أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: 78 - Suuratun-Naba' السبت 29 يوليو 2023, 12:16 am | |
| 78 - Suuratun-Naba' Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run. (1) Nípa kí ni wọ́n ń bíra wọn léèrè ná? (2) Nípa ìró ìkọ̀kọ̀ ńlá ni, (3) èyí tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀. (4) Rárá! Wọ́n ń bọ̀ wá mọ̀. (5) Lẹ́yìn náà, rárá sẹ́, wọ́n ń bọ̀ wá mọ̀. (6) Ǹjẹ́ Àwa kò ṣe ilẹ̀ ní ìtẹ́ bí, (7) àti àwọn àpáta ní èèkàn (fún ilẹ̀)? (8) A sì ṣẹ̀dá yín ní oríṣiríṣi (akọ àti abo). (9) A ṣe oorun yín ní ìsinmi. (10) A tún ṣe alẹ́ ní ìbora. (11) A tún ṣe ọ̀sán ní (àsìkò fún) wíwá ìjẹ-ìmu. (12) A tún mọ sánmọ̀ méje tó lágbára sókè yín. (13) A tún ṣe òòrùn ní ìmọ́lẹ̀ tó ń tàn gbòlà. (14) Àti pé A sọ omi tó ń bọ́ tẹ̀léra wọn kalẹ̀ láti inú àwọn ẹ̀ṣújò (15) nítorí kí Á lè fi mú kóró èso àti irúgbìn jáde (16) pẹ̀lú àwọn ọgbà tó kún digbí fún n̄ǹkan oko. (17) Dájúdájú ọjọ́ ìpínyà, ó ní gbèdéke àkókò kan. (18) (Ìyẹn ni) ọjọ́ tí wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. Ẹ̀yin yó sì máa wá níjọ-níjọ. (19) Wọ́n sì máa ṣí sánmọ̀ sílẹ̀. Ó sì máa di àwọn ìlẹ̀kùn. (20) Wọ́n máa mú àwọn àpáta rìn (bọ́ sí àyè mìíràn). Ó sì máa di ahúnpeéná. (21) Dájúdájú iná Jahanamọ, ó lúgọ sílẹ̀ lójú ọ̀nà. (22) (Ó jẹ́) ibùgbé fún àwọn alákọyọ. (23) Wọn yóò máa gbé inú rẹ̀ fún ìgbà gbọọrọ. (24) Wọn kò níí rí ìtura tàbí ohun mímu kan tọ́wò nínú rẹ̀, (25) àyàfi omi tó gbóná parí àti àwọnúwẹ̀jẹ̀.
|
|
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 78 - Suuratun-Naba' السبت 29 يوليو 2023, 12:16 am | |
| (26) (Ó jẹ́) ẹ̀san tó ṣe wẹ́kú (iṣẹ́ wọn). (27) Dájúdájú wọn kì í retí ìṣírò-iṣẹ́. (28) Wọ́n sì pe àwọn āyah Wa ní irọ́ gan-an. (29) Gbogbo n̄ǹkan sì ni A ti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú Tírà kan. (30) Nítorí náà, ẹ tọ́ (ìyà) wò. A ò sì níí ṣe àlékún kan fún yín bí kò ṣe ìyà. (31) Dájúdájú ìgbàlà wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu). (32) Àwọn ọgbà oko àti èso àjàrà, (33) àti àwọn ọlọ́mọge, tí wọn kò júra wọn lọ lọ́jọ́-orí, (34) àti ife ọtí tó kún dẹnu (ni ẹ̀san wọn). (35) Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ àti ọ̀rọ̀ irọ́ nínú rẹ̀. (36) (Ó jẹ́) ẹ̀san láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, (ó sì jẹ́) ọrẹ ní ìbámu sí ìṣírò-iṣẹ́ (wọn). (37) (Ẹsan náà wá láti ọ̀dọ̀) Olúwa àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti ohun tó wà láààrin méjèèjì, Àjọkẹ́-ayé. Wọn kò sì ní ìkápá ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Rẹ̀. (38) Ọjọ́ tí mọlāika Jibrīl àti àwọn mọlāika (mìíràn) yóò dúró ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Wọn kò sì níí sọ̀rọ̀ àfi ẹni tí Àjọké-ayé bá yọ̀ǹda fún. Onítọ̀ún sì máa sọ̀rọ̀ tó máa ṣe wẹ́kú. (39) Ìyẹn ni ọjọ́ òdodo. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mú ọ̀nà tó máa gbà ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ pọ̀n (ní ti ìronúpìwàdà). (40) Dájúdájú A fi ìyà tó súnmọ́ ṣe ìkìlọ̀ fún yín. Ọjọ́ tí ènìyàn yóò máa wo ohun tí ó tì síwájú, aláìgbàgbọ́ yó sì wí pé: “Yéè, èmi ìbá sì jẹ́ erùpẹ̀, (èmi ìbá là nínú ìyà).”
|
|