71 - Suuratu Nuuh
Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
(1) Dájúdájú Àwa rán (Ànábì) Nūh níṣẹ́ sí ìjọ rẹ̀ pé: “Ṣèkìlọ̀ fún ìjọ rẹ ṣíwájú kí ìyà ẹlẹ́ta-eléro tó dé bá wọn.”
(2) Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé fún yín
(3) pé kí ẹ jọ́sìn fún Allāhu, kí ẹ bẹ̀rù Rẹ̀, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
(4) (Allāhu) máa ṣàforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín fún yín. Ó sì máa lọ yín lára títí di gbèdéke àkókò kan. Dájúdájú àkókò (ikú tí) Allāhu (kọ mọ́ ẹ̀dá), nígbà tí ó bá dé, wọn kò níí sún un ṣíwájú tí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ̀.”
(5) Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi pe ìjọ mi ní òru àti ní ọ̀sán.
(6) Ìpè mi kò sì ṣe àlékún kan fún wọn àyàfi sísá sẹ́yìn (fún òdodo).
(7) Àti pé ìgbàkígbà tí mo bá pè wọ́n pé kí O lè foríjìn wọ́n, wọ́n ń fi ọmọníka wọn dí etí wọn, wọ́n ń yíṣọ wọn borí, wọ́n ń takú (sórí ẹ̀ṣẹ̀), wọ́n sì ń ṣègbéraga gan-an.
(8) Lẹ́yìn náà, dájúdájú èmí pè wọ́n pẹ̀lú ohùn òkè.
(9) Lẹ́yìn náà, dájúdájú èmí kéde fún wọn, mo sì tún pè wọ́n ní ìdá kọ́ńkọ́.
(10) Mo sì sọ pé, ẹ tọrọ àforíjìn ní ọ̀dọ̀ Olúwa yín, dájúdájú Ó ń jẹ́ Aláforíjìn.
(11) Ó máa rọ̀jò fún yín ní òjò púpọ̀,
(12) Ó máa fi àwọn dúkìá àti àwọn ọmọkùnrin ràn yín lọ́wọ́. Ó máa ṣe àwọn ọgbà oko fún yín. Ó sì máa ṣe àwọn odò fún yín.
(13) Kí ló mu yín tí ẹ kò páyà títóbi Allāhu?
(14) Ó sì kúkú ṣẹ̀dá yín láti ìrísí kan sí òmíràn (nínú oyún).¹
1. Ìyẹn ni pé, láti ìrísí àtọ̀ sí ìrísí ẹ̀jẹ̀ dídì, lẹ́yìn náà sí bááṣí ẹran.
(15) Ṣé ẹ kò wòye sí bí Allāhu ṣe dá àwọn sánmọ̀ méje ní ìpele ìpele ni?
(16) Ó sì ṣe òṣùpá ní ìmọ́lẹ̀ sínú wọn. Ó tún ṣe òòrùn ní àtùpà.
(17) Allāhu mu yín jáde láti ara erùpẹ̀ ilẹ̀.
(18) Lẹ́yìn náà, Ó máa da yín padà sínú rẹ̀. Ó sì máa mu yín jáde tààrà.
(19) Allāhu ṣe ilẹ̀ fún yín ní ìtẹ́
(20) nítorí kí ẹ lè tọ àwọn ojú ọ̀nà fífẹ̀ gbẹ̀gẹ̀dẹ̀ lórí rẹ̀.”
(21) (Ànábì) Nūh sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú wọ́n yapa mi. Wọ́n sì tẹ̀lé ẹni tí dúkìá rẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ kò ṣe àlékún kan fún bí kò ṣe òfò.
(22) Wọ́n sì déte ní ète tó tóbi.”
(23) Wọ́n sì wí pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ fi àwọn òrìṣà yín sílẹ̀. Ẹ kò gbọ́dọ̀ fi òrìṣà Wadd, Suwā‘u, Yẹgūth, Yẹ‘ūƙ àti Nasr sílẹ̀.”
(24) Dájúdájú wọ́n ti kó ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ṣìnà. (Olúwa mi) má ṣe jẹ́ kí àwọn alábòsí lékún ní kiní kan bí kò ṣe ìṣìnà.
(25) Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n tẹ̀ wọ́n rì sínú omi. Wọ́n sì máa fi wọ́n sínú Iná. Wọn kò sì níí rí àwọn alárànṣe kan fún wọn lẹ́yìn Allāhu.
(26) (Ànábì) Nūh tún sọ pé: “Olúwa mi, má ṣe fi ẹnì kan kan nínú àwọn aláìgbàgbọ́ sílẹ̀ lórí ilẹ̀.
(27) Dájúdájú tí Ìwọ bá fi wọ́n sílẹ̀, wọn yóò kó ìṣìnà bá àwọn ẹrú Rẹ. Wọn kò sì níí bí ọmọ kan àfi ẹni burúkú, aláìgbàgbọ́.
(28) Olúwa mi foríjìn èmi, àwọn òbí mi méjèèjì àti ẹni tó bá wọ inú ilé mi (tí ó jẹ́) onígbàgbọ́ òdodo àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin. Má sì ṣàlékún kan fún àwọn alábòsí àfi ìparun.”