أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52580 العمر : 72
| موضوع: 74 - Suuratul-Muddathir الجمعة 28 يوليو 2023, 11:56 pm | |
| 74 - Suuratul-Muddathir Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run. (1) Ìwọ olùdaṣọbora. (2) Dìde kí o ṣèkìlọ̀. (3) Olúwa rẹ sì ni kí o gbé títóbi fún. (4) Aṣọ rẹ ni kí o fọ̀ mọ́. (5) Òrìṣà ni kí o jìnnà sí. (6) Má ṣe tọrẹ nítorí kí o lè rí púpọ̀ gbà. (7) Olúwa rẹ ni kí o ṣe sùúrù fún. (8) Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún àjíǹde, (9) ìyẹn, ní ọjọ́ yẹn, ni ọjọ́ ìnira, (10) tí kò níí rọrùn fún àwọn aláìgbàgbọ́. (11) Fi Mí dá ẹni tí Mo dá ní òun nìkan (ìyẹn nínú ikùn ìyá rẹ̀). (12) Mo sì fún un ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ dúkìá (13) àti àwọn ọmọkúnrin tó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀. (14) Mo sì fi àyè ìrọ̀rùn gbá a dáadáa. (15) Lẹ́yìn náà, ó tún ń jẹ̀rankàn pé kí N̄g ṣe àlékún. (16) Rárá o! Dájúdájú ó jẹ́ alátakò sí àwọn āyah Wa. (17) Èmi yóò la ìyà pọ́nkèpọ́nkè bọ̀ ọ́ lọ́rùn (nínú Iná)¹. [1] Orúkọ àpáta ńlá kan nínú Iná ni Sọ‘ūd. Kèfèrí yóò máa pọ́n òkè náà láààrin àádọ́rin ọdún ní àpọ́njábọ́. Ìdí nìyí tí wọ́n fi pe ìyà náà ní ìyà pọ́nkèpọ́nkè. (18) Dájúdájú ó ronú (lódì nípa al-Ƙur’ān). Ó sì pinnu (ọ̀rọ̀ kan nínú ẹ̀mí rẹ̀). (19) Wọ́n sì ṣẹ́bi lé e nípa bí ó ṣe pinnu. (20) Lẹ́yìn náà, Wọ́n tún ṣẹ́bi lé e nípa bí ó ṣe pinnu. (21) Lẹ́yìn náà, ó wò sùn. (22) Lẹ́yìn náà, ó fajú ro, ó sì dijú mágbárí. (23) Lẹ́yìn náà, ó pẹ̀yìndà, ó sì ṣègbéraga. (24) Ó sì wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe idán àtọwọ́dọ́wọ́. (25) Kí ni èyí bí kò ṣe ọ̀rọ̀ abara” (26) Èmi yóò fi sínú iná Saƙọr. (27) Kí l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ iná Saƙọr? (28) (Saƙọr) kò níí ṣẹ́ ẹ kù, kò sì níí pa á tì.¹ 1. Ìyẹn ni pé, Iná náà yóò máa jó o lọ, kò sì níí gba ẹ̀mí rẹ̀. (29) Ó máa jó awọ ara di dúdú. (30) (Àwọn mọlāika) mọ́kàndínlógún ni ẹ̀ṣọ́ rẹ̀. (31) Àwa kò ṣe ẹnì kan ní ẹ̀ṣọ́ Iná àfi àwọn mọlāika. Àwa kò sì ṣe òǹkà wọn (bẹ́ẹ̀) bí kò ṣe (nítorí kí ó lè jẹ́) àdánwò fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àti nítorí kí àwọn tí A fún ní Tírà lè ní àmọ̀dájú àti nítorí kí àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo lè lékún ní ìgbàgbọ́ òdodo. (Ó rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí àwọn tí A fún ní Tírà àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo má baà ṣeyèméjì àti nítorí kí àwọn tí àrùn wà nínú ọkàn wọn àti àwọn aláìgbàgbọ́ lè wí pé: “Kí ni Allāhu gbà lérò pẹ̀lú àpèjúwe yìí?” Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà, Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sọ́nà. Kò sì sí ẹni tí ó mọ àwọn ọmọ ogun Olúwa rẹ àfi Òun náà. (Iná Saƙọr) kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìrántí fún abara. (32) Ẹ gbọ́! Allāhu fi òṣùpá búra. (33) Ó tún fi alẹ́ nígbà tí ó bá lọ búra. (34) Ó tún fi òwúrọ̀ nígbà tí ojúmọ́ bá mọ́ búra. (35) Dájúdájú (iná Saƙọr) ni ọ̀kan nínú (àwọn àdánwò) tó tóbi. (36) (Ó jẹ́) ìkìlọ̀ fún abara. (37) Fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti tẹ̀ síwájú tàbí láti fà sẹ́yìn (nínú ẹ̀ṣẹ̀). (38) Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ni onídùúró fún ohun tó ṣe níṣẹ́. (39) Àyàfi àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún. (40) Wọn yóò máa bira wọn léèrè ọ̀rọ̀ nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra (41) nípa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pé: (42) “Kí ni ó mu yín wọ inú iná Saƙọr?” (43) Wọn yóò wí pé: “Àwa kò sí nínú àwọn olùkírun ni. (44) Àwa kò sì sí nínú àwọn tó ń bọ́ àwọn mẹ̀kúnnù. (45) Àwa sì máa ń sọ ìsọkúsọ pẹ̀lú àwọn onísọkúsọ. (46) Àti pé àwa máa ń pe Ọjọ́ ẹ̀san ní irọ́ (47) títí ikú fi dé bá wa.” (48) Ìpẹ̀ àwọn olùṣìpẹ̀ kò sì níí ṣe wọ́n ní àǹfààní. (49) Kí ló mú wọn ná tí wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi ìrántí (50) bí ẹni pé àwọn ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó ń sá lọ, (51) tó sá fún kìnìhún? (52) Rárá, ńṣe ni ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ń fẹ́ kí Á fún òun náà ní Tírà tí ó máa ṣeé tẹ́ han àwọn ènìyàn (bíi ti al-Ƙur’ān). (53) Rárá. Wọn kò páyà ọ̀run ni. (54) Ẹ gbọ́! Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ìrántí. (55) Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́, kí ó rántí rẹ̀. (56) Wọn kò sì níí rántí (al-Ƙur’ān) àfi tí Allāhu bá fẹ́. (Allāhu) Òun l’a gbọ́dọ̀ bẹ̀rù. Òun l’ó sì ni àforíjìn.
|
|