92 - Suuratul-Lay'l
Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.  
(1) Allāhu fi alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú búra.
(2) Ó tún fi ọ̀sán nígbà tí (ọ̀sán) bá pọ́n búra.
(3) Ó tún fi Ẹni tí Ó dá akọ àti abo búra.¹
1. Allāhu Ẹlẹ́dàá ni Ẹni tí Ó dá akọ àti abo. Ó sì ń fi ara Rẹ̀ búra.
(4) Dájúdájú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni iṣẹ́ yín.
(5) Ní ti ẹni tí ó bá tọrẹ, tí ó sì bẹ̀rù (Allāhu),
(6) (tí) ó tún pe ẹ̀san rere (Ọgbà Ìdẹ̀ra) ní òdodo,
(7) A sì máa ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún un.
(8) Ní ti ẹni tí ó bá yahun, tí ó sì rí ara rẹ̀ lẹ́ni tó rọrọ̀ tayọ ẹ̀san ọ̀run,
(9) (tí) ó tún pe ẹ̀san rere (Ọgbà Ìdẹ̀ra) ní irọ́,
(10) A sì máa ṣe iṣẹ́ aburú ní ìrọ̀rùn fún un.
(11) Dúkìá rẹ̀ kò sì níí rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ nígbà tí ó bá parun, tí ó já bọ́ (sínú Iná).
(12) Dájúdájú tiWa ni (láti ṣàlàyé) ìmọ̀nà.
(13) Àti pé dájúdájú tiWa ni ọ̀run àti ayé.
(14) Nítorí náà, Mo ti fi Iná tó ń jò fòfò kìlọ̀ fún yín.
(15) Kò sí ẹni tí ó máa wọ inú rẹ̀ àfi olórí burúkú,
(16) ẹni tí ó pe òdodo ní irọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i.
(17) Wọ́n sì máa gbé (Iná) jìnnà sí olùbẹ̀rù (Allāhu),
(18) ẹni tó ń fi dúkìá rẹ̀ tọrẹ, tí ó ń ṣàfọ̀mọ́ (rẹ̀).
(19) Kò sì sí oore ìdẹ̀ra kan tí (ó ní lọ́kàn) láti gbà ní ẹ̀san ní ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni,
(20) bí kò ṣe pé láti fi wá ojú rere Olúwa rẹ̀, Ẹni Gíga jùlọ.
(21) Láìpẹ́ ó sì máa yọ́nú (sí ẹ̀san rere rẹ̀).