82 - Suuratul-Infitoor
Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.  
(1) Nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,¹
1. Ẹ wo sūrah al-Baƙọrah ; 2:210, sūrah al-Furƙọ̄n; 25:25 àti Sūrah al-’Inṣiƙọ̄ƙ; 84:1-2
(2) àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,
(3) àti nígbà tí àwọn ibúdò bá ṣàn jára wọn,
(4) àti (nígbà tí A bá ta ilẹ̀ sókè), tí A sì mú àwọn òkú jáde (láàyè) láti inú àwọn sàréè,
(5) (nígbà náà ni) ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò mọ ohun tí ó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tí ó fi sẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀).
(6) Ìwọ ènìyàn, kí ni ó tàn ọ́ jẹ nípa Olúwa rẹ, Alápọ̀n-ọ́nlé,
(7) Ẹni t’Ó ṣẹ̀dá rẹ? Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ ní pípé. Ó sì mú ọ dọ́gba jalẹ̀ léèyàn.
(8) Ó to ẹ̀yà ara rẹ papọ̀ sínú èyíkéyìí àwòrán tí Ó fẹ́.
(9) Rárá! Bí kò ṣe pé ẹ̀ ń pe Ọjọ́ ẹ̀san ní irọ́.
(10) Dájúdájú àwọn ẹ̀ṣọ́ sì wà ní ọ̀dọ̀ yín.
(11) (Wọ́n jẹ́) alápọ̀n-ọ́nlé, òǹkọ̀wé-iṣẹ́ ẹ̀dá.
(12) Wọ́n mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
(13) Dájúdájú àwọn ẹni rere yóò kúkú wà nínú ìgbádùn.
(14) Dájúdájú àwọn ẹni ibi yó sì kúkú wà nínú iná Jẹhīm.
(15) Wọn yóò wọ inú rẹ̀ ní Ọjọ́ ẹ̀san.
(16) Wọn kò sì níí kúrò nínú rẹ̀.
(17) Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san?
(18) Lẹ́yìn náà, kí ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san?
(19) (Ọjọ́ ẹ̀san ni) ọjọ́ tí ẹ̀mí kan kò níí kápá kiní kan fún ẹ̀mí kan. Gbogbo àṣẹ ọjọ́ yẹn sì ń jẹ́ ti Allāhu.