63 - Suuratul-Munaafikuun
Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
(1) Nígbà tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí bá wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, wọ́n á wí pé: “À ń jẹ́rìí pé dájúdájú ìwọ, Òjíṣẹ́ Allāhu ni ọ́.” Allāhu sì mọ̀ pé dájúdájú ìwọ, Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ni ọ́. Allāhu sì ń jẹ́rìí pé dájúdájú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí, òpùrọ́ ni wọ́n.
(2) Wọ́n fi àwọn ìbúra wọn ṣe ààbò (fún ẹ̀mí ara wọn), wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu; dájúdájú ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ burú.
(3) (Wọ́n ṣe) ìyẹn nítorí pé, wọ́n gbàgbọ́, lẹ́yìn náà wọ́n ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, A ti fi èdídí dí ọkàn wọn; wọn kò sì níí gbọ́ àgbọ́yé.
(4) Nígbà tí o bá rí wọn, ìrísí wọn yóò jọ ọ́ lójú. Tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀, ìwọ yóò tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn. Wọ́n sì dà bí igi tí wọ́n gbé ti ògiri.¹ Wọ́n sì ń lérò pé gbogbo igbe (ìbòsí) ń bẹ lórí wọn (nípa ìṣọ̀bẹ-ṣèlu wọn).² Ọ̀tá ni wọ́n. Nítorí náà, ṣọ́ra fún wọn. Allāhu ti ṣẹ́bi lé wọn. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo!
1. Ìyẹn ni pé, kò sí èso kan tí igi wọn máa so. Ó ti di òkú igi. 2. Gbólóhùn yìí jọ sūrah at-Taobah; 9:127.
(5) Àti pé nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ wá kí Òjíṣẹ́ ba yín tọrọ àforíjìn.” Wọ́n á gbúnrí. O sì máa rí wọn tí wọn yóò máa gbúnrí lọ, tí wọn yóò máa ṣègbéraga.
(6) Bákan náà ni fún wọn; yálà o bá wọn tọrọ àforíjìn tàbí o ò bá wọn tọrọ àforíjìn.¹ Allāhu kò níí foríjìn wọ́n. Dájúdájú Allāhu kò nií fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.
1. Fún àlàyé lórí āyah yìí, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah at-Taobah; 9:80.
(7) Àwọn ni àwọn tó ń wí pé: “Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ ná owó fún àwọn tó wà lọ́dọ̀ Ójíṣẹ́ Allāhu títí wọn yóò fi fọ́nká. Ti Allāhu sì ni àwọn ilé ọrọ̀ sánmọ̀ àti ilẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí kò gbọ́ àgbọ́yé.
(8) Wọ́n ń wí pé: “Dájúdájú tí a bá padà dé sínú ìlú Mọdīnah, ńṣe ni àwọn alágbára (ìlú) yóò yọ àwọn ẹni yẹpẹrẹ jáde kúrò nínú ìlú.” Agbára sì ń jẹ́ ti Allāhu, àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo, ṣùgbọ́n àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí kò mọ̀.
(9) Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe jẹ́ kí àwọn dúkìá yín àti àwọn ọmọ yín kó àìrójú ba yín níbi ìrántí Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá kó sínú (àìrójú) yẹn, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni ẹni òfò.
(10) Ẹ ná nínú ohun tí A pèsè fún yín ṣíwájú kí ikú tó dé bá ẹnì kan yín, kí ó wá wí pé: “Olúwa mi, kí ó sì jẹ́ pé O lọ́ mi lára sí i títí di ìgbà kan tó súnmọ́, èmi ìbá sì lè máa tọrẹ, èmi ìbá sì wà lára àwọn ẹni rere.”
(11) Allāhu kò sì níí lọ́ ẹ̀mí kan lára nígbà tí ọjọ́ ikú rẹ̀ bá dé. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.