أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: 32 - Suuratus-Saj'dah السبت 22 يوليو 2023, 7:57 am | |
| 32 - Suuratus-Saj'dah Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run. (1) ’Alif lām mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)¹ 1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1. (2) Ìsọ̀kalẹ̀ Tírà náà, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀ (pé ó wá) láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá. (3) Tàbí wọ́n ń wí pé: “Ó dá àdápa irọ́ rẹ̀ ni.” Rárá o! Òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ nítorí kí o lè fi ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn kan, tí olùkìlọ̀ kan kò wá bá wọn rí ṣíwájú rẹ, nítorí kí wọ́n lè mọ̀nà.¹ 1 Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Ƙọsọs; 28:46. (4) Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan tó wà láààrin méjèèjì láààrin ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá. Kò sí aláàbò àti olùṣìpẹ̀ kan fún yín lẹ́yìn Rẹ̀. Ṣé ẹ kò níí lo ìrántí ni? (5) Ó ń ṣètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá) láti sánmọ̀ wá sórí ilẹ̀. Lẹ́yìn náà, (àbọ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀dá) yóò gùnkè tọ̀ Ọ́ lọ láààrin ọjọ́ kan tí òdiwọ̀n rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún ọdún nínú òǹkà tí ẹ̀ ń kà.¹ 1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Hajj; 22:47. (6) Ìyẹn ni Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba, Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run, (7) Ẹni tó ṣe gbogbo n̄ǹkan tí Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ ní dáadáa. Ó sì bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ènìyàn láti inú ẹrẹ̀. (8) Lẹ́yìn náà, Ó ṣe àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ láti ara ohun tí A mú jáde láti ara omi lílẹ yẹpẹrẹ. (9) Lẹ́yìn náà, Ó to (oríkèéríkèé) rẹ̀ dọ́gba. Ó sì fẹ́ (ẹ̀mí) sí i lára nínú ẹ̀mí Rẹ̀ (tí Ó dá).¹ Ó tún ṣe ìgbọ́rọ̀, ìríran àti ọkàn fún yín. Díẹ̀ ni ọpẹ́ tí ẹ̀ ń dá! 1. “ẹ̀mí” nínú āyah yìí ṣe wẹ́kú “ẹ̀mí” tó jẹyọ nínú sūrah an-Nisā’; 4:171. (10) Wọ́n sì wí pé: “Ǹjẹ́ nígbà tí a bá ti pòórá sínú ilẹ̀, ǹjẹ́ àwa tún lè wà ní ẹ̀dá titun mọ́? Àní sẹ́, àwọn ni aláìgbàgbọ́ nínú ìpàdé Olúwa wọn. (11) Sọ pé: “Mọlāika ikú èyí tí A yàn fún yín máa gba ẹ̀mí yín. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni wọn máa da yín padà sí.”¹ 1. Àwọn nasọ̄rọ̄ lérò pé àwọn āyah tó ń sọ nípa ẹ̀mí gbígbà tàbí ikú takora wọn nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Wọ́n ní àwọn āyah náà ni: sūrah az-Zumọr; 39:42, sūrah al-’Anfāl; 8:50, sūrah al-’Ani‘ām; 6:61 àti sūrah as-Sajdah; 32:11. Èsì: Ní àkọ́kọ́ ná, Allāhu ni Ẹlẹ́dàá ìṣẹ̀mí àti ikú, gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe jẹ́ Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. Kò sí ẹ̀dá kan tí ó máa tọ́ ìṣẹ̀mí wò àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu ẹni tí Ó ń sọni di alààyè. Kò sì sí ẹ̀dá kan tí ó máa tọ́ ikú wò àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu ẹni tí Ó ń sọni di òkú. Nípa èyí, Allāhu l’Ó ń fi àṣẹ Rẹ̀ gba ẹ̀mí kúrò lára ẹ̀dá Rẹ̀ ní àkókò tí Ó ti kọ mọ́ ọn nínú kádàrá. Ìyẹn ni ó jẹyọ nínú sūrah az-Zumọr; 39:42. Bákan náà, Allāhu ṣẹ̀dá àwọn mọlāika gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ àti òjíṣẹ́ Rẹ̀ lórí gbogbo n̄ǹkan. Nípa èyí, àwọn mọlāika kan wà fún ẹ̀mí gbígbà. Ìyẹn l’ó jẹyọ nínú sūrah al-’Anfāl; 8:50 àti sūrah al-’Ani‘ām; 6:61. Allāhu sì fi ẹnì kan ṣe ọ̀gá nínú àwọn mọlāika tó wà níbi ẹ̀mí gbígbà. Ọ̀gá yìí l’ó sì gbé orúkọ àti àwòrán ikú rù. Ìyẹn ni ó jẹyọ nínú sūrah as-Sajdah; 32:11. Níbo wá ni ìtakora wà? Kò sí. Al-hamdulillah. (12) (Ìwọ ìbá rí èèmọ̀) tí ó bá jẹ́ pé o rí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ nígbà tí wọ́n bá sorí kọ́ ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn, (wọ́n sì máa wí pé): “Olúwa wa, a ti ríran, a sì ti gbọ́ràn (báyìí), nítorí náà, dá wa padà (sí ilé ayé) nítorí kí á lè lọ ṣe iṣẹ́ rere; dájúdájú àwa ni alámọ̀dájú.” (13) Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́ ni, dájúdájú A ìbá fún gbogbo ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ìmọ̀nà rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà ti ṣẹ láti ọ̀dọ̀ Mi (báyìí pé): “Dájúdájú Mo máa mú nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn ní àpapọ̀ kún inú iná Jahanamọ.” (14) Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà wò nítorí pé ẹ ti gbàgbé ìpàdé ọjọ́ yín (òní) yìí. Dájúdájú Àwa náà yóò gbàgbé yín (sínú Iná). Ẹ tọ́ ìyà gbére wò nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.¹ 1. Allāhu kì í ṣe onígbàgbé. Nítorí náà, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:15. (15) Àwọn tó gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa ni àwọn tí ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá fi ṣe ìṣítí fún wọn, wọn yóò dojú bolẹ̀ ní olùforíkanlẹ̀, wọn yó sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa wọn. Wọn kò sì níí ṣègbéraga. (16) Wọ́n ń gbé ẹ̀gbẹ́ wọn jìnnà sí ibùsùn. Wọ́n sì ń pe Olúwa wọn ní ti ìpáyà àti ìrètí. Wọ́n sì ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn. (17) Kò sí ẹ̀mí kan tí ó mọ ohun tí A fi pamọ́ fún wọn nínú àwọn n̄ǹkan ìtutù ojú. (Ó jẹ́) ẹ̀san ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (rere). (18) Ǹjẹ́ ẹni tó jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo dà bí ẹni tó jẹ́ òbìlẹ̀jẹ́ bí? Wọn kò dọ́gba. (19) Ní ti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, àwọn ibùgbé (nínú) Ọ̀gbà Ìdẹ̀ra ń bẹ fún wọn. (Ó jẹ́) ohun tí A pèsè sílẹ̀ (dè wọ́n) nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (rere). (20) Ní ti àwọn tó balẹ̀jẹ́, Iná ni ibùgbé wọn. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá fẹ́ jáde kúrò nínú rẹ̀, A ó sì máa dá wọn padà sínú rẹ̀. A sì máa sọ fún wọn pé: “Ẹ tọ́ ìyà Iná tí ẹ̀ ń pè ní irọ́ wò.”¹ 1. Láti ọ̀dọ̀ Yẹzīd Faƙīr, ó sọ pé, ìròrí kan nínú ìròrí ìjọ Kawārij ti kó sínú ọkàn mi. A sì jáde pẹ̀lú àwọn ènìyàn kan tí ó ní òǹkà, à = = ń lọ ṣe hajj. Lẹ́yìn náà, a máa ń jáde lọ bá àwọn ènìyàn. A sì gba Mọdīnah kọjá ni a bá rí Jābir ọmọ ‘Abdullāh tí ó ń sọ hadīth fún àwọn ènìyàn, ó jókòó síbi òpó kan, ó sọ pé láti ọ̀dọ̀ Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ó sọ pé, … Àti pé Jābir sọ ọ̀rọ̀ àwọn Jahannamiyyūn. Yẹzīd sọ pé, mo sọ fún un pé, “Ìwọ Sọhābah Òjíṣẹ́ Allāhu, kí ni èyí tí ò ń sọ nínú hadīth báyìí o, tí Allāhu sì ń sọ pé, “ẹnikẹ́ni tí O bá mú wọ inú Iná, O ti dójú tì í.” (Sūrah āli-‘Imrọ̄n; 3:192), Allāhu tún sọ pé, “Ìgbàkígbà tí wọ́n bá fẹ́ jáde kúrò nínú rẹ̀, A ó sì máa dá wọn padà sínú rẹ̀.” (sūrah as-Sajdah; 32:20) Nítorí náà, kí ni èyí tí ẹ wá ń sọ (pé hadīth kan sọ pe - àwọn kan máa jáde kúrò nínú Iná)?” Yẹzīd sọ pé, Jābir sọ pé, “Ṣé o máa ń ké al-Ƙur’ān?” Mo sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.” Jābir tún sọ pé, “Ǹjẹ́ o gbọ́ nípa àyè Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ìyẹn, ibi tí Allāhu máa gbé e sí ní ọ̀run?” Mo sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.” Jābir sọ pé, “Dájúdájú àyè Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni àyè ògo èyí tí Allāhu yóò máa fi ẹni tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - bá fẹ́ mú jáde kúrò nínú Iná kúrò nínú Iná.” Yẹzīd sọ pé, lẹ́yìn náà Jābir ròyìn àgbékalẹ̀ afárá Iná àti kíkọjá àwọn ènìyàn lórí rẹ̀. Yẹzīd sọ pé, “Mò ń páyà pé èmi kò rí i há sórí ju ìyẹn.” Yẹzīd tún sọ pé, yàtọ̀ sí pé dájúdájú Jābir sọ pé, “Dájúdájú àwọn ìjọ kan máa jáde kúrò nínú Iná lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wà nínú rẹ̀.” Ó sọ pé, ìyẹn túmọ̀ sí pé, “Wọ́n máa jáde kúrò nínú rẹ̀, wọ́n sì máa dàbí igi ìdáná simsim.” Jābir sọ pé, “Wọ́n máa wọ inú odò kan nínú odò Ọgbà Ìdẹ̀ra. Wọ́n máa wẹ̀ nínú rẹ̀, wọ́n sì máa jáde bí ẹni pé dájúdájú ìwé àjákọ fúnfun ni wọ́n.” Lẹ́yìn náà, a padà sí ìlú, a sì sọ pé, “Ṣíọ̀ yín - ẹ̀yin Kawārij - ṣé ẹ lérò pé àgbàlágbà Sọhābah ń parọ́ mọ́ Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni?” Nítorí náà, àwa ṣẹ́rí padà kúrò níbi ìròrí kawārij. Mo sì fi Allāhu búra, kò sí ẹnì kan nínú wa tí ó yapa òdodo náà yàtọ̀ sí ọkùnrin ẹyọ kan - tàbí gẹ́gẹ́ bí bàbá Nu‘aem ṣe sọ.” (Àwọn ènìyàn wọ̀nyí wá fún iṣẹ́ hajj, wọ́n sì ní àdánwò àṣìgbọ́ kan pé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ńlá, yàtọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ abẹ̀sìnjẹ́, wọn kò níí jáde kúrò nínú Iná gẹ́gẹ́ bí àwọn kèfèrí àti àwọn ọ̀ṣẹbọ ṣe máa ṣe gbére nínú Iná. Àwọn ènìyàn náà ń lo àwọn āyah tó wá lórí ọ̀rọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́ fún àwọn mùsùlùmí tí wọ́n kú sórí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá. Àdìsọ́kàn náà jẹ ọ̀kan nínú àwọn àdìsọ́kàn ìjọ Kawārij. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí sì ń jáde sí àwọn ènìyàn pẹ̀lú àdìsọ́kàn burúkú yìí lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n parí iṣẹ́ hajj. Àmọ́ lórí ìrìn-àjò náà, Allāhu fi wọ́n ṣe kòǹgẹ́ Sọhābah kan Jābir ọmọ ‘Abdullāh ’Ansọ̄riy - kí Allāhu yọ́nú sí àwọn méjèèjì -. Ó sì ṣàlàyé aburú àṣìgbọ́ wọn fún wọn. Wọ́n sì kúrò lórí ohun tí wọ́n ti dì sọ́kàn tẹ́lẹ̀ àfi ẹnì kan nínú wọn tí ó kọ òdodo náà. Ìṣẹ̀lẹ́ yìí tún fi hàn pé, àlòpọ̀ mọ́ra wọn ni al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé àti hadīth Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tí ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àṣìgbọ̀ ẹ̀sìn ni mùsùlùmí yóò máa kàkún àgbọ́yé ẹ̀sìn.) (21) Dájúdájú A máa fún wọn tọ́ wò nínú ìyà tó kéré jùlọ (nílé ayé) yàtọ̀ sí ìyà tó tóbi jùlọ (lọ́run) nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo ṣíwájú ikú wọn). (22) Àti pé ta l’ó ṣe àbòsí tó tayọ ẹni tí wọn fi àwọn āyah Wa ṣe ìṣítí fún, lẹ́yìn náà, tí ó gbúnrí kúrò níbẹ̀? Dájúdájú Àwa máa gbẹ̀san lára àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. (23) Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. Nítorí náà, má ṣe wà nínú iyèméjì nípa bí ó ṣe pàdé rẹ̀ (ìyẹn, nínú ìrìn-àjò òru àti gígun sánmọ̀).¹ A sì ṣe Tírà A sì ṣe Tírà náà ní ìmọ̀nà fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. 1. ﴿ فَلَا تَكُن فِى مِرْيَةٍۢ مِّن لِّقَآئِهِۦ ﴾ Ìtúmọ̀ mìíran fún gbólóhùn yìí, “Nítorí náà, má ṣe wà nínú iyèméjì nípa kéú al-Ƙur’ān tí ò ń gbà lọ́dọ̀ mọlāika Jibrīl - kí ọlà Allāhu máa bá a - . ” (24) Àti pé A ṣe àwọn kan nínú wọn ní Imām (aṣíwájú) tí wọ́n ń fi àṣẹ Wa (ohun tí A pa wọ́n ní àṣẹ rẹ̀ nínú at-Taorāh) tọ́ àwọn ènìyàn wọn sí ọ̀nà òdodo. (A ṣe wọ́n bẹ́ẹ̀) nígbà tí wọ́n ṣe sùúrù, tí wọ́n sì ní àmọ̀dájú nípa àwọn āyah Wa. (25) Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó máa ṣe ìdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀. |
|
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 32 - Suuratus-Saj'dah السبت 22 يوليو 2023, 7:57 am | |
| (26) Ṣé kò fojú hàn sí wọn pé, mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn. Àwọn náà sì ń rìn kọjá nínú àwọn ibùgbé wọn! Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn. Nítorí náà, ṣé wọn kò níí tẹ́tí gbọ́rọ̀ (òdodo ni)? (27) Tàbí wọn kò rí i pé dájúdájú Àwa l’À ń wa omi òjò lọ sórí ilẹ̀ gbígbẹ, tí A sì ń fi mú irúgbìn jáde? Àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn àti àwọn náà sì ń jẹ nínú rẹ̀. Nítorí náà, ṣé wọn kò ríran ni? (28) Wọ́n sì ń wí pé: “Ìgbà wo ni Ìdájọ́ yìí máa ṣẹlẹ̀ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?” (29) Sọ pé: “Ní Ọjọ́ Ìdájọ́, ìgbàgbọ́ tí àwọn ọ̀ṣẹbọ máa fẹ́ ní nígbà tí wọ́n bá fojú rí ìyà Iná kò níí ṣe wọ́n ní àǹfààní. A kò sì níí fún wọn ní ìsinmi (nínú Iná).”¹ 1. Irú āyah yìí ni sūrah al-’An‘ām; 6:158. (30) Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn, kí o sì máa retí (Ọjọ́ Ìdájọ́). Dájúdájú àwọn náà ń retí (rẹ̀). |
|