|
| 9 - Suuratut-Taobah | |
| | كاتب الموضوع | رسالة |
---|
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: 9 - Suuratut-Taobah الجمعة 21 يوليو 2023, 10:57 pm | |
| 9 - Suuratut-Taobah (1) (Èyí ni) ìyọwọ́-yọsẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sí àwọn tí ẹ ṣe àdéhùn fún nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ. 1. Ẹ́ẹ́rìnlé láàádọ́fà sūrah (114) ni àpapọ̀ sūrah tí ó wà nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Gbólóhùn “Bismi-llāhir-Rahmọ̄nir-Rọhīm.” sì ni ohun tí wọ́n fi ṣe ìpínrọ̀ láààrin sūrah kan àti òmíràn. Ó tún lè dá dúró lọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí āyah àkọ́kọ́ nínú sūrah al-Fātihah. Bákan náà, ó jẹ́ awẹ́ āyah gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹyọ nínú sūrah an-Naml; 27:30. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpín-sūrah ní gbólóhùn “Bismi-llāhir-Rahmọ̄nir-Rọhīm.” dúró fún jùlọ nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé, wọn kò fi pín sūrah at-Taobah sọ́tọ̀ nítorí pé Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò pa á láṣẹ fún àwọn Sọhābah láti ṣe bẹ́ẹ̀ ṣíwájú kí ó tó jáde kúrò láyé. Kò sì lẹ́tọ̀ó fún àwọn Sọhābah - kí Allāhu yọ́nú sí wọn - láti ṣe àfikún ohunkóhun sí àkọsílẹ̀ al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé yálà lójú ayé Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tàbí lẹ́yìn ikú rẹ̀. Báyìí sì ni ó ṣe di sunnah pé sūrah at-Taobah kò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú gbólóhùn ìpín-sūrah, èyí tí a mọ̀ sí gbólóhùn “Bismi-llāhir-Rahmọ̄nir-Rọhīm.” Kíyè sí i, kò sí orí-ọ̀rọ̀ kan tó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú “Ní orúkọ Ọlọ́hun.” nínú àwọn ìwé kan tí àwọn kan tún ń pè ní “Ìwé Ọlọ́hun”. Àwọn ìwé náà ìbá jẹ́ òdodo ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun, àwọn orí-ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ìbá máa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú orúkọ Ọlọ́hun tí wọ́n sọ pé Òun l’Ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀! Ẹyìn àti ọpẹ́ ni fún Allāhu, Ọba tó fi orúkọ ara Rẹ̀ ṣe ìbẹ̀rẹ̀ fún àwọn sūrah al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. (2) Nítorí náà, (ẹ̀yin ọ̀ṣẹbọ) ẹ rìn (kiri) lórí ilẹ̀ fún oṣù mẹ́rin. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú ẹ̀yin kò lè mórí bọ́ (nínú ìyà) Allāhu. Àti pé dájúdájú Allāhu yóò dójú ti àwọn aláìgbàgbọ́. (3) Ìkéde kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sí àwọn ènìyàn ní ọjọ́ Hajj Ńlá¹ ni pé, “Dájúdájú Allāhu yọwọ́yọsẹ̀ (nínú ọ̀rọ̀) àwọn ọ̀ṣẹbọ. Òjíṣẹ́ Rẹ̀ náà (yọwọ́yọsẹ̀). Tí ẹ bá ronú pìwàdà, ó sì lóore jùlọ fún yín. Tí ẹ bá gbúnrí, ẹ mọ̀ pé dájúdájú ẹ kò lè móríbọ́ nínú (ìyà) Allāhu.” Kí o sì fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro. 1. Àgékúrú fún “Hajj Ńlá” ni “Hajj”. Ìdà kejì Hajj Ńlá ni Hajj Kékeré. Hajj Kékeré ni a tún mọ̀ sí ‘Umrah. Ìyapa-ẹnu wà lórí ọjọ́ tí a lè pè ní ọjọ́ Hajj Ńlá. Ìdí ni pé, ọjọ́ Hajj Ńlá lè jẹ́ ọjọ́ ‘Arafah tàbí ọjọ́ ìgúnran tàbí àpapọ̀ ọjọ́ tí iṣẹ́ Hajj bẹ̀rẹ̀ mọ́ ọjọ́ tí ó máa parí. (4) Àyàfi àwọn tí ẹ bá ṣe àdéhùn nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ, lẹ́yìn náà, tí wọn kò sì fi ọ̀nà kan kan yẹ àdéhùn yín, tí wọn kò sì ṣàtìlẹ́yìn fún ẹnì kan kan le yín lórí. Nítorí náà, ẹ pé àdéhùn wọn fún wọn títí di àsìkò wọn. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀). (5) Nítorí náà, nígbà tí àwọn oṣù ọ̀wọ̀ bá lọ tán¹, ẹ pa àwọn ọ̀ṣẹbọ níbikíbi tí ẹ bá ti bá wọn. Ẹ mú wọn, ẹ ṣéde mọ́ wọn, kí ẹ sì ba dè wọ́n ní gbogbo ibùba. Tí wọ́n bá sì ronú pìwàdà, tí wọ́n ń kírun, tí wọ́n sì ń yọ Zakāh, ẹ yàgò fún wọn lójú ọ̀nà. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run. 1. Àwọn oṣù ọ̀wọ̀ nìwọ̀nyí: oṣù kìíní (Muharram), oṣù keje (Rajab), oṣù kọkànlá (Thul-ƙọ‘dah) àti oṣù kejìlá (Thul-hijjah). (6) Tí ẹnì kan nínú àwọn ọ̀sẹbọ bá wá ètò ààbò wá sọ́dọ̀ rẹ, ṣ’ètò ààbò fún un títí ó fi máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Allāhu. Lẹ́yìn náà, mú un dé àyè ìfọ̀kànbalẹ̀ rẹ̀. Ìyẹn nítorí pé dájúdájú àwọn ni ìjọ tí kò nímọ̀. (7) Báwo ni àdéhùn kan yóò ṣe wà fún àwọn ọ̀ṣẹbọ lọ́dọ̀ Allāhu àti lọ́dọ̀ Òjísẹ́ Rẹ̀ yàtọ̀ sí àwọn tí ẹ bá ṣe àdéhùn nítòsí Mọ́sálásí Haram? Nítorí náà, tí wọ́n bá dúró déédé pẹ̀lú yín, ẹ dúró déédé pẹ̀lú wọn. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀). (8) Báwo (ni àdéhùn kan yóò ṣe wà fún wọn) nígbà tí ó jẹ́ pé tí wọ́n bá borí yín, wọn kò níí ṣọ́ okùn ìbí àti àdéhùn. Wọ́n ń fi ẹnu wọn wí pé àwọn yọ́nú si yín, ọkàn wọn sì kọ̀ ọ́. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́. (9) Wọ́n ta àwọn āyah Allāhu ní owó pọ́ọ́kú, wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Rẹ̀. Dájúdájú àwọn (wọ̀nyí), ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ burú. (10) Àwọn ọ̀ṣẹbọ kò níí ṣọ́ okùn ìbí àti àdéhùn kan fún onígbàgbọ́ òdodo kan. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùtayọ ẹnu-ààlà. (11) Nítorí náà, tí wọ́n bá ronú pìwàdà, tí wọ́n ń kírun, tí wọ́n sì ń yọ Zakāh, nígbà náà ọmọ-ìyá yín nínú ẹ̀sìn ni wọ́n. À ń ṣàlàyé àwọn āyah náà fún ìjọ tó nímọ̀. (12) Tí wọ́n bá rú ìbúra wọn lẹ́yìn àdéhùn wọn, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ àìdara sí ẹ̀sìn yín, nígbà náà ẹ ja àwọn olórí aláìgbàgbọ́ lógun - dájúdájú ìbúra wọn kò ní ìtúmọ̀ kan sí wọn - kí wọ́n lè jáwọ́ (níbi aburú). (13) Ṣé ẹ ò níí gbógun ti ìjọ kan tó ba ìbúra rẹ̀ jẹ́ (ó sì jù ú nù), tí wọ́n sì gbèrò láti lé Òjíṣẹ́ kúrò (nínú ìlú); àwọn sì ni wọ́n kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí gbógun tì yín ní ìgbà àkọ́kọ́? Ṣé ẹ̀ ń páyà wọn ni? Allāhu l’Ó ní ẹ̀tọ́ jùlọ sí pé kí ẹ páyà Rẹ̀ tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.¹ 1. Ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn nasọ̄rọ̄ máa ń sọ̀rọ̀ àtakò burúkú sí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - nítorí ọ̀rọ̀ ogun ẹ̀sìn “Jihād”, èyí tí ó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú ìlànà ẹ̀sìn ’Islām. Bí àwọn nasọ̄rọ̄ kan ṣe ka jihād kún ìfipámúni-ṣẹ̀sìn-’Islām, bẹ́ẹ̀ ni àwọn nasọ̄rọ̄ mìíràn ka jihād kún ọ̀nà ìdigunjalè l’órúkọ́ ẹ̀sìn ’Islām. Nínú ọ̀rọ̀ burúkú àwọn nasọ̄rọ̄ mìíràn lórí ọ̀rọ̀ jihād ni pé, wọ́n ti ìpasẹ̀ jihād sọ àwa mùsùlùmí di mùjẹ̀mùjẹ̀ bí àwọn Boko Harām. Ó kéré parí, dípò kí àwọn nasọ̄rọ̄ ṣẹ̀ṣà orúkọ rere fún àwa mùsùlùmí lórí ọ̀rọ̀ jihād, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣẹ̀ṣà orúkọ rere fún àwọn kan tí wọ́n ń pè ni “ajàjàgbara” tàbí “ajàfẹ́tọ̀ọ́-ọmọnìyàn”, “alákatakítí-ẹ̀sìn ’Islām” ni orúkọ abunikù mìíràn tí àwọn nasọ̄rọ̄ tún fún wa nítorí ọ̀rọ̀ Jihād. Àwọn ọ̀rọ̀ burúkú wọ̀nyí tí àwọn nasọ̄rọ̄ ń sọ sí àwa mùsùlùmí lórí ọ̀rọ̀ jihād burú gan-an tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tó fi jẹ́ pé, tí ẹnì kan bá kọ́kọ́ ka èyíkéyìí ìwé àtakò wọn sí ẹ̀sìn ’Islām tí wọ́n tẹ̀ jáde lórí ọ̀rọ̀ jihad, kò níí rí dáadáa kan kan lára Allāhu, Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àwa mùsùlùmí àti ’Islām gan-an fúnra rẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ àtakò burúkú àwọn nasọ̄rọ̄ wọ̀nyí sì ni ohun àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ń gbìn sínú ọkàn àwọn èwe wẹẹrẹ bẹ̀rẹ̀ láti àwọn ilé-ìwé alákọ̀ọ́-bẹ̀rẹ̀ pé “’Islām bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú idà lọ́wọ́ ọ̀tún, Kurāni lọ́wọ́ òsì!” Àwọn nasọ̄rọ̄, wọn a tún máa fi kún un pé, “Ìsọ̀rí mẹ́ta péré ni Allāhu àti Muhammad pín gbogbo ayé sí lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn. Ìsọ̀rí àwọn ènìyàn kìíní ni àwọn mùsùlùmí tó lè pa àwọn ènìyàn bí àwọn pààyàn-pààyàn, tó sì lè gba àwọn dúkìá àwọn ènìyàn lọ́wọ́ wọn bí ìgárá-ọlọ́ṣà; àwọn wọ̀nyẹn ni onígbàgbọ́ òdodo tó máa wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ìsọ̀rí àwọn ènìyàn kejì ni àwọn mùsùlùmí tí wọn kò fẹ́ kí ẹ̀mí ènìyàn kan kan tọwọ́ àwọn bọ́, tí wọ́n sì ka fífi ogun jíjà gba dúkìá àwọn ènìyàn kún ìwà ọ̀daràn pọ́nńbélé; àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu wọn pè ní munāfiki, alágàbàǹgebè tó máa wà nínú àjà ìṣàlẹ̀ pátápátá nínú Iná. Ìsọ̀rí àwọn ènìyàn kẹta ni gbogbo àwọn ẹlẹ́sìn mìíràn yàtọ̀ sí ẹ̀sìn ‘Islām; àwọn wọ̀nyẹn sì ni àwọn aláìgbàgbọ́, àwọn ọ̀ṣẹbọ.” Ní àkótán, àwọn nasọ̄rọ̄, wọn á tún máa sọ pé. “Àlàáfíà ni ‘Īsā ọmọ Mọryam mú wá sáyé ni kò fi jagun ẹ̀sìn. Àmọ́ ìparun ni Muhammad mú wá sáyé ló fi kógun ja gbogbo ayé!” Ìwọ̀nyẹn ni díẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ àtakò tí àwọn nasọ̄rọ̄ máa ń sọ lásọtúnsọ sí àwa mùsùlùmí. Kódà, nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, wọn máa ń tọ́ka sí àwọn āyah kọ̀ọ̀kan àti àwọn hadīth kọ̀ọ̀kan tó ń pa àwa mùsùlùmí òdodo láṣẹ ogun jíjà s’ójú ọ̀nà Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti ka ẹyọ kan tàbí òmíràn nínú àwọn ìwé àwọn nasọ̄rọ̄ lórí àwa mùsùlùmí kò níí ṣàì rí irúfẹ́ ọ̀kan-ò-jọ̀kan àwọn ọ̀rọ̀ tí mo mú wá ṣíwájú wọ̀nyẹn nínú wọn. Ní pàápàá jùlọ, àwọn oníròyìn lórí ẹ̀rọ rédíò àti tẹlifísọ̀n àti àwọn ìwé ìròyìn gbogbo kò là nínú sísọ àwọn ọ̀rọ̀ abunikù bẹ́ẹ̀ sí àwa mùsùlùmí. Mo ṣetán báyìí láti mú àlàyé díẹ̀ ní ṣókíṣókí wá lórí ọ̀rọ̀ jihād. Ní àkọ́kọ́ ná, bóyá ni ẹnì kan fi lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ogun jíjà fún ẹ̀sìn ‘Islām yé tí onítọ̀ún kò bá ní ìmọ̀ òdodo pọ́nńbélé nípa ìtàn ìgbésí ayé Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - àti ìtàn àwọn ẹlẹ̀sìn tó wà lásìkò rẹ̀. Ìdí èyí ni pé, kódà tí ẹnì kan bá ń tọ́ka sí āyah ogun tàbí hadīth ogun, ó gbọ́dọ̀ yé onítọ̀ún - tí kò bá níí ṣàbòsí sórí ara rẹ̀ - pé ọ̀rọ̀ ló ń ṣíwájú ogun, ọ̀rọ̀ l’ó ń kẹ́yìn ogun. Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - bẹ̀rẹ̀ ’Islām rẹ̀ nínú ìlú Mọkkah láààrin kìkìdá ọ̀ṣẹbọ. Àwọn ará ìlú Mọkkah, lásìkò náà, ni ọmọ-ojúmọ́-kan òòṣà kan. Àwọn ọ̀ṣẹbọ náà sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ọwọ́ ìnira tó lágbára kan Ànábì àti àwọn ènìyàn díẹ̀ tó ti gbà fún Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Ṣíwájú kí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tó di Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun, ìyẹn ogójì ọdún àkọ́kọ́ nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ̀, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - jẹ́ ẹni rere, olódodo, olùfọkàntán, oníwà-ìrẹ̀lẹ̀, akínkanjú ènìyàn àti ọmọlúàbí láààrin ìlú Mọkkah. Kò sì sí ẹnì kan nígbà náà tó ń f’ẹnu àbùkù kàn án. Kódà gbogbo ará ìlú wọn ló mọ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sí olódodo àti olùfọkàntán. Àmọ́ níkété tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Ọlọ́hun nínú ìlú, àwọn ará ìlú sọ ọ́ di “wèrè, òpìdán, akéwì” fún wí pé ìpèpè rẹ̀ lòdì sí ìbọ̀rìṣà. Ìdí nìyí tí wọ́n fi kọ’jú oro sí òun àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Àwọn ọ̀ṣẹbọ lu èyí tí ó ṣe é lù lálùbami nínú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Àwọn ọ̀ṣẹbọ sì pa èyí tí ó ṣe é pa nínú wọn ní ìpakúpa. Bí àwọn ọ̀ṣẹbọ ṣe ń pa àwọn ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń pa àwọn obìnrin. Àwọn ọmọ wẹẹrẹ gan-an kò mórí bọ́ lọ́wọ́ àwọn ọ̀ṣẹbọ lásìkò náà. Kò sì sí ìgbà kan tí àwọn ọ̀ṣẹbọ bá pitú ọwọ́ wọn han àwọn mùsùlùmí lásìkò náà, àfi kí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - fún wọn ní àrọwà sùúrù. Ó sì tún máa jẹ́ kí ó yé wọn pé, irú ìyà mìíràn tí òun kò mọ̀ tún lè tọ̀dọ̀ àwọn ọ̀ṣẹbọ wá lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́ sá, kí àwọn mùsùlùmí má ṣe tìtorí ìnira àwọn ọ̀ṣẹbọ fi ẹ̀sìn Ọlọ́hun sílẹ̀. Èyí l’ó jẹyọ nínú sūrah al-‘Ahƙọ̄f; 46:9. Ní òdodo kàkà kí àwọn ọ̀ṣẹbọ yìí fi àwọn mùsùlùmí lọ́rùn sílẹ̀, ńṣe ni wọ́n tún le mọ́ wọn sí i. Nígbà tí ìnira yìí sì ń lọ síbi ìfojú-egbò-rìn, láì dáràn kan tayọ pípe “Allāhu ni Ọlọ́hun àti Olúwa”, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - yọ̀ǹda fún àwọn mùsùlùmí kan pé kí wọ́n fi ìlú bàbá wọn sílẹ̀, kí wọ́n gbé ẹ̀sìn wọn sá fún àwọn ọ̀ṣẹbọ, kí wọ́n lọ forí pamọ́ sínú ìlú mìíràn. Èyí ló ṣokùnfà bí àwọn kan nínú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe lọ ṣàtìpó nílẹ̀ Habaṣah (Ethopia). Èyí sì ni ohun tí a mọ̀ sí Hijrah àkọ́kọ́ tó wáyé nínú ìjọ Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Ìkọ̀ kìíní lọ. Ìkọ̀ kejì náà lọ. Ilẹ̀ Habaṣah wà lábẹ́ ọba nasọ̄rọ̄ kan lásìkò náà. Orúkọ ọba náà ni ’Ashamọh bun al-Hurr an-Najāṣīy - kí Allāhu yọ́nú sí i -. Àwọn ọ̀ṣẹbọ ìlú Mọkkah kúkú tọpasẹ̀ àwọn mùsùlùmí dé inú ìlú náà. Wọ́n sì lọ ṣe tánàdí àwọn mùsùlùmí lọ́dọ̀ ọba náà. Wọ́n fi ẹ̀sùn gban̄kọ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kan àwọn mùsùlùmí. Àwọn ọ̀ṣẹbọ sọ fún ọba pé, “ẹrú àwọn tó sá mọ́ àwọn lọ́wọ́ ni àwọn mùsùlùmí náà.” Wọ́n ní, “àwọn mùsùlùmí náà kò ní ìtẹríba fún àwọn àgbà.” Paríparí rẹ̀ ni pé, àwọn ọ̀ṣẹbọ sọ pé, “àwọn mùsùlùmí ń sọ àìdáa sí ‘Īsā ọmọ Mọryam àti ìyá rẹ̀.” Orí ọba náà gbóná wá. Lójú ẹsẹ̀, ó pàṣẹ pé kí wọ́n lọ kó gbogbo àwọn mùsùlùmí náà wá ṣíwájú òun. Èsì tí àwọn mùsùlùmí fọ̀ sí àwọn ẹ̀sùn náà ni pé, “àwọn kì í kúnlẹ̀ tàbí dọ̀bálẹ̀ fún ẹnikẹ́ni àfi Allāhu. Ìkíni “àlàáfíà fún ọ” ni ìkíni tàwọn. Àwọn kì í ṣe ẹrú tó sá mọ́ olówó rẹ̀ lọ́wọ́, àmọ́ nítorí pé àwọn kọ̀ láti máa bá wọn bọ̀rìṣà lọ ló mú àwọn ọ̀ṣẹbọ tó ń darí ìlú gbógun líle ti àwọn. Wọ́n pa nínú àwọn nípakúpa nígbà tí lílù àlùbami àti lílẹ̀lókò kò ran àwọn mọ́. Níwọ̀n ìgbà tí àyè mìíràn sì wà láyé l’àwọn fi sá wá síbí. Nípa ti ọ̀rọ̀ ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - àti ìyá rẹ̀, kò sí ẹni tó fẹnu àbùkù kàn wọ́n rí nínú àwọn.” Agbẹnusọ wọn, Ja‘far - kí Allāhu yọ́nú sí i - sì ké sūrah Mọryam fún wọn nínú ààfin ọba. Orí ọba wú nígbà tí ó ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ òdodo tí al-Ƙur’ān ń sọ nípa ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - àti ìyá rẹ̀. Èyí tí ń ṣe àfihàn pé “wòlíì náà tí à ń retí ti dé”. Ọba náà kò ṣe méní, kò ṣe méjì, ó gbàfà fún Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Ó sì fínnúfíndọ̀ gba ’Islām. Ó sì ṣe ẹ̀sìn ’Islām d’ọjọ́ ikú rẹ̀ - kí Allāhu yọ́nú sí i -. Ọba wá ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe àdéhùn àtìlẹ́yìn rẹ̀ fún àwọn mùsùlùmí nínú ìlú rẹ̀. Ojú ti àwọn ọ̀ṣẹbọ náà. Wọ́n sì dárí padà wá sínú ìlú Mọkkah láti tẹ̀ síwájú nínú ìfìnira kan àwọn mùsùlùmí tó ṣẹ́kù nínú ìlú wọn. Ọba yìí àti irú rẹ̀ mìíràn nínú àwọn èèkàn èèkàn nasọ̄rọ̄ tó gba ẹ̀sìn ’Islām sínú ayé wọn wọ́ọ́rọ́wọ́ ni al-Ƙur’ān ń tọ́ka sí nínú àwọn súrah kan bíi tinú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:82-85. Síwájú sí i, àwọn ọ̀ṣẹbọ ìlú Mọkkah tún ń fínná mọ́ àwọn mùsùlùmí ìlú Mọkkah ju ti àtẹ̀yìnwá lọ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí wọ́n fi ṣèpàdé lórí bí wọ́n ṣe máa pa Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Ní alẹ́ ọjọ́ tí àwọn ọ̀ṣẹbọ ìlú Mọkkah gbéra láti gbẹ̀mí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni Allāhu tú àṣírí èròkérò wọn fún Ànábì Rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Ó sì pa á láṣẹ láti sá kúrò nínú ìlú bàbá rẹ̀ fún wọn. Allāhu pa òun àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láṣẹ pé kí wọ́n lọ ṣàtìpó sínú ìlú Mọdīnah. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀ṣẹbọ tọpasẹ̀ òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ Abu-Bakr as-Siddīƙ - kí Allāhu yọ́nú sí i - lórí ìrìn-àjò wọn sí ìlú Mọdināh, Allāhu kó àwọn méjèèjì yọ nínú ṣùtá àwọn tó tọpasẹ̀ wọn. Èyí mú kí àwọn ọ̀ṣẹbọ fàbọ̀ sórí àwọn tó kù lẹ́yìn. Àwọn ọ̀ṣẹbọ ń dènà dè wọ́n bí ìgbà tí ẹkùn bá ń dènà de ẹranko. Àwọn tí ọwọ́ àwọn ọ̀ṣẹbọ ba bà nínú àwọn mùsùlùmí, yálà kí ó padà sínú ìlú Mọkkah fún ìdíyàjẹ tó kọjá ìfaradà tàbí tí ó bá kọ̀ kí wọ́n pa á lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ sójú ọ̀nà. Àyà kò tún ko àwọn ọ̀ṣẹbọ ìlú Mọkkah láti máa lé àwọn mùsùlùmí wọnú ìlú Modīnah. Nígbà tí ọwọ́ wọn bá sì tẹ̀ wọ́n níbẹ̀, wọ́n sì máa dá wọn padà sínú ìlú Mọkkah pẹ̀lú ìjìyà tó dópin. Lásìkò yìí ni Allāhu - Ọba tó ga jùlọ - yọ̀ǹda fún àwọn mùsùlùmí náà láti jàjà gbára fún ẹ̀mí ara wọn, láti gba àwọn ìyàwó wọn sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn àti àwọn tí kò rọ́nà jáde kúrò nínú ìlú Mọkkah. Kí wọ́n lè dáàbò bo ẹ̀sìn wọn lọ́wọ́ àwọn ọ̀ṣẹbọ. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah al-Hajj; 22: 39-41 àti sūrah an-Nisā’; 4:75. Gbogbo ìwọ̀nyí ló kúkú bi āyah ogun ẹ̀sìn, èyí tí àwọn nasọ̄rọ̄ ń tọ́ka sí lódì lódì báyìí. Āyah àti hadīth tí wọ́n sì tún ń tọ́ka sí lórí jíja àwọn nasọ̄rọ̄ àti àwọn yẹhudi lógun kò ṣàdédé wáyé bí kò ṣe nítorí ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí àwọn ìjọ méjèèjì hù níwà sí àwọn mùsùlùmí nínú ìlú Mọdinah Onímọ̀ọ́lẹ́. Ìdí ni pé, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - bá ìjọ yẹhudi àti nasọ̄rọ̄ nínú ìlú Mọdīnah gẹ́gẹ́ bí àrè, wọn kì í ṣe ọmọ-onílùú rárá nítorí pé àwọn ìdílé ’Aos àti ìdílé Kazraj ló ni ìlú wọn, ìlú Mọdīnah. Níkété tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - gúnlẹ̀ sínú ìlú Mọdīnah ni àwọn ìdílé méjèèjì wọ̀nyí fa àkóṣo àti ìjọba ìlú Mọdīnah lé Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lọ́wọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́ láì bèèrè fún un nítorí pé, kò fẹ́ẹ̀ ṣẹ́ku ẹnì kan kan tí kò gba ’Islām wọ́ọ́rọ́wọ́. Ìgbàláàyè tí àwọn ọmọ ìlú Mọdīnah ṣe fún Ànábì wa yìí l’ó kúkú sọ àwọn náà di “al-’Ansọ̄r” - alárànṣe-ẹ̀sìn. Àti pé orúkọ ìlú Mọdīnah yí padà kúrò ní Yẹthrib, ó sì di Mọdīnah Onímọ̀ọ́lẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn tó wá ṣàtìpó sínú ìlú náà ṣe ń jẹ́ “al-Muhājirūn” - àwọn tó gbé ìlú wọn jù sílẹ̀ nítorí ẹ̀sìn -. Nígbà tí àṣẹ ìlú Mọdīnah Onímọ̀ọ́lẹ̀ dé ọwọ́ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ó di alásẹ gbogbogbò fún ìlú Mọdīnah láti ọdún àkọ́kọ́ tó ti wọ inú ìlú náà. Tòhun ti bẹ́ẹ̀ náà, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò lé àwọn yẹhudi àti àwọn nasọ̄rọ̄ kúrò nínú ìlú Mọdīnah àti ìgbéríko rẹ̀. Kódà àwọn ìjọ yẹhudi ní abúlé tiwọn tí wọ́n mọ odi yíra wọn ká pẹ̀lú rẹ̀. Lábẹ́ “ààbò-ara-ẹni lààbò ìlú” l’ó mú kí àdéhùn ojú-lalákàn fi í ṣọ́rí wáyé láààriin ìjọ mùsùlùmí àti àwọn yẹhudi tó ń gbé nínú ìlú Mọdīnah. Àmọ́ ńṣe ni àwọn yẹhudi wọ̀nyí lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ àwọn ọ̀ṣẹbọ ìlú Mọkkah. Wọ́n sì fi ọ̀bẹ ẹ̀yìn jẹ àwọn mùsùlùmí níṣu. Èyí lóbí àwọn āyah àti hadīth tí wọ́n ń tọ́ka sí lónìí lódì lódì lórí gbígbé ogun tí àwọn ahlul-kitāb. Nípasẹ̀ Jihād, ìṣẹ́gun ńlá àti àrànṣe tó lágbára fún àwọn mùsùlùmí àkọ́kọ́ dé lórí àwọn ọ̀tá ’Islām àkọ́kọ́. Allāhu sì kó Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ yọ lọ́wọ́ ṣùtá àwọn ọ̀ṣẹbọ àti àwọn ahlul-kitāb. Ní ti Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -, ọwọ́ rẹ̀ kò tẹ èkù-idà rárá títí Allāhu fi gbé e lọ sínú sánmọ̀. Òun náà ìbá kúkú jagun nítorí pé, àwọn yẹhudi kò fi òun àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sílẹ̀ láì gbógun tì wọ́n. Àmọ́, Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - kò wọ ipò aláṣẹ ìlú, áḿbọ̀sìbọ̀sí pé ó máa ní ọmọ ogun tó lè kó jagun ẹ̀sìn. Àti pé mélòó gan-an ni àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó fi máa dira ogun? Gbígbà tí Allāhu gbà fún Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí Ó fi jogún ìjọba ìlú fún un l’ó fi rí ogun àjàyè jà lórí àwọn ọ̀tá ẹ̀sìn ’Islām. Tàbí ṣe a rí ìjọba kan láyé tí kò ní ọmọ ogun ni? Ìjọba ni Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Ìjọba àlàáfíà sì ni pẹ̀lú nítorí pé, nípasẹ̀ ogun ẹ̀sìn ni àlàáfíà fi jọba lérékùsù Lárúbáwá. Ìkọjá-ẹnu-ààlà àwọn ọ̀ṣẹbọ àti àwọn ahlul-kitāb l’ó sì bí jihad nítorí pé, ìwàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun ni Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - fi pèpè sẹ́sìn. Àwọn ọ̀ṣẹbọ àti àwọn onítírà wọ̀nyẹn kò sì yé tayọ ẹnu-ààlà sí àwa mùsùlùmí títí di àsìkò yìí. Ṣebí ọ̀rọ̀-ẹnu ni àwa mùsùlùmí sì fi ń yanjú rẹ̀ lọ́wọ́ lásìkò tiwa yìí. Ó sàn fún àwọn olùtayọ-ẹnu-ààlà wọ̀nyẹn kí wọ́n jẹ́ kí ó mọ bẹ́ẹ̀. Kò sí ìfipámúni-ṣẹ̀sìn ’Islām nítorí pé, àwọn āyah kan, bíi sūrah Yūnus; 10:99-100, ti fi rinlẹ̀ pé, kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni Allāhu máa ṣe ní mùsùlùmí. Àmọ́ Allāhu kọ kí ẹlẹ̀sìn máa fi ìnira kan ẹlẹ̀sìn mìíràn. Nítorí náà, òkìkí tí àwọn nasọ̄rọ̄ ń fún àwa mùsùlùmí kò lè yọ jihād kúrò nínú ẹ̀sìn ’Islām. Tí wọn kò bá fẹ́ ká ṣe jihād lórí àwọn kí wọ́n so ewé agbéjẹ́ mọ́wọ́. (14) Ẹ jà wọ́n lógun. Allāhu yóò jẹ wọ́n níyà láti ọwọ́ yín. Ó máa yẹpẹrẹ wọn. Ó máa ràn yín lọ́wọ́ lórí wọn. Ó sì máa wo ọkàn ìjọ onígbàgbọ́ òdodo sàn. (15) Ó tún máa kó ìbínú ọkàn wọn lọ. Ó sì máa gba ìronúpìwàdà lọ́wọ́ ẹni t’Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. (16) Tàbí ẹ lérò pé A óò fi yín sílẹ̀ láì jẹ́ pé Allāhu ti ṣàfi hàn àwọn tó máa jagun ẹ̀sìn nínú yín, tí wọn kò sì ní ọ̀rẹ́ àyò kan lẹ́yìn Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo? Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. (17) Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún àwọn ọ̀ṣẹbọ láti máa ṣàmójútó àwọn mọ́sálásí Allāhu, nígbà tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́rìí sí àìgbàgbọ́ lórí ara wọn. Àwọn wọ̀nyẹn ni iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú Iná. (18) Ẹni tí yóò máa ṣàmójútó àwọn mọ́sálásí Allāhu ni ẹni tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tó sì ń kírun, tó ń yọ Zakāh, kò sì páyà (òrìṣà kan) lẹ́yìn Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n kúkú wà nínú àwọn olùmọ̀nà. (19) Ṣé ẹ máa ṣe fífún alálàájì ní omi mu àti ṣíṣe àmójútó Mọ́sálásí Haram ní ohun tó dọ́gba sí ẹni tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tó sì jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu? Wọn kò dọ́gba lọ́dọ̀ Allāhu. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí. (20) Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀,¹ tí wọ́n sì fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu, wọ́n tóbi jùlọ ní ipò lọ́dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùjèrè. 1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah an-Nisā’; 4:100. (21) Olúwa wọn ń fún wọn ní ìró ìdùnnú nípa ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú ìyọ́nú àti àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí ìdẹ̀ra gbére wà fún wọn nínú rẹ̀. (22) Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Dájúdájú Allāhu, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ẹ̀san ńlá wà. (23) Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú àwọn bàbá yín àti àwọn arakùnrin yín ní ọ̀rẹ́ àyò bí wọ́n bá gbọ́lá fún àìgbàgbọ́ lórí ìgbàgbọ́ òdodo. Ẹnikẹ́ni tó bá mú wọn ní ọ̀rẹ́ àyò nínú yín, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni alábòsí.¹ 1. Nínú sūrah al-’Isrọ̄’; 17:23 - 24, sūrah Luƙmọ̄n; 31:14 - 15 àti sūrah al-’Ankabūt; 29:8, Allāhu - Subhānahu - pa ọmọ láṣẹ láti ṣe rere sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì, kódà kí àwọn méjèèjì jẹ́ aláìgbàgbọ́ tàbí ọ̀ṣẹbọ. Àmọ́ ìyàtọ̀ wà láààrin ṣíṣe rere sí òbí àti títẹ̀lé àṣẹ òbí lórí ohun tó yapa sí ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Ìdí nìyí tí àwọn sūrah at-Taobah; 9:23 àti sūrah al-Mujādilah; 58:22 fi ń ṣe é ní èèwọ̀ fún àwọn ọmọ láti tẹ̀lé àṣẹ òbí wọn nígbà tí àṣẹ wọn bá ti jẹmọ́ ìbọ̀rìṣà, àìgbàgbọ́ àti ìyapa àṣẹ Òjíṣẹ́ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tàbí ṣíṣe bid'ah. Nítorí náà, ọmọ ní ẹ̀tọ́ láti ṣe rere sí òbí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ní ẹ̀tọ́ láti kọ̀rọ̀ sí òbí rẹ̀ lẹ́nu nígbà tí wọ́n bá páṣẹ tó yapa sí ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ fún un. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ìṣẹ̀yá-ṣẹbàbá. (24) Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé àwọn bàbá yín, àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn arákùnrin yín, àwọn ìyàwó yín àti àwọn ìbátan yín pẹ̀lú àwọn dúkìá kan tí ẹ ti kó jọ àti òkòwò kan tí ẹ̀ ń bẹ̀rù pé kí ó má kùtà àti àwọn ibùgbé tí ẹ yọ́nú sí, (tí ìwọ̀nyí) bá wù yín ju Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ pẹ̀lú jíja ogun sí ojú-ọ̀nà Rẹ̀, ẹ máa retí (ìkángun) nígbà náà títí Allāhu yóò fi mú àṣẹ Rẹ̀ wá. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́ (25) Dájúdájú Allāhu ti ṣe àrànṣe fún yín ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ojú ogun àti ní ọjọ́ (ogun) Hunaen, nígbà tí pípọ̀ yín jọ yín lójú, (àmọ́) kò rọ̀ yín lọ́rọ̀ kan kan; ilẹ̀ sì fún mọ yín tòhun ti bí ó ṣe fẹ̀ tó. Lẹ́yìn náà, ẹ pẹ̀yìn dà, ẹ sì ń sá lọ. |
| | | أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 9 - Suuratut-Taobah الجمعة 21 يوليو 2023, 10:57 pm | |
| (26) Lẹ́yìn náà, Allāhu sọ ìfàyàbalẹ̀ Rẹ̀ kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Ó tún sọ àwọn ọmọ ogun kan kalẹ̀, tí ẹ ò fojú rí wọn. Ó sì jẹ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ níyà. Ìyẹn sì ni ẹ̀san àwọn aláìgbàgbọ́. (27) Lẹ́yìn náà, Allāhu yóò gba ìronúpìwàdà lọ́wọ́ ẹni t’Ó bá fẹ́ lẹ́yìn ìyẹn. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run. (28) Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú ẹ̀gbin ni àwọn ọ̀sẹbọ. Nítorí náà, wọn kò gbọdọ̀ súnmọ́ Mọ́sálásí Haram lẹ́yìn ọdún wọn yìí. Tí ẹ bá ń bẹ̀rù òṣì, láìpẹ́ Allāhu máa rọ̀ yín lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀, tí Ó bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. (29) Ẹ gbógun ti àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn àti àwọn tí kò ṣe ní èèwọ̀ ohun tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ṣe ní èèwọ̀¹ àti àwọn tí kò ṣe ẹ̀sìn òdodo nínú àwọn tí A fún ní tírà. (Ẹ gbógun tì wọ́n) títí wọ́n yóò fi máa fi ọwọ́ ará wọn san owó-orí ní ẹni yẹpẹrẹ. 1. Awẹ́ gbólóhùn yìí “ ohun tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ṣe ní èèwọ̀” ti fi hàn pé, al-Ƙur'ān àti hadīth Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ìkíní kejì ló lè ṣe n̄ǹkan kan ní èèwọ̀ fún mùsùlùmí. Nítorí náà, èèwọ̀ ni ohunkóhun tí hadīth Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ bá ṣe ní èèwọ̀, ìbáà má sìí nínú al-Ƙur'ān alápọ̀n-ọ́nlé. Bí àpẹ̀erẹ, èèwọ̀ ni fún obìnrin láti fi irun kún irun, èèwọ̀ sì ni fún obìnrin láti ṣe irun tí ó máa yọké. Irun tó yọké ni irun tí ó yọ ìkúùkù lórí obìnrin. Nínú hadīth Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni ìwọ̀nyẹn wà. (30) Àwọn yẹhudi wí pé: “‘Uzaer ni ọmọ Allāhu.” Àwọn nasọ̄rọ̄ sì wí pé: “Mọsīh ni ọmọ Allāhu.” Ìyẹn ni ọ̀rọ̀ wọn ní ẹnu wọn. Wọ́n ń fi jọ ọ̀rọ̀ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ṣíwájú (wọn). Allāhu fi wọ́n gégùn-ún. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo! (31) Wọ́n mú àwọn àlùfáà wọn (nínú yẹhudi) àti àwọn àlùfáà wọn (nínú nasọ̄rọ̄) ní olúwa lẹ́yìn Allāhu. (Wọ́n tún mú) Mọsīh ọmọ Mọryam (ní olúwa lẹ́yìn Allāhu). Bẹ́ẹ̀ sì ni A ò pa wọ́n láṣẹ kan tayọ jíjọ́sìn fún Ọlọ́hun, Ọ̀kan ṣoṣo. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Ó mọ́ tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I. (32) Wọ́n fẹ́ fi ẹnu wọn pa ìmọ́lẹ̀ (ẹ̀sìn) Allāhu, Allāhu yó sì kọ̀ (fún wọn) títí Ó fi máa pé ìmọ́lẹ̀ (ẹ̀sìn) Rẹ̀, àwọn aláìgbàgbọ́ ìbáà kórira rẹ̀. (33) (Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó fi ìmọ̀nà àti ẹ̀sìn òdodo (ẹ̀sìn ’Islām) rán Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí Ó lè fi borí gbogbo ẹ̀sìn (mìíràn) pátápátá, àwọn ọ̀ṣẹbọ ìbáà kórira rẹ̀. (34) Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn àlùfáà (nínú yẹhudi) àti àwọn àlùfáà (nínú nasọ̄rọ̄), wọ́n kúkú ń fi ọ̀nà èrú jẹ dúkìá àwọn ènìyàn ni, wọ́n sì ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Àwọn tó sì ń kó wúrà àti fàdákà jọ, tí wọn kò sì máa ná an sí ojú-ọ̀nà Allāhu, fún wọn ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro. (35) Ní ọjọ́ tí A óò máa yọ́ (wúrà àti fàdákà náà) nínú iná Jahanamọ, A ó sì máa fi jó iwájú wọn, ẹ̀gbẹ́ wọn àti ẹ̀yìn wọn. (A sì máa sọ pé): “Èyí ni ohun tí ẹ kó jọ fún ẹ̀mí ara yín. Nítorí náà, ẹ tọ́ ohun tí ẹ kó jọ wò.” (36) Dájúdájú òǹkà àwọn oṣù lọ́dọ̀ Allāhu ń jẹ́ oṣù méjìlá nínú àkọsílẹ̀ ti Allāhu ní ọjọ́ tí Ó ti dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Mẹ́rin ni oṣù ọ̀wọ̀ nínú rẹ̀.¹ Ìyẹn ni ẹ̀sìn tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀.² Nítorí náà, ẹ má ṣàbòsí sí ara yín nínú àwọn oṣù ọ̀wọ̀. Kí gbogbo yín sì gbógun ti àwọn ọ̀ṣẹbọ gẹ́gẹ́ bí gbogbo wọn ṣe ń gbógun tì yín. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀). 1. Àwọn oṣù ọ̀wọ̀ ni oṣù kìíní, Muharram; oṣú keje, Rajab; oṣù kọkànlá, Thul-Ƙọ‘dah àti oṣù kejìlá, Thul-Hijjah. 2. Ìyẹn ni pé, lára ẹ̀sìn àti ìjọ́sìn ’Islām ni lílo àwọn oṣù wọ̀nyí nítorí pé, oṣù náà ni à ń lò fún jíjọ́sìn fún Allāhu - subhānahu -. Bí àpẹ̀ẹrẹ, à ń kí ìrun Jum‘ah ní ọjọ́ Jum‘ah, à ń gba ààwẹ̀ Rọmọdọ̄n nínú oṣù Rọmọdọ̄n, a sì ń ṣe iṣẹ́ hajj nínú oṣù Thul-Hijjah. (37) Àlékún nínú àìgbàgbọ́ ni dídájọ́ sí àwọn oṣù ọ̀wọ̀ (láti ọwọ́ àwọn ọ̀ṣẹbọ). Wọ́n ń fi kó ìṣìnà bá àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ (nípa pé) wọ́n ń ṣe oṣù ọ̀wọ̀ kan ní oṣù ẹ̀tọ́ (fún ogun jíjà) nínú ọdún kan, wọ́n sì ń bu ọ̀wọ̀ fún oṣù (tí kì í ṣe oṣù ọ̀wọ̀) nínú ọdún (mìíràn, wọn kò níí jagun nínú rẹ̀, wọ́n sì máa yọ òǹkà oṣù náà síra wọn) nítorí kí òǹkà tí Allāhu ṣe ní èèwọ̀ lè papọ̀ mọ́ra wọn (sínú àwọn oṣù tí kì í ṣe oṣù ọ̀wọ̀). Wọ́n sì tipasẹ̀ bẹ́ẹ̀ ṣe ní ẹ̀tọ́ ohun tí Allāhu ṣe ní èèwọ̀. Wọ́n ṣe iṣẹ́ aburú wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ aláìgbàgbọ́. (38) Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, kí ni ó mu yín tí ó fi jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá sọ fún yín pé kí ẹ tú jáde (láti jagun) sí ojú- ọ̀nà Allāhu, (ìgbà náà ni) ẹ máa kàndí mọ́lẹ̀! Ṣé ẹ yọ́nú sí ìṣẹ̀mí ayé (yìí) ju ti ọ̀run ni? Ìgbádùn ìṣẹ̀mí ayé (yìí) kò sì jẹ́ kiní kan nínú ti ọ̀run àfi díẹ̀. (39) Àfi kí ẹ tú jáde (sógun ẹ̀sìn) ni Allāhu kò fi níí jẹ yín níyà ẹlẹ́ta-eléro àti pé ni kò fi níí fi ìjọ tó yàtọ̀ si yín pààrọ̀ yín. Ẹ kò sì lè fi kiní kan kó ìnira bá (Allāhu). Allāhu sì ni Alagbára lórí gbogbo n̄ǹkan. (40) Àfi kí ẹ ràn án lọ́wọ́, Allāhu kúkú ti ràn án lọ́wọ́ nígbà tí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lé e jáde (kúrò nínú ìlú). Ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méjì.¹ Nígbà tí àwọn méjèèjì wà nínú ọ̀gbun, tí (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) sì ń sọ fún olùbárìn rẹ̀ pé: “Má ṣe banújẹ́, dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú wa.”² Nígbà náà, Allāhu sọ ìfàyàbalẹ̀ Rẹ̀ kalẹ̀ fún un. Ó fi àwọn ọmọ ogun kan tí ẹ kò fojú rí ràn án lọ́wọ́. Ó sì mú ọ̀rọ̀ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wálẹ̀. Ọ̀rọ̀ Allāhu, òhun ló sì lékè. Allāhu sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n. 1. Olùbárìn rẹ̀ lórí ìrìn àjò náà ni ’Abū-Bakr as-Siddīƙ - kí Allāhu yọ́nú sí i -. 2. “Allāhu wà pẹ̀lú wa” Ìyẹn ni pé, “Allāhu mọ̀ pé àwa méjèèjì wà nínú ọ̀gbun yìí, Ó ń gbọ́ wa, Ó ń rí wa. Nítorí náà, Ó máa kó wa yọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀ṣẹbọ wọ̀nyí tí wọ́n ń lépa wa.” Gbólóhùn yìí jọ sūrah Tọ̄hā; 20:46. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Mujādilah; 58:7. (41) Ẹ tú jáde (fún ogun ẹ̀sìn) pẹ̀lú okun àti ìrọ́jú. Kí ẹ sì fi àwọn dúkìá yín àti ẹ̀mí yin jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu. Ìyẹn lóore jùlọ fún yín tí ẹ bá mọ̀ (42) Tí ó bá jẹ́ pé n̄ǹkan ìgbádùn (ọrọ̀ ogun) àrọ́wótó àti ìrìn-àjò tí kò jìnnà (lo pè wọ́n sí ni), wọn ìbá tẹ̀lé ọ. Ṣùgbọ́n ìrìn-àjò tó lágbára (ti t'ogun Tabūk) jìnnà lójú wọn. Wọ́n yó sì máa fi Allāhu búra pé: “Tí ó bá jẹ́ pé a lágbára ni, àwa ìbá jáde (fún ogun ẹ̀sìn) pẹ̀lú yín.” - Wọ́n sì ń kó ìparun bá ẹ̀mí ara wọn (nípa ṣíṣe ìṣọ̀bẹ-ṣèlu.) - Allāhu sì mọ̀ pé dájúdájú òpùrọ́ ni wọ́n. (43) Allāhu ti ṣàmójúkúrò fún ọ. Kí ló mú ọ yọ̀ǹda fún wọn (pé kí wọ́n dúró sílé? Ìwọ ìbá má ṣe bẹ́ẹ̀) títí ọ̀rọ̀ àwọn tó sòdodo yóò fi hàn sí ọ kedere. Ìwọ yó sì mọ àwọn òpùrọ́. (44) Àwọn tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn kò níí tọrọ ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ láti má fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun fún ẹ̀sìn Allāhu. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀). (45) Àwọn tó ń tọrọ ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ (láti jókòó sílé, dípò lílọ sí ojú-ogun) ni àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn; ọkan wọn sì ń ṣeyèméjì. Nítorí náà, wọ́n ń dààmú kiri níbi ìṣeyè-méjì wọn. (46) Tí ó bá jẹ́ pé wọn gbèrò ìjáde fún ogun ẹ̀sìn ni, wọn ìbá ṣe ìpalẹ̀mọ́ fún un. Ṣùgbọ́n Allāhu kórira ìdìde wọn fún ogun ẹ̀sìn, Ó sì kó ìfàsẹ́yìn bá wọn. Wọ́n sì sọ fún wọn pé: “Ẹ jókòó pẹ̀lú àwọn olùjókòó sílé.” (47) Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n jáde pẹ̀lú yín, wọn kò níí kun yín àfi pẹ̀lú ìbàjẹ́. Wọn yó sì sáré máa dá rúkèrúdò sílẹ̀ láààrin yín, tí wọn yóò máa ko yín sínú ìyọnu. Àti pé wọ́n ní olùgbọ́rọ̀ fún wọn láààrin yín. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn alábòsí. (48) Wọ́n kúkú ti wá ìyọnu tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì fimú fínlẹ̀ sì ọ (tí wọ́n dete sì ọ) títí òdodo fi dé, tí àṣẹ Allāhu sì borí; ẹ̀mí wọn sì kórira rẹ̀. (49) Ó wà nínú wọn, ẹni tí ń wí pé: “Yọ̀ǹda fún mi (kí n̄g jókòó sílé); má ṣe kó mi sínú àdánwò.” Inú àdánwò (sísá fógun ẹ̀sìn) má ni wọ́n ti ṣubú sí yìí. Dájúdájú iná Jahanamọ yó sì kúkú yí àwọn aláìgbàgbọ́ po. (50) Tí dáadáa kan bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, ó máa bà wọ́n nínú jẹ́. Tí aburú kan bá sì ṣẹlẹ̀ sí ọ, wọ́n á wí pé: “A kúkú ti gba àṣẹ tiwa ṣíwájú (láti jókòó sílé.)” Wọ́n á pẹ̀yìn dà; wọn yó sì máa dunnú.
|
| | | أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 9 - Suuratut-Taobah الجمعة 21 يوليو 2023, 10:58 pm | |
| (51) Sọ pé: “Kò sí ohun kan tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa àyàfi ohun tí Allāhu kọ mọ́ wa. Òun ni Aláàbò wa.” Allāhu sì ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé. (52) Sọ pé: “Ṣé ẹ̀ ń retí kiní kan pẹ̀lú wa ni bí kò ṣe ọ̀kan nínú dáadáa méjì (ikú ogun tàbí ìṣẹ́gun)? Àwa náà ń retí pẹ̀lú yín pé kí Allāhu mú ìyà kan wá ba yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ tàbí láti ọwọ́ wa. Nítorí náà, ẹ máa retí, dájúdájú àwa náà wà pẹ̀lú yín tí à ń retí.” (53) Sọ pé: “Ẹ fínnú-fíndọ̀ náwó ni tàbí pẹ̀lú tipátipá, A ò níí gbà á lọ́wọ́ yín (nítorí pé) dájúdájú ẹ̀yin jẹ́ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.” (54) Kò sì sí ohun kan tí kò jẹ́ kí Á gba ìnáwó wọn lọ́wọ́ wọn bí kò ṣe pé dájúdájú wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Wọn kò níí wá kírun àfi kí wọ́n jẹ́ òròjú aláìníkan-ánṣe. Wọn kò sì níí náwó fẹ́sìn àfi kí ẹ̀mí wọn kórira rẹ̀. (55) Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn jọ ọ́ lójú; Allāhu kàn fẹ́ fi jẹ wọ́n níyà nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí) ni. Ẹ̀mí yó sì bọ́ lára wọn, tí wọ́n máa wà nípò aláìgbàgbọ́. (56) Wọ́n ń fi Allāhu búra pé dájúdájú àwọn kúkú wà lára yín. Wọn kò sì sí lára yín, ṣùgbọ́n dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ kan tó ń bẹ̀rù.¹ 1. Wọ́n bẹ̀rù láti fi àìgbàgbọ́ wọn hàn síta, wọ́n yáa ń fi ’Islām wọn ṣe bojúbojú. (57) Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n rí ibùsásí kan, tàbí àwọn ihò àpáta kan, tàbí ibùsáwọ̀ kan, wọn ìbá ṣẹ́rí síbẹ̀ ní wéréwéré. (58) Ó tún wà nínú wọn, ẹni tí ń bú ọ níbi (pípín) àwọn ọrẹ. Tí A bá fún wọn nínú rẹ̀, wọ́n á yọ́nú (sí i). Tí A ò bá sì fún wọn nínú rẹ̀, nígbà náà ni wọn yóò máa bínú. (59) Àti pé (ìbá lóore fún wọn) tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n yọ́nú sí ohun tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ fún wọn, kí wọ́n sì sọ pé: “Allāhu tó wa. Allāhu yó sì fún wa nínú oore àjùlọ Rẹ̀ àti pé Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (sì máa pín ọrẹ)¹, dájúdájú ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àwa ń wá oore sí.” 1. N̄ǹkan tí āyah yìí ń sọ ni pé, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lẹ́tọ̀ọ́ sí pípín àwọn ọrẹ tí Allāhu pín kàn án nínú àwọn oore ayé àrígbámú yálà nípasẹ̀ ọrọ̀ ogun, zakāh gbígbà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Èyí rí bẹ́ẹ̀ ní ìbámu sí āyah 58 tí ó ṣíwájú rẹ̀ àti āyah 60 tí ó tẹ̀lé e. Kì í ṣe pé Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ló ń pín oore ayé tàbí oore àjùlọ fún àwọn ẹ̀dá. (60) Àwọn tí ọrẹ (Zakāh) wà fún ni àwọn aláìní, àwọn mẹ̀kúnnù,¹ àwọn òṣìṣẹ́ Zakāh, àwọn tí ọkàn wọn fẹ́ gba ’Islām (ìyẹn àwọn tí wọ́n fẹ́ fi fa ọkàn wọn mọ́ra sínú ẹ̀sìn), àwọn ẹrú (fún gbígba òmìnira), àwọn onígbèsè, àwọn tó wà lójú ogun (ẹ̀sìn) Allāhu àti onírìn-àjò (tí agara dá). Ọ̀ran-anyàn ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. 1. “Faƙīr” ni aláìní, tálíkà, olòṣì. Ìyẹn ni ẹni tí ó fẹ́ ṣiṣẹ́, àmọ́ tí kò rí iṣẹ́ kan kan ṣe, yálà lábẹ́ ènìyàn tàbí iṣẹ́ àdáni. Kò sì ní ọ̀nà kan kan tí ó lè gbà rí owó. Kí wọ́n fún un nínú zakah kí ó fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tara tirẹ̀. “Miskīn” ni mẹ̀kúnnù. Ìyẹn ni ẹni tí ó ń rí iṣẹ́ kan ṣe, àmọ́ tí owó tó ń rí lórí iṣẹ́ náà kò ká àpapọ̀ bùkátà ìjẹ-ìmu rẹ̀, owó ilé gbígbé rẹ̀ àti gbígbọ́ bùkátà lórí ará ilé rẹ̀. Kí wọ́n fún un nínú zakah kí ó fi yanjú bùkátà ọrùn rẹ̀. (61) Àwọn tó ń kó ìnira bá Ànábì wà nínú wọn, tí wọ́n sì ń wí pé: “Elétí-ọfẹ ni.” Sọ pé: “Elétí-ọfẹ rere ni fún yín; ó gbàgbọ́ nínú Allāhu. Ó sì gba àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbọ́. Ìkẹ́ ni fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo nínú yín. Àti pé àwọn tó ń kó ìnira bá Òjíṣẹ́ Allāhu, ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún wọn.” (62) Wọ́n ń fi Allāhu búra fún yín láti wá ìyọ́nú yín. Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ló sì lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ pe kí wọ́n wá ìyọ́nú Rẹ̀ tí wọ́n bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. (63) Ṣé wọn kò mọ̀ pé dájúdájú ẹnikẹ́ni tó bá ń tako Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, dájúdájú iná Jahanamọ ti wà fún un ni? Olùṣegbére sì ni nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni àbùkù ńlá. (64) Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ń bẹ̀rù pé kí Á má ṣe sọ sūrah kan kalẹ̀ nípa wọn, tí ó máa fún wọn ní ìró ohun tí ń bẹ nínú ọkàn wọn. Sọ pé: “Ẹ máa ṣe yẹ̀yẹ́ lọ. Dájúdájú Allāhu yóò ṣàfi hàn ohun tí ẹ̀ ń bẹ̀rù.” (65) Tí o bá kúkú bi wọ́n léèrè, dájúdájú wọ́n á wí pé: “Àwa kàn ń rojọ́ lásán ni, a sì ń ṣàwàdà ni.” Sọ pé: “Ṣé Allāhu, àwọn āyah Rẹ̀ àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ni ẹ̀ ń fi ṣe yẹ̀yẹ́?” (66) Ẹ má ṣe mú àwáwí wá. Dájúdájú ẹ ti ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn ìgbàgbọ́ yín. Tí A bá ṣe àmójúkúrò fún apá kan nínú yín, A óò fìyà jẹ apá kan nítorí pé wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀. (67) Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lọ́kùnrin àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmọ́ lóbìnrin, irú kan-ùn ni wọ́n; wọ́n ń pàṣẹ ohun burúkú, wọ́n ń kọ ohun rere, wọ́n sì ń káwọ́ gbera (láti náwó fẹ́sìn). Wọ́n gbàgbé Allāhu. Nítorí náà, Allāhu gbàgbé wọn.¹ Dájúdájú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí, àwọn ni òbìlẹ̀jẹ́. 1. Kò sí ìgbàgbé nínú ìròyìn Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā -. Àmọ́ Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - lo orúkọ iṣẹ́ aburú wọn fún wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san iṣẹ́ wọn. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:15. (68) Allāhu sì ti ṣe àdéhùn iná Jahanamọ fún àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lọ́kùnrin àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmọ́ lóbìnrin àti àwọn aláìgbàgbọ́. Olùṣegbére ni wọn nínú rẹ̀. Iná máa tó wọn. Allāhu sì ti ṣẹ́bi lé wọn. Ìyà gbére sì wà fún wọn. (69) (Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí dà) gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ṣíwájú yín; wọ́n le jù yín lọ ní agbára, wọ́n sì pọ̀ (jù yín lọ) ní àwọn dúkìá àti àwọn ọmọ. Nígbà náà, wọ́n jẹ ìgbádùn ìpín tiwọn (nínú oore ayé). Ẹ̀yin (ṣọ̀bẹ-ṣèlu wọ̀nyìí náà yóò) jẹ ìgbádùn ìpín tiyín gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ṣíwájú yín ṣe jẹ ìgbádùn ìpín tiwọn. Ẹ̀yin náà sì sọ̀sọkúsọ bí èyí tí àwọn náà sọ ní ìsọkúsọ. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́ ní ayé àti ní ọ̀run. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni ẹni òfò. (70) Ṣé ìròyìn àwọn tó ṣíwájú wọn kò tí ì dé bá wọn ni? (Ìròyìn) ìjọ (Ànábì) Nūh, ìran ‘Ād, ìran Thamūd, ìjọ (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, àwọn ará Mọdyan àti àwọn ìlú tí A dojú rẹ̀ bolẹ̀ (ìjọ Ànábì Lūt); àwọn Òjíṣẹ́ wọn wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú. Nítorí náà, Allāhu kò ṣe àbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ṣàbòsí sí. (71) Àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, apá kan wọn lọ̀rẹ́ alátìlẹ́yìn fún apá kan; wọ́n ń pàṣẹ ohun rere, wọ́n ń kọ ohun burúkú, wọ́n ń kírun, wọ́n ń yọ Zakāh, wọ́n sì ń tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu yóò ṣàkẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n. (72) Allāhu ṣe àdéhùn àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. (Ó tún ṣe àdéhùn) àwọn ibùgbé tó dára nínú àwọn ọgbà ìdẹ̀ra gbére (fún wọn). Ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu ló sì tóbi jùlọ (fún wọn). Ìyẹn, òhun ni èrèǹjẹ ńlá. (73) Ìwọ Ànábì, gbógun ti àwọn aláìgbàgbọ́ àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí. Kí o sì le mọ́ wọn. Iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn. Ìkángun náà sì burú.¹ 1. Mẹ́ta ni gbogbo ènìyàn pín sí lórí òṣùwọ̀n ẹ̀sìn. Igun àkọ́kọ́ ni àwa mùsùlùmí tí a jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. Igun yìí nìkan ló sì máa jèrè ní Ọjọ́ Àjíǹde. Igun kejì ni igun tó jẹ́ ìdàkejì sí igun àkọ́kọ́. Igun tí kì í ṣe mùsùlùmí rárá. Àwọn sì ni igun aláìgbàgbọ́ àti àwọn ọ̀ṣẹbọ. Wàyí ní ti igun kẹta, àwọn ni igun alágàbàǹgebè. Igun yìí ni igun tí ó ń pe ara rẹ̀ ní mùsùlùmí, tí ó sì ń ṣe ìṣe mùsùlùmí. Wọ́n ń kírun wákàtí márààrún, wọ́n ń dojú kọ Ƙiblah, wọ́n ń gbààwẹ̀ Rọmọdọ̄n, wọ́n ń ṣe hajj, wọ́n sì ń wí kalmọtu-ṣṣahādah, àmọ́ wọn kò faramọ́ àwọn ìgbàgbọ́ òdodo àti àdìsọ́kàn Islām. Ìgbàgbọ́ igun kẹta yìí máa ń bá ti igun kejì lọ ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìgbà. Ìsọ̀rí méjì sì ni àwọn igun ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí. Ìsọ̀rí àkọ́kọ́ ni igun àwọn ahlul-bid‘ah bí ìjọ Ahmadiyyah, Ìjọ Tijāniyyah, ìjọ Ƙọ̄diriyyah, ìjọ Ṣī‘ah. Ìsọ̀rí kejì ni gbogbo ẹnikẹ́ni tí ó ń pe ara rẹ̀ ní mùsùlùmí àmọ́ tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ àyò àti alátìlẹ́yìn fún àwọn kèfèrí àti àwọn ọ̀ṣẹbọ. Nítorí náà, āyah yìí ń pa àwa mùsùlùmí onígbàgbọ́ òdodo ní àṣẹ láti gbógun ti gbogbo ìjọ méjèèjì. Èyí sì máa jẹ́ nípasẹ̀ ṣíṣe wáàsí tó lágbára fún gbogbo wọn àti dídojú ìjà kọ èyí tí ó bá dojú ìjà kọ wá. (74) Wọ́n ń fi Allāhu búra pé àwọn kò sọ̀rọ̀ (burúkú). Wọ́n sì kúkú ti sọ ọ̀rọ̀ àìgbàgbọ́, wọ́n sì ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti gba ’Islām. Wọ́n tún gbèròkérò sí n̄ǹkan tí ọwọ́ wọn kò níí bà. Wọn kò rí àlèébù kan (wọn kò sì kórira kiní kan) bí kò ṣe nítorí pé, Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ rọ àwọn (Sọhābah) lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀. Tí wọ́n bá ronú pìwàdà, ó máa dára fún wọn. Tí wọ́n bá sì gbúnrí (tí wọ́n kọ̀yìn si yín), Allāhu yóò jẹ wọ́n níyà ẹlẹ́ta-eléro ní ayé àti ní ọ̀run. Kò sì níí sí aláàbò àti alárànṣe kan fún wọn lórí ilẹ̀ ayé. (75) Ó wà nínú wọn, ẹni tó bá Allāhu ṣe àdéhùn pé: “Tí Ó bá fún wa nínú oore àjùlọ Rẹ̀, dájúdájú a óò máa tọrẹ, dájúdájú a ó sì wà nínú àwọn ẹni ire.”
|
| | | أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 9 - Suuratut-Taobah الجمعة 21 يوليو 2023, 10:58 pm | |
| (76) Àmọ́ nígbà tí Ó fún wọn nínú oore àjùlọ Rẹ̀, wọ́n ṣahun sí I. Wọ́n pẹ̀yìn dà, wọ́n sì ń gbúnrí (láti náwó fẹ́sìn). (77) Nítorí náà, ahun wọn mú ọ̀rọ̀ wọn kángun sí ìṣọ̀bẹ-ṣèlu nínú ọkàn wọn títí di ọjọ́ tí wọn yóò pàdé Allāhu nítorí pé wọ́n yẹ àdéhùn tí wọ́n bá Allāhu ṣe àti nítorí pé wọ́n ń parọ́. (78) Ṣé wọn kò mọ̀ pé Allāhu mọ àṣírí wọn àti ọ̀rọ̀ àtẹ̀sọ wọn, àti pé dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa àwọn ìkọ̀kọ̀? (79) Àwọn tó ń bú àwọn olùtọrẹ-àánú nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo lórí ọrẹ títa àti àwọn tí kò rí n̄ǹkan kan tayọ ìwọ̀n agbára wọn, wọ́n sì ń fi wọn ṣe yẹ̀yẹ́, Allāhu fi àwọn náà ṣe yẹ̀yẹ́. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn. (80) Yálà o tọrọ àforíjìn fún wọ́n tàbí o ò tọrọ àforíjìn fún wọn - kódà kí o tọrọ àforíjìn fún wọn nígbà ààdọ́rin - Allāhu kò níí foríjìn wọ́n. Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjísẹ́ Rẹ̀. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.¹ 1. Pẹ̀lú gbólóhùn yìí, àwọn kò-gbédè-ó-gbékèé nínú àwọn nasọ̄rọ̄ lérò pé Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò lè tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu fún àwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀, kí Allāhu sì foríjìn wá. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀ rárá. Àmọ́ ohun tí ń bẹ nínú āyah yìí ni pé, kò sí àforíjìn Allāhu fún òkú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí, gẹ́gẹ́ bí kò ṣe sí àforíjìn Allāhu fún òkú àwọn aláìgbàgbọ́ àti òkú àwọn ọ̀ṣẹbọ, ẹni yòówù ó bá wọn tọrọ àforíjìn. Nípa ti òkú àwọn aláìgbàgbọ́, ẹ wo āyah 84 níwájú. Nípa ti òkú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí, ẹ wo sūrah al-Munāfiƙūn; 63:6. Bákan náà, nípa ti òkú àwọn ọ̀ṣẹbọ, ẹ wo sūrah an-Nisā’; 4:48 àti 116 àti sūrah at-Taobah; 9:113. Bákàn náà, bíbá tí Allāhu ni kí àwọn mùsùlùmí lọ bá Ànábí - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - láti lè bá wọn tọrọ àforíjìn, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah an-Nisā’; 4:64, ìyẹn náà ti wá sópin nípasẹ̀ ikú Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Ọ̀wọ́ ìgbà tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ń bẹ nílé ayé ṣíwájú kí ó tó kú nìkan ni ó lè bá ẹnikẹ́ni nínú àwọn mùsùlùmí tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu - subhānahu wa ta'ālā -. Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - sì máa foríjìn ín. Àmọ́, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò lè ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́ lẹ́yìn ikú rẹ̀ nínú sàréè rẹ̀. Ó sì di Ọjọ́ Àjíǹde kí Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -tó lè bá wa ṣ’ìpẹ̀ àṣegbà níwájú Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā -. Nítorí náà, ìṣẹbọ sí Allāhu ni fún ẹnikẹ́ni láti lọ bá Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ní ìdí sàréè rẹ̀ fún títọrọ n̄ǹkan lọ́dọ̀ rẹ̀. (81) Àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun ẹ̀sìn dunnú sí jíjókòó sínú ilé wọn lẹ́yìn Òjíṣẹ́ Allāhu. Wọ́n sì kórira láti fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu. Wọ́n tún wí pé: “Ẹ má lọ jagun nínú ooru gbígbóná.” Sọ pé: “Iná Jahanamọ le jùlọ ní gbígbóná, tí ó bá jẹ́ pé wọ́n gbọ́ àgbọ́yé ọ̀rọ̀.” (82) Nítorí náà, kí wọ́n rẹ́rìn-ín díẹ̀, kí wọ́n sì sunkún púpọ̀; (ó jẹ́) ẹ̀san (fún) ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́. (83) Tí Allāhu bá mú ọ délé bá igun kan nínú wọn, tí wọ́n bá wá ń gbàṣẹ lọ́dọ̀ rẹ fún jíjáde fún ogun ẹ̀sìn, sọ nígbà náà pé: “Ẹ̀yin kò lè jáde fún ogun ẹ̀sìn mọ́ pẹ̀lú mi. Ẹ̀yin kò sì lè ja ọ̀tá kan lógun mọ́ pẹ̀lú mi, nítorí pé ẹ ti yọ́nú sí ìjókòó sílé ní ìgbà àkọ́kọ́. Nítorí náà, ẹ jókòó sílé ti àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun ẹ̀sìn.” (84) Láéláé, o ò gbọdọ̀ kírun sí ẹnì kan kan lára nínú wọn, tí ó bá kú, o ò sì gbọdọ̀ dúró níbi sàréè rẹ̀, nítorí pé wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Wọ́n sì kú nígbà tí wọ́n wà nípò òbìlẹ̀jẹ́. (85) Má ṣe jẹ́ kí àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn jọ ọ́ lójú; Allāhu kàn fẹ́ fi jẹ wọ́n níyà nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí) ni. (Ó sì fẹ́ kí) ẹ̀mí bọ́ lára wọn, nígbà tí wọ́n bá wà nípò aláìgbàgbọ́. (86) Nígbà tí A bá sọ sūrah kan kalẹ̀ pé kí wọ́n gbàgbọ́ nínú Allāhu, kí wọ́n sí jagun pẹ̀lú Òjíṣẹ́ Rẹ̀, (nígbà náà ni) àwọn ọlọ́rọ̀ nínú wọn yóò máa tọrọ ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ, wọ́n á sì wí pé: “Fi wá sílẹ̀ kí á wà pẹ̀lú àwọn olùjókòó sílé.” (87) Wọ́n yọ́nú sí kí wọ́n máa wà pẹ̀lú àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun ẹ̀sìn. Wọ́n ti fi èdídí dí ọkàn wọn pa; nítorí náà, wọn kò níí gbọ́ àgbọ́yé. (88) Ṣùgbọ́n Òjíṣẹ́ àti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun ẹ̀sìn. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn oore ń bẹ fún wọn. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùjèrè. (89) Allāhu ti pèsè sílẹ̀ dè wọ́n àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá. (90) Àwọn aláwàáwí nínú àwọn Lárúbáwá oko wá (bá ọ) nítorí kí wọ́n lè yọ̀ǹda (ìjókòó sílé) fún wọn. Àwọn tó sì pe ọ̀rọ̀ Allāhu àti ọ̀rọ̀ Òjíṣẹ́ nírọ́ náà jókòó sílé. Ọwọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro máa ba àwọn aláìgbàgbọ́ nínú wọn. (91) Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn aláìlágbára, àwọn aláìsàn àti àwọn tí kò rí ohun tí wọn máa ná ní owó (láti fi jagun ẹ̀sìn) nígbà tí wọ́n bá ti ní òtítọ́-inú sí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Kò sí ọ̀nà kan (tó máa já sí ìyà) fún àwọn olùṣe-rere sẹ́. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run. (92) Kò tún sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá wá bá ọ pé kí o fún àwọn ní n̄ǹkan tí àwọn yóò gùn (lọ sójú ogun), tí o sì sọ pé, “Èmi kò rí n̄ǹkan tí mo lè fún yín gùn (lọ sójú ogun), wọ́n máa padà pẹ̀lú ojú wọn tí yóò máa damije ní ti ìbànújẹ́ pé wọn kò rí n̄ǹkan tí wọ́n máa ná (lọ sójú ogun ẹ̀sìn). (93) Àwọn tí ọ̀nà kan (tó máa já sí ìyà) wà fún ni àwọn tó ń tọrọ ìyọ̀ǹda lọ́dọ̀ rẹ (láti jókòó sílé, tí) wọ́n sì jẹ́ ọlọ́rọ̀, tí wọ́n yọ́nú sí kí wọ́n wà pẹ̀lú àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun ẹ̀sìn. Allāhu ti fi èdídí dí ọkàn wọn pa; nítorí náà, wọn kò sì mọ̀. (94) Wọ́n yóò mú àwáwí wá fún yín nígbà tí ẹ bá dé bá wọn nílé. Sọ pé: "Ẹ má ṣe mú àwáwí wá; a ò níí gbà yín gbọ́. Allāhu kúkú ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ yín fún wa. Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ yó sì rí iṣẹ́ (ọwọ́) yín.¹ Lẹ́yìn náà, A óò da yín padà sí ọ̀dọ̀ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba. Nígbà náà, Ó máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. 1. Āyah yìí jọ āyah 105 níwájú nínú sūrah yìí. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Āli ‘Imrọ̄n; 3:101 àti sūrah an-Nisā’; 4:64. (95) Wọ́n yóò máa fi Allāhu búra fún yín nígbà tí ẹ bá dé bá wọn, nítorí kí ẹ lè pa wọ́n tì. Nítorí náà, ẹ pa wọ́n tì; dájúdájú ẹ̀gbin ni wọ́n. Iná Jahanamọ sì ni ibùgbé wọn. (Ó jẹ́) ẹ̀san nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́. (96) Wọ́n yóò máa búra fún yín nítorí kí ẹ lè yọ́nú sí wọn. Tí ẹ bá yọ́nú sí wọn, dájúdájú Allāhu kò níí yọ́nú sí ìjọ òbìlẹ̀jẹ́. (97) Àwọn Lárúbáwá oko le nínú àìgbàgbọ́ àti ìṣọ̀bẹ-ṣèlu. Ó sì súnmọ́ jùlọ pé wọ́n kò mọ àwọn ẹnu-ààlà ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. (98) Àti pé ó wà nínú àwọn Lárúbáwá oko ẹni tí ó ka ìnáwó tó ń ná (fún ẹ̀sìn) sí owó ọ̀ràn. Ó sì ń retí àpadàsí aburú fún yín. Àwọn sì ni àpadàsí aburú yóò dé bá. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀. (99) Ó tún wà nínú àwọn Lárúbáwá oko, ẹni tí ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí ó sì sọ ìnáwó tó ń ná (fún ẹ̀sìn) di ohun tí ó máa mú wọn súnmọ́ Allāhu àti ohun tí ó máa mú wọn gba àdùá lọ́dọ̀ Òjíṣẹ́. Kíyè sí i, dájúdájú ó máa mú wọn súnmọ́ Allāhu. Allāhu yó sì fi wọ́n sínú ìkẹ́ Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run. (100) Àwọn aṣíwájú, àwọn ẹni àkọ́kọ́ nínú àwọn Muhājirūn àti àwọn ’Ansọ̄r àti àwọn tó fi dáadáa tẹ̀lé wọn, Allāhu yọ́nú sí wọn. Wọ́n sì yọ́nú sí (ohun tí Allāhu fún wọn). Ó tún pa lésè sílẹ̀ dè wọ́n àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra tí odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ títí láéláé. Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá.
|
| | | أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 9 - Suuratut-Taobah الجمعة 21 يوليو 2023, 10:59 pm | |
| (101) Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí kan ń bẹ nínú àwọn tí ó wà ní àyíká yín nínú àwọn Lárúbáwá oko àti nínú àwọn ará ìlú Mọdīnah, tí wọ́n won̄koko mọ́ ìṣọ̀bẹ-ṣèlú. Ìwọ kò mọ̀ wọ́n, Àwa l’A mọ̀ wọ́n. A óò jẹ wọ́n níyà ní ẹ̀ẹ̀ mejì.¹ Lẹ́yìn náà, A óò dá wọn padà sínú ìyà ńlá. 1. Ìyà ẹ̀ẹ̀ mejì dúró fún ìyà tayé àti ìya tinú sàréè. (102) Àwọn mìíràn jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Wọ́n da iṣẹ́ rere pọ̀ mọ́ iṣẹ́ mìíràn tó burú. Bóyá Allāhu yóò gba ìronúpìwàdà wọn. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run. (103) Gba ọrẹ (Zakāh) nínú dúkìá wọn, kí o fi sọ wọ́n di ẹni mímọ́, kí o sì fi ṣe àfọ̀mọ́ fún wọn. Ṣe àdúà fún wọn. Dájúdájú àdúà rẹ ni ìfàyàbalẹ̀ fún wọn. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.¹ 1. Àwọn ikọ̀ méjì ni āyah yìí ń sọ nípa wọn. Ikọ̀ kìíní ni àwọn tó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá wọn - ní ìbámu sí āyah 102 tó ṣíwájú. Ikọ̀ kejì ni àwọn tó ń yọ zakāh. Zakāh yíyọ sì jẹ́ àfọ̀mọ́ dúkìá fún ẹni tí ó yọ ọ́. Àmọ́ lílo āyah náà fún gbígba owó àdúà yálà níbi ìsìnkú tàbí ní àyè mìíràn, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣe ń lo āyah náà, kò jẹmọ́ bẹ́ẹ̀ rárá nínú àwọn tírà Tafsīr. (104) Ṣé wọn kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu Òun l’Ó ń gba ìronúpìwàdà lọ́wọ́ àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, Ó sì ń gba àwọn ọrẹ, àti pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run? (105) Sọ pé: “Ẹ ṣiṣẹ́. Allāhu á rí iṣẹ́ yín. Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo náà (máa rí i).¹ Wọ́n sì máa da yín padà sọ́dọ̀ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀-àti-gban̄gba. Ó sì máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.” 1. Āyah yìí jọ āyah 94 nínú sūrah yìí. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Āli ‘Imrọ̄n; 3:101 àti sūrah an-Nisā’; 4:64. (106) Wọ́n so ọ̀rọ̀ àwọn yòókù rọ̀ ná títí àṣẹ Allāhu máa fi dé; yálà kí Ó jẹ wọ́n níyà tàbí kí Ó gba ìronúpìwàdà wọn.¹ Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. ² 1. Ìyẹn, àwọn tó ṣàì lọ sógun, àmọ́ tí wọn kò mú àwáwí irọ́ wá. 2. Àṣẹ náà dé nínú āyah 118 níwájú. (107) Àwọn tó kọ́ mọ́sálásí láti fi dá ìnira àti àìgbàgbọ́ sílẹ̀ àti láti fi ṣe òpínyà láààrin àwọn onígbàgbọ́ òdodo àti láti fi ṣe ibùlúgọ fún àwọn tó gbógun ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ní ìṣáájú - dájúdájú wọ́n ń búra pé “A ò gbèrò kiní kan bí kò ṣe ohun rere.” - Allāhu sì ń jẹ́rìí pé dájúdájú òpùrọ́ ni wọ́n. (108) Má ṣe dúró (kírun) nínú rẹ̀ láéláé.¹ Dájúdájú mọ́sálásí tí wọ́n bá fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí ìbẹ̀rù Allāhu láti ọjọ́ àkọ́kọ́ lo lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ pé kí o dúró (kírun) nínú rẹ̀. Àwọn ènìyàn tó nífẹ̀ẹ́ láti máa ṣe ìmọ́ra wà nínú rẹ̀. Allāhu sì fẹ́ràn àwọn olùṣèmọ́ra. 1. Kíyè sí i! Gbólóhùn yìí “Má ṣe dúró (kírun) nínú rẹ̀ láéláé.” àti āyah 107 ló ń ṣe é ní èèwọ̀ fún àwa mùsùlùmí onisunnah láti kírun nínú àwọn mọ́sálásí àwọn mùsùlùmí onibidiah pẹ̀lú májẹ̀mu pé tí ó bá jẹ́ pé wọ́n fi mọ́sálásí náà sọrí bid‘ah wọn. Irú àwọn mọ́sálásí tí èyí kàn ni mọ́sálásí Ahmadiyyah àti Zāwiyah àwọn oníwírìdí Tijāniyah, Ƙọ̄diriyyah àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Tí ó bá wá jẹ́ pé wọn kò fi mọ́sálásí sọrí bid‘ah, àmọ́ tí wọ́n fi imām ẹlẹ́sìn Ahmadiyyah tàbí ẹlẹ́sìn Tijāniyyah tàbí Ƙọ̄diriyyah ṣe imām nínú mọ́sálásí náà, mùsùlùmí lè kírun nínú mọ́sálásí náà kò kàn níí kírun lẹ́yìn imām onibid'ah yẹn ni. (109) Ǹjẹ́ ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilé mímọ tirẹ̀ lélẹ̀ lórí ìbẹ̀rù Allāhu àti ìyọ́nú (Rẹ̀) ló lóore jùlọ ni tàbí ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilé mímọ tirẹ̀ lélẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ kan létí ọ̀gbun tó máa yẹ̀ lulẹ̀, tí ó sì máa yẹ̀ ẹ́ lẹ́sẹ̀ sínú iná Jahanamọ? Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí. (110) Ilé wọn tí wọ́n mọ kalẹ̀ kò níí yé kó iyèméjì sínú ọkàn wọn títí ọkàn wọn yóò fi já kélekèle. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. (111) Dájúdájú Allāhu ra ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo àti dúkìá wọn nítorí pé dájúdájú tiwọn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra. Wọ́n ń jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu; wọ́n ń pa ọ̀tá ẹ̀sìn, wọ́n sì ń pa àwọn náà. (Ó jẹ́) àdéhùn òdodo lọ́dọ̀ Allāhu nínú at-Taorāh, al-’Injīl àti al-Ƙur’ān. Ta sì ni ó lè mú àdéhùn rẹ̀ ṣẹ ju Allāhu? Nítorí náà, ẹ dunnú sí òkòwò yín tí ẹ (fi ẹ̀mí àti dúkìá yin) ṣe. Ìyẹn, òhun sì ni èrèǹjẹ ńlá. (112) Àwọn olùronúpìwàdà, àwọn olùjọ́sìn (fún Allāhu), àwọn olùdúpẹ́ (fún Allāhu), àwọn aláààwẹ̀, àwọn olùdáwọ́tẹ-orúnkún (lórí ìrun), àwọn olùforíkanlẹ̀ (fún Allāhu), àwọn olùpàṣẹ-ohun rere, àwọn olùkọ-ohun burúkú àti àwọn olùṣọ́-ẹnu-ààlà tí Allāhu gbékalẹ̀, fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo (wọ̀nyí) ní ìró ìdùnnú (Ọgbà Ìdẹ̀ra). (113) Kò yẹ fún Ànábì àti àwọn tó gbàgbọ́ lódodo láti tọrọ àforíjìn fún àwọn ọ̀sẹbọ, wọn ìbáà jẹ́ ẹbí, lẹ́yìn tí ó ti hàn sí wọn pé dájúdájú èrò inú iná Jẹhīm ni wọ́n. (114) Àti pé àforíjìn tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm tọrọ fún bàbá rẹ̀ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe nítorí àdéhùn tó ṣe fún un. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó hàn sí i pé dájúdájú ọ̀tá Allāhu ni (bàbá rẹ̀), ó yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú rẹ̀. Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ni olùrawọ́rasẹ̀, olùfaradà. (115) Allāhu kì í mú ìṣìnà bá ìjọ kan, lẹ́yìn ìgbà tí Ó ti tọ́ wọn sọ́nà, títí (Allāhu) yóò fi ṣe àlàyé n̄ǹkan tí wọ́n máa ṣọ́ra fún fún wọn. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.¹ 1. Ìyẹn ni pé, à ò níí pe mùsùlùmí ní olùṣìnà bí ó bá ṣe n̄ǹkan tí kò yẹ kí ó ṣe níwọ̀n ìgbà tí kò ì sí ẹ̀rí kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu tí ó ṣe é ní èèwọ̀ fún un àfi lẹ́yìn ìgbà tí ẹ̀rí bá dé bá a, tí ó tún wá ń ṣe n̄ǹkan náà lọ. (116) Dájúdájú Allāhu ló ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Kò sì sí aláàbò àti alárànṣe kan fún yín lẹ́yìn Allāhu. (117) Dájúdájú Allāhu ti gba ìronúpìwàdà Ànábì, àwọn Muhājirūn àti àwọn ’Ansọ̄r, àwọn tó tẹ̀lé e ní àkókò ìṣòro lẹ́yìn tí ọkàn ìgun kan nínú wọn fẹ́ẹ̀ yí padà, (àmọ́) lẹ́yìn náà, Allāhu gba ìronúpìwàdà wọn. Dájúdájú Òun ni Aláàánú, Àṣàkẹ́-ọ̀run fún wọn. (118) (Ó tún gba ìronúpìwàdà) àwọn mẹ́ta tí A so ọ̀rọ̀ gbígba ìronúpìwàdà wọn rọ̀ (nínú àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun Tabūk. Àwọn mùsùlùmí dẹ́yẹ sí wọn) títí ilẹ̀ fi fún mọ́ wọn tòhun ti bí ó ṣe fẹjú tó. Ọ̀rọ̀ ara wọn sì ṣú ara wọn. Wọ́n sì mọ̀ (ní àmọ̀dájú) pé kò sí ibùsásí kan tí àwọn fi lè sá mọ́ Allāhu lọ́wọ́ àfi kí wọ́n sá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Allāhu gba ìronúpìwàdà wọn nítorí kí wọ́n lè máa ronú pìwàdà. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run. (119) Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì wà pẹ̀lú àwọn olódodo. (120) Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún àwọn ará ìlú Mọdīnah àti ẹni tí ó wà ní àyíká wọn nínú àwọn Lárúbáwá oko láti sá sẹ́yìn fún Òjíṣẹ́ Allāhu (nípa ogun ẹ̀sìn. Kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún wọn) láti fẹ́ràn ẹ̀mí ara wọn ju ẹ̀mí rẹ̀. Ìyẹn nítorí pé dájúdájú òǹgbẹ, ìnira àti ebi kan kò níí ṣẹlẹ̀ sí wọn ní ojú-ọ̀nà Allāhu (lójú ogun), wọn kò sì níí tẹ ọ̀nà kan tí ń bí àwọn aláìgbàgbọ́ nínú, àti pé ọwọ́ wọn kò níí ba kiní kan lára ọ̀tá (yálà ọrọ̀ ogun tàbí ẹ̀mí wọn) àfi kí wọ́n fi kọ iṣẹ́ rere sílẹ̀ fún wọn. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ẹ̀san àwọn olùṣe-rere ráre. (121) Wọn kò sì níí ná owó kékeré tàbí púpọ̀ (fún ogun ẹ̀sìn), tàbí kí wọ́n la àfonífojì kan kọ já àfi kí wọ́n kọ ọ́ sílẹ̀ fún wọn nítorí kí Allāhu lè san wọ́n ní ẹ̀san rere tó dára ju ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́. (122) Àwọn mùsùlùmí kò ní láti tú jáde tán nílé pátápátá. Èé ṣe tí igun kan nínú wọn nínú ikọ̀ kọ̀ọ̀kan kò fi jáde láti wá àgbọ́yé ìmọ̀ nípa ẹ̀sìn, kí wọ́n sì máa ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn wọn nígbà tí wọ́n bá padà sọ́dọ̀ wọn nítorí kí wọ́n lè ṣọ́ra ṣe. (123) Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ gbógun ti àwọn tó súnmọ́ yín nínú àwọn aláìgbàgbọ́; kí wọ́n rí ìlekoko lára yín. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀). (124) Nígbà tí A bá sì sọ sūrah kan kalẹ̀, ó ń bẹ nínú wọn ẹni tí ó máa wí pé: “Èwo nínú yín ni èyí lé ìgbàgbọ́ (rẹ̀) kún?” Ní ti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, (āyah náà) yóò lé ìgbàgbọ́ (wọn) kún. Wọn yó sì máa dunnú. (125) Ní ti àwọn tí àìsàn kan wà nínú ọkàn wọn, (āyah náà) yó sì ṣe àlékún ẹ̀gbin sí ẹ̀gbin wọn. Wọn yó sì kú sí ipò aláìgbàgbọ́. (126) Ṣé wọn kò rí i pé wọ́n ń dán wọn wò ní ẹ̀ẹ̀ kan tàbí ẹ̀ẹ̀ méjì ní ọdọọdún. Lẹ́yìn náà, wọn kò ronú pìwàdà, wọn kò sì lo ìrántí. (127) Àti pé nígbà tí A bá sọ sūrah kan kalẹ̀, apá kan wọn yóò wo apá kan lójú (wọn yó sì wí pé): “Ṣé ẹnì kan ń wò yín bí?” Lẹ́yìn náà, wọ́n máa pẹ̀yìndà. Allāhu sì pa ọkàn wọn dà (sódì) nítorí pé dájúdájú àwọn ni ìjọ kan tí kò gbọ́ àgbọ́yé. (128) Dájúdájú Òjíṣẹ́ kan ti wá ba yín láti ààrin yín. Ohun tí ó máa kó wàhálà ba yín lágbára lára rẹ̀. Ó ń ṣe àkólékàn (oore) fún yín; aláàánú àti oníkẹ̀ẹ́ ni fún àwọn oní gbàgbọ́ òdodo. (129) Nítorí náà, tí wọ́n bá pẹ̀yìndà, sọ pé: “Allāhu tó fún mi. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Òun ni mo gbáralé. Òun sì ni Olúwa Ìtẹ́ ńlá.
|
| | | | 9 - Suuratut-Taobah | |
|
| صلاحيات هذا المنتدى: | لاتستطيع الرد على المواضيع في هذا المنتدى
| |
| |
| |