|
| 13 - Suuratur-Ra'd | |
| | كاتب الموضوع | رسالة |
---|
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: 13 - Suuratur-Ra'd الجمعة 21 يوليو 2023, 11:14 pm | |
| 13 - Suuratur-Ra'd Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run. (1) ’Alif lām mīm rọ̄. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)¹ Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà náà. Àti pé òdodo ni ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò gbàgbọ́. 1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1. (2) Allāhu ni Ẹni tí Ó gbé àwọn sánmọ̀ ga sókè láì sí àwọn òpó kan (fún un) tí ẹ lè fojú rí. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá. Ó rọ òòrùn àti òṣùpá; ìkọ̀ọ̀kan wọn máa rìn fún gbèdéke àkókò kan.¹ Ó ń ṣe ètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá). Ó ń ṣe àlàyé àwọn āyah nítorí kí ẹ lè mọ àmọ̀dájú nípa ìpàdé Olúwa yín. 1. Gbèdéke àkókò náà ni òpin ayé. (3) Òun ni Ẹni tí Ó tẹ́ ilẹ̀ pẹrẹsẹ. Ó sì fi àwọn àpáta tó dúró gbagidi àti àwọn odò tó ń ṣàn sínú ilẹ̀. Àti pé nínú gbogbo àwọn èso, Ó ṣe é ní oríṣi méjì-méjì.¹ Ó ń fi òru bo ọ̀sán lójú. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní àròjinlẹ̀. 1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Yāsīn; 36:36. (4) Ó tún wà nínú ilẹ̀ àwọn abala-abala ilẹ̀ (oníran-ànran) tó wà nítòsí ara wọn¹ àti àwọn ọgbà oko àjàrà, irúgbìn àti igi dàbínù tó pẹka àti èyí tí kò pẹka, tí wọ́n ń fún wọn ní omi ẹyọ kan mu. (Síbẹ̀síbẹ̀) A ṣe àjùlọ fún apá kan rẹ̀ lórí apá kan níbi àwọn èso wọn. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní làákàyè. 1. Bíi ilẹ̀ yanrìn nítòsí ilẹ̀ amọ̀, ilẹ́ yangí nítòsí ilẹ̀ tí kì í ṣe ilẹ̀ yangí, ilẹ̀ tó lọ́ràá nítòsí ilẹ̀ tó sá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (5) Tí o bá ṣèèmọ̀, èèmọ̀ mà ni ọ̀rọ̀ (ẹnu) wọn (nípa bí wọ́n ṣe sọ pé): “Ṣé nígbà tí a bá ti di erùpẹ̀ tán, ṣé nígbà náà ni àwa yóò tún di ẹ̀dá titun?” Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn. Àwọn wọ̀nyẹn ni ẹ̀wọ̀n ń bẹ lọ́rùn wọn. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. (6) Wọ́n tún ń kán ọ lójú pé kí aburú ṣẹlẹ̀ ṣíwájú rere. Àwọn ìyà (tó jẹ irú wọn) kúkú ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú wọn. Àti pé dájúdájú Olúwa rẹ ni Aláforíjìn fún àwọn ènìyàn lórí àbòsí (ọwọ́) wọn. Dájúdájú Olúwa rẹ le níbi ìyà. (7) Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ń wí pé: “Kí ni kò jẹ́ kí wọ́n sọ àmì kan kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Olùkìlọ̀ mà ni ìwọ. Olùtọ́sọ́nà sì wà fún ìjọ kọ̀ọ̀kan.¹ 1. Ọ̀rọ̀ pọ̀ lórí ìtúmọ̀ “hād” àti ohun tó dúró fún nínú āyah yìí nínú àwọn tírà Tafsīr. Mẹ́ta nínú àwọn ìtúmọ̀ “hād” nínú āyah nìyí: (1) “hād” túmọ̀ sí “Allāhu”, ìyẹn ni pé, “Allāhu ni olùtọ́sọ́nà fún ìjọ kọ̀ọ̀kan”. (2) “hād” túmọ̀ sí “Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ìyẹn ni pé, Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni olùpèpè fún àwọn ènìyàn. (3) “hād” túmọ̀ sí “Ànábì kọ̀ọ̀kan”, ìyẹn ni pé, Ànábì kọ̀ọ̀kan ni olùpèpè fún ìjọ Ànábì kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ sá, kò sí tírà Tafsīr kan kan tí ó túmọ̀ āyah náà lọ síbi sísọ pé, “ànábì kan wà fún ọmọ Yorùbá” tàbí sísọ pé “ànábì kan wà fún ilẹ̀ Haúsá”. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Yūnus 10; 47. (8) Allāhu mọ ohun tí obìnrin kọ̀ọ̀kan ní lóyún àti ohun tí ilé ọmọ yóò fi dín kù (nínú ọjọ́ ìbímọ) àti ohun tí ó máa fi lékún. N̄ǹkan kọ̀ọ̀kan ló sì ní òdíwọ̀n lọ́dọ̀ Rẹ̀. (9) (Allāhu ni) Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀-àti- gban̄gba. Ó tóbi, Ó ga jùlọ. (10) Bákan náà ni (lọ́dọ̀ Allāhu), ẹni tí ó fi ọ̀rọ̀ pamọ́ sínú nínú yín àti ẹni tí ó sọ ọ́ síta pẹ̀lú ẹni tí ó fi òru bojú àti ẹni tí ó ń rìn kiri ní ọ̀sán. (11) Ó ń bẹ fún ènìyàn (kọ̀ọ̀kan) àwọn mọlāika tí ń gbaṣẹ́ fúnra wọn; wọ́n wà níwájú (ènìyàn) àti lẹ́yìn rẹ̀; wọ́n ń ṣọ́ (iṣẹ́ ọwọ́) rẹ̀ pẹ̀lú àṣẹ Allāhu. Dájúdájú Allāhu kò níí ṣe ìyípadà n̄ǹkan tó ń bẹ lọ́dọ̀ ìjọ kan títí wọn yóò fi yí n̄ǹkan tó ń bẹ nínú ẹ̀mí wọn padà. Nígbà tí Allāhu bá gbèrò aburú kan ro ìjọ kan, kò sí ẹni tó lè dá a padà. Kò sì sí aláààbò kan fún wọn lẹ́yìn Rẹ̀. (12) Òun ni Ẹni tó ń fi mọ̀nàmọ́ná hàn yín ní ìbẹ̀rù àti ní ìrètí (fún yín). Ó sì ń ṣẹ̀dá ẹ̀ṣújò tó ṣú dẹ̀dẹ̀. (13) Àrá ń ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Un, àwọn mọlāika náà (ń ṣe bẹ́ẹ̀) fún ìbẹ̀rù Rẹ̀. Ó ń rán iná láti ojú sánmọ̀ níṣẹ́. Ó sì ń fi kọlu ẹni tí Ó bá fẹ́. Síbẹ̀ wọ́n ń jiyàn nípa Allāhu. (Allāhu) sì lágbára gan-an. (14) TiRẹ̀ ni ìpè òdodo. Àwọn tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò lè fi kiní kan jẹ́ pè wọn àfi bí ẹni tí ó tẹ́wọ́ rẹ̀ méjèèjì (lásán) sí omi nítorí kí omi lè dé ẹnu rẹ̀. Omi kò sì lè dé ẹnu rẹ̀. Àdúà (àti ìpè) àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe sínú ìṣìnà.¹ 1. Nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:186, Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - fi kalmọh “rọṣād” parí àdúà àwọn onígbàgbọ́ òdodo (ìyẹn, “la‘llahum yẹrṣudūn”) àmọ́ nínú sūrah yìí àti sūrah Gọ̄fir; 40:50 , Ó fi kalmọh “dọlāl” parí àdúà àwọn aláìgbàgbọ́. “Rọṣād” túmọ̀ sí “ìmọ̀nà”, “dọlāl” sì túmọ̀ sí “ìṣìnà”. Àdúà tó wà lórí ìmọ̀nà ni àdúà tó máa lọ tààrà sọ́dọ̀ Allāhu. Àdúà náà sì máa jẹ́ àtẹ́wọ́gbà. Èyí ni Allāhu fi rinlẹ̀ nínú sūrah aṣ-Ṣūrọ̄; 42:26. Àmọ́ àdúà tó wà lórí ìṣìnà, kò níí lọ sọ́dọ̀ Allāhu. Ẹ̀dá tí wọ́n sì dojú àdúà kọ kò níí gbọ́ ìpè náà, áḿbọ̀sìbọ́sí pé ó máa jẹ́pè rẹ̀ (ní ìbámu sí sūrah al-’Ahƙọ̄f; 46:5). Kò sì sí ẹni tí ó ń gba àdúà lẹ́yìn Allāhu. Ìdí nìyí tí àdúà náà fi máa gúnlẹ̀ sí èbúté anù àti òfò. Kí á wá wòye sí àwọn n̄ǹkan méjì wọ̀nyí: Ìkíní: Ọ̀nà wo ni àwọn aláìgbàgbọ́ ń gbà rí oore láyé? Kò sí oore ayé kan ní'lé ayé tí ó lè tẹ aláìgbàgbọ́ lọ́wọ́ nípasẹ̀ àdúà bí kò ṣe nípasẹ̀ ìpín kan tí ó wà fún un nínú kádàrá rẹ̀. Àmọ́ ní ti onígbàgbọ́ òdodo, oore inú kádàrá àti oore àdúà ló wà fún un níwọ̀n ìgbà tí àdúà rẹ̀ bá ti wà ní ìbámu sí sunnah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - . Ìkejì: Ìdí tí kò fi sí gbígbà àdúà fún àwọn aláìgbàgbọ́ ni pé, wọ́n dojú àdúà wọn kọ àwọn ẹ̀dá kan lẹ́yìn Allāhu - tó ga jùlọ - . Bí mùsùlùmí kan bá ṣe bẹ́ẹ̀, tàbí ó ṣe “āmīn” sí àdúà ẹni tí ó ṣe bẹ́ẹ̀, òun náà kò níí rí gbígbà àdúà náà, ẹ̀sìn rẹ̀ sì máa bàjẹ́ pẹ̀lú. (15) Allāhu ni àwọn tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ń forí kanlẹ̀ fún, wọ́n fẹ́, wọ́n kọ̀, - òòji wọn (náà ń ṣe bẹ́ẹ̀) - ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́.¹ 1. Àwọn sūfī (Tijāniyyah) ṣi āyah yìí àti tinú sūrah an-Nahl; 16:49 túmọ̀ lábẹ́ àdìsọ́kàn wọn tí wọ́n ń pè ní “‘Ilmu bātiniy” - “Ìmọ̀ Awo-inú”. Àwọn sūfī (Tijāniyyah) sọ pé, pẹ̀lú àwọn āyah méjèèjì wọ̀nyẹn, “gbogbo olùjọ́sìn tàbí olùforíkanlẹ̀ fún n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn Allāhu lójú-ìta, kò jọ́sìn kò sì forí kanlẹ̀ fún kiní kan àyàfi Allāhu (ta‘ālā) nítorí pé, Òun l’Ó wà nínú àwọn aṣọ wọ̀nyẹn.” (Jawāhir al Ma‘āniy wa Bulūg al ’Amọ̄niy) Irọ́ ńlá nìyí. Mímọ́ sì ni fún Allāhu tayọ ìsọkúsọ wọn. Āyah onípọ́n-na ni āyah méjèèjì wọ̀nyẹn. Pọ́n-na inú wọn ni pé, kò sí ẹni tí kì í forí kanlẹ̀ fún Allāhu. Èyí ni àwọn sūfī ṣe àfikún rẹ̀ pé, “Kódà kí ó forí kanlẹ̀ fún òrìṣà, Allāhu nínú àwòrán òrìṣà ló ń forí kanlẹ̀ fún!” Kíyè sí i, ìgbàkígbà tí a bá rí āyah onípọ́n-na, āyah aláìnípọ́n-na ni a máa fi yanjú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Allāhu ṣe fi èyí rinlẹ̀ nínú sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:7. Nítorí náà, sūrah al-Hajj;22:18 àti sūrah al-̓Anbiyā’; 21:98 ti yọ pọ́n-na tí ó jẹyọ nínú āyah méjèèjì náà. Ní ti sūrah al-Hajj;22:18, òhun fi rinlẹ̀ pé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ni kò forí kanlẹ̀ fún Allāhu. Ní ti sūrah al-̓Anbiyā’; 21:98, òhun sì fi rinlẹ̀ pé àwọn tó ń forí kanlẹ̀ fún n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn Allāhu, àti àwọn àti òrìṣà wọn ló máa wọ inú Iná nítorí pé, wọn kò forí kanlẹ̀ fún Allāhu, wọn kò sì jọ́sìn fún Un. Èyí ti túmọ̀ sí pé, sūrah ar-Ra‘d; 13:15 àti sūrah an-Nahl; 16:49 kò kan olùforíkanlẹ̀ àti olùjọ́sìn fún n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn Allāhu. Nítorí náà, gbólóhùn “wọ́n fẹ́” dúró fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo; “wọ́n kọ̀” sì dúró fún àwọn munāfiki. Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah ar-Rūm; 30:26. (16) Sọ pé: “Ta ni Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?” Sọ pé: “Allāhu ni.” Sọ pé: “Ṣé lẹ́yìn Rẹ̀ ni ẹ tún mú àwọn aláfẹ̀yìntì kan, tí wọn kò ní ìkápá oore àti ìnira fún ẹ̀mí ara wọn?” Sọ pé: “Ṣé afọ́jú àti olùríran dọ́gba bí? Tàbí àwọn òkùnkùn àti ìmọ́lẹ̀ dọ́gba? Tàbí wọ́n yóò fún Allāhu ní àwọn akẹgbẹ́ kan tí àwọn náà dá ẹ̀dá bíi ti ẹ̀dá Rẹ̀, (tó bẹ́ẹ̀ gẹ́) tí ẹ̀dá fi jọra wọn lójú wọn?” Sọ pé: “Allāhu ni Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Òun sì ni Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí. (17) Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Àwọn ojú-odò sì ń ṣàn pẹ̀lú òdiwọ̀n rẹ̀. Àgbàrá sì ń gbé ìfòfó orí-omi tó ga lọ. Bákan náà, nínú n̄ǹkan tí wọ́n ń yọ́ nínú iná láti fi ṣe n̄ǹkan-ọ̀ṣọ́ tàbí n̄ǹkan-èlò, òhun náà ní ìfòfó bí irú rẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń mú àkàwé wá fún òdodo àti irọ́. Ní ti ìfòfó, ó máa lọ ní ìlọ pàǹtí. Ní ti èyí tí ó sì máa ṣe àwọn ènìyàn ní àǹfààní, ó máa dúró sí orí ilẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń mú àwọn àkàwé wá.¹ 1. Ìtúmọ̀ àkàwé yìí ni pé, òdodo ló ń ṣàǹfààní, òfò ni irọ́. (18) Ohun rere (ìyẹn Ọgbà Ìdẹ̀ra) wà fún àwọn tó jẹ́pè Olúwa wọn. Àwọn tí kò sì jẹ́pè Rẹ̀, tí ó bá jẹ́ pé tiwọn ni gbogbo n̄ǹkan tó ń bẹ lórí ilẹ̀ pátápátá àti irú rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, wọn ìbá fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara wọn níbi Iná). Àwọn wọ̀nyẹn ni aburú ìṣírò-iṣẹ́ wà fún.¹ Iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn; ibùgbé náà sì burú. 1. Aburú ìṣírò-iṣẹ́ ni kí Allāhu kọ iṣẹ́ rere ẹ̀dá lé e lọ́wọ́, kí Ó má ṣàforíjìn fún un nítorí pé, ẹ̀dá náà kú sórí ẹbọ ṣíṣe tàbí àìgbàgbọ́ tàbí ìṣọ̀bẹ-ṣèlu àfọkànṣe. (19) Ǹjẹ́ ẹni tí ó mọ̀ pé òdodo kúkú ni n̄ǹkan tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, ó wa dà bí ẹni tí ó fọ́jú (nípa rẹ̀ bí)? Àwọn onílàákàyè ló ń lo ìrántí. (20) (Àwọn ni) àwọn tó ń mú àdéhùn Allāhu ṣẹ. Àti pé wọn kì í tú àdéhùn. (21) (Àwọn ni) àwọn tó ń da ohun tí Allāhu pa láṣẹ pé kí wọ́n dàpọ̀ pọ̀. Wọ́n ń páyà Olúwa wọn. Wọ́n sì ń páyà aburú ìṣírò-iṣẹ́. (22) (Àwọn ni) àwọn tó ṣe sùúrù láti fi wá Ojú rere Olúwa wọn. Wọ́n ń kírun. Wọ́n ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba. Wọ́n sì ń fi rere dènà aburú.¹ Àwọn wọ̀nyẹn ni àtubọ̀tán Ilé rere ń bẹ fún. 1. Ìyẹn ni pé, wọ́n máa ń ṣe rere sí ẹni tí ó bá ń ṣe aburú sí wọn, wọn kò níí fi aburú gbẹ̀san aburú. (23) Inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére ni wọ́n máa wọ̀, (àwọn) àti ẹni tó bá ṣe rere nínú àwọn bàbá wọn, àwọn ìyàwó wọn àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn. Àwọn mọlāika yó sì máa wọlé tọ̀ wọ́n láti ẹnu ọ̀nà kọ̀ọ̀kan. (24) (Wọn yóò sọ pé): “Àlàáfíà fún yín nítorí sùúrù yín.” Àtubọ̀tán Ilé rere náà sì dára. (25) Àwọn tó ń tú àdéhùn Allāhu lẹ́yìn tí wọ́n ti gba àdéhùn Rẹ̀, tí wọ́n ń já ohun tí Allāhu pa láṣẹ pé kí wọ́n dàpọ̀, tí wọ́n sì ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀; àwọn wọ̀nyẹn ni ègún wà fún. Àti pé Ilé (Iná) burúkú wà fún wọn. |
| | | أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 13 - Suuratur-Ra'd الجمعة 21 يوليو 2023, 11:16 pm | |
| (26) Allāhu ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ rẹgẹdẹ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹni tí Ó bá fẹ́). Wọ́n sì dunnú sí ìṣẹ̀mí ilé ayé! Kí sì ni ìṣẹ̀mí ayé ní ẹ̀gbẹ́ ti ọ̀run bí kò ṣe ìgbádùn bín-íntín. (27) Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ń wí pé: “Kí ni kò jẹ́ kí wọ́n sọ àmì kan kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Sọ pé: “Dájúdájú Allāhu ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà. Ó sì ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó bá ṣẹ́rí padà sọ́dọ̀ Rẹ̀.” (28) Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ọkàn wọn sì balẹ̀ pẹ̀lú ìrántí Allāhu; ẹ gbọ́, pẹ̀lú ìrántí Allāhu ni àwọn ọkàn máa fi balẹ̀.¹ 1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:152. (29) Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, orí ire àti àbọ̀ rere wà fún wọn. (30) Báyẹn ni A ṣe rán ọ níṣẹ́ sí ìjọ kan, - àwọn ìjọ kan kúkú ti ré kọjá lọ ṣíwájú wọn -, nítorí kí o lè máa ka n̄ǹkan tí A fi ránṣẹ́ sí ọ ní ìmísí fún wọn. Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ń ṣàì gbàgbọ́ nínú Àjọkẹ́-ayé. Sọ pé: “Òun ni Olúwa mi. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Òun ni mo gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ mi.” (31) Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú al-Ƙur’ān, wọ́n ké e láti fi mú àwọn àpáta rìn (kúrò ní àyè wọn), tàbí wọ́n fi gé ilẹ̀ (kélekèle, kí ó yanu fún àwọn àlùmọ́nì), tàbí wọ́n fi bá àwọn òkú sọ̀rọ̀ (kí wọ́n sì jí dìde, wọn kò níí gbàgbọ́). Àmọ́ sá, ti Allāhu ni gbogbo àṣẹ pátápátá. Ṣé àwọn tó gbàgbọ́ kò mọ̀ pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá tọ́ gbogbo ènìyàn sọ́nà. Àjálù kò sì níí yé ṣẹlẹ̀ sí àwọn aláìgbàgbọ́ nítorí ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ tàbí (àjálù náà kò níí yé) sọ̀kalẹ̀ sí tòsí ilé wọn títí di ìgbà tí àdéhùn Allāhu yóò fi dé. Dájúdájú Allāhu kò níí yapa àdéhùn. (32) Dájúdájú wọn ti fi àwọn Òjíṣẹ́ kan ṣe yẹ̀yẹ́ ṣíwájú rẹ. Mo sì lọ́ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lára. Lẹ́yìn náà, Mo gbá wọn mú. Nítorí náà, báwo ni ìyà (tí mo fi jẹ wọ́n) ti rí (lára wọn ná)! (33) Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó ń mójútó ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan nípa iṣẹ́ tí ó ṣe (dà bí ẹni tí kò lè ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Síbẹ̀) wọ́n tún bá Allāhu wá àwọn akẹgbẹ́ kan! Sọ pé: “Ẹ dárúkọ wọn ná.” Tàbí ẹ̀yin yóò fún (Allāhu) ní ìró ohun tí kò mọ̀ lórí ilẹ̀ tàbí (ẹ fẹ́ mú) irọ́ àti àbá dídá wá? Rárá, wọ́n ti ṣe ète àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ní ọ̀ṣọ́ fún wọn ni. Wọ́n sì ṣẹ́rí wọn kúrò lójú ọ̀nà òdodo. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò níí sí olùtọ́sọ́nà kan fún un. (34) Ìyà wà fún wọn nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí). Ìyà ti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn kúkú gbópọn jùlọ. Kò sì níí sì aláàbò kan fún wọn lọ́dọ̀ Allāhu. (35) Àpèjúwe Ọgbà Ìdẹ̀ra tí wọ́n ṣe ní àdéhùn fún àwọn olùbẹ̀rù Allāhu (ni èyí tí) àwọn odò ń ṣàn kọjá nísàlẹ̀ rẹ̀. Èso rẹ̀ àti ibòji rẹ̀ yó máa wà títí láéláé. Ìyẹn ni ìkángun àwọn tó bẹ̀rù (Allāhu). Iná sì ni ìkángun àwọn aláìgbàgbọ́. (36) Àwọn tí A fún ní Tírà ń dunnú sí ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ. Ó sì wà nínú àwọn ìjọ kèfèrí-parapọ̀ tó ń ṣe àtakò sí apá kan rẹ̀. Sọ pé: “N̄ǹkan tí wọ́n pa mí láṣẹ rẹ̀ ni pé kí n̄g jọ́sìn fún Allāhu. Èmi kò sì gbọdọ̀ wá akẹgbẹ́ fún Un. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni mò ń pèpè sí. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ mi.” (37) Báyẹn ni A ṣe sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ní ìdájọ́ pẹ̀lú èdè Lárúbáwá. Dájúdájú tí o bá fi lè tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn, lẹ́yìn n̄ǹkan tí ó dé bá ọ nínú ìmọ̀, kò sí aláàbò àti olùṣọ́ kan fún ọ mọ́ lọ́dọ̀ Allāhu. (38) Dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ. A sì fún wọn ní àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọọmọ.¹ Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún Òjíṣẹ́ kan láti mú àmì kan wá àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu.² Gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ ló ní àkọsílẹ̀. 1. Kíyè sí i, àwọn kan ń sọ pé gbólóhùn yìí “Dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ. A sì fún wọn ní àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọọmọ.”, ó ń tọ́ka sí pé “Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - fẹ́ ìyàwó, ó sì bí ọmọ ṣíwájú kí ó tó kúrò láyé. Nítorí náà, ó ti kú. Kò sì níí padà wá sáyé mọ́.” Ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ yìí jẹ́ ọ̀rọ̀ fífi àtamọ́ mọ́ àtamọ̀. Àti pé, ìrònú wọn nípa gbólóhùn náà jẹ́ ìrònú ọpọlọ lásán, kò sì sí ìtọ́sọ́nà nínú rẹ̀ nítorí àwọn ìdí pàtàkì márùn-ún wọ̀nyí: Ìdí àkọ́kọ́: Kò kọ́kọ́ sí tírà tafsīr àwọn onisunnah tó sọ pé gbólóhùn náà dúró fún pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - fẹ́ ìyàwó tàbí pé ó bí ọmọ ṣíwájú kí ó tó kúrò láyé. Àwọn onibidiah bí ìjọ Ahmadiyyah ló ń fá ìtúmọ̀ gbólóhùn náà síbẹ̀. Ìdí kejì: Gbólóhùn náà dúró sórí àdámọ́ tí Allāhu fi sára gbogbo ọmọ Ànábì Ādam - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Kì í ṣe àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun nìkan ni wọ́n fẹ́ ìyàwó tàbí bí ọmọ. Tòhun ti bẹ́ẹ̀ náà, ṣe gbogbo ẹ̀dá tó wá sáyé ló rí ìyàwó fẹ́? Tàbí ṣe gbogbo ẹni tó sì rí ìyàwó fẹ́ ló rí ọmọ bí? Ìdí kẹta: Kì í ṣe nítorí ìfirinlẹ̀ pé kò sí Ànábì kan tàbí Òjíṣẹ́ kan nínú àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun tí kò fẹ́ ìyàwó rí tàbí tí kò bí ọmọ rí ni Allāhu fi mú ọ̀rọ̀ náà wá nítorí pé, ó wà nínú àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ tí kò fẹ́ ìyàwó, áḿbọ̀sìbọ́sí pé wọ́n bí ọmọ. Àpẹ̀ẹrẹ ni Ànábì Yahya - kí ọlà Allāhu máa bá a - nínú sūrah āli-’Imrọ̄n 3:39. Ìdí kẹrin; Allāhu - Ọba mímọ́ - fi gbólóhùn náà fọ èsì fún àwọn aláìgbàgbọ́ nínú ìjọ Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni. Àwọn aláìgbàgbọ́ tó ń sọ pé, “Tí ó bá jẹ́ Ànábì Ọlọ́hun ní òdodo ni kò yẹ kó jẹ́ òjíṣẹ́ abara tí ó máa fẹ́ ìyàwó, kò sì yẹ fún un láti máa bímọ.”, gẹ́gẹ́ bí Allāhu - Ọba mímọ́ - ṣe mú ọ̀rọ̀ wọn wá nínú sūrah al-’Isrọ̄’; 17:94. Ìdí karùn-ún: Ìbá jẹ́ pé āyah náà jẹmọ́ pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - ti kú ni, ìbá tí sí hadīth kan kan tó máa fẹsẹ̀ rinlẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lórí ìpadàbọ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - lópin ayé. Hadīth lórí ìpadàbọ̀ rẹ̀ kò sì mọ ní ẹyọ kan. Nítorí náà, ṣé àwọn tó ń lo gbólóhùn náà fún àìpadàbọ̀ Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - lópin ayé mọ ìtúmọ̀ al-Ƙur’ān ju Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lọ ni tàbí wọ́n kàn jẹ́ asòòkùn-sẹ́sìn?! 2. “àmì kan” nínú āyah yìí dúró fún ìyà kan tàbí ìparun kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu fún àwọn aláìgbàgbọ́ nínú Òjíṣẹ́ náà. Kíyè sí i, “àmì kan” láti ọ̀dọ̀ Allāhu - Ọba mímọ́ - tún lè jẹ́ “iṣẹ́ ìyanu” tàbí “ẹsẹ ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun”. (39) Allāhu ń pa ohun tí Ó bá fẹ́ rẹ́. Ó sì ń mú (ohun tí Ó bá fẹ́) ṣẹ. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni Tírà Ìpìlẹ̀ wà.¹ 1. Kí ni n̄ǹkan tí Allāhu ń parẹ́? Ki sì ni n̄ǹkan tí Ó ń mú ṣẹ? Ọ̀rọ̀ pọ̀ lórí àwọn n̄ǹkan náà nínú àwọn tírà Tafsīr. Àgbọ́yé kìíní tí ó tẹ̀ṣùwọ̀n jùlọ ni pé, āyah náà jẹ́ àlàyé fún āyah tí ó ṣíwájú rẹ̀. Ìdí ni pé, āyah tí ó ṣíwájú rẹ̀ ń tọ́ka sí bí ó ṣe jẹ́ pé ọjọ́ ìyà, tí ó jẹ́ “àmì kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu - Ọba mímọ́ -”, èyí tí ó máa kò lé àwọn aláìgbàgbọ́ lórí ti ṣe wà nínú àkọsílẹ̀. Āyah 39 yìí wá ń sọ pé ní ọjọ́kọ́jọ́ tí ìyà náà bá dé sí àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́rùn, ó ń bẹ nínú àwọn aláìgbàgbọ́ tí ó máa bá ìyà náà lọ. Ó sì ń bẹ nínú wọn ẹni tí ìyà náà yóò dá sí títí dí ọjọ́ mìíràn. Àti ẹni tí ó máa bá ìyà lọ àtí ẹni tí ọjọ́ ìyà rẹ̀ yóò sún ṣíwájú, gbogbo rẹ̀ ni ó kúkú ti wà nínú Tírà Laohul-Mahfūṭḥ, tí í ṣe àkọsílẹ̀ ìpìlẹ̀ lọ́dọ̀ Allāhu - Ọba mímọ́ -. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni nínú àwọn aláìgbàgbọ́ tí ó bá bá ìyà lọ ni àgbọ́yé “yamhū-llāhu mọ̄ yaṣā’”. Bákàn náà, ẹnikẹ́ni nínú àwọn aláìgbàgbọ́ tí ó bá ru ìyà náà là títí di ọjọ́ mìíràn ni àgbọ́yé “wa yuthbit”. Lẹ́yìn àgbọ́yé yìí ní ọ̀rọ̀ kan àwọn àgbọ́yé tí ó dá āyah náà tú lọ́tọ̀, láì so ó pọ̀ mọ́ āyah 38. Àgbọ́yé kejì: Inú àkọsílẹ̀ méjì ni kádàrá ẹ̀dá wà. Àkọsílẹ̀ kan wà lọ́dọ̀ àwọn mọlāika. Àkọsílẹ̀ ti ọ̀dọ̀ àwọn mọlāika ni àkọsílẹ̀ tí Allāhu - Ọba mímọ́ - ń gbé fún wọn lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan ní ọdọọdún nínú Òru Abiyì (Laelatul-Ƙọdr). Ìyípadà lè ṣẹlẹ̀ sí kádàrá ẹ̀dá nínú àkọsílẹ̀ ti ọ̀dọ̀ àwọn mọlāika nípa ki ohun titun tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ lórí àwọn àlámọ̀rí ẹ̀dá kan. Bákàn náà, àwọn àlámòrí kan lè wà bí ó ṣe wà tẹ́lẹ̀ ní èsín. Àkọsílẹ̀ kejì ni àkọsílẹ̀ tí ó wà = = lọ́dọ̀ Allāhu nínú Tírà Laohul-mahfūṭḥ. Àkọsílẹ̀ yìí ló kó gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀dá sínú tán pátápátá, bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí ẹ̀dá kò tí ì máa jẹ́ ẹ̀dá títí dé ìkángun ẹ̀dá nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra tàbí nínú Iná. Nínú àkọsílẹ̀ yìí ni Allāhu - Ọba mímọ́ - ti ń yọ àkọsílẹ̀ ọlọ́dọọdún fún àwọn mọlāika Rẹ̀. Nítorí náà, ohun titun nínú kádàrá tí ń bẹ́ lọ́wọ́ àwọn mọlāika ni àgbọ́yé “yamhū-llāhu mọ̄ yaṣā’”. Bákàn náà, ohun tí ó bá wà bí ó ṣe wà tẹ́lẹ̀ ní èsín ni àgbọ́yé “wa yuthbit”. Àmọ́ àti ohun titun àti èyí tí kò titun nínú kádàrá tí ń bẹ́ lọ́wọ́ àwọn mọlāika, ìkíní kejì ló wà bẹ́ẹ̀ nínú Tírà Laohul-Mahfūṭḥ. Àgbọ́yé kẹta: Àgbọ́yé fún “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’ wa yuthbit” ni pé, kí ọkùnrin kan ti máa tẹ̀lé àṣẹ Allāhu bọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Lẹ́yìn náà, kí ó padà síbi ìyapa àṣẹ Allāhu, kí ó sì kú sínú ìṣìnà àìgbàgbọ́. Onítọ̀ún ni ẹni tí Allāhu pa orúkọ rẹ̀ rẹ́ nínú ìmọ̀nà. Irúfẹ́ ẹni yìí ló wà ní abẹ́ “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’”. Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀, ẹni tí Allāhu fí orúkọ rẹ̀ rinlẹ̀ sínú ìmọ̀nà ni kí ọkùnrin kan ti máa yapa àṣẹ Allāhu bọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Lẹ́yìn náà, kí ó padà síbi ìtẹ̀lé àṣẹ Allāhu, kí ó sì kú sínú ìmọ̀nà ’Islām. Onítọ̀ún ló wà ní abẹ́ “wa yuthbit”. Àgbọ́yé kẹrin: Àgbọ́yé fún “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’ wa yuthbit” ni pé, àwọn mọlāika yóò máa kọ gbogbo ọ̀rọ̀ àti ìṣe ẹ̀dá sílẹ̀ ní ojoojúmọ́. Nígbà tí ó bá dí ọjọ́ Àlàmísì, wọn yóò yọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí kò la láádá àti ìyà lọ sílẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ bíi “Mo jẹ; mo mu; mo sùn; mo jí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ”. Èyí sì ni ìtúmọ̀ “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’” Wọn yó sì fi àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe yòókù tí ó la láádá àti ìyà lọ sílẹ̀ nínú àkọsílẹ̀ iṣẹ́ ẹ̀dá. Èyí sì ni ìtúmọ̀ “wa yuthbit”. Àgbọ́yé karùn-ún: Àgbọ́yé fún “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’ wa yuthbit” ni pé, àwọn āyah kan ń bẹ lásìkò tí al-Ƙur’ān ń sọ̀kalẹ̀ lọ́wọ́ fún Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, tí Allāhu yóò pa ìdájọ́ inú wọn rẹ́. Irúfẹ́ àwọn āyah bẹ́ẹ̀ sì ló wà ní abẹ́ “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’”. Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn āyah kan sì ń bẹ tí Allāhu kò níí pa ìdájọ́ inú wọn rẹ́. Irúfẹ́ àwọn āyah bẹ́ẹ̀ ló sì wà ní abẹ́ “wa yuthbit”. Àgbọ́yé kẹfà: Àgbọ́yé fún “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’ wa yuthbit” ni pé, Allāhu - Ọba mímọ́ - yóò máa ṣe àforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wẹẹrẹ kan fún ẹ̀dá. Èyí sì ni “yamhu-llāhu mọ̄ yaṣā’”. Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀, Allāhu - Ọba mímọ́ - yó sì fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wẹẹrẹ kan mú ẹ̀dá. Èyí sì ni “wa yuthbit”. Gbogbo àwọn àlàyé wọ̀nyí wà nínú tafsīr at-Tọbarīy. Nítorí náà, āyah yìí kò túmọ̀ sí yíyí kádàrá ẹ̀dá padà nínú Tírà Laohul-Mahfūṭḥ. Ó sì kúkú ti rinlẹ̀ nínú hadīth Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - pé: “ A ti gbé gègé sókè kúrò lórí kíkọ kádàrá. Àwọn àkọsílẹ̀ sì ti gbẹ.” Ìyẹn nínú Tírà Laohul-Mahfūṭḥ. Èyí sì ló ko gbogbo kádàrá ẹ̀dá sínú pátápátá àti gbogbo àwọn tírà tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ fún gbogbo àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a. Fún ìdí èyí, àdúà tí ẹ̀dá yóò ṣe àti ọ̀nà tí àdúà náà yó fi gbà, méjèèjì ti wà nínú kádàrá ẹ̀dá tí ó wà nínú Tírà Laohul-mahfūṭḥ. Àti pé kò sí ẹ̀dá tó nímọ̀ èwo nínú àwọn oore ayé àti tọ̀run ló máa tẹ ẹ̀dá lọ́wọ́ nípasẹ̀ àdúà. Èyí jẹ́ ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ ní abala kan. Ó tún jẹ́ ọlá fún àdúà ṣíṣe lábala kan nítorí pé, oore àdúà ọ̀tọ̀, oore ẹ̀bùn Ọlọ́hun ọ̀tọ̀. Nítorí náà, gbogbo gbígbà àdúà wà ní abẹ́ àkọsílẹ̀ tí Allāhu - Ọba mímọ́ - ti kọ lé ẹ̀dá lórí nínú Tírà Laohul-Mahfūṭḥ ṣíwájú ìṣẹ̀dá rẹ̀. (40) Ó ṣeé ṣe kí Á fi apá kan èyí tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́ tàbí kí Á ti gba ẹ̀mí rẹ (ṣíwájú àsìkò náà), ìkéde (ẹ̀sìn) nìkan ni ojúṣe tìrẹ, ìṣírò-iṣẹ́ sì ni tiWa. (41) Ṣé wọn kò wòye pé dájúdájú À ń dé sórí ilẹ̀, À ń dín in kù (mọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́wọ́) láti àwọn eteetí ìlú (wọ inú ìlú nípa fífún àwọn mùsùlùmí ní ìṣẹ́gun lórí wọn)? Allāhu l’Ó ń ṣe ìdájọ́. Kò sí ẹnì kan tí ó lè dá ìdájọ́ Rẹ̀ padà (fún Un). Òun sì ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́. (42) Dájúdájú àwọn tó ṣíwájú wọn déte. Ti Allāhu sì ni gbogbo ète pátápátá.¹ Ó mọ ohun tí ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ń ṣe níṣẹ́. Àti pé àwọn aláìgbàgbọ́ ń bọ̀ wá mọ ẹni tí àtubọ̀tán Ilé (rere) wà fún. 1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:15. (43) Àwọn aláìgbàgbọ́ ń wí pé: “Ìwọ kì í ṣe Òjíṣẹ́.” Sọ pé: “Allāhu tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin àti ẹni tí ìmọ̀ Tírà ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀.¹” 1. Ìyẹn ni pé, àwọn àlùfáà nínú àwọn yẹhudi àti nasọ̄rọ̄ mọ̀ pé àsọtọ́lẹ̀ nípa Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - wà nínú tírà at-Taorāt àti al-’Injīl.
|
| | | | 13 - Suuratur-Ra'd | |
|
مواضيع مماثلة | |
|
| صلاحيات هذا المنتدى: | لاتستطيع الرد على المواضيع في هذا المنتدى
| |
| |
| |