منتديات إنما المؤمنون إخوة (2024 - 2010) The Believers Are Brothers

(إسلامي.. ثقافي.. اجتماعي.. إعلامي.. علمي.. تاريخي.. دعوي.. تربوي.. طبي.. رياضي.. أدبي..)
 
الرئيسيةالأحداثأحدث الصورالتسجيل
(وما من كاتب إلا سيبلى ** ويبقى الدهر ما كتبت يداه) (فلا تكتب بكفك غير شيء ** يسرك في القيامة أن تراه)

IZHAR UL-HAQ

(Truth Revealed) By: Rahmatullah Kairanvi
قال الفيلسوف توماس كارليل في كتابه الأبطال عن رسول الله -صلى الله عليه وسلم-: "لقد أصبح من أكبر العار على أي فرد مُتمدين من أبناء هذا العصر؛ أن يُصْغِي إلى ما يظن من أنَّ دِينَ الإسلام كَذِبٌ، وأنَّ مُحَمَّداً -صلى الله عليه وسلم- خَدَّاعٌ مُزُوِّرٌ، وآنَ لنا أنْ نُحارب ما يُشَاعُ من مثل هذه الأقوال السَّخيفة المُخْجِلَةِ؛ فإنَّ الرِّسَالة التي أدَّاهَا ذلك الرَّسُولُ ما زالت السِّراج المُنير مُدَّةَ اثني عشر قرناً، لنحو مائتي مليون من الناس أمثالنا، خلقهم اللهُ الذي خلقنا، (وقت كتابة الفيلسوف توماس كارليل لهذا الكتاب)، إقرأ بقية كتاب الفيلسوف توماس كارليل عن سيدنا محمد -صلى الله عليه وسلم-، على هذا الرابط: محمد بن عبد الله -صلى الله عليه وسلم-.

يقول المستشرق الإسباني جان ليك في كتاب (العرب): "لا يمكن أن توصف حياة محمد بأحسن مما وصفها الله بقوله: (وَمَا أَرْسَلْنَاكَ إِلَّا رَحْمَةً لِّلْعَالَمِين) فكان محمدٌ رحمة حقيقية، وإني أصلي عليه بلهفة وشوق".
فَضَّلَ اللهُ مِصْرَ على سائر البُلدان، كما فَضَّلَ بعض الناس على بعض والأيام والليالي بعضها على بعض، والفضلُ على ضربين: في دِينٍ أو دُنْيَا، أو فيهما جميعاً، وقد فَضَّلَ اللهُ مِصْرَ وشَهِدَ لها في كتابهِ بالكَرَمِ وعِظَم المَنزلة وذَكَرَهَا باسمها وخَصَّهَا دُونَ غيرها، وكَرَّرَ ذِكْرَهَا، وأبَانَ فضلها في آياتٍ تُتْلَى من القرآن العظيم.
المهندس حسن فتحي فيلسوف العمارة ومهندس الفقراء: هو معماري مصري بارز، من مواليد مدينة الأسكندرية، وتخرَّجَ من المُهندس خانة بجامعة فؤاد الأول، اشْتُهِرَ بطرازهِ المعماري الفريد الذي استمَدَّ مَصَادِرَهُ مِنَ العِمَارَةِ الريفية النوبية المَبنية بالطوب اللبن، ومن البيوت والقصور بالقاهرة القديمة في العصرين المملوكي والعُثماني.
رُبَّ ضَارَّةٍ نَافِعَةٍ.. فوائدُ فيروس كورونا غير المتوقعة للبشرية أنَّه لم يكن يَخطرُ على بال أحَدِنَا منذ أن ظهر وباء فيروس كورونا المُستجد، أنْ يكونَ لهذه الجائحة فوائدُ وإيجابيات ملموسة أفادَت كوكب الأرض.. فكيف حدث ذلك؟!...
تخليص الإبريز في تلخيص باريز: هو الكتاب الذي ألّفَهُ الشيخ "رفاعة رافع الطهطاوي" رائد التنوير في العصر الحديث كما يُلَقَّب، ويُمَثِّلُ هذا الكتاب علامة بارزة من علامات التاريخ الثقافي المصري والعربي الحديث.
الشيخ علي الجرجاوي (رحمه الله) قَامَ برحلةٍ إلى اليابان العام 1906م لحُضُورِ مؤتمر الأديان بطوكيو، الذي دعا إليه الإمبراطور الياباني عُلَمَاءَ الأديان لعرض عقائد دينهم على الشعب الياباني، وقد أنفق على رحلته الشَّاقَّةِ من مَالِهِ الخاص، وكان رُكُوبُ البحر وسيلته؛ مِمَّا أتَاحَ لَهُ مُشَاهَدَةَ العَدِيدِ مِنَ المُدُنِ السَّاحِلِيَّةِ في أنحاء العالم، ويُعَدُّ أوَّلَ دَاعِيَةٍ للإسلام في بلاد اليابان في العصر الحديث.

أحْـلامٌ مِـنْ أبِـي (باراك أوباما) ***

 

 70 - Suuratul-Mahaarij

اذهب الى الأسفل 
كاتب الموضوعرسالة
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn
مؤسس ومدير المنتدى
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn


عدد المساهمات : 52644
العمر : 72

70 - Suuratul-Mahaarij  Empty
مُساهمةموضوع: 70 - Suuratul-Mahaarij    70 - Suuratul-Mahaarij  Emptyالخميس 27 يوليو 2023, 1:17 am

70 - Suuratul-Mahaarij
Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
(1) Oníbèéèrè kan bèèrè nípa ìyà tó máa ṣẹlẹ̀
(2) sí àwọn aláìgbàgbọ́. Kò sì sí ẹni tí ó máa dí i lọ́wọ́
(3) lọ́dọ̀ Allāhu, Onípò-àyè gíga.
(4) Àwọn mọlāika àti mọlāika Jibrīl ń gùnkè wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nínú ọjọ́ kan tí òdiwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ ọdún (tí ẹ bá fẹ́ rìn ín).¹
1. Ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ ọdún ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta ọdún (50,000). Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Hajj; 22:47.
(5) Nítorí náà, ṣe sùúrù ní sùúrù tó rẹwà.
(6) Dájúdájú wọ́n ń wo (ìyà náà) ní ohun tó jìnnà.
(7) A sì ń wò ó ní ohun tó súnmọ́.
(8) (Ọjọ́ náà ni) ọjọ́ tí sánmọ̀ yó dà bí ògéré epo gbígbóná,
(9) àwọn àpáta yó sì dà bí ẹ̀gbọ̀n òwú-irun,
(10) ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan kò sì níí bèèrè ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ (rẹ̀).
(11) Wọ́n máa rí ara wọn (wọ́n sì máa dára wọn mọ̀). Ẹlẹ́ṣẹ̀ sì máa fẹ́ kí òun fi àwọn ọmọ rẹ̀ ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà ní ọjọ́ yẹn.
(12) Ìyàwó rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀,
(13) àti àwọn ẹbí rẹ̀ tó pa tì, tí àwọn sì ń gbà á sọ́dọ̀ nílé ayé,
(14) àti gbogbo ẹni tó wà lórí ilẹ̀ ayé pátápátá, (ó máa fẹ́ fi wọ́n ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà). Lẹ́yìn náà, (ó máa fẹ́) kí Allāhu gba òun là (nínú ìyà Iná).
(15) Rárá! Dájúdájú (ó máa wọ) iná Laṭḥọ̄ (iná tó ń jò fòfò).
(16) Ó máa bó awọ orí tòró.
(17) (Iná) yó máa ké sí ẹni tó kẹ̀yìn sí (ìgbágbọ́ òdodo), tí ó sì takété sí i,
(18) ó kó (ọrọ̀) jọ, ó sì fi pamọ́ (kò ná an fún ẹ̀sìn).
(19) Dájúdájú ènìyàn, A ṣẹ̀dá rẹ̀ ní aláìlọ́kàn, ọ̀kánjúà.
(20) Nígbà tí aburú bá fọwọ́ bà á, ó máa kanra gógó.
(21) Nígbà tí ọwọ́ rẹ̀ bá sì ba oore, ó máa yahun.
(22) Àyàfi àwọn olùkírun,
(23) àwọn tí wọ́n dúnnímọ́ ìrun wọn;
(24) àwọn tó mọ ojúṣe (wọn) nínú dúkìá wọn
(25) sí alágbe àti ẹni tí A ṣe arísìkí ní èèwọ̀ fún; 



70 - Suuratul-Mahaarij  2013_110
الرجوع الى أعلى الصفحة اذهب الى الأسفل
https://almomenoon1.0wn0.com/
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn
مؤسس ومدير المنتدى
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn


عدد المساهمات : 52644
العمر : 72

70 - Suuratul-Mahaarij  Empty
مُساهمةموضوع: رد: 70 - Suuratul-Mahaarij    70 - Suuratul-Mahaarij  Emptyالخميس 27 يوليو 2023, 1:18 am


(26) àwọn tó ń gba ọjọ́ ẹ̀san gbọ́ ní òdodo;
(27) àwọn tó ń páyà ìyà Olúwa wọn,
(28) dájúdájú ìyà Olúwa wọn kò ṣeé fàyàbalẹ̀ sí;
(29) àwọn tó ń ṣọ́ abẹ́ wọn,
(30) àyàfi lọ́dọ̀ àwọn ìyàwó wọn tàbí ẹrúbìnrin wọn ni wọn kò ti lè jẹ́ ẹni-èébú,
(31) nítorí náà, ẹnikẹ́ni tó bá ń wá n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olùtayọ-ẹnu ààlà;
(32) àwọn tó ń ṣọ́ àgbàfipamọ́ wọn àti àdéhùn wọn;
(33) àwọn tó ń dúró ti ìjẹ́rìí (òdodo) wọn;
(34) àti àwọn tó ń ṣọ́ àwọn ìrun wọn.
(35) Àwọn wọ̀nyẹn ni alápọ̀n-ọ́nlé nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.
(36) Kí ló mú àwọn tí kò gbàgbọ́ tí ara wọn kò balẹ̀ níwájú rẹ,
(37) tí wọ́n sì jókòó ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí sí ọwọ́ ọ̀tún àti ọwọ́ òsì (rẹ)?
(38) Ṣé ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ń jẹ̀rankàn pé A óò mú òun wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra ni?
(39) Rárá o! Dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá wọn láti inú ohun tí wọ́n mọ̀.
(40) Nítorí náà, Èmi ń fi Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn àti àwọn ibùwọ̀ òòrùn¹ búra, dájúdájú Àwa ni Alágbára
1. Ìyẹn ni pé, Èmi, Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn ń fi ara Mi búra. Wòóore: Èròǹgbà Allāhu pẹ̀lú “mọṣriƙ” àti “mọgrib” nínú sūrah al-Muzzammil; 73:9 ni agbègbè ibùyọ òòrùn àti agbègbè ibùwọ̀ òòrùn. Èròǹgbà Allāhu pẹ̀lú “mọṣriƙọen” nínú sūrah ar-Rahmọ̄n; 55:17 ni ibùyọ òòrùn lásìkò ẹ̀rùn àti ibùyọ òòrùn lásìkò òjò. Bákan náà, “mọgribaen” ibùwọ̀ òòrùn lásìkò ẹ̀rùn àti ibùwọ̀ òòrùn lásìkò òjò. Bákan náà, èròǹgbà Allāhu pẹ̀lú “mọṣāriƙ àti mọgārib” ni àwọn ọgọ́sàn-án ibùyọ òòrùn àti ọgọ́sàn-án ibùwọ̀ òòrùn. (Tafsīr Bagawiy)
(41) láti yí (ìrísí wọn) padà (ní ọjọ́ Àjíǹde) sí (ìrísí kan) tó máa dára ju (ìrísí) wọn (tayé). Kò sì sí ẹni tó lè dá Wa lágara.¹
1. Ẹ tún wo sūrah al-Wāƙi‘ah; 56:60-61 àti sūrah al-Ƙiyāmọh; 75:3-4.
(42) Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ ìsọkúsọ (wọn), kí wọ́n sì máa ṣeré títí wọn yóò fi pàdé ọjọ́ wọn tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.
(43) Ọjọ́ tí wọn yóò sáré jáde wéréwéré láti inú àwọn sàréè, wọn yó sì dà bí ẹni pé wọ́n ń yára lọ sídìí ohun àfojúsùn kan.
(44) Ojú wọn yóò wálẹ̀. Ìyẹpẹrẹ máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ọjọ́ yẹn ni èyí tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn. 



70 - Suuratul-Mahaarij  2013_110
الرجوع الى أعلى الصفحة اذهب الى الأسفل
https://almomenoon1.0wn0.com/
 
70 - Suuratul-Mahaarij
الرجوع الى أعلى الصفحة 
صفحة 1 من اصل 1

صلاحيات هذا المنتدى:لاتستطيع الرد على المواضيع في هذا المنتدى
منتديات إنما المؤمنون إخوة (2024 - 2010) The Believers Are Brothers :: (English) :: The Holy Quran is translated :: Yoruba-
انتقل الى: