100 - Suuratul-Aadiyaat
 Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
(1) Allāhu fi àwọn ẹṣin tó ń sáré tó ń mí hẹlẹhẹlẹ ní ojú-ogun búra.
(2) Ó tún fi àwọn ẹṣin tí pátákò ẹsẹ̀ wọn ń ṣáná (níbi eré sísá) búra.
(3) Ó tún fi àwọn ẹṣin tó ń kọlu ọ̀tá ẹ̀sìn ní òwúrọ̀ kùtùkùtù búra.
(4) Wọ́n sì fi (pátákò ẹsẹ̀ wọn) tu eruku (ilẹ̀ ọ̀tá) sókè.
(5) Wọ́n tún bẹ́ gìjà pẹ̀lú eruku ẹsẹ̀ wọn sáààrin àkójọ ọ̀tá.
(6) Dájúdájú ènìyàn ni aláìmoore sí Olúwa rẹ̀.
(7) Dájúdájú Allāhu sì ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí ìyẹn.
(8) Àti pé dájúdájú ènìyàn le gan-an níbi ìfẹ́ oore ayé.
(9) Ṣé kò mọ̀ pé nígbà tí wọ́n bá tú ohun tó wà nínú sàréè jáde (fún àjíǹde),
(10) tí wọ́n sì tú ohun tó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá síta pátápátá,
(11) dájúdájú Olúwa wọn ni Alámọ̀tán nípa wọn ní Ọjọ́ yẹn?