98 - Suuratul-Bayyinah
 Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
(1) Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn ahlul-kitāb àti àwọn ọ̀ṣẹbọ, wọn kò níí kúrò nínú àìgbàgbọ́ wọn títí di ìgbà tí ẹ̀rí tó yanjú yó fi máa dé ọ̀dọ̀ wọn.
(2) Òjíṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu yó (sì) máa ké àwọn tákàdá mímọ́.
(3) Àwọn ìwé òfin tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ sì wà nínú rẹ̀.
(4) Àwọn tí A fún ní tírà kò sì di ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àfi lẹ́yìn tí ẹ̀rí tó yanjú dé bá wọn.
(5) Àwa kò sì pa wọ́n ní àṣẹ kan bí kò ṣe pé kí wọ́n jọ́sìn fún Allāhu lẹ́ni tí yóò máa ṣe àfọ̀mọ́ ẹ̀sìn fún Un,¹ lẹ́ni tí yóò dúró ṣinṣin nínú ẹ̀sìn.² Kí wọ́n kírun, kí wọ́n sì yọ Zakāh. Ìyẹn sì ni ẹ̀sìn tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Al-’a‘rọ̄f 7:29. 2. Ìdúró ṣinṣin nínú ẹ̀sìn ni pé, ènìyàn kò gbọ́dọ̀ máa gbàgbọ́ ní òdodo, kó tún máa ṣàì gbàgbọ́, kí ó wá máa ṣe bẹ́ẹ̀ lọ ní tẹ̀léǹtẹ̀lé. Inú àìgbàgbọ́ ni ó máa padà kú sí. Ẹ wo sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:90 àti sūrah an-Nisā’; 4:137. Nítorí náà, mùsùlùmí gbọ́dọ̀ dúró ṣinṣin sínú ẹ̀sìn ’Islām títí di ọjọ́ ikú rẹ̀ ni ní ìbámu sí sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:102.
(6) Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ (wọ̀nyí) nínú àwọn ahlul-kitāb àti àwọn ọ̀ṣẹbọ, wọn yóò wà nínú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹ̀dá tó burú jùlọ.
(7) Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo (ìyẹn, àwọn mùsùlùmí), tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹ̀dá tó dára jùlọ.
(8) Ẹ̀san wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Allāhu yọ́nú sí wọn. Àwọn náà yọ́nú sí (ohun tí Allāhu fún wọn). Ìyẹn wà fún ẹnikẹ́ni tí ó bá páyà Olúwa rẹ̀.