57 - Suuratul-Hadiid
Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
(1) Ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ń ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
(2) TiRẹ̀ ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Òun ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
(3) Òun ni Àkọ́kọ́ àti Ìkẹ́yìn. Ó hàn (pẹ̀lú àmì bíbẹ Rẹ̀). Ó sì pamọ́ (fún gbogbo ojú nílé ayé). Òun ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
(4) Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sí orí Ìtẹ́-ọlá. Ó mọ n̄ǹkan tó ń wọ inú ilẹ̀ àti n̄ǹkan tó ń jáde láti inú rẹ̀, àti n̄ǹkan tó ń sọ̀kalẹ̀ láti inú sánmọ̀ àti n̄ǹkan tó ń gùnkè sínú rẹ̀. Àti pé Ó wà pẹ̀lú yín ní ibikíbi tí ẹ bá wà (pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀).¹ Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Mujādilah 58:7.
(5) TiRẹ̀ ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí.
(6) Ó ń ti òru bọ inú ọ̀sán. Ó sì ń ti ọ̀sán bọ inú òru. Òun sì ni Onímọ̀ nípa ohun tó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá.
(7) Ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Kí ẹ sì ná nínú ohun tí Ó fi yín ṣe àrólé lórí rẹ̀. Nítorí náà, àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nínú yín, tí wọ́n sì náwó (sí ojú ọ̀nà ẹ̀sìn), ẹ̀san tó tóbi wà fún wọn.
(8) Kí ni ó mu yín tí ẹ̀yin kò fi níí gbàgbọ́ ní òdodo nínú Allāhu? Òjíṣẹ́ náà sì ń pè yín nítorí kí ẹ lè gbàgbọ́ ní òdodo nínú Olúwa yín. Allāhu sì ti gba àdéhùn lọ́wọ́ yín, tí ẹ̀yin bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
(9) Òun ni Ẹni tó ń sọ àwọn āyah tó yanjú kalẹ̀ fún ẹrúsìn Rẹ̀ nítorí kí ó lè mu yín kúrò nínú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀. Dájúdájú Allāhu ni Aláàánú, Àṣàkẹ́-ọ̀run fún yín.
(10) Kí ni ó mu yín tí ẹ̀yin kò fi níí náwó sí ojú-ọ̀nà Allāhu? Ti Allāhu sì ni ogún àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ẹni tí ó náwó ṣíwájú ṣíṣí ìlú Mọkkah, tí ó tún jagun ẹ̀sìn, kò dọ́gba láààrin yín (sí àwọn mìíràn). Àwọn wọ̀nyẹn ni ẹ̀san wọn tóbi ju ti àwọn tó náwó lẹ́yìn ìgbà náà, tí wọ́n tún jagun ẹ̀sìn. Ẹnì kọ̀ọ̀kan sì ni Allāhu ṣ’àdéhùn ẹ̀san rere fún. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
(11) Ta ni ẹni tí ó máa yá Allāhu ní dúkìá tó dára, Ó sì máa ṣàdìpèlé rẹ̀ fún un. Ẹ̀san alápọ̀n-ọ́nlé sì tún wà fún un.
(12) Ní ọjọ́ tí o máa rí àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, tí ìmọ́lẹ̀ wọn yóò máa tàn níwájú wọn àti ní ọwọ́ ọ̀tún wọn, (A óò sọ pé:) “́Ìró ìdùnnú yín ní òní ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀.” Olùṣegbére ni yín nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá.
(13) Ní ọjọ́ tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lọ́kùnrin àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lóbìnrin yóò wí fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo pé: “Ẹ dúró fún wa ná, ẹ jẹ́ kí á mú nínú ìmọ́lẹ̀ yín.” A óò sọ fún wọn pé: “Ẹ padà s’ẹ́yìn yín, kí ẹ lọ mú ìmọ́lẹ̀.”¹ Wọ́n sì máa fi ògiri kan tó ní ìlẹ̀kùn sáàrin wọn. Ìkẹ́ wà nínú rẹ̀ (ìyẹn ní ẹ̀yìn ìlẹ̀kùn náà ní ibi tí àwọn onígbàgbọ́ òdodo wà), ìyà sì wà ní òde rẹ̀ ní ọwọ́ iwájú rẹ̀ (ní ibi tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí).
1. Èyí ni ọjọ́ tí Allāhu - Ọba Ẹlẹ́san - máa tan àwọn munāfiki gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe sọ ṣíwájú nínú sūrah an-Nisā’; 4:142. Lẹ́yìn náà, kí ẹ ka ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:15.
(14) (Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí) yóò pe (àwọn onígbàgbọ́ òdodo) pé: “́Ṣé àwa kò ti wà pẹ̀lú yín ni?”́ Wọ́n sọ pé: “́Rárá, ṣùgbọ́n ẹ kó ìyọnu bá ẹ̀mí ara yín (nípasẹ̀ ìṣọ̀bẹ-ṣèlu), ẹ retí ìparun (wá), ẹ sì ṣeyèméjì (sí òdodo). Àwọn ìfẹ́-ọkàn àti ọ̀rọ̀ irọ́ sì tàn yín jẹ títí àṣẹ Allāhu fi dé. Àti pé (Èṣù) ẹlẹ́tàn sì tàn yín jẹ nípa Allāhu.
(15) Nítorí náà, ní òní Àwa kò níí gba ìtánràn kan ní ọwọ́ ẹ̀yin àti àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Iná ni ibùgbé yín. Òhun l’ó tọ́ si yín. Ìkángun náà sì burú.
(16) Ṣé àkókò kò tí ì tó fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo pé kí ọkàn wọn rọ̀ fún ìrántí Allāhu àti ohun tó sọ̀kalẹ̀ nínú òdodo (ìyẹn, al-Ƙur’ān). Kí wọ́n sì má ṣe dà bí àwọn tí A fún ní Tírà ní ìṣáájú; ìgbà pẹ́ lórí wọn, ọkàn wọn bá le. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́.
(17) Ẹ mọ̀ pé dájúdájú Allāhu l’Ó ń sọ ilẹ̀ di àyè lẹ́yìn tí ilẹ̀ ti kú. A kúkú ti ṣàlàyé àwọn āyah náá nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.
(18) Dájúdájú àwọn olùtọrẹ lọ́kùnrin àti àwọn olùtọrẹ lóbìnrin, tí wọ́n tún yá Allāhu ní dúkìá tó dára, (Allāhu) yóò ṣàdìpèlé rẹ̀ fún wọn. Ẹ̀san alápọ̀n-ọ́nlé sì wà fún wọn.
(19) Àwọn tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olódodo àti ẹlẹ́rìí ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Ẹ̀san wọn àti ìmọ́lẹ̀ wọn wà fún wọn. Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n tún pe àwọn āyah Wa ní irọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú iná Jẹhīm.
(20) Ẹ mọ̀ pé dájúdájú ìṣẹ̀mí ayé yìí jẹ́ eré, ìranù, ọ̀ṣọ́, ṣíṣe ìyanràn láààrin ara yín àti wíwá ọ̀pọ̀ dúkìá àti ọmọ. (Ìwọ̀nyí) dà bí òjò (tó mú irúgbìn jáde). Irúgbìn rẹ̀ sì ń jọ àwọn aláìgbàgbọ́ lójú. Lẹ́yìn náà, ó máa gbẹ. O sì máa rí i ní pípọ́n. Lẹ́yìn náà, ó máa di rírún (tí atẹ́gùn máa fẹ́ dànù). Ìyà líle àti àforíjìn pẹ̀lú ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu sì wà ní ọ̀run. Kí sì ni ìṣẹ̀mí ayé yìí bí kò ṣe ìgbádùn ẹ̀tàn.
(21) Ẹ yára lọ síbi àforíjìn láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín àti Ọgbà Ìdẹ̀ra tí fífẹ̀ rẹ̀ dà bí fífẹ̀ sánmọ̀ àti ilẹ̀. Wọ́n pa á lésè sílẹ̀ de àwọn tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ìyẹn ni oore àjùlọ Allāhu tí Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Olóore ńlá.
(22) Àdánwò kan kò níí ṣẹlẹ̀ ní orí ilẹ̀ tàbí (kí ó ṣẹlẹ̀) sí ẹ̀yin àyàfi kí ó ti wà nínú Tírà ṣíwájú kí A tó dá ẹ̀dá. Dájúdájú ìyẹn rọ̀rùn fún Allāhu.
(23) (Ìṣẹ̀lẹ̀ ń tọ kádàrá lẹ́yìn) nítorí kí ẹ má ṣe banújẹ́ lórí ohun tí ó bá bọ́ fún yín àti nítorí kí ẹ má ṣe yọ àyọ̀jù lórí ohun tí Ó bá fún yín. Allāhu kò sì nífẹ̀ẹ́ sí gbogbo onígbèéraga, onífáàrí.
(24) Àwọn tó ń ṣahun, tí wọ́n sì ń pa àwọn ènìyàn láṣẹ ahun ṣíṣe (kí wọ́n mọ̀ pé) ẹnikẹ́ni tí ó bá pẹ̀yìndà (tí kò náwó fún ẹ̀sìn), dájúdájú Allāhu, Òun ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn.
(25) Dájúdájú A fi àwọn ẹ̀rí tó yanjú rán àwọn Òjíṣẹ́ Wa níṣẹ́. A sọ Tírà àti òṣùwọ̀n kalẹ̀ fún wọn nítorí kí àwọn ènìyàn lè rí déédé ṣe (láààrin ara wọn). A tún sọ irin kalẹ̀. Ohun ìjagun tó lágbára àti àwọn àǹfààní wà nínú rẹ̀ fún àwọn ènìyàn nítorí kí Allāhu lè ṣàfi hàn ẹni tó ń ran (ẹ̀sìn) Rẹ̀ àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ lọ́wọ́ ní ìkọ̀kọ̀. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Olùborí.
(26) Dájúdájú A fi iṣẹ́ rán (Ànábì) Nūh àti (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. A fi ipò Ànábì sínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ àwọn méjèèjì pẹ̀lú Tírà (tí A fún wọn). Olùmọ̀nà wà nínú wọn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́.
(27) Lẹ́yìn náà, A fi àwọn Òjíṣẹ́ Wa tẹ̀lé orípa wọn. A sì mú ‘Īsā ọmọ Mọryam tẹ̀lé wọn. A fún un ni al-’Injīl. A fi àánú àti ìkẹ́ sínú ọkàn àwọn tó tẹ̀lé e. Àṣà àdáwà (láì lọ́kọ tàbí láì laya) wọ́n ṣe àdádáálẹ̀ rẹ̀ ni. A kò ṣe é ní ọ̀ran-anyàn fún wọn. (Wọn kò sì ṣe àdáwà fún kiní kan) bí kò ṣe láti fi wá ìyọ́nú Allāhu. Wọn kò sì rí i ṣọ́ bí ó ṣe yẹ kí wọ́n ṣọ́ ọ. Nítorí náà, A fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nínú wọn ní ẹ̀san wọn. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́.¹
1. Irú āyah yìí wà nínú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:83 - 86.
(28) Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì gba Òjíṣẹ́ Rẹ̀ gbọ́ ní òdodo, Allāhu máa fún yín ní ìlọ́po méjì nínú ìkẹ́ Rẹ̀, Ó máa fún yín ní ìmọ́lẹ̀ tí ẹ óò máa fi rìn,¹ Ó sì máa forí jìn yín. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
1. Gbólóhùn yìí: “Ìmọ́lẹ̀ tí ẹ óò máa fi rìn” ó túmọ̀ sí ìmọ̀ nípa al-Ƙur’ān àti sunnah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tí a ó fi máa rí ẹ̀sìn ṣe dáadáa. Ìmọ̀ ni ìmọ́lẹ̀, àìmọ̀ sì ni òkùnkùn.
(29) (Allāhu ṣe bẹ́ẹ̀ fún yín) nítorí kí àwọn ahlu-l-kitāb lè mọ̀ pé àwọn kò ní agbára lórí kiní kan nínú oore àjùlọ Allāhu. Àti pé dájúdájú oore àjùlọ, ọwọ́ Allāhu l’ó wà. Ó sì ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Olóore ńlá.