أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: 69 - Suuratul-Haaqqah الخميس 27 يوليو 2023, 1:16 am | |
| 69 - Suuratul-Haaqqah Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run. (1) Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà! (2) Kí ni Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà? (3) Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà? (4) Àwọn ìjọ Thamūd àti ìjọ ‘Ād pe Àjíǹde (ajámọláya bí àrá) ní irọ́.¹ 1. Nínú àwọn orúkọ fún Ọjọ́ Àjíǹde ni Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà àti Ajámọláyà bí àrá. (5) Ní ti ìjọ Thamūd, wọ́n fi igbe tó tayọ ẹnu-ààlà pa wọ́n rẹ́. (6) Ní ti ìjọ ‘Ād, wọ́n fi atẹ́gùn líle tó tayọ ẹnu-ààlà pa wọ́n rẹ́. (7) Ó dẹ ẹ́ sí wọn fún òru méje àti ọ̀sán mẹ́jọ láì dáwọ́ dúró. O sì máa rí ìjọ náà tí wọ́n ti kú sínú rẹ̀ bí ẹni pé kùkùté igi dàbínù tó ti luhò nínú ni wọ́n.¹ 1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Fussilat; 41:16. (8) Ǹjẹ́ o rí ẹnì kan nínú wọn tó ṣẹ́ kù bí? (9) Fir‘aon àti àwọn tó ṣíwájú rẹ̀ àti àwọn ìlú tí wọ́n dojú rẹ̀ bolẹ̀ dé pẹ̀lú àwọn àṣìṣe. (10) Wọ́n yapa Òjíṣẹ́ Olúwa wọn. Ó sì gbá wọn mú ní ìgbámú tóléken̄kà. (11) Dájúdájú nígbà tí omi tayọ ẹnu-ààlà. A gbe yín gun ọkọ̀ ojú-omi. (12) Nítorí kí Á lè fi ṣe ìrántí fún yín àti nítorí kí etí tó ń ṣọ́ n̄ǹkan lè ṣọ́ ọ. (13) Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún ikú ní fífọn ẹyọ kan, (14) tí wọ́n gbé ilẹ̀ àti àpáta sókè, tí wọ́n sì rún méjèèjì wómúwómú ní rírún ẹ̀ẹ̀ kan, (15) ní ọjọ́ yẹn ni Ìṣẹ̀lẹ̀ máa ṣẹlẹ̀. (16) Àti pé sánmọ̀ yó fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Ó sì máa fúyẹ́ gẹgẹ ní ọjọ́ yẹn. (17) Àwọn mọlāika sì máa wà ní àwọn ẹ̀gbẹ́ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àti pé ní ọjọ́ yẹn, lókè wọn, àwọn (mọlāika) mẹ́jọ ni wọ́n máa ru Ìtẹ́ Olúwa rẹ. (18) Ní ọjọ́ yẹn, wọn yóò máa ṣẹ́rí yín wá (fún ìṣírò-iṣẹ́). Kò sì níí sí àṣírí yín kan tó máa pamọ́ (fún Wa). (19) Nítorí náà, ní ti ẹni tí wọ́n bá fún ní tírà rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ó máa sọ pé: “Ẹ gbà, ẹ ka tírà mi wò. (20) Dájúdájú èmi ti mọ àmọ̀dájú pé dájúdájú èmi yóò bá ìṣírò-iṣẹ́ mi pàdé.” (21) Nítorí náà, ó máa wà nínú ìṣẹ̀mí tó máa yọ́nú sí (22) nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra gíga. (23) Àwọn èso rẹ̀ (sì) máa wà ní àrọ́wọ́tó. (24) Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu pẹ̀lú ìgbàdún nítorí ohun tí ẹ tì síwájú nínú àwọn ọjọ́ tí ó ti ré kọjá. (25) Ní ti ẹni tí wọ́n bá sì fún ní tírà rẹ̀ ní ọwọ́ òsì rẹ̀, ó máa wí pé: “Háà! Kí wọ́n sì má fún mi ni tírà mi!¹ 1. Àwọn nasọ̄rọ̄ sọ pé, “Āyah yìí ń sọ pé ọwọ́ òsì ni àwọn aláìgbàgbọ́ máa fi gba ìwé iṣẹ́ wọn, àmọ́ sūrah al-’Inṣiƙọ̄ƙ; 84:10 ń sọ pé láti ẹ̀yìn ni wọ́n máa ti gbà á.” Wọ́n ní, “Ìtakora nìyẹn!” Èsì: Ìtakora tófẹ́jọbẹ́ẹ̀ ni, kì í ṣe ìtakora tóríbẹ́ẹ̀. Àlàyé rẹ̀ nìyí, méjéèjì ló máa ṣẹlẹ̀ sí wọn nítorí pé, ọwọ́ òsì ni aláìgbàgbọ́ máa tì bọ inú igbá-àyà rẹ̀ bọ́ sí ẹ̀yìn rẹ̀ láti fi gba ìwé iṣẹ́ rẹ̀. |
|
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 69 - Suuratul-Haaqqah الخميس 27 يوليو 2023, 1:16 am | |
| (26) Àti pé kí èmi sì má mọ ohun tí ìṣírò-iṣẹ́ mi jẹ́. (27) Háà! Kí ikú sì jẹ́ òpin (ọ̀rọ̀ ẹ̀dá). (28) Dúkìá mi kò sì rọ̀ mí lọ́rọ̀. (29) Agbára mi sì ti parun.” (30) Ẹ mú un, kí ẹ dè é ní ọwọ́ mọ́ ọrùn. (31) Lẹ́yìn náà, inú iná Jẹhīm ni kí ẹ mú un wọ̀. (32) Lẹ́yìn náà, inú ẹ̀wọ̀n tí gígùn rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin gígùn thar‘u¹ ni kí ẹ kì í sí. 1. Gígùn “Thar‘u” kan ni gígùn láti ìlú Mọkkah sí ibi tí ó jìnnà jùlọ sí ìlú Mọkkah. (33) Dájúdájú òun kì í gbàgbọ́ nínú Allāhu, Atóbi. (34) Kì í sì gba ènìyàn níyànjú láti bọ́ àwọn mẹ̀kúnnù. (35) Nítorí náà, kò níí sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan fún un níbí yìí ní òní. (36) Kò sì níí sí oúnjẹ kan (fún un) bí kò ṣe (oúnjẹ) àwọnúwẹ̀jẹ̀. (37) Kò sí ẹni tí ó máa jẹ ẹ́ bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. (38) Nítorí náà, Èmi ń fi ohun tí ẹ̀ ń fojú rí búra (39) àti ohun tí ẹ ò fojú rí. (40) Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé.¹ 1. “Ọ̀rọ̀ òjíṣẹ́” ni ìtúmọ̀ “ƙọolu rọsūl, àmọ́ al-Ƙur’ān kì í ṣe ọ̀rọ̀ Òjíṣẹ́ bí kò ṣe “Ọ̀rọ̀ Allāhu”. Àgbékalẹ̀ irúfẹ́ ọ̀rọ̀ yìí ni ṣíṣe àfitì ọ̀rọ̀ sí ọ̀dọ̀ alágbàsọ. Bákan náà, āyah yìí jọ āyah 19 nínú sūrah at-Tẹkwīr ní ìsọ, àmọ “Òjíṣẹ́” tí wọ́n gbàlérò nínú āyah ti sūrah al-Hāƙƙọh ni Òjíṣẹ́ abara, ìyẹn Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, Òjíṣẹ́ mọlāika ni wọ́n sì gbàlérò nínú āyah ti sūrah at-Tẹkwīr. Sàkánì ti ìkọ̀ọ̀kan ti jẹyọ l’ó ṣàfi hàn èyí bẹ́ẹ̀. (41) Kì í ṣe ọ̀rọ̀ eléwì. Ohun tí ẹ gbàgbọ́ kéré púpọ̀. (42) Kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ adábigba. Díẹ̀ lẹ̀ ń lò nínú ìrántí. (43) Wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá. (44) Tí ó bá jẹ́ pé (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ) dá àdápa apá kan ọ̀rọ̀ náà mọ́ Wa ni, (45) Àwa ìbá gbá a mú lọ́wọ́ ọ̀tún. (46) Lẹ́yìn náà, Àwa ìbá já isan ọrùn rẹ̀. (47) Kò sì sí ẹnì kan nínú yín tí ó máa gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ (Wa). (48) Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ìrántí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu). (49) Dájúdájú Àwa sì mọ̀ pé àwọn tó ń pe al-Ƙur’ān ní irọ́ wà nínú yín. (50) Dájúdájú al-Ƙur’ān máa jẹ́ àbámọ̀ ńlá fún àwọn aláìgbàgbọ́. (51) Dájúdájú al-Ƙur’ān ni òdodo tó dájú. (52) Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa Rẹ, Atóbi.
|
|