91 - Suuratu Sham's
 Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
(1) Allāhu fi òòrùn àti ìyálẹ̀ta rẹ̀ búra.
(2) Ó tún fi òṣùpá nígbà tí ó bá (yọ) tẹ̀lé (òòrùn) búra.
(3) Ó tún fi ọ̀sán nígbà tí ó bá mú ìmọ́lẹ̀ bá òkùnkùn òru búra.
(4) Ó tún fi alẹ́ nígbà tí ó bá bo ọ̀sán mọ́lẹ̀ búra.
(5) Ó tún fi sánmọ̀ àti Ẹni tí Ó mọ ọ́n¹ búra?
1. Allāhu - Ẹlẹ́dàá - ni Ẹni tí Ó mọ àwọn sánmọ̀. Ó sì ń fi ara Rẹ̀ búra.
(6) Ó tún fi ilẹ̀ àti Ẹni tí Ó tẹ́ ẹ kalẹ̀ pẹrẹsẹ búra.
(7) Ó tún fi ẹ̀mí (ènìyàn) àti Ẹni tí Ó ṣe (oríkèé rẹ̀) dọ́gba búra.
(8) Ó sì fi ẹ̀ṣẹ̀ (tí ẹ̀mí lè dá) àti ìbẹ̀rù rẹ̀ mọ̀ ọ́n.
(9) Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àfọ̀mọ́ (ẹ̀mí ara) rẹ̀ (níbi ẹ̀ṣẹ̀), ó mà ti jèrè.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Mu’minūn; 23:4.
(10) Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi (ìwà ẹ̀ṣẹ̀) ba ẹ̀mí (ara) rẹ̀ jẹ́, ó mà ti pàdánù.
(11) Ìjọ Thamūd pe òdodo ní irọ́ nípa ìtayọ ẹnu-ààlà wọn.
(12) (Rántí) nígbà tí ẹni tí orí rẹ̀ burú jùlọ nínú wọn sáré dìde (láti gún ràkúnmí pa).
(13) Nígbà náà, Òjíṣẹ́ Allāhu sọ fún wọn pé: “(Ẹ fi) abo ràkúnmí Allāhu àti omi rẹ̀ (sílẹ̀).”
(14) Wọ́n pè é ní òpùrọ́. Wọ́n sì gún (ràkúnmí) pa. Nítorí náà, Olúwa wọn pa wọ́n rẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ó sì fi ìparun náà kárí wọn.
(15) (Ẹni tó gún ràkúnmí pa) kò sì páyà ìkángun ọ̀rọ̀ wọn.