61 - Suuratus-Soff
Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
(1) Ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ń ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
(2) Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nítorí kí ni ẹ ṣe ń sọ ohun tí ẹ ò níí ṣe níṣẹ́?
(3) Ó jẹ́ ohun ìbínú tó tóbi ní ọ̀dọ̀ Allāhu pé kí ẹ sọ ohun tí ẹ ò níí ṣe.
(4) Dájúdájú Allāhu fẹ́ràn àwọn tó ń jagun sí ojú-ọ̀nà Rẹ̀ (tí wọ́n tò ní) ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ bí ẹni pé ilé tí wọ́n lẹ̀pọ̀ mọ́ra wọn ni wọ́n
(5) (Rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, nítorí kí ni ẹ óò ṣe fi ìnira kàn mí. Ẹ sì kúkú mọ̀ pé, dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu ni èmi jẹ́ si yín.” Nígbà tí wọ́n sì yẹ̀ (kúrò níbi òdodo), Allāhu yẹ ọkàn wọn. Allāhu kò sì níí fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.
(6) (Rántí) nígbà tí ‘Īsā ọmọ Mọryam sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ Allāhu si yín. Mò ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó ṣíwájú mi nínú Taorāh. Mo sì ń mú ìró-ìdùnnú wá nípa Òjíṣẹ́ kan tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi. Orúkọ rẹ̀ ni ’Ahmọd.”¹ Nígbà tí ó bá sì wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú, wọ́n á wí pé: “Idán pọ́nńbélé ni èyí.”
1. Láti ọ̀dọ̀ Jubaer ọmọ Mut‘im - kí Allāhu yọ́nú sí i -, Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu má abá a - sọ pé: “(Orúkọ mi nìwọ̀nyí): èmi ni Muhammad. Èmi ni ’Ahmad. Èmi ni Mọ̄hī, ẹni tí Allāhu fi pa àìgbàgbọ́ rẹ́. Èmi ni Hāṣir, ẹni tí wọn yóò kó àwọn ènìyàn jọ lẹ́yìn rẹ̀ fún Àjíǹde. Èmi sì ni ‘Āƙib, ẹni tí kò níí sí Ànábì kan mọ́ lẹ́yìn rẹ̀.” (Muslim).
(7) Ta sì ni ó ṣàbòsí tó tayọ ẹni tí ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu, tí wọ́n sì ń pè é sínú ’Islām! Allāhu kò sì níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.
(8) Wọ́n ń gbèrò láti fi (ọ̀rọ̀) ẹnu wọn pa ìmọ́lẹ̀ Allāhu. Allāhu yó sì mú ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ tàn kárí, àwọn aláìgbàgbọ́ ìbáà kórira rẹ̀.
(9) (Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó fi ìmọ̀nà àti ẹ̀sìn òdodo (’Islām) rán Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí Ó lè fi borí gbogbo ẹ̀sìn (mìíràn) pátápátá, àwọn ọ̀ṣẹbọ ìbáà kórira rẹ̀.
(10) Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ṣé kí N̄g tọ́ka yín sí òkòwò kan tí ó máa gbà yín là nínú ìyà ẹlẹ́ta-eléro?
(11) Ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, ẹ jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu pẹ̀lú àwọn dúkìá yín àti ẹ̀mí yín. Ìyẹn lóore jùlọ fún yín tí ẹ bá mọ̀.
(12) (Allāhu) máa forí ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. Ó sì máa mu yín wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀ àti àwọn ibùgbé tó dára nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére. Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá.
(13) Àti n̄ǹkan mìíràn tí ẹ tún nífẹ̀ẹ́ sí; (ìyẹn) àrànṣe láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti ìṣẹ́gun tó súnmọ́. Kí o sì fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ìró ìdùnnú.
(14) Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jẹ́ alárànṣe fún (ẹ̀sìn) Allāhu gẹ́gẹ́ bí (Ànábì) ‘Īsā ọmọ Mọryam ṣe sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ta ni ó máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi nípa (ẹ̀sìn) Allāhu?” Àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sọ pé: “Àwa ni alárànṣe (fún ẹ̀sìn) Allāhu.” Igun kan nínú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl gbàgbọ́ ní òdodo nígbà náà, igun kan sì ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀. A sì fún àwọn tó gbàgbọ́ lágbára lórí àwọn ọ̀tá wọn; wọ́n sì di olùborí.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah āl ‘Imrọ̄n; 3:55.