85 - Suuratul-Buruuj
Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.  
(1) (Allāhu) fi sánmọ̀ tí àwọn ibùsọ̀ (òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀) wà nínú rẹ̀ búra.
(2) Ó tún fi ọjọ́ tí wọ́n ṣe ní àdéhùn (ìyẹn Ọjọ́ Àjíǹde) búra.
(3) Ó tún fi olùjẹ́rìí àti ohun tó jẹ́rìí sí búra.
(4) A ṣẹ́bi lé àwọn tó gbẹ́ kòtò (iná),
(5) (ìyẹn) iná tí wọ́n ń fi igi kò (nínú kòtò).
(6) (Rántí) nígbà tí wọ́n jókòó sí ìtòsí rẹ̀.
(7) Wọ́n sì ń wo ohun tí wọ́n ń ṣe fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
(8) Wọn kò rí àlèébù kan (wọn kò sì kórira kiní kan) lára wọn bí kò ṣe pé, wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu, Alágbára, Ẹlẹ́yìn,
(9) Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ni Ẹlẹ́rìí lórí gbogbo n̄ǹkan.
(10) Dájúdájú àwọn tó fi ìnira kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí wọn kò ronú pìwàdà, ìyà iná Jahanamọ ń bẹ fún wọn. Ìyà iná tó ń jó sì wà fún wọn.
(11) Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tiwọn ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá.
(12) Dájúdájú ìgbámú ti Olúwa rẹ mà le.
(13) Dájúdájú Òun ni Ó pìlẹ̀ (ẹ̀dá), Ó sì máa dá (ẹ̀dá) padà (fún àjíǹde).
(14) Òun ni Aláforíjìn, Olólùfẹ́ (ẹ̀dá),
(15) Òun l’Ó ni Ìtẹ́-ọlá, Ológo (Ẹni-ọ̀wọ̀ jùlọ),
(16) Olùṣe-ohun-t’Ó-bá-fẹ́.
(17) Ṣebí ìró àwọn ọmọ ogun ti dé ọ̀dọ̀ rẹ,
(18) (ọmọ ogun) Fir‘aon àti (ìjọ) Thamūd?
(19) Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ sì ń pe òdodo ní irọ́.
(20) Allāhu sì yí wọn ká lẹ́yìn wọn.
(21) Àmọ́ sá, ohun (tí A fi ránṣẹ́ sí ọ ni) al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé,
(22) tí ó wà nínú wàláà tí wọ́n ń ṣọ́.