|
| 17 - Suuratul-Is'raa' | |
| | كاتب الموضوع | رسالة |
---|
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: 17 - Suuratul-Is'raa' الجمعة 21 يوليو 2023, 11:35 pm | |
| 17 - Suuratul-Is'raa' Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run. (1) Mímọ́ ni fún Ẹni tí Ó mú ẹrúsìn Rẹ̀ ṣe ìrìn-àjò ní alẹ́ láti Mọ́sálásí Haram sí Mọ́sálásí Aƙsọ̄ tí A fi ìbùkún yí ká, nítorí kí Á lè fi nínú àwọn àmì Wa hàn án. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran.¹ 1. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lérò pé àlá lílá ni ìrìn-àjò òru tí Allāhu - subhānahu wa ta ‘ālā - mú Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -rìn, ohun tí ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ jùlọ ni pé, ìrìn-àjò òru náà jẹ́ ìrìn-àjò ẹ̀mí àti ara. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé Allāhu - subhānahu wa ta ‘ālā - kò sọ ọ̀rọ̀ ìrìn-àjò náà ní ìsọ àlá lílá páàpáà. Ẹ wo àgbékalẹ̀ āyah ìrìn-àjò ẹ̀mí àti ara yìí sí àgbékalẹ̀ àwọn āyah àlá lílá wọ̀nyí nínú sūrah Yūsuf; 12:4 & 43, sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:102 àti sūrah al-Fat-h; 48:27. Bákan náà, ìrìn-àjò náà ìbá jẹ́ àlá lílá, àwọn ọ̀ṣẹbọ ìbá tí ṣe àtakò sí i. Àti pé ṣíṣe àtakò sí ìrìn-àjò náà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀ṣẹbọ nípa bí ìró ìṣẹ̀lẹ̀ ìrìn-àjò òru náà ṣe ga tayọ òye wọn ló kó wọn sínú àdánwò tí Allāhu - subhānahu wa ta ‘ālā - sọ nípa rẹ̀ nínú āyah 60 nínú sūrah yìí. Kíyè sí i, gbólóhùn “subhān-llathī” ìbá tí bẹ̀rẹ̀ āyah yìí, Tí ó bá jẹ́ pé ìrìn-àjò ojú àlá lásán ni. Síwájú sí i, àwọn n̄ǹkan pàtàkì pàtàkì ni Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - fojú rí nínú àwọn sánmọ̀ àti lókè sánmọ̀ keje lórí ìrìn-àjò òru rẹ̀ tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - mú un rìn. Nínú ìrìn-àjò òru náà ni Allāhu sì ti fún un ní àwọn ìrun wákàtí = = márùn-ún. Àmọ́ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò fojú rí Allāhu rárá - subhānahu wa ta‘ālā - ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ ìyá wa ‘Ā’iṣah - kí Allāhu yọ́nú sí i - tí ó sọ pé: “Dájúdájú òpùrọ́ ni ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ pé (Ànábì) Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - fojú rí Olúwa rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìyá wa, ‘Ā’iṣah - kí Allāhu yọ́nú sí i - fi sūrah al-’An‘ām; 6:103 àti sūrah aṣ-Ṣūrọ̄; 42:51 ṣe ẹ̀rí ọ̀rọ̀ náà.” (al-Bukāriy) Síwájú sí i, àwọn mùsùlùmí, wọ́n ti ń kí ìrun ṣíwájú ìrìn-àjò òru náà, àmọ́ kì í ṣe ìrun wákàtí márùn-ún, kódà kì í ṣe ìrun ọ̀ran-anyàn. Ìrìn-àjò òru àti ìgun-sánmọ̀-lọ Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ló bí ìrun ọ̀ran-anyàn àti ìrun wákàtí márùn-ún ojoojúmọ́. Síwájú sí i, ọ̀rọ̀ yìí “bi ‘abdih” (ẹrúsìn Rẹ̀). Ẹrúsìn Rẹ̀ nínú āyah yìí kò dúró fún ẹnì kan bí kò ṣe Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Àpẹ̀ẹrẹ àyè mìíràn nìyí: sūrah al-Kahf; 18:1, sūrah al-Furƙọ̄n; 25:1, sūrah az-Zumọr; 39:36, sūrah an-Najm; 53:10 àti sūrah al-Hadīd; 57:9. Àyè ẹyọ kan péré tí “‘abdah” kò ti dúró fún un, Allāhu - subhānahu wa ta ‘ālā - kúkú dárúkọ ẹni tí “‘abdah” dúró fún níbẹ̀. Àyè náà ni sūrah Mọryam; 19:2. (2) A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. A sì ṣe é ní ìmọ̀nà fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. (A sì sọ) pé: “Ẹ má ṣe mú aláààbò kan lẹ́yìn Mi.” (3) (Ẹ jẹ́) àrọ́mọdọ́mọ àwọn tí A gbé gun ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú (Ànábì) Nūh. Dájúdájú (Nūh) jẹ́ ẹrúsìn, olùdúpẹ́. (4) A sì fi mọ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl nínú Tírà pé: “Dájúdájú ẹ máa ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀ nígbà mejì.¹ Dájúdájú ẹ tún máa ṣègbéraga tó tóbi.” 1. Ìbàjẹ́ tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl ní ìsọ ti ìkìlọ̀, òhun ni pípa tí wọ́n máa fi ọwọ́ ara wọn pa Ànábì Zakariyyā - kí ọlà Allāhu máa bá a - àti pípa tí wọ́n tún máa fi ọwọ́ ara wọn pa Ànábì Yahyā - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Wọ́n kúkú padà fọwọ́ ara wọn pa àwọn Ànábì méjèèjì náà ni, bàbá àti ọmọ - kí ọlà Allāhu máa bá àwọn méjèèjì -. (5) Nítorí náà, nígbà tí àdéhùn fún àkọ́kọ́ nínú méjèèjì bá ṣẹlẹ̀,¹ A máa gbé àwọn ẹrúsìn Wa kan, tí wọ́n lágbára gan-an, dìde si yín. Wọn yóò dá rògbòdìyàn sílẹ̀ láààrin ìlú (yín). Ó jẹ́ àdéhùn kan tí A máa mú ṣẹ. 1. Ìyẹn ni pé, nígbà tí àsìkò ìyà bá tó fún wọn lórí ìbàjẹ́ wọn tí wọ́n á ṣe nígbà àkọ́kọ́. (6) Lẹ́yìn náà, A dá ìṣẹ́gun lórí wọn padà fún yín. A sì fi àwọn dúkìá àti àwọn ọmọ ṣèrànwọ́ fún yín. A sì ṣe yín ní ìjọ tó pọ̀ jùlọ. (7) Tí ẹ bá ṣe rere, ẹ ṣe rere fún ẹ̀mí ara yín. Tí ẹ bá sì ṣe aburú, fún ẹ̀mí ara yín ni. Nígbà tí àdéhùn ìkẹ́yìn bá dé, (A óò gbé ọmọ ogun mìíràn dìde) nítorí kí wọ́n lè kó ìbànújẹ́ ba yín àti nítorí kí wọ́n lè wọ inú Mọ́sálásí gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe wọ̀ ọ́ nígbà àkọ́kọ́ àti nítorí kí wọ́n lè pa ohun tí (àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl) jọba lórí rẹ̀ run pátápátá. (8) Ó lè jẹ́ pé Olúwa yín máa ṣààánú yín. Tí ẹ bá sì padà (síbi ẹ̀ṣẹ̀), A máa padà (síbi ẹ̀san). A sì ṣe iná Jahanamọ ní ẹ̀wọ̀n fún àwọn aláìgbàgbọ́. (9) Dájúdájú al-Ƙur’ān yìí, ó ń fini mọ̀nà sí ọ̀nà tààrà, ó sì ń fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo tó ń ṣe àwọn iṣẹ́ rere ní ìró ìdùnnú pé dájúdájú ẹ̀san tó tóbi wà fún wọn. (10) Dájúdájú àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́, A ti pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ dè wọ́n. (11) Ènìyàn ń tọrọ aburú bí ó ṣe ń tọrọ ohun rere; ènìyàn sì jẹ́ olùkánjú.¹ 1. Ìyẹn ni pé, ènìyàn ń yára ṣépè lásìkò ìbínú. Ó sì yẹ kó ṣe sùúrù ni. (12) A ṣe alẹ́ àti ọ̀sán ní àmì méjì; A pa àmì alẹ́ rẹ́, A sì ṣe àmì ọ̀sán ní ìríran¹ nítorí kí ẹ lè wá oore àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín àti nítorí kí ẹ lè mọ òǹkà àwọn ọdún àti ìṣírò (àwọn ọjọ́). Gbogbo n̄ǹkan ni A ti ṣàlàyé rẹ̀ ní ìfọ́síwẹ́wẹ́.² 1. Àmì alẹ́ ni òṣùpá, àmì ọ̀sán ni òòrùn. Ní ìpìlẹ̀, àti òṣùpá àti òòrùn ni wọ́n dìjọ ní ìmọ́lẹ̀ irú kan náà; wọ́n sì dìjọ mọ́lẹ̀ gbòlà. Pẹ̀lú bí ìmọ́lẹ̀ òṣùpá àti ìmọ́lẹ̀ òòrùn ṣe mọ́lẹ̀ gbòlà bákan náà yìí, kò lè rọrùn fún àwa ẹ̀dá láti rí oorun sùn, láti gbin n̄ǹkan ọ̀gbìn, láti mọ ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ àti òpin ọjọ́ pẹ̀lú òǹkà ọdún. Àmọ́ nípasẹ̀ àánú Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - lórí wa, Allāhu pa ìmọ́lẹ̀ gbòlà ti òṣùpá rẹ́. Ó sì ṣẹ́ ti òòrùn kù. Al-Hamdulillāh rọbbil-‘ālamīn. (Ẹ wo àlàyé yìí ní kíkún nínú al-Ƙurtubiy.) 2, Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Ani‘ām; 6:114. (13) Ènìyàn kọ̀ọ̀kan, A ti so iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ mọ́ ọn lọ́rùn. A sì máa mú ìwé kan jáde fún un ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó máa pàdé rẹ̀ ní ṣíṣí sílẹ̀. (14) Ka ìwé (iṣẹ́) rẹ. Ìwọ ti tó ní olùṣírò fún ẹ̀mí ara rẹ lónìí. (15) Ẹnikẹ́ni tó bá mọ̀nà, ó mọ̀nà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tó bá sì ṣìnà, ó ń ṣìnà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò níí ru ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn.¹ A ò sì níí jẹ àwọn ẹ̀dá níyà títí A fi máa gbé òjíṣẹ́ kan dìde (sí wọn). 1. Bẹ́ẹ̀ ni àyàfi tí ó bá jẹ́ òun ni onísábàbí rẹ̀ ní ìbámu sí sūrah al-‘Ankabūt; 29:13. (16) Nígbà tí A bá sì gbèrò láti pa ìlú kan run, A máa pa àwọn onígbẹdẹmukẹ ìlú náà láṣẹ (rere). Àmọ́ wọ́n máa ṣèbàjẹ́ sínú ìlú. Ọ̀rọ̀ náà yó sì kò lé wọn lórí. A ó sì pa wọ́n rẹ́ pátápátá.¹ 1. Āyah yìí jọ sūrah al-’Ani‘ām; 6:123. (17) Mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parun lẹ́yìn (Ànábì) Nūh! Olúwa rẹ tó ní Alámọ̀tán, Olùríran nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹrúsìn Rẹ̀. (18) Ẹni tí ó bá ń gbèrò (oore) ayé yìí (nìkan), A máa taari ohun tí A bá fẹ́ sí i nínú rẹ̀ ní kíákíá fún ẹni tí A bá fẹ́. Lẹ́yìn náà, A máa ṣe iná Jahanamọ fún un; ó máa wọ inú rẹ̀ ní ẹni yẹpẹrẹ, ẹni ẹ̀kọ̀. (19) Ẹni tí ó bá sì gbèrò (oore) ọ̀run, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rẹ̀ fún ọ̀run náà, ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, àwọn wọ̀nyẹn, wọ́n máa fi ẹ̀san rere àdìpèlé dúpẹ́ iṣẹ́ wọn fún wọn. (20) Àwọn wọ̀nyí (tó ń gbèrò oore ayé) àti àwọn wọ̀nyí (tó ń gbèrò oore ọ̀run), gbogbo wọn ni À ń ṣe oore ayé fún láti inú ọrẹ Olúwa rẹ. Wọn kò níí dí ọrẹ Olúwa rẹ lọ́wọ́ (fún ìkíní kejì nílé ayé). (21) Wo bí A ṣe fún apá kan wọn lóore àjùlọ lórí apá kan (nílé ayé). Dájúdájú tọ̀run tún tóbi jùlọ ní ipò, ó sì tóbi jùlọ lóore àjùlọ. (22) Má ṣe mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu nítorí kí o má baà jókòó (sínú Iná) ní ẹni àbùkù, ẹni ẹ̀kọ̀ (tí wọ́n máa dá ìṣòro rẹ̀ dá). (23) Olúwa rẹ pàṣẹ pé: “Ẹ má ṣe jọ́sìn fún ẹnì kan àyàfi Òun. Kí ẹ sì ṣe dáadáa sí àwọn òbí (yín) méjèèjì. Tí ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì tàbí ìkíní kejì wọn bá dàgbà sí ọ lọ́dọ̀, má ṣe ṣíọ̀ sí wọn, má ṣe jágbe mọ́ wọn. Máa bá àwọn méjèèjì sọ ọ̀rọ̀ àpọ́nlé. (24) Rẹ apá rẹ nílẹ̀ dáadáa (bọ̀wọ̀) fún àwọn méjèèjì nípa ṣíṣe àánú wọn. Kí o sì sọ pé: “Olúwa Ẹlẹ́dàá mi, kẹ́ àwọn méjèèjì nítorí pé, àwọn méjèèjì náà tọ́ mi ní kékeré.” (25) Olúwa yín nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ń bẹ nínú ẹ̀mí yín, tí ẹ bá jẹ́ ẹni rere. Dájúdájú Ó ń jẹ́ Aláforíjìn fún àwọn olùronúpìwàdà. |
| | | أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 17 - Suuratul-Is'raa' الجمعة 21 يوليو 2023, 11:36 pm | |
| (26) Ẹ fún ẹbí ní ẹ̀tọ́ rẹ̀. (Ẹ fún) mẹ̀kúnnù àti onírìn-àjò (tí agara dá ní n̄ǹkan). Kí ẹ sì má ṣe ná dúkìá yín ní ìná-àpà. (27) Dájúdájú àwọn àpà, wọ́n jẹ́ ọmọ ìyá Èṣù. Aláìmoore sì ni Èṣù jẹ́ sí Olúwa rẹ̀. (28) Tí o bá ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn (ìyẹn àwọn aláìní) láti wá ìkẹ́ kan tí ò ń retí láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, bá wọn sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀lẹ̀. (29) Má di ọwọ́ rẹ mọ́ ọrùn rẹ (má ya ahun), má sì tẹ́ ẹ sílẹ̀ tán pátápátá (má ya àpà), kí o má baà jókòó kalẹ̀ ní ẹni èébú (tí o bá jẹ́ ahun), ẹni tí kò níí sí lọ́wọ́ rẹ̀ mọ́ (tí o bá jẹ́ àpà). (30) Dájúdájú Olúwa rẹ l’Ó ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn). Dájúdájú Ó ń jẹ́ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀, Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. (31) Ẹ má pa àwọn ọmọ yín nítorí ìpáyà òṣì. Àwa l’À ń pèsè fún àwọn àti ẹ̀yin. Dájúdájú pípa wọ́n jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó tóbi. (32) Ẹ má ṣe súnmọ́ àgbèrè. Dájúdájú ó jẹ́ ìwà burúkú. Ó sì burú ní ojú ọ̀nà. (33) Ẹ má pa ẹ̀mí tí Allāhu ṣe (pípa rẹ̀) ní èèwọ̀ àyàfi ní ọ̀nà ẹ̀tọ́.¹ Ẹni tí wọ́n bá pa ní ìpa àbòsí, dájúdájú A ti fún alámòjúútó rẹ̀ ní agbára (láti gbẹ̀san). Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe tayọ ẹnu-ààlà níbi ìpànìyàn (nítorí pé) dájúdájú A máa ran (ẹbí òkú) lọ́wọ́ (láti gbẹ̀san).² 1. Àwọn ọ̀nà ẹ̀tọ́ tí ó lè mú kí ìjọba ’Islām pa ènìyàn ni kí ènìyàn jẹ̀bi ẹ̀sùn àgbèrè lẹ́yìn tí onítọ̀ún ti ní ọkọ tàbí aya, ìpànìyàn lọ́nà àìtọ́ àti fífi ẹ̀sìn ’Islām sílẹ̀. 2. Ọ̀nà ìgbẹ̀san fún ẹ̀sùn ìpànìyàn wà nínú sūrah an-Nisā’; 4: 92-93 àti sūrah al-Mọ̄’idah; 5:45. (34) Ẹ má ṣe súnmọ́ dúkìá ọmọ òrukàn, àyàfi ní ọ̀nà tó dára jùlọ, títí ó fi máa dàgbà dáadáa. Kí ẹ sì mú àdéhùn ṣẹ. Dájúdájú àdéhùn jẹ́ ohun tí A ó bèèrè nípa rẹ̀. (35) Ẹ wọn òṣùwọ̀n kún nígbà tí ẹ bá wọ̀n ọ́n. Ẹ fi ìwọ̀n tó tọ́¹ wọ̀n ọ́n. Ìyẹn lóore jùlọ, ó sì dára jùlọ ní ìkángun. 1. Ìyẹn òṣùwọ̀n tí kò tẹ̀ tí kò wọ́. (36) Má ṣe tẹ̀lé ohun tí ìwọ kò nímọ̀ nípa rẹ̀. Dájúdájú ìgbọ́rọ̀, ìríran àti ọkàn; ìkọ̀ọ̀kan ìwọ̀nyẹn ni A óò bèèrè nípa rẹ̀. (37) Má ṣe rìn lórí ilẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga; dájúdájú ìwọ kò lè dá ilẹ̀ lu, ìwọ kò sì lè ga tó àpáta. (38) Gbogbo ìyẹn, aburú rẹ̀ jẹ́ ohun ìkórira lọ́dọ̀ Olúwa rẹ. (39) Ìyẹn wà nínú ohun tí Olúwa rẹ fi ránṣẹ́ sí ọ nínú ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n (al-Ƙur’ān). Má ṣe mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu kí wọ́n má baà jù ọ́ sínú iná Jahanamọ ní ẹni àbùkù, ẹni ẹ̀kọ̀. (40) Ṣé Olúwa yín fi àwọn ọmọkùnrin ṣà yín lẹ́ṣà, Òun wá mú àwọn ọmọbìnrin nínú àwọn mọlāika (ní tiRẹ̀)? Dájúdájú ẹ mà ń sọ ọ̀rọ̀ ńlá (tó burú). (41) Dájúdájú A ti ṣe àlàyé sínú al- Ƙur’ān yìí nítorí kí wọ́n lè lo ìṣítí. Síbẹ̀síbẹ̀ kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe sísá (fún ìrántí). (42) Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé àwọn ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń wí, wọn ìbá wá ọ̀nà láti súnmọ́ (Allāhu) Onítẹ̀ẹ́-ọlá ni.”¹ 1. Ìyẹn ni pé, àwọn òrìṣà gan-an ń wá oore sọ́dọ̀ Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā -. (43) Mímọ́ ni fún Un. Ó sì ga ní gíga tó tóbi tayọ ohun tí wọ́n ń wí (ní àìda nípa Rẹ̀). (44) Àwọn sánmọ̀ méjèèje, ilẹ̀ àti àwọn tí wọ́n wà nínú wọn ń ṣe àfọ̀mọ́ fún Un. Kò sì sí kiní kan àfi kí ó máa ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Un.¹ Ṣùgbọ́n ẹ kò lè gbọ́ àgbọ́yé àfọ̀mọ́ wọn. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláfaradà, Aláforíjìn. 1. Ìyẹn ni pé, kò sí kiní kan tí kì í ṣe àfọ̀mọ́ fún Allāhu kúrò níbi gbogbo àdínkù àti àbùkù, tí yó sì máa yìn Ín lógo pé, O pé tán pátápátá. (45) Nígbà tí o bá ń ké al-Ƙur’ān, A máa fi gàgá ààbò sáààrin ìwọ àti àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. (46) A fi èbìbò bo ọkàn wọn nítorí kí wọ́n má baà gbọ́ ọ yé. (A tún fi) èdídí sínú etí wọn. Nígbà tí o bá sì dárúkọ Olúwa rẹ nìkan ṣoṣo nínú al-Ƙur’ān, wọ́n máa pẹ̀yìndà tí wọn yóò máa sá lọ. (47) Àwa nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń gbọ́ nígbà tí wọ́n bá ń tẹ́tí sí ọ àti nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, nígbà tí àwọn alábòsí bá ń wí pé: “Ẹ kò tẹ̀lé ẹnì kan bí kò ṣe ọkùnrin eléèdì kan.” (48) Wo bí wọ́n ṣe fún ọ ní àwọn àfiwé (burúkú)! Nítorí náà, wọ́n ti ṣìnà; wọn kò sì lè mọ̀nà. (49) Wọ́n wí pé: “Ṣé nígbà tí a bá ti di egungun, tí a ti jẹrà, ṣé Wọ́n máa gbé wa dìde ní ẹ̀dá titun ni?” (50) Sọ pé: “Ẹ di òkúta tàbí irin.
|
| | | أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 17 - Suuratul-Is'raa' الجمعة 21 يوليو 2023, 11:37 pm | |
| (51) Tàbí (kí ẹ di) ẹ̀dá kan nínú ohun tí ó tóbi nínú ọkàn yín.” Síbẹ̀síbẹ̀ wọn yóò wí pé: “Ta ni Ó máa dá wa padà (fún àjíǹde)?” Sọ pé: “Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá yín ní ìgbà àkọ́kọ́ ni.” Síbẹ̀síbẹ̀ wọn yóò mi orí wọn sí ọ (ní ti àbùkù). Nígbà náà, wọn yóò wí pé: “Ìgbà wo ni?” Sọ pé: “Ó lè jẹ́ pé ó ti súnmọ́.” (52) Ọjọ́ tí Allāhu yóò pè yín. Ẹ sì máa jẹ́pè pẹ̀lú ẹyìn Rẹ̀. Ẹ sì máa lérò pé ẹ kò gbé ilé ayé bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀. (53) Sọ fún àwọn ẹrúsìn Mi pé kí wọ́n máa sọ èyí tó dára jùlọ (nínú ọ̀rọ̀). Dájúdájú Èṣù yóò máa dá yánpọn-yánrin sílẹ̀ láààrin wọn. Dájúdájú Èṣù jẹ́ ọ̀tá pọ́nńbélé fún ènìyàn. (54) Olúwa yín nímọ̀ jùlọ nípa yín. Tí Ó bá fẹ́, Ó máa kẹ yín. Tàbí tí Ó bá sì fẹ́, Ó máa jẹ yín níyà. A kò rán ọ pé kí o jẹ́ olùṣọ́ lórí wọn. (55) Olúwa rẹ nímọ̀ jùlọ nípa àwọn tó ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Dájúdájú A ti ṣe oore àjùlọ fún apá kan àwọn Ànábì lórí apá kan. A sì fún (Ànábì) Dāwūd ní Zabūr. (56) Sọ pé: “Ẹ pe àwọn tí ẹ sọ nípa wọn - láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ - pé wọ́n jẹ́ ọlọ́hun lẹ́yìn Rẹ̀, (ẹ máa rí i pé) wọn kò ní ìkápá láti gbé ìnira kúrò tàbí láti ṣe ìyípadà kan fún yín.” (57) Àwọn wọ̀nyẹn tí wọ́n ń pè (lẹ́yìn Rẹ̀) ń wá àtẹ̀gùn sọ́dọ̀ Olúwa wọn ni! - Èwo nínú wọn ló súnmọ́ (Allāhu) jùlọ (báyìí)? - Àwọn náà ń retí ìkẹ́ Allāhu, wọ́n sì ń páyà ìyà Rẹ̀. Dájúdájú ìyà Olúwa rẹ jẹ́ ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún. (58) Kò sí ìlú kan (tó ṣàbòsí) àfi kí Àwa pa á rẹ́ ṣíwájú Ọjọ́ Àjíǹde tàbí kí Á jẹ ẹ́ níyà líle. Ìyẹn ti wà ní kíkọ sílẹ̀ nínú Tírà (Laohul-Mahfūṭḥ). (59) Àti pé kò sí ohun tí ó dí Wa lọ́wọ́ láti fi àwọn àmì (iṣẹ́ ìyanu) ránṣẹ́ bí kò ṣe pé àwọn ẹni àkọ́kọ́ ti pè é nírọ́. A fún ìjọ Thamūd ní abo ràkúnmí; (àmì) tó fojú hàn kedere ni. Àmọ́ wọ́n ṣàbòsí sí i. A ò sì níí fi àwọn àmì ránṣẹ́ bí kò ṣe fún ìdẹ́rùbà. (60) (Rántí) nígbà tí A sọ fún ọ pé: “Dájúdájú Olúwa rẹ yí àwọn ènìyàn po (pẹ̀lú agbára Rẹ̀). Àti pé A kò ṣe ìran (wíwò) tí A fi hàn ọ́ àti igi (zaƙūm) tí A ṣẹ́bi lé nínú al-Ƙur’ān ní kiní kan bí kò ṣe pé (ó jẹ́) àdánwò fún àwọn ènìyàn. À ń dẹ́rù bà wọ́n, àmọ́ kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe ìwà àgbéré tó tóbi.¹ 1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ āyah àkọ́kọ́ tó bẹ̀rẹ̀ sūrah yìí fún àgbọ́yé āyah yìí. Bákan náà, híhù tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - mú igi zaƙūm hù jáde láti inú Iná jẹ́ ohun tí ó tako òye àwọn aláìgbàgbọ́. Wọ́n takò ó. Àtakò wọn sì di àdánwò fún wọn. (61) (Rántí) nígbà tí A sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ kí (Ànábì) Ādam.” Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àfi ’Iblīs. Ó wí pé: “Ṣé kí n̄g forí kanlẹ̀ kí ẹni tí O fi ẹrẹ̀ ṣẹ̀dá rẹ̀ ni?” (62) Ó wí pé: “Sọ fún mi nípa èyí tí O gbé àpọ́nlé fún lórí mí, (nítorí kí ni?) Dájúdájú tí O bá lè lọ́ mi lára di Ọjọ́ Àjíǹde, dájúdájú mo máa jẹgàba lórí àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ àfi àwọn díẹ̀.” (63) (Allāhu) sọ pé: “Máa lọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ọ nínú wọn, dájúdájú iná Jahanamọ ni ẹ̀san yín. (Ó sì jẹ́) ẹ̀san tó kún kẹ́kẹ́. (64) Fi ohùn rẹ kó ẹni tí agbára rẹ bá ká nínú wọn láyà jẹ. Fi àwọn ọmọ ogun ẹlẹ́sin rẹ àti ọmọ ogun ẹlẹ́sẹ̀ rẹ pè wọ́n (sínú ìṣìnà). Kópa pẹ̀lú wọn nínú àwọn dúkìá àti àwọn ọmọ.¹ Kí o sì ṣe àdéhùn fún wọn.” Èṣù kò sì níí ṣe àdéhùn kan fún wọn bí kò ṣe ẹ̀tàn. ² 1. Ìyẹn ni pé, Èṣù yóò bá wọn lọ́wọ́ sí fífi harām wá owó àti dúkìá. Bákan náà, Èṣù yóò bá wọn lọ́wọ́ sí bíbí ọmọ ní ìpasẹ̀ ìbàjẹ́ àti àgbèrè ṣíṣe. 2. Ohùn Èṣù ni orin àlùjó oníran-ànran, eré ṣíṣe àti ayò títa. Àwọn ọmọ ogun ẹlẹ́sin àti àwọn ọmọ ogun ẹlẹ́sẹ̀ tí Èṣù ń lò fún àwọn iṣẹ́ rẹ̀ wọ̀nyí ni gbogbo olùpèpè sínú ìyapa àṣẹ Allāhu àti àṣẹ àwọn Ànábì Rẹ̀ (‘aleehim sọlātun wa salām). (65) Dájúdájú àwọn ẹrúsìn Mi, kò sí agbára kan fún ọ lórí wọn. Olúwa rẹ sì tó ní Olùṣọ́. (66) Olúwa yín ni Ẹni tó ń mú ọkọ̀ ojú-omi rìn fún yín nítorí kí ẹ lè wá nínú oore àjùlọ Rẹ̀. Dájúdájú Ó ń jẹ́ Aláàánú fún yín. (67) Nígbà tí ìnira bá fọwọ́ bà yín lójú omi, ẹni tí ẹ̀ ń pè yó sì dòfo (mọ yín lọ́wọ́) àfi Òun nìkan (Allāhu). Nígbà ti Ó bá sì gbà yín là (tí ẹ) gúnlẹ̀ sórí ilẹ̀, ẹ̀ ń gbúnrí (kúrò lọ́dọ̀ Rẹ̀). Ènìyàn sì jẹ́ aláìmoore. (68) Ṣé ẹ fọkàn balẹ̀ pé (Allāhu) kò lè mú apá kan ilẹ̀ ri mọ yín lẹ́sẹ̀ ni? Tàbí pé kò lè fi òkúta iná ránṣẹ́ si yín? Lẹ́yìn náà, ẹ̀ ko níí rí olùṣọ́ kan tí ó máa gbà yín là. (69) Tàbí ẹ fọkàn balẹ̀ pé (Allāhu) kò níí padà mu yín wá sí (orí omi) nígbà mìíràn ni; tí Ó máa rán ìjì atẹ́gùn si yín, tí Ó sì máa tẹ̀ yín rì (sínú omi) nítorí pé ẹ ṣàì moore? Lẹ́yìn náà, ẹ ò sì níí rí olùrànlọ́wọ́ kan tó máa ba yín gbẹ̀san lára Wa. (70) Dájúdájú A ṣe àpọ́nlé fún àwọn ọmọ (Ànábì) Ādam; A gbé wọn rìn lórí ilẹ̀ àti lórí omi; A fún wọn ní ìjẹ-ìmu nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa; A sì ṣoore àjùlọ fún wọn gan-an lórí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn tí A dá. (71) Ní ọjọ́ tí A óò máa pe gbogbo ènìyàn pẹ̀lú aṣíwájú wọn¹. Nígbà náà, ẹnikẹ́ni tí A bá fún ní ìwé (iṣẹ́) rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni wọn yóò máa ka ìwé (iṣẹ́) wọn. A ò sì níí fi ìbójú kóró èso dàbínú ṣàbòsí sí wọn. 1. “aṣíwájú wọn” nínú āyah yìí lè túmọ̀ sí ọ̀kan nínú àwọn wọ̀nyí: Ànábì ìjọ kọ̀ọ̀kan, tàbí ẹni tí ẹnì kọ̀ọ̀kan tẹ̀lé n’ílé ayé tàbí tírà tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ fún ìjọ kọ̀ọ̀kan tàbí ìwé iṣẹ́ ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan. (72) Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ afọ́jú (nípa ’Islām) nílé ayé yìí, òun ni afọ́jú ní ọ̀run. Ó sì (ti) ṣìnà jùlọ. (73) Wọ́n fẹ́ẹ̀ kó ìyọnu bá ọ nípa n̄ǹkan tí A mú wá fún ọ ní ìmísí nítorí kí o lè hun n̄ǹkan mìíràn nípa Wa. Nígbà náà, wọn ìbá mú ọ ní ọ̀rẹ́ àyò. (74) Tí kò bá jẹ́ pé A fi ẹsẹ̀ rẹ rinlẹ̀ ni, dájúdájú o fẹ́ẹ̀ fi n̄ǹkan díẹ̀ tẹ̀ sí ọ̀dọ̀ wọn. (75) Nígbà náà, Àwa ìbá jẹ́ kí o tọ́ ìlọ́po (ìyà) ìṣẹ̀mí ayé àti ìlọ́po (ìyà lẹ́yìn) ikú wò. Lẹ́yìn náà, ìwọ kò níí rí olùrànlọ́wọ́ kan tí ó máa gbà ọ́ sílẹ̀ níbi ìyà Wa.
|
| | | أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 17 - Suuratul-Is'raa' الجمعة 21 يوليو 2023, 11:37 pm | |
| (76) Wọ́n fẹ́ẹ̀ pin ọ́ lẹ́mìí nínú ìlú nítorí kí wọ́n lè lé ọ jáde kúrò nínú rẹ̀. Nígbà náà, àwọn náà kò níí wà nínú rẹ̀ lẹ́yìn rẹ tayọ ìgbà díẹ̀. (77) (Èyí jẹ́) ìṣe (Allāhu) lórí àwọn tí A ti rán níṣẹ́ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Wa ṣíwájú rẹ. O ò sì níí rí ìyípadà kan fún ìṣe Wa. (78) Gbé ìrun kíkí dúró ní (ìgbà tí) òòrùn bá yẹ̀tàrí títí di ìgbà tí alẹ́ yóò fi lẹ́. Àti pé ìrun Subh, dájúdájú ìrun Subh jẹ́ ohun tí (àwọn mọlāika alẹ́ àti ọ̀sán) yóò jẹ́rìí sí.¹ 1. Ní ṣísẹ̀n̄tẹ̀lé, ìrun méjì tí a óò kí nígbà tí òòrùn bá yẹ̀tàrí ni ìrun Ṭḥuhur àti ìrun ‘Asr. Ìrun méjì tí a óò kí nígbà tí ilẹ̀ bá ṣú ni ìrun Mọgrib àti ìrun ‘Iṣā’. Irun Subh sì ni āyah yìí dàpè ni Ƙur’ānul-fajr. (79) Àti pé nínú òru, fi kíké al-Ƙur’ān (lórí ìrun) ṣàì sùn. (Èyí jẹ́) iṣẹ́ àṣegbọrẹ fún ọ. Láìpẹ́, Olúwa rẹ yóò gbé ọ sí ipò kan tí àwọn ẹ̀dá máa ti yìn ọ́.¹ 1. “Ipò tí gbogbo ẹ̀dá máa ti yìn ọ́” dúró fún ibi tí Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - máa ti ṣìpẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá lọ́dọ̀ Allāhu - ta‘ālā - ní Ọjọ́ Àjíǹde. (80) Sọ pé: “Olúwa mi, mú mi wọ inú ìlú ní ìwọ̀lú ọ̀nà òdodo. Mú mi jáde kúrò nínú ìlú ní ìjáde ọ̀nà òdodo. Kí O sì fún mi ní àrànṣe tó lágbára láti ọ̀dọ̀ Rẹ. (81) Sọ pé: “Òdodo dé. Irọ́ sì sá lọ. Dájúdájú irọ́ jẹ́ ohun tí ó máa sá lọ.” (82) À ń sọ ohun tí ó jẹ́ ìwòsàn àti ìkẹ́ kalẹ̀ sínú al-Ƙur’ān fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo. (al-Ƙur’ān) kò sì ṣàlékún fún àwọn alábòsí bí kò ṣe òfò. (83) Nígbà tí A bá ṣèdẹ̀ra fún ènìyàn, ó máa gbúnrí (kúrò níbi òdodo), ó sì máa takété (sí àṣẹ Allāhu). Nígbà tí aburú bá sì fọwọ́ bà á, ó máa di olùsọ̀rètínù. (84) Sọ pé: “Ẹnì kọ̀ọ̀kan ń ṣiṣẹ́ lórí àdámọ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n Olúwa yín nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tí ó mọ̀nà.” (85) Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa ẹ̀mí. Sọ pé: “Ẹ̀mí ń bẹ nínú àṣẹ Olúwa mi. A ò sì fún yín nínú ìmọ̀ bí kò ṣe díẹ̀.” (86) Àti pé dájúdájú tí A bá fẹ́ ni, A ìbá kúkú gba ìmísí tí A fi ránṣẹ́ sí ọ (kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ). Lẹ́yìn náà, ìwọ kò níí rí aláàbò kan tí ó máa là ọ́ lọ́dọ̀ Wa. (87) Àyàfi ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ (ni kò fi ṣe bẹ́ẹ̀). Dájúdájú oore àjùlọ Rẹ̀ lórí rẹ tóbi. (88) Sọ pé: “Dájúdájú tí àwọn ènìyàn àti àlùjànnú bá parapọ̀ láti mú irú al-Ƙur’ān yìí wá, wọn kò lè mú irú rẹ̀ wá, apá kan wọn ìbáà jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún apá kan.”¹ 1. Kíyè sí i, āyah yìí kò túmọ̀ sí pé àwọn olórí kunkun ènìyàn kan kò níí gbìyànjú láti hun ọ̀rọ̀ jọ láti pè é ní Kur’ān. Ṣebí àwọn kan mú àwọn àròsọ kan wá, wọ́n sì ń pè é ní “Bíbélì”. Àmọ́ èyíkéyìí àròsọ náà yóò máa jẹ́ ọ̀rọ̀ tí kò níí ní ìbùkún, kò sì níí ti ipasẹ̀ mọlāika wá. Ó tún máa jẹ́ ọ̀rọ̀ tí àwọn mùsùlùmí kó níí tẹ́wọ́ gbà. Kódà ọ̀rọ̀ àdáhun bẹ́ẹ̀ máa kún fún ìtakora, irọ́, ìsọkúsọ àti ọ̀rọ̀ ẹlẹ́mìí Èṣù. (89) Dájúdájú A ti fi àkàwé kọ̀ọ̀kan ṣàlàyé (oríṣiríṣi) fún àwọn ènìyàn sínú al-Ƙur’ān yìí. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn kọ̀ láti gbà àfi àtakò sá. (90) Wọ́n sì wí pé: “A kò níí gbàgbọ́ nínú rẹ títí o máa fi mú omi ìṣẹ́lẹ̀rú ṣẹ́yọ fún wa. (91) Tàbí kí o ní ọgbà oko dàbínù àti ọgbà oko àjàrà, tí o sì máa jẹ́ kí àwọn odò ṣàn kọ já dáadáa láààrin wọn. (92) Tàbí kí o jẹ́ kí sánmọ̀ já lù wá ní kélekèle gẹ́gẹ́ bí o ṣe sọ (pé Allāhu lè ṣe bẹ́ẹ̀). Tàbí kí o mú Allāhu àti àwọn mọlāika wá (bá wa) ní ojúkojú. (93) Tàbí kí o ní ilé wúrà kan, tàbí kí o gun òkè sánmọ̀ lọ. A kò sì níí gba gígun-sánmọ̀ rẹ gbọ́ títí o fi máa sọ tírà kan tí a óò máa ké kalẹ̀ fún wa.” Sọ pé: “Mímọ́ ni fún Olúwa mi, ǹjẹ́ mo jẹ́ kiní kan bí kò ṣe Òjíṣẹ́ abara?” (94) Kò sí ohun tí ó kọ̀ fún àwọn ènìyàn láti gbàgbọ́ ní òdodo nígbà tí ìmọ̀nà dé bá wọn àfi kí wọ́n wí pé: “Ṣé Allāhu rán Òjíṣẹ́ abara níṣẹ́ ni?” (95) Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé àwọn mọlāika wà lórí ilẹ̀ ayé, tí wọ́n ń rìn kiri, (tí wọ́n ń gbé lórí ilẹ̀) pẹ̀lú ìfàyàbalẹ̀, A ìbá sọ mọlāika kan kalẹ̀ fún wọn láti inú sánmọ̀ (láti jẹ́) Òjíṣẹ́.”¹ 1. Ìyẹn ni pé, tí ẹ̀yin bá jẹ́ mọlāika ni, mọlāika ni ìbá jẹ́ Òjíṣẹ́ yín. Àmọ́ ènìyàn ni yín, Òjíṣẹ́ yín náà gbọ́dọ̀ jẹ́ ènìyàn. Kíyè sí i, nígbà tí Allāhu - tó ga jùlọ - kò níí sọ mọlāika di Òjíṣẹ́ láààrin àwọn ènìyàn, báwo wá ni Allāhu yó ṣe wá sọ ara Rẹ̀ di Òjíṣẹ́ láààrin àwọn ènìyàn? Ìyẹn ni pé, irọ́ ńlá ni láti ẹnu àwọn nasọ̄rọ̄ láti sọ pé Ọlọ́hun fúnra Rẹ̀ l’ó wá jíṣẹ́ ara Rẹ̀ ní àwòrán ‘Īsā ọmọ Mọryam láààrin àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl! Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n ń sọ nípa Rẹ̀ ní irọ́. (96) Sọ pé: “Allāhu tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin. Dájúdájú Ó ń jẹ́ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀, Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.” (97) Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi mọ̀nà (’Islām), òun ni olùmọ̀nà. Ẹnikẹ́ni tí Ó bá ṣì lọ́nà, o kò níí rí àwọn olùrànlọ́wọ́ kan fún wọn lẹ́yìn Rẹ̀. Àti pé A máa kó wọn jọ ní Ọjọ́ Àjíǹde ní ìdojúbolẹ̀. (Wọn yóò di) afọ́jú, ayaya àti odi. Iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn. Nígbàkígbà tí Iná bá jó lọọlẹ̀, A óò máa ṣàlékún iná (mìíràn) tó ń jó fún wọn. (98) Ìyẹn ni ẹ̀san wọn nítorí pé, dájúdájú wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa. Wọ́n sì wí pé: “Ṣé nígbà tí a bá ti di egungun, tí a sì ti jẹrà, ṣé wọ́n tún máa gbé wa dìde ní ẹ̀dá titun ni?” (99) Ṣé wọn kò wòye pé dájúdájú Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ lágbára láti ṣẹ̀dá irú wọn (mìíràn)? Ó sì máa fún wọn ní gbèdéke àkókò kan, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn alábòsí kọ̀ láti gbà àfi àtakò sá. (100) Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé ẹ̀yin l’ẹ ni ìkápá lórí àwọn ilé ọrọ̀ ìkẹ́ Olúwa mi ni, nígbà náà ẹ̀yin ìbá diwọ́ mọ́ ọn ní ti ìbẹ̀rù òṣì. Ènìyàn sì jẹ́ ahun.
|
| | | أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 17 - Suuratul-Is'raa' الجمعة 21 يوليو 2023, 11:38 pm | |
| (101) Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní àwọn àmì mẹ́sàn-án tó yanjú. Bi àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl léèrè wò. Rántí, nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ wọn, Fir‘aon wí fún un pé: “Dájúdájú èmi lérò pé eléèdì ni ọ́, Mūsā.” (102) (Ànábì Mūsā) sọ pé: “O kúkú mọ̀ pé kò sí ẹni tí ó sọ àwọn (àmì) wọ̀nyí kalẹ̀ bí kò ṣe Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀; (ó sì jẹ́) ìmọ̀ àmọ̀dájú àti ẹ̀rí. Dájúdájú èmi náà lérò pé ẹni ìparun ni ọ́, Fir‘aon.” (103) Nítorí náà, (Fir‘aon) fẹ́ kó ìdààmú bá wọn lórí ilẹ̀. A sì tẹ òun àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ rì pátápátá. (104) A sì sọ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lẹ́yìn (ikú) rẹ̀ pé: “Ẹ máa gbé orí ilẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n nígbà tí Àdéhùn Ìkẹ́yìn bá dé, A óò mú gbogbo yín wá ní àpapọ̀ (ní ọjọ́ ẹ̀san). (105) A sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó sì sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo. A kò sì rán ọ níṣẹ́ bí kò ṣe pé (kí o jẹ́) oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀.¹ 1. Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni oníròó-ìdùnnú fún èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, òun náà sì ni olùkìlọ̀ fún èrò inú Iná. Jíjẹ́ tí Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - jẹ́ oníròó-ìdùnnú túmọ̀ sí pé láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni a óò ti máa gbọ́ ìró nípa ìjọ́sìn, ìwà dáradára àti ọ̀nà ìṣẹ̀mí tí a óò fi rí Ọgbà Ìdẹ̀ra wọ̀. Àti pé lára ìró ìdùnnú tí A óò máa gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Ànábì ni òdíwọ̀n ẹ̀san tí a lè rí gbà lórí àwọn iṣẹ́ Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀, jíjẹ́ tí Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - jẹ́ olùkìlọ̀ túmọ̀ sí pé, láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni a óò ti máa gbọ́ ìkìlọ̀ lórí àwọn n̄ǹkan tí ó lè múni wọ inú Iná. Àti pé lára ìkìlọ̀ tí A óò máa gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Ànábì ni òdíwọ̀n àti irú ìyà tí ẹ̀dá lè rí lórí àwọn iṣẹ́ Iná. Al-Ƙur’ān àti Hadīth Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni orísun fún ìmọ̀ nípa ìró-ìdùnnú àti ìkìlọ̀. Nítorí náà, ọ̀kan nínú àwọn abẹ̀sìnjẹ́ (ohun tó ń ba ẹ̀sìn jẹ́) mọ́ mùsùlùmí lọ́wọ́ ni kí ẹlòmíìràn nínú ìjọ rẹ̀ sọra rẹ̀ di oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀ nítorí pé, onítọ̀ún ti sọra rẹ̀ di arímìísígbà. Ìmísí sánmọ̀ sì ti dòpin. (106) Àti pé al-Ƙur’ān, A ṣàlàyé rẹ̀ (fún ọ) nítorí kí o lè ké e fún àwọn ènìyàn pẹ̀lú pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́. A sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ díẹ̀ díẹ̀.¹ 1. Àwọn nasọ̄rọ̄ sọ pé, “Āyah yìí àti sūrah al-’Insān; 76:23 tako sūrah ad-Dukān; 44:3 àti sūrah al-Ƙọdr’; 97:1.” Èsì: Èyí jẹ́ “ìtakora tófẹ́jọbẹ́ẹ̀”, kì í ṣe “ìtakora tóríbẹ́ẹ̀” nítorí pé, oríṣi ìsọ̀kalẹ̀ méjì ló wà fún al-Ƙur’ān. Ìsọ̀kalẹ̀ kìíní ni ìsọ̀kalẹ̀ olódidi láti inú Laohul-Mahfuṭḥ sínú sánmọ̀ ilé ayé. Ìsọ̀kalẹ̀ yìí ló ṣẹlẹ̀ nínú òru Laelatul-ƙọdr. Èyí ló jẹyọ nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:185, sūrah ad-Dukān; 44:3 àti sūrah al-Ƙọdr; 97:1. Ìsọ̀kalẹ̀ kejì ni ìsọ̀kalẹ̀ onídíẹ̀díẹ̀ láti inú sánmọ̀ ilé ayé sórí ilẹ̀ ayé. Èyí ṣẹlẹ̀ fún òǹkà ọdún mẹ́tàlélógún. Ìsọ̀kalẹ̀ yìí ni āyah yìí ń sọ nípa rẹ̀. (107) Sọ pé: “Ẹ gbàgbọ́ nínú al-Ƙur’ān gbọ́ tàbí ẹ kò gbàgbọ́ nínú rẹ̀, dájúdájú àwọn tí A fún ní ìmọ̀ ṣíwájú (ìsọ̀kalẹ̀) rẹ̀, nígbà tí wọ́n bá ń ké e fún wọn, wọn yóò dojú bolẹ̀, tí wọ́n yóò forí kanlẹ̀ (fún Allāhu). (108) Wọ́n ń sọ pé: “Mímọ́ ni fún Olúwa wa. Dájúdájú àdéhùn Olúwa wa máa wá sí ìmúṣẹ ni.” (109) Wọ́n ń dojú bolẹ̀, tí wọ́n yóò máa sunkún (fún Allāhu. Al-Ƙur’ān) sì ń ṣàlékún ìtẹríba fún wọn. (110) Sọ pé: “Ẹ pe Allāhu tàbí ẹ pe ar-Rahmọ̄n (Àjọkẹ́-ayé).”¹ Èyíkéyìí tí ẹ bá fi pè É (nínú rẹ̀), ṣebí tiRẹ̀ ni àwọn orúkọ tó dára jùlọ. Má ṣe kígbe lórí ìrun (àti àdúà) rẹ. Má sì ṣe wà ní ìdákẹ́ rọ́rọ́. Wá ọ̀nà sáààrin méjèèjì yẹn. 1. Pípe Allāhu tàbí ar-Rahmọ̄n tàbí èyíkéyìí nínú àwọn orúkọ Allāhu tí ó dára jùlọ, kò túmọ̀ sí fífa orúkọ kan nínú àwọn orúkọ Allāhu pẹ̀lú òǹkà púpọ̀ bíi sísọ pé Allāhu, Allāhu … tàbí ar-Rahmọ̄n, ar-Rahmọ̄n … Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìlànà àwọn onibid‘ah. Èyí tí ó tọ sunnah ni lílo àwọn orúkọ náà nínú gbólóhùn. Kí á wo àwọn ìhun àti àgbékalẹ̀ àdúà Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - nínú àwọn tírà hadīth lórí èyí tàbí tíra Hisnul-muslim “Odi Ìṣọ́ Mùsùlùmí” ti ààfáà wa Ƙọhtọ̄niy. (111) Kí o sì sọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu,¹ Ẹni tí kò fi ẹnì kan ṣe ọmọ. Kò sì ní akẹgbẹ́ nínú ìjọba. Kò sì ní ọ̀rẹ́ kan torí àìlágbára.”² Gbé títóbi fún Un gan-an. 1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Fātihah;1:2. 2. Ìyẹn ni pé, mímú tí Allāhu - tó ga jùlọ - bá mú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ ní ọ̀rẹ́ kì í ṣe nítorí ìrànlọ́wọ́ wọn tàbí ìkúnlọ́wọ́ wọn, bí kò ṣe nítorí pé, Allāhu gan-an ní Olùrànlọ́wọ́ wọn, Alágbára àti Olùborí lórí wọn.
|
| | | | 17 - Suuratul-Is'raa' | |
|
مواضيع مماثلة | |
|
| صلاحيات هذا المنتدى: | لاتستطيع الرد على المواضيع في هذا المنتدى
| |
| |
| |