أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: 75 - Suuratul-Qiyaamah الجمعة 28 يوليو 2023, 11:58 pm | |
| 75 - Suuratul-Qiyaamah Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run. (1) Èmi (Allāhu) ń fi Ọjọ́ Àjíǹde búra. (2) Mo tún ń fi ẹ̀mí tó máa dá ara rẹ̀ ní ẹ̀bi búra. (3) Ṣé ènìyàn lérò pé A kò níí kó àwọn eegun rẹ̀ jọ ni? (4) Rárá. (À ń jẹ́) Alágbára láti to eegun ọmọníka rẹ̀ dọ́gba. 1.Àwọn ọmọníka ọwọ́ àti ọmọníka ẹsẹ̀, ọ̀tún rẹ̀ àti òsì rẹ̀. Ẹ tún wo sūrah al-Wāƙi‘ah; 56:60-61 àti sūrah al-Mọ̄‘rij; 70:40-41. (5) Rárá ènìyàn fẹ́ máa ṣe aburú lọ bẹ́ẹ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ̀ (6) ni ó fi ń bèèrè pé: “Ìgbà wo ni Ọjọ́ Àjíǹde?” (7) Nígbà tí ojú bá rí ìdààmú tó sì yà sílẹ̀ tí kò lè padé, (8) àti (nígbà) tí òṣùpá bá wọ̀ọ̀kùn, (9) àti (nígbà) tí wọ́n bá pa òòrùn àti òṣùpá pọ̀ mọ́ra wọn tí ìmọ́lẹ̀ méjèèjì pòóró, (10) ènìyàn yóò wí ní ọjọ́ yẹn pé: “Níbo ni ibùsásí wà?” (11) Rárá, kò sí ibùsásí. (12) Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni ibùdúró ní ọjọ́ yẹn. (13) Wọ́n máa fún ènìyàn ní ìró ní ọjọ́ yẹn nípa ohun tó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tó fi kẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀). (14) Ṣebí ènìyàn dá ara rẹ̀ mọ̀, (15) ìbáà mú àwọn àwáwí rẹ̀ wá. (16) Má ṣe gbé ahọ́n rẹ sí ìmísí láti kánjú ké e. (17) Dájúdájú Àwa l’A máa ṣe àkójọ rẹ̀ (sínú ọkàn rẹ) àti kíké rẹ̀. (18) Nígbà tí A bá ń ké e (fún ọ), kí o sì máa tẹ̀lé kíké rẹ̀. (19) Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe àlàyé rẹ̀ fún ọ. (20) Kò rí bẹ́ẹ̀, bí kò ṣe pé, ẹ nífẹ̀ẹ́ ayé ni. (21) Ẹ sì ń gbé ọ̀run jù sílẹ̀. (22) Àwọn ojú kan ní ọjọ́ yẹn yóò tutù (fún ìdùnnú). (23) Olúwa wọn ni wọn yóò máa wò. (24) Àwọn ojú kan ní ọjọ́ yẹn sì máa bàjẹ́. (25) (Ojú náà) yóò mọ̀ dájú pé wọ́n máa fi aburú kan òhun.
|
|
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 75 - Suuratul-Qiyaamah الجمعة 28 يوليو 2023, 11:59 pm | |
| (26) Kò rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí ẹ̀mí bá dé gògòńgò. (27) A sì máa sọ pé: “Ǹjẹ́ olùpọfọ̀ kan wà bí (tí ó máa pọfọ̀ láti gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú)? (28) Ó sì máa dá a lójú pé dájúdájú ìpínyà ayé ti dé. (29) Ojúgun yó sì lọ́mọ́ ojúgun. (30) Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì ni wíwa ẹ̀dá lọ ní ọjọ́ yẹn. (31) Kò kúkú gba òdodo gbọ́, kò sì kírun. (32) Ṣùgbọ́n ó pe òdodo ní irọ́. Ó sì kẹ̀yìn sí i. (33) Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ń ṣe fáàrí. (34) (Ìparun nílé ayé) ló tọ́ sí ọ jùlọ (lórí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ wọ̀nyẹn). (Ìyẹn) ló sì tọ́ sí ọ jùlọ. (35) Lẹ́yìn náà, (Iná) ló tọ́ sí ọ jùlọ (ní ọ̀run). (Ìyẹn) ló sì tọ́ sí ọ jùlọ. (36) Ṣé ènìyàn lérò pé A máa fi òun sílẹ̀ lásán ni? (37) Ṣé kò ti jẹ́ àtọ̀ mọnī tí wọ́n dà jáde sínú àpòlùkẹ́ ni? (38) Lẹ́yìn náà, ó di ẹ̀jẹ̀ dídì. (Allāhu) sì ṣẹ̀dá (rẹ̀). Ó sì ṣe é tó dọ́gba jálẹ̀ léèyàn. (39) (Allāhu) sì ṣe ìran méjì jáde láti ara rẹ̀, akọ àti abo. (40) Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó ṣe ìyẹn kò níí ní agbára láti jí àwọn òkú dìde bí?
|
|