhīm. (69) Dájúdájú wọ́n bá àwọn bàbá wọn ní olùṣìnà. (70) Àwọn náà sì ń yára tẹ̀lé orípa wọn. (71) Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ẹni àkọ́kọ́ ti ṣìnà ṣíwájú wọn. (72) Dájúdájú A ti rán àwọn olùkìlọ̀ sí wọn. (73) Nítorí náà, wo bí àtubọ̀tán àwọn ẹni-akìlọ̀-fún ti rí. (74) Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo). (75) Dájúdájú (Ànábì) Nūh pè Wá. A sì dára ní olùjẹ́pè.
|
| | | أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 37 - Suuratu Sooffaat الأحد 23 يوليو 2023, 6:26 pm | |
| (76) A gba òun àti àwọn ará ilé rẹ̀ là kúrò nínú ìbànújẹ́ ńlá náà. (77) A dá àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ sí lẹ́yìn rẹ̀. (78) A sì fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn. (79) Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) Nūh láààrin gbogbo ẹ̀dá. (80) Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere). (81) Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo. (82) Lẹ́yìn náà, A tẹ àwọn yòókù rì sínú agbami. (83) Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm wà nínú ìjọ (tí ó tẹ̀lé ìlànà) rẹ̀.¹ 1. Ìyẹn ni pé, ẹ̀sìn Ànábì Nūh ni ẹ̀sìn Ànábì ’Ibrọ̄hīm - aleehimọ sọlātu wa salām -, ẹ̀sìn ’Islām. (84) (Ẹ rántí) nígbà tí ó dojú kọ Olúwa rẹ̀ pẹ̀lú ọkàn mímọ́. (85) (Rántí) nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: "Kí ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún? (86) Ṣé ẹ̀ ń gbèrò láti sọ irọ́ di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu? (87) Kí sì ni èrò ọkàn yín sí Olúwa gbogbo ẹ̀dá?”¹ 1. Ìyẹn ni pé, ẹ̀san rere ni ẹ̀ ń retí ni tàbí ẹ̀san aburú? (88) Ó ṣíjú wo àwọn ìràwọ̀ ní wíwò kan. (89) Ó sì sọ pé: “Dájúdájú ó rẹ̀ mí.” (90) Nítorí náà, wọ́n pa á tì, wọ́n sì lọ. (91) Nígbà náà, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn òrìṣà wọn. Ó sì sọ pé: “Ṣé ẹ kò níí jẹun ni? (92) Kí ni ó ṣe yín tí ẹ kò sọ̀rọ̀?” (93) Nígbà náà, ó dojú lílù kọ wọ́n pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún (ó sì rún wọn wómúwómú). (94) (Àwọn abọ̀rìṣà) sáré wá dojú kọ ọ́. (95) Ó sọ pé: “Ṣé ẹ óò máa jọ́sìn fún n̄ǹkan tí ẹ gbẹ́ kalẹ̀ lére ni? (96) Allāhu l’Ó sì dá ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.” (97) Wọ́n wí pé: “Ẹ mọ ilé kan fún un, kí ẹ sì jù ú sínú iná.” (98) Wọ́n gbèrò ète sí i. A sì sọ wọ́n di ẹni yẹpẹrẹ. (99) Ó sọ pé: “Dájúdájú mo máa lọ sí (ìlú tí) Olúwa mi (pa mí láṣẹ láti lọ). Ó sì máa tọ́ mi sọ́nà (láti dé ibẹ̀).¹ 1. Ìyẹn ìlú Ṣām. (100) Olúwa mi, ta mí lọ́rẹ ọmọ nínú àwọn ẹni rere.”
|
| | | أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 37 - Suuratu Sooffaat الأحد 23 يوليو 2023, 6:27 pm | |
| (101) A sì fún un ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin kan tí ó máa ní ìfaradà. (102) Nígbà tí (ọmọ náà) dàgbà, tí ó tó bá (bàbá rẹ̀) ṣe iṣẹ́, (bàbá rẹ̀) sọ pé: "Ọmọ mi, dájúdájú èmi lá àlá pé dájúdájú mò ń dúńbú rẹ. Nítorí náà, wòye sí i, kí ni o rí sí i." Ó sọ pé: “Bàbá mi, ṣe ohun tí Wọ́n pa láṣẹ fún ọ. O máa bá mi nínú àwọn onísùúrù, tí Allāhu bá fẹ́.” (103) Nígbà tí àwọn méjèèjì juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀, tí (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sì dojú¹ (ọmọ) rẹ̀ bolẹ̀, 1. Ìtúmọ̀ “jẹbīn” ni iwájú orí. (104) A pè é (báyìí) pé, ’Ibrọ̄hīm, (105) o kúkú ti mú àlá náà ṣẹ. Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere). (106) Dájúdájú èyí, òhun ni àdánwò pọ́nńbélé. (107) A sì fi àgbò ńlá ṣèràpadà rẹ̀. (108) A tún fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn. (109) Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. (110) Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere). (111) Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo. (112) A tún fún un ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ’Ishāƙ, (ó máa jẹ́) Ànábì. (Ó sì máa wà) nínú àwọn ẹni rere. (113) Àti pé A fún òun àti ’Ishāƙ ní ìbùkún. Ẹni rere àti alábòsí pọ́nńbélé (tó ń ṣàbòsí sí) ẹ̀mí ara rẹ̀ wà nínú àrọ́mọdọ́mọ àwọn méjèèjì.¹ 1. Bẹ̀rẹ̀ láti āyah 100 títí dé āyah 113, ó ti hàn kedere pé: (ìkíní) Ànábì ’Ismā‘īl - kí ọlà Allāhu máa bá a - ni àkọ́bí Ànábì ’Ibrọ̄hīm - kí ọlà Allāhu máa bá a -; (ìkejì) Ànábì ’Ismā‘īl - kí ọlà Allāhu máa bá a - ni ẹni tí Allāhu Ẹlẹ́dàá pa láṣẹ pé kí Ànábì ’Ibrọ̄hīm - kí ọlà Allāhu máa bá a - pa láti fi jọ́sìn fún Òun; (ìkẹta) Kò sí ohun tó jẹmọ́ ẹ̀jẹ́ àti ìmúṣẹ ẹ̀jẹ́ nínú àlá àti ìṣẹ̀lẹ̀ náà; (ìkẹrin) Ìkíní kejì àwọn ọmọ méjèèjì náà ni ẹni ìbùkún. Àmọ́, àwọn nasọ̄rọ̄, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti àṣà wọn, orúkọ burúkú ni wọ́n ń fún Ànábì ’Ismā‘īl - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Hūd; 11:71. (114) Dájúdájú A ṣoore fún (Ànábì) Mūsā àti Hārūn. (115) A gba àwọn méjèèjì àti ìjọ àwọn méjèèjì là kúrò nínú ìbànújẹ́ ńlá náà. (116) A tún ṣàrànṣe fún wọn. Àwọn ni wọ́n jẹ́ olùborí (ọ̀tá wọn). (117) A sì fún àwọn méjèèjì ní Tírà tó yanjú. (118) A tún fi àwọn méjèèjì mọ̀nà tààrà. (119) A fún àwọn méjèèjì ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn. (120) Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) Mūsā àti Hārūn. (121) Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere). (122) Dájúdájú àwọn méjèèjì wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo. (123) Dájúdájú (Ànábì) ’Ilyās wà nínú àwọn Òjíṣẹ́. (124) (Ẹ rántí) nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù Allāhu ni? (125) Ṣé ẹ óò máa pe òrìṣà kan, ẹ sì máa fi Ẹni tó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá sílẹ̀?¹ 1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Mu’minūn; 23:14.
|
| | | أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 37 - Suuratu Sooffaat الأحد 23 يوليو 2023, 6:28 pm | |
| (126) (ẹ̀ ń fi) Allāhu (sílẹ̀), Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́?” (127) Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, wọ́n máa mú wọn wá sínú Iná. (128) Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo). (129) A fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn. (130) Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) ’Ilyās. (131) Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere). (132) Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo. (133) Dájúdájú (Ànábì) Lūt wà nínú àwọn Òjíṣẹ́. (134) (Ẹ rántí) nígbà tí A gba òun àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ là. (135) Àyàfi arúgbóbìnrin kan tí ó wà nínú àwọn tó ṣẹ́ kù lẹ́yìn (láààrin àwọn tí A parẹ́).¹ 1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah aṣ-Ṣu‘arọ̄’; 26:171. (136) Lẹ́yìn náà, A pa àwọn yòókù run. (137) Dájúdájú ẹ̀yin náà kúkú ń gba ọ̀dọ̀ wọn kọjá láàárọ̀-láàárọ̀ (138) àti ní alaalẹ́. Ṣé ẹ kò níí ṣe làákàyè ni? (139) Dájúdájú (Ànábì) Yūnus kúkú wà nínú àwọn Òjíṣẹ́. (140) (Ẹ rántí) nígbà tí ó sá lọ sínú ọkọ̀ ojú-omi tó kún (fún èrò). (141) Ó sì bá wọn ṣe kúríà papọ̀. Ó sì wà nínú àwọn tí kúrìá já.¹ 1. Ìyẹn ni pé, nígbà tí ọkọ̀ ojú-omi fẹ́ yí dànù láààrin agbami odò nítorí èrò àkúnfàya, ọ̀rọ̀ jẹmọ́ kí ẹnì kan kúrò nínú rẹ̀ bí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbogbo wọn máa bá omi lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣe ƙur‘ah. Ìyẹn ni pé, wọ́n kọ, bí àpẹ̀ẹrẹ, “orúkọ” olúkùlùkù sára n̄ǹkan kan ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Wọ́n sì kó gbogbo rẹ̀ papọ̀ sínú n̄ǹkan kan bí igbá. Wọ́n sì yan ẹnì kan láààrin wọn pé kí ó mú ẹyọ kan péré nínú rẹ̀ pẹ̀lú ìfẹnukò wọn pé, ẹni tí wọ́n bá mú “orúkọ” rẹ̀ jáde ni wọ́n máa já jù sínú omi odò nítorí kí èrò ọkọ̀ lè fà fún ìtẹ̀síwájú lórí ìrìn náà. Èyí tí wọ́n kọ orúkọ Ànábì Yūnus - kí ọlà Allāhu máa bá a - sí lára ní ọwọ́ ẹni náà bà. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n jù ú sínú odò. Ó sì ṣe wẹ́kú ẹnu ẹja. (142) Nítorí náà, ẹja gbé e mì; ó sì ń dá ara rẹ̀ lẹ́bi. (143) Nítorí náà, tí kò bá jẹ́ pé ó wà nínú àwọn olùṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu, (144) dájúdájú ìbá wà nínú ẹja títí di ọjọ́ tí wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde. (145) Nítorí náà, A jù ú sí orí ilẹ́ gban̄sasa létí omi. Ó sì jẹ́ aláìlera. (146) A sì mú igi Yẹƙtīn hù jáde láti ṣíji bò ó. (147) A tún rán an níṣẹ́ sí ọ̀kẹ́ márùn-ún (ènìyàn) tàbí kí wọ́n lékún sí i.¹ 1. Ọ̀kẹ́ márùn-ún ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún (100,000). Wàyí, àwọn nasọ̄rọ̄ lérò pé, Allāhu kò nímọ̀ nípa pàtó òǹkà ìjọ Ànábì Yūnus - kí ọlà Allāhu máa bá a - l’Ó fi mú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ wá pẹ̀lú “ ’ao” - “tàbí”. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀ rárá. Nítorí náà, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:74 fún àlàyé lórí rẹ̀. (148) Wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo. A sì fún wọn ní ìgbádùn títí di ìgbà díẹ̀. (149) Bi wọ́n léèrè wò pé: “Ṣé Olúwa rẹ l’ó ni àwọn ọmọbìnrin, tiwọn sì ni ọmọkùnrin? (150) Tàbí A dá àwọn mọlāika ní obìnrin, tí àwọn sì jẹ́ ẹlẹ́rìí?”
|
| | | أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 37 - Suuratu Sooffaat الأحد 23 يوليو 2023, 6:29 pm | |
| (151) Gbọ́, nínú irọ́ wọn ni pé dájúdájú wọ́n ń wí pé: (152) “Allāhu bímọ.” Dájúdájú òpùrọ́ sì ni wọ́n. (153) Ṣé (Allāhu) ṣẹ̀ṣà àwọn ọmọbìnrin lórí àwọn ọmọkùnrin ni? (154) Kí l’ó ń ṣe yín tí ẹ fi ń dájọ́ báyìí? (155) Ṣé ẹ kò níí lo ìrántí ni? (156) Tàbí ẹ ní ẹ̀rí tó yanjú lọ́wọ́ ni? (157) Ẹ mú tírà yín wà nígbà náà tí ẹ bá jẹ́ olódodo. (158) Wọ́n tún fi ìbátan sáààrin (Allāhu) àti àlùjànnú! Àwọn àlùjànnú sì ti mọ̀ pé, dájúdájú wọ́n kúkú máa mú àwọn wá sínú Iná ni. (159) Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀). (160) Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo). (161) Dájúdájú ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún (lẹ́yìn Allāhu), (162) ẹ kò lè fi ṣi ẹnì kan kan lọ́nà (163) àfi ẹni tí ó bá fẹ́ wọ inú iná Jẹhīm. (164) Kò sí ẹnì kan nínú àwa (mọlāika) àfi kí ó ní ibùdúró tí wọ́n ti mọ̀. (165) Dájúdájú àwa, a kúkú wà ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ni. (166) Àti pé dájúdájú àwa, àwa kúkú ni olùṣàfọ̀mọ́ (fún Allāhu). (167) Wọ́n kúkú ń wí pé: (168) “Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú a bá ní (tírà) ìrántí kan nínú (àwọn tírà) àwọn ẹni àkọ́kọ́, (169) dájúdájú àwa ìbá jẹ́ ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).” (170) Ṣùgbọ́n wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú (Allāhu). Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.
|
| | | أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 37 - Suuratu Sooffaat الأحد 23 يوليو 2023, 6:29 pm | |
| (171) Dájúdájú ọ̀rọ̀ Wa ti ṣíwájú fún àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn Òjíṣẹ́. (172) Dájúdájú àwọn, àwọn l’a kúkú máa ṣàrànṣe fún. (173) Àti pé dájúdájú àwọn ọmọ ogun Wa, àwọn kúkú ni olùborí. (174) Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn fún ìgbà díẹ̀. (175) Àti pé máa wò wọ́n níran ná, àwọn náà ń bọ̀ wá ríran wò. (176) Ṣé ìyà Wa ni wọ́n ń wá pẹ̀lú ìkánjú? (177) Nígbà tí ó bá sọ̀kalẹ̀ sí gbàgede wọn, òwúrọ̀ ọjọ́ náà yó sì burú fún àwọn ẹni-akìlọ̀-fún. (178) Kúrò lọ́dọ̀ wọn títí di ìgbà kan ná. (179) Àti pé máa wò wọ́n níran ná, àwọn náà ń bọ̀ wá ríran wò. (180) Mímọ́ ni fún Olúwa rẹ, Olúwa (tó ni) agbára, tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀). (181) Kí àlàáfíà máa bá àwọn Òjíṣẹ́ (182) Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
|
| | | | 37 - Suuratu Sooffaat | |
|
| صلاحيات هذا المنتدى: | لاتستطيع الرد على المواضيع في هذا المنتدى
| |
| |
| |