|
| 55 - Suuratur-Rahmaan | |
| | كاتب الموضوع | رسالة |
---|
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: 55 - Suuratur-Rahmaan الخميس 27 يوليو 2023, 12:53 am | |
| 55 - Suuratur-Rahmaan Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run. (1) Àjọkẹ́-ayé, (2) Ó fi ìmọ̀ al-Ƙur’ān mọ (ẹni tí Ó fẹ́). (3) Ó ṣẹ̀dá ènìyàn. (4) Ó sì fi àlàyé (ọ̀rọ̀ sísọ) mọ̀ ọ́n. (5) Òòrùn àti òṣùpá (ń rìn) fún ìṣírò (ọjọ́ ayé). (6) Àwọn ìtàkùn ilẹ̀ àti igi ń forí kanlẹ̀ (fún Allāhu). (7) Àti sánmọ̀, Allāhu gbé e sókè. Ó sì fi òṣùwọ̀n òfin déédé lélẹ̀ (fún ẹ̀dá) (8) pé kí ẹ má ṣe tayọ ẹnu-ààlà níbi òṣùwọ̀n. (9) Ẹ gbé òṣùwọ̀n náà dúró pẹ̀lú dọ́gbadọ́gba. Kí ẹ sì má ṣe dín òṣùwọ̀n kù. (10) Ilẹ̀, (Allāhu) gbé e kalẹ̀ (sí abẹ́ sánmọ̀ fún àwọn ẹ̀dá. (11) Èso àti dàbínù alápó wà lórí (ilẹ̀). (12) Àti èso onípòpórò àti olóòórùn dídùn (wà lórí ilẹ̀). (13) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (14) (Allāhu) ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara amọ̀ gbígbẹ tó ń dún kokoko bí ìkòkò amọ̀. (15) Ó sì ṣẹ̀dá àlùjànnú láti ara ahọ́n iná tí kò ní èéfín. (16) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (17) Olúwa ibùyọ òòrùn méjèèjì àti ibùwọ̀ òòrùn méjèèjì.¹ 1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Mọ‘ārij; 70:40. (18) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (19) (Allāhu) mú odò méjì (odò oníyọ̀ àti odò aládùn) ṣàn pàdé ara wọn. (20) Gàgá kan sì wà láààrin àwọn méjèèjì tí wọn kò sì lè tayọ ẹnu-ààlà (rẹ̀ láààrin ara wọn). (21) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (22) Òkúta oníyebíye àti ìlẹ̀kẹ̀ iyùn ń jáde nínú àwọn (odò) méjèèjì náà. (23) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (24) Ti (Allāhu) ni àwọn ọkọ̀ ojú-omi gogoro tó ń rìn nínú agbami òdò (tí wọ́n dà) bí àpáta gíga. (25) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? |
| | | أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 55 - Suuratur-Rahmaan الخميس 27 يوليو 2023, 12:53 am | |
| (26) Gbogbo ẹni tó wà lórí ilẹ̀ máa tán. (27) Ojú Olúwa rẹ, Atóbi, Alápọ̀n-ọ́nlé sì máa wà títí láéláé. (28) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (29) Àwọn tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ń bèèrè (n̄ǹkan) lọ́dọ̀ Rẹ̀; Ó sì wà lórí ìṣe lójoojúmọ́. (30) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (31) A óò mú tiyín gbọ́ (lọ́jọ́ ẹ̀san), ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú. (32) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (33) Ẹ̀yin àwùjọ àlùjànnú àti ènìyàn, tí ẹ bá lágbára láti sá jáde nínú àwọn agbègbè sánmọ̀ àti ilẹ̀, ẹ sá jáde. Ẹ kò lè sá jáde àfi pẹ̀lú agbára. (34) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (35) Wọ́n máa ju ahọ́n iná àti èéfín (tàbí oje idẹ) iná lé ẹ̀yin méjèèjì lórí, ẹ̀yin méjèèjì kò sì níí lè ranra yín lọ́wọ́. (36) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (37) Nítorí náà, nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ó sì máa pọ́n wá wẹ̀ bí epo pupa gbígbá. (38) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (39) Nítorí náà, ní ọjọ́ yẹn Wọn kò níí bi ènìyàn àti àlùjànnú kan léèrè nípa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; (ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ní ọ̀dọ̀ Wa). (40) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (41) Wọ́n máa dá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ mọ̀ pẹ̀lú àmì ara wọn. Wọ́n sì máa fi àásó orí àti ẹsẹ̀ gbá wọn mú. (42) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (43) Èyí ni iná Jahanamọ tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń pè ní irọ́. (44) Wọn yóò máa rìn lọ rìn bọ̀ láààrin Iná àti omi tó gbóná parí.¹ 1. Ìyẹn ni pé, nínú Iná, yàtọ̀ sí pé oríṣiríṣi omi burúkú l’ó wà nínú rẹ̀ bíi omi tó gbóná parí, omi rẹ́funrẹ́fun, omi ètútú, omi àwọnúwẹ̀jẹ̀, àwọn omi wọ̀nyí máa wà nínú ọ̀gbun kan fún àwọn ọmọ Iná nínú Iná, bí Iná bá ti ń jó wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n á lọ máa mu omi ìmukúmu wọ̀nyí sí i, wọ́n á tún padà síbi Iná, wọ́n á tún padà síbi omi, wọ́n á tún padà síbi Ina. Wọ́n á wà bẹ́ẹ̀ títí láéláé. (45) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (46) Ọgbà Ìdẹ̀ra méjì ń bẹ fún ẹni tó bá páyà ìdúró rẹ̀ níwájú Olúwa rẹ̀. (47) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (48) (Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra méjèèjì ní) àwọn ẹ̀ka igi tó kún fún àwọn èso oríṣiríṣi. (49) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (50) Odò méjì tó ń ṣàn wà nínú ọgbà méjèèjì.
|
| | | أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 55 - Suuratur-Rahmaan الخميس 27 يوليو 2023, 12:54 am | |
| (51) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (52) Oríṣi méjì méjì ni èso kọ̀ọ̀kan tó wà nínú ọgbà méjèèjì.¹ 1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Yāsīn; 36:36. (53) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (54) Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú lórí ìtẹ́, tí àwọn ìtẹ́ inú rẹ̀ jẹ́ àrán tó nípọn. Àwọn èso ọgbà méjèèjì sì wà ní àrọ́wọ́tó. (55) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (56) Àwọn obìnrin tí kì í wo ọkùnrin mìíràn wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ènìyàn àti àlùjànnú kan kò sì fọwọ́ kàn wọ́n rí ṣíwájú wọn. (57) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (58) Wọ́n dà bíi ìlẹ̀kẹ̀ ṣẹ̀gi àti ìlẹ̀kẹ̀ iyùn (nípa ẹwà àti dídára wọn). (59) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (60) Ǹjẹ́ ẹ̀san mìíràn wà fún ṣíṣe rere bí kò ṣe (ẹ̀san) rere. (61) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (62) Ọgbà Ìdẹ̀ra méjì kan tún ń bẹ yàtọ̀ sí méjì (àkọ́kọ́ yẹn). (63) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (64) Aláwọ̀ ewéko (ni Ọgbà méjèèjì náà). (65) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (66) Àwọn odò méjì tó ń tú omi jáde láì dáwọ́ dúró wà (nínú ọgbà méjèèjì náà). (67) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (68) Èso ìpanu, dàbínù àti èso rumọ̄n wà nínú ọgbà méjèèjì náà. (69) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (70) Àwọn obìnrin rere, arẹwà wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra náà. (71) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (72) Àwọn ẹlẹ́yinjú-ẹgẹ́ kan (ni wọ́n), tí A fi pamọ́ sínú ilé-ọ̀ṣọ́. (73) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (74) Ènìyàn àti àlùjànnú kan kò fọwọ́ kàn wọ́n rí ṣíwájú wọn. (75) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (76) Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú lórí àwọn tìmùtìmù aláwọ̀ ewéko àti ìtẹ́ tó dára. (77) Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́? (78) Ìbùkún ni fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi, Alápọ̀n-ọ́nlé.
|
| | | | 55 - Suuratur-Rahmaan | |
|
مواضيع مماثلة | |
|
| صلاحيات هذا المنتدى: | لاتستطيع الرد على المواضيع في هذا المنتدى
| |
| |
| |