أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: 96 - Suuratul-Halaq السبت 29 يوليو 2023, 1:14 am | |
| 96 - Suuratul-Halaq Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run. (1) Ké (al-Ƙur’ān) pẹ̀lú orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá. (2) Ó ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara ẹ̀jẹ̀ dídì. (3) Ké e. Olúwa rẹ ni Alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ. (4) Ẹni tí Ó fi ìmọ̀ nípa gègé ìkọ̀wé mọ ènìyàn. (5) Ó fi ìmọ̀ tí ènìyàn kò mọ̀ mọ̀ ọ́n. (6) Ní ti òdodo, dájúdájú ènìyàn kúkú ń tayọ ẹnu-ààlà (7) nítorí pé ó rí ara rẹ̀ ní ọlọ́rọ̀. (8) Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni àbọ̀ ẹ̀dá. (9) Sọ fún mi nípa ẹni tó ń kọ̀ (10) fún ẹrúsìn kan nígbà tí (ẹrúsìn náà) kírun! (11) Sọ fún mi (nípa ẹ̀san rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó wà lórí ìmọ̀nà (’Islām) (12) tàbí pé ó pàṣẹ ìbẹ̀rù (Allāhu)! (13) Sọ fún mi (nípa ìyà rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó pe òdodo ní irọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i? (14) Ṣé kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń rí (òun ni?) (15) Rárá (ọ̀rọ̀ kò rí bí ọ̀tá Allāhu ṣe rò ó sí.¹) Dájúdájú tí kò bá jáwọ́ (níbi dídí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lọ́wọ́), dájúdájú A máa fi àásó orí² rẹ̀ wọ́ ọ (sínú Iná); 1. Ẹni yẹn ni Abu Jahl. 2. àásó orí; irun iwájú orí. (16) àásó orí òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀. (17) Nítorí náà, kí ó pe àwọn olùbájókòó rẹ̀. (18) Àwa máa pe àwọn mọlāika ẹ̀ṣọ́ Iná. (19) Rárá (ọ̀rọ̀ kò rí bí ó ṣe ń sọ nípa Wa). Má ṣe tẹ̀lé tirẹ̀. Forí kanlẹ̀ (kí o kírun), kí o sì súnmọ́ (Allāhu). |
|