أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: 88 - Suuratul-Gaashiyah السبت 29 يوليو 2023, 12:35 am | |
| 88 - Suuratul-Gaashiyah Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run. (1) Ṣebí ọ̀rọ̀ nípa ohun tó máa bo ẹ̀dá mọ́lẹ̀ ti dé ọ̀dọ̀ rẹ? (2) Àwọn ojú kan yóò wálẹ̀ (ní ti ìyẹpẹrẹ) ní ọjọ́ yẹn. (3) Wọ́n ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó (ni nílé ayé). (4) Wọ́n sì máa wọ inú Iná tó gbóná janjan (ní ọ̀run). (5) Wọ́n sì máa fún (wọn) ní omi ìṣẹ́lẹ̀rú gbígbóná mu. (6) Kò sí oúnjẹ kan fún wọn àyàfi igi ẹlẹ́gùn-ún gbígbẹ. (7) Kò níí mú wọn sanra. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ebi. (8) Àwọn ojú kan yó sì kún fún ìgbádùn ní ọjọ́ yẹn (9) nítorí pé (ó) yọ́nú sí (ẹ̀san) iṣẹ́ rẹ̀. (10) (Ó máa) wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra gíga. (11) Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ nínú rẹ̀. (12) Omi ìṣẹ́lẹ̀rú tó ń ṣàn wà nínú rẹ̀. (13) Àwọn ibùsùn tí wọ́n gbé sókè wà nínú rẹ̀, (14) àti àwọn ife ìmumi tí wọ́n gbé kalẹ̀ (sí àrọ́wọ́tó wọn), (15) àti àwọn ìrọ̀rí tí wọ́n tò sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn, (16) àti àwọn ìtẹ́ àtẹ́ẹ̀ká. (17) Nítorí náà, ṣé wọn kò wòye sí ràkúnmí, bí A ti ṣẹ̀dá rẹ̀ ni; (18) àti sánmọ̀, bí A ti ṣe gbé e sókè; (19) àti àpáta, bí A ti ṣe gbé e nàró (sínú ilẹ̀); (20) àti ilẹ̀, bí A ti ṣe tẹ́ ẹ sílẹ̀ pẹrẹsẹ? (21) Nítorí náà, ṣèrántí. Ìwọ kúkú ni olùṣèràntí. (22) Ìwọ kì í ṣe ajẹni-nípá lórí wọn (23) àfi ẹni tí ó bá pẹ̀yìndà (sí òdodo), tí ó sì ṣàì gbàgbọ́. (24) Allāhu sì máa jẹ ẹ́ níyà tó tóbi jùlọ. (25) Dájúdájú ọ̀dọ̀ Wa ni àbọ̀ wọn wà. (26) Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ wọn.
|
|