منتديات إنما المؤمنون إخوة (2024 - 2010) The Believers Are Brothers

(إسلامي.. ثقافي.. اجتماعي.. إعلامي.. علمي.. تاريخي.. دعوي.. تربوي.. طبي.. رياضي.. أدبي..)
 
الرئيسيةالأحداثأحدث الصورالتسجيل
(وما من كاتب إلا سيبلى ** ويبقى الدهر ما كتبت يداه) (فلا تكتب بكفك غير شيء ** يسرك في القيامة أن تراه)

IZHAR UL-HAQ

(Truth Revealed) By: Rahmatullah Kairanvi
قال الفيلسوف توماس كارليل في كتابه الأبطال عن رسول الله -صلى الله عليه وسلم-: "لقد أصبح من أكبر العار على أي فرد مُتمدين من أبناء هذا العصر؛ أن يُصْغِي إلى ما يظن من أنَّ دِينَ الإسلام كَذِبٌ، وأنَّ مُحَمَّداً -صلى الله عليه وسلم- خَدَّاعٌ مُزُوِّرٌ، وآنَ لنا أنْ نُحارب ما يُشَاعُ من مثل هذه الأقوال السَّخيفة المُخْجِلَةِ؛ فإنَّ الرِّسَالة التي أدَّاهَا ذلك الرَّسُولُ ما زالت السِّراج المُنير مُدَّةَ اثني عشر قرناً، لنحو مائتي مليون من الناس أمثالنا، خلقهم اللهُ الذي خلقنا، (وقت كتابة الفيلسوف توماس كارليل لهذا الكتاب)، إقرأ بقية كتاب الفيلسوف توماس كارليل عن سيدنا محمد -صلى الله عليه وسلم-، على هذا الرابط: محمد بن عبد الله -صلى الله عليه وسلم-.

يقول المستشرق الإسباني جان ليك في كتاب (العرب): "لا يمكن أن توصف حياة محمد بأحسن مما وصفها الله بقوله: (وَمَا أَرْسَلْنَاكَ إِلَّا رَحْمَةً لِّلْعَالَمِين) فكان محمدٌ رحمة حقيقية، وإني أصلي عليه بلهفة وشوق".
فَضَّلَ اللهُ مِصْرَ على سائر البُلدان، كما فَضَّلَ بعض الناس على بعض والأيام والليالي بعضها على بعض، والفضلُ على ضربين: في دِينٍ أو دُنْيَا، أو فيهما جميعاً، وقد فَضَّلَ اللهُ مِصْرَ وشَهِدَ لها في كتابهِ بالكَرَمِ وعِظَم المَنزلة وذَكَرَهَا باسمها وخَصَّهَا دُونَ غيرها، وكَرَّرَ ذِكْرَهَا، وأبَانَ فضلها في آياتٍ تُتْلَى من القرآن العظيم.
المهندس حسن فتحي فيلسوف العمارة ومهندس الفقراء: هو معماري مصري بارز، من مواليد مدينة الأسكندرية، وتخرَّجَ من المُهندس خانة بجامعة فؤاد الأول، اشْتُهِرَ بطرازهِ المعماري الفريد الذي استمَدَّ مَصَادِرَهُ مِنَ العِمَارَةِ الريفية النوبية المَبنية بالطوب اللبن، ومن البيوت والقصور بالقاهرة القديمة في العصرين المملوكي والعُثماني.
رُبَّ ضَارَّةٍ نَافِعَةٍ.. فوائدُ فيروس كورونا غير المتوقعة للبشرية أنَّه لم يكن يَخطرُ على بال أحَدِنَا منذ أن ظهر وباء فيروس كورونا المُستجد، أنْ يكونَ لهذه الجائحة فوائدُ وإيجابيات ملموسة أفادَت كوكب الأرض.. فكيف حدث ذلك؟!...
تخليص الإبريز في تلخيص باريز: هو الكتاب الذي ألّفَهُ الشيخ "رفاعة رافع الطهطاوي" رائد التنوير في العصر الحديث كما يُلَقَّب، ويُمَثِّلُ هذا الكتاب علامة بارزة من علامات التاريخ الثقافي المصري والعربي الحديث.
الشيخ علي الجرجاوي (رحمه الله) قَامَ برحلةٍ إلى اليابان العام 1906م لحُضُورِ مؤتمر الأديان بطوكيو، الذي دعا إليه الإمبراطور الياباني عُلَمَاءَ الأديان لعرض عقائد دينهم على الشعب الياباني، وقد أنفق على رحلته الشَّاقَّةِ من مَالِهِ الخاص، وكان رُكُوبُ البحر وسيلته؛ مِمَّا أتَاحَ لَهُ مُشَاهَدَةَ العَدِيدِ مِنَ المُدُنِ السَّاحِلِيَّةِ في أنحاء العالم، ويُعَدُّ أوَّلَ دَاعِيَةٍ للإسلام في بلاد اليابان في العصر الحديث.

أحْـلامٌ مِـنْ أبِـي (باراك أوباما) ***

 

 54 - Suuratul-Qamar

اذهب الى الأسفل 
كاتب الموضوعرسالة
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn
مؤسس ومدير المنتدى
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn


عدد المساهمات : 52644
العمر : 72

54 - Suuratul-Qamar  Empty
مُساهمةموضوع: 54 - Suuratul-Qamar    54 - Suuratul-Qamar  Emptyالخميس 27 يوليو 2023, 12:50 am

54 - Suuratul-Qamar
Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
(1) Àkókò náà súnmọ́. Òṣùpá sì là pẹrẹgẹdẹ (sí méjì).¹
1. Ìyẹn ṣẹlẹ̀ ní àsìkò Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - nígbà tí àwọn ọ̀ṣẹbọ bèèrè fún àmì ìyanu lọ́wọ́ rẹ̀.
(2) Tí wọ́n bá rí àmì kan, wọ́n máa gbúnrí. Wọn yó sí wí pé: “Idán kan tó máa parẹ́ (ni èyí).”¹
1. Ìtúmọ̀ mìíràn fún “sihrun mustamirr” idán kan tó lágbára (ni èyí).
(3) Wọ́n pè é ní irọ́. Wọ́n sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn. Gbogbo iṣẹ́ ẹ̀dá sì máa jókòó tì í lọ́rùn. ¹
1. Ìtúmọ̀ mìíràn fún “wa kullu ’amrin mustaƙirr” Gbogbo ìṣe ẹ̀dá ló ní ìkángun.
(4) Dájúdájú wáàsí tí ó ń kọ aburú¹ wà nínú àwọn ìró tó dé bá wọn.
1. “Muzdajar” wáàsí tó le tó kún fún ìṣẹ̀rùbà àti àpẹ̀ẹrẹ ìjìyà tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹni àkọ́kọ́ nínú àwọn ọ̀tá òdodo.
(5) (al-Ƙur’ān sì ni) ọgbọ́n tó péye pátápátá; ṣùgbọ́n àwọn ìkìlọ̀ náà kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀.
(6) Ṣẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn. Ní ọjọ́ tí olùpèpè yóò pèpè fún kiní kan tí ẹ̀mí kórira (ìyẹn, Àjíǹde),
(7) Ojú wọn máa wálẹ̀ ní ti àbùkù. Wọn yó sì máa jáde láti inú sàréè bí ẹni pé eṣú tí wọ́n fọ́nká síta ni wọ́n.
(8) Wọn yó sì máa yára lọ sí ọ̀dọ̀ olùpèpè náà. Àwọn aláìgbàgbọ́ yó sì wí pé: “Èyí ni ọjọ́ ìṣòro.”
(9) Ìjọ (Ànábì) Nūh pe òdodo ní irọ́ ṣíwájú wọn. Nígbà náà, wọ́n pe ẹrúsìn Wa ní òpùrọ́. Wọ́n sì wí pé: “Wèrè ni.” Wọ́n sì kọ̀ fún un pẹ̀lú ohùn líle.¹
1. Àwọn nasọ̄rọ̄ sọ pé, “Gbólóhùn ìparí āyah yìí ń sọ pé, ‘ìjọ Nūh lé Nūh jáde kúrò nínú ìlú’. Àmọ́ sūrah Hūd; 11:38 ń sọ pé, ‘Nígbàkígbà tí àwọn ọ̀tọ̀kùlú nínú ìjọ rẹ̀ bá kọjá lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n yó sì máa fi ṣe yẹ̀yẹ́.” Wọ́n ní, “Kò gbọ́dọ̀ jẹ́ Nūh tí wọ́n ti lé jáde kúrò nínú ìlú ni ẹni tí wọ́n fi ń ṣe yẹ̀yẹ́!” Èsì: Kò sí ìtakora kan nínú rẹ̀. Al-Ƙur’ān kò fi rinlẹ̀ níbì kan kan pé, ìjọ Nūh lé Ànábì Nūh - kí ọlà Allāhu máa bá a - jáde kúrò nínú ìlú. Ìpìlẹ̀ “wa-zdujir” ni “zajara” láti ara “zajr” – kíkọ n̄ǹkan àti híhánnà n̄ǹkan pẹ̀lú ohùn líle. Ìyẹn ni pé, wọ́n fi ohùn líle kọ òdodo sílẹ̀ fún Ànábì Nūh - kí ọlà Allāhu máa bá a - ní kíkọ̀ àlésá-sẹ́yìn fún wọn nípasẹ̀ sísọ ọ̀rọ̀ burúkú sí i, híhalẹ̀ mọ̀ ọn, dídúnkokò mọ́ ọn nítorí kí ó lè máa wò wọ́n níran. Ìtúmọ̀ “wa-zdujir” yìí ni Allāhu ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú sūrah aṣ-Ṣu‘arā’; 26:116 pé wọ́n ń fi lílẹ̀ lókò halẹ̀ mọ́ ọn. Ìtúmọ̀ kíkọ̀ náà ni ìtúmọ̀ tó jẹyọ nínú “muzdajar” tó parí āyah 4 ṣíwájú. Ìtúmọ̀ àkànlò fún “zajr” sì jẹyọ nínú sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:2. Kókó ọ̀rọ̀ ni pé, ìjọ Nūh fi ohùn líle kọ ọ̀rọ̀ sí Ànábì Nūh - kí ọlà Allāhu máa bá a - lẹ́nu ni, kì í ṣe pé wọ́n lé e jáde kúrò nínú ìlú. Wọ́n kọ ìtẹ̀lé Ànábì Nūh - kí ọlà Allāhu máa bá a - sílẹ̀ pẹ̀lú sísọ ọ̀rọ̀ burúkú sí i. Àmọ́ Ànábì Nūh - kí ọlà Allāhu máa bá a - wà nínú ìlú pẹ̀lú wọn títí ó fi kan ọkọ̀ ojú omi. W-Allāhu ’a‘lam.
(10) Nítorí náà, ó pe Olúwa rẹ̀ pé: “Dájúdájú wọ́n ti borí mi. Bá mi gbẹ̀san.”
(11) Nítorí náà, A ṣí àwọn ìlẹ̀kùn sánmọ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú omi tó lágbára.
(12) A tún mú àwọn odò ṣàn jáde láti inú ilẹ̀. Omi (sánmọ̀) pàdé (omi ilẹ̀) pẹ̀lú àṣẹ tí A ti kọ (lé wọn lórí).
(13) A sì gbé (Ànábì) Nūh gun ọkọ̀ onípákó, ọkọ̀ eléṣòó,
(14) tí ó ń rìn (lórí omi) lójú Wa. (Ó jẹ́) ẹ̀san nítorí ẹni tí wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀.
(15) Dájúdájú A ṣẹ́ ẹ kù (tí A fi ṣe) àmì. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
(16) Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?
(17) Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
(18) Ìran ‘Ād pé òdodo ní irọ́. Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?
(19) Dájúdájú Àwa rán atẹ́gùn líle sí wọn ní ọjọ́ burúkú kan tó ń tẹ̀ síwájú.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Fussilat; 41:16.
(20) Ó ń fa àwọn ènìyàn tu bí ẹni pé kùkùté igi ọ̀pẹ tí wọ́n fà tu tegbòtegbò ni wọ́n.
(21) Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?
(22) Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
(23) Ìjọ Thamūd pe àwọn ìkìlọ̀ ní irọ́.
(24) Wọ́n wí pé: “Ṣé abara kan, ẹnì kan ṣoṣo nínú wa ni a óò máa tẹ̀lé. (Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀) nígbà náà dájúdájú àwa ti wà nínú ìṣìnà àti wàhálà.
(25) Ṣé òun ni wọ́n sọ tírà ìrántí kalẹ̀ fún láààrin wa? Rárá o, òpùrọ́ onígbèéraga ni.” 



54 - Suuratul-Qamar  2013_110
الرجوع الى أعلى الصفحة اذهب الى الأسفل
https://almomenoon1.0wn0.com/
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn
مؤسس ومدير المنتدى
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn


عدد المساهمات : 52644
العمر : 72

54 - Suuratul-Qamar  Empty
مُساهمةموضوع: رد: 54 - Suuratul-Qamar    54 - Suuratul-Qamar  Emptyالخميس 27 يوليو 2023, 12:51 am


(26) Ní ọ̀la ni wọn yóò mọ ta ni òpùrọ́ onígbèéraga.
(27) Dájúdájú Àwa máa rán abo ràkúnmí sí wọn; (ó máa jẹ́) àdánwò fún wọn. Nítorí náà, máa wò wọ́n níran ná, kí o sì ṣe sùúrù.¹
1. Ṣe sùúrù láì níí fi ẹjọ́ wọn sùn mọ́.
(28) Kí o sì fún wọn ní ìró pé dájúdájú pípín ni omi láààrin wọn. Gbogbo ìpín omi sì wà fún ẹni tí ó bá kàn láti wá sí odò.
(29) Wọ́n pe ẹni wọn. Ó yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ nawọ́ mú (ràkúnmí náà mọ́lẹ̀). Ó sì pa á.
(30) Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)?
(31) Dájúdájú Àwa rán igbe kan ṣoṣo sí wọn. Wọ́n sì dà bí koríko gbígbẹ tí àgbẹ̀ dáná sun.
(32) Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
(33) Ìjọ Lūt pe àwọn ìkìlọ̀ ní irọ́.
(34) Dájúdájú Àwa fi òkúta iná ránṣẹ́ sí wọn àfi ará ilé Lūt, tí A gbàlà ní àsìkò sààrì.
(35) (Ó jẹ́) ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa. Báyẹn ni A ṣe ń san ẹ̀san fún ẹni tó bá dúpẹ́ (fún Wa).
(36) Ó kúkú fi ìgbámú Wa ṣe ìkìlọ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ja àwọn ìkìlọ̀ níyàn.
(37) Wọ́n kúkú làkàkà lọ́dọ̀ rẹ̀ láti bá àwọn aléjò rẹ̀ ṣèbàjẹ́. Nítorí náà, A fọ́ ojú wọn. Ẹ tọ́ ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi wò.
(38) Àti pé dájúdájú ìyà gbére ni wọ́n mọ́júmọ́ sínú rẹ̀ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù.
(39) Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi wò.
(40) Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
(41) Dájúdájú àwọn ìkìlọ̀ dé bá àwọn ènìyàn Fir‘aon.
(42) Wọ́n pe gbogbo àwọn āyah Wa ní irọ́ pátápátá. A sì gbá wọn mú ní ìgbámú (tí) Alágbára, Olùkápá (máa ń gbá ẹ̀dá mú).
(43) Ṣé àwọn aláìgbàgbọ́ (nínú) yín l’ó lóore ju àwọn wọ̀nyẹn (tí wọ́n ti parẹ́ bọ́ sẹ́yìn) ni tàbí ẹ̀yin ní ìmóríbọ́ kan nínú ìpín-ìpín Tírà (pé ẹ̀yin kò níí jìyà)?
(44) Tàbí wọ́n ń wí pé: “Àwa wà papọ̀ tí a óò ranra wa lọ́wọ́ láti borí (Òjíṣẹ́)”
(45) A máa fọ́ àkójọ náà lógun. Wọn sì máa fẹsẹ̀ fẹ́ẹ lójú ogun.
(46) Àmọ́ sá, Àkókò náà ni ọjọ́ àdéhùn wọn. Àkókò náà burú jùlọ. Ó sì korò jùlọ.
(47) Dájúdájú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wà nínú ìṣìnà àti wàhálà.
(48) Ní ọjọ́ tí A óò dojú wọn bolẹ̀ wọ inú Iná, (A ó sì sọ pé): Ẹ tọ́ ìfọwọ́bà Iná wò.
(49) Dájúdájú A ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan pẹ̀lú kádàrá.
(50) Àṣẹ Wa (fún mímú n̄ǹkan bẹ) kò tayọ (àṣẹ) ẹyọ kan ṣoṣo gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ́jú.¹
1. Ìyẹn ni pé, a máa lo ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọdún nínú sàréè, àmọ́ láààrin ká ṣẹ́jú ká lajú, gbogbo ẹ̀dá máa jí dìde láti inú sàréè wọn.
(51) Àti pé dájúdájú A ti pa àwọn irú yín rẹ́. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí?
(52) Gbogbo n̄ǹkan tí wọ́n ṣe níṣẹ́ sì wà nínú ìpín-ìpín tírà.
(53) Àti pé gbogbo n̄ǹkan kékeré àti n̄ǹkan ńlá (tí wọ́n ṣe) wà ní àkọsílẹ̀.
(54) Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) yóò wà nínú àwọn Ọgbà (Ìdẹ̀ra) pẹ̀lú àwọn odò (tó ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀).
(55) Ní ibùjókòó òdodo nítòsí Ọba Alágbára Olùkápá. 



54 - Suuratul-Qamar  2013_110
الرجوع الى أعلى الصفحة اذهب الى الأسفل
https://almomenoon1.0wn0.com/
 
54 - Suuratul-Qamar
الرجوع الى أعلى الصفحة 
صفحة 1 من اصل 1
 مواضيع مماثلة
-
» QUR’AAN 54, SUURATUL QAMAR
» Al-Qamar
» Al-Qamar
» 54 - AL-QAMAR
» Al-Qamar

صلاحيات هذا المنتدى:لاتستطيع الرد على المواضيع في هذا المنتدى
منتديات إنما المؤمنون إخوة (2024 - 2010) The Believers Are Brothers :: (English) :: The Holy Quran is translated :: Yoruba-
انتقل الى: