97 - Suuratul-qad'r
 Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
(1) Dájúdájú Àwa sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ nínú Òru Abiyì.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Isrọ̄’; 17:106.
(2) Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Òru Abiyì?
(3) Òru Abiyì lóore ju ẹgbẹ̀rún oṣù.
(4) Àwọn mọlāika àti Jibrīl yó sì máa sọ̀kalẹ̀ nínú òru náà pẹ̀lú àṣẹ Olúwa wọn fún gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan.
(5) Àlàáfíà ni òru náà títí di àsìkò àfẹ̀mọ́júmọ́.