منتديات إنما المؤمنون إخوة (2024 - 2010) The Believers Are Brothers

(إسلامي.. ثقافي.. اجتماعي.. إعلامي.. علمي.. تاريخي.. دعوي.. تربوي.. طبي.. رياضي.. أدبي..)
 
الرئيسيةالأحداثأحدث الصورالتسجيل
(وما من كاتب إلا سيبلى ** ويبقى الدهر ما كتبت يداه) (فلا تكتب بكفك غير شيء ** يسرك في القيامة أن تراه)

IZHAR UL-HAQ

(Truth Revealed) By: Rahmatullah Kairanvi
قال الفيلسوف توماس كارليل في كتابه الأبطال عن رسول الله -صلى الله عليه وسلم-: "لقد أصبح من أكبر العار على أي فرد مُتمدين من أبناء هذا العصر؛ أن يُصْغِي إلى ما يظن من أنَّ دِينَ الإسلام كَذِبٌ، وأنَّ مُحَمَّداً -صلى الله عليه وسلم- خَدَّاعٌ مُزُوِّرٌ، وآنَ لنا أنْ نُحارب ما يُشَاعُ من مثل هذه الأقوال السَّخيفة المُخْجِلَةِ؛ فإنَّ الرِّسَالة التي أدَّاهَا ذلك الرَّسُولُ ما زالت السِّراج المُنير مُدَّةَ اثني عشر قرناً، لنحو مائتي مليون من الناس أمثالنا، خلقهم اللهُ الذي خلقنا، (وقت كتابة الفيلسوف توماس كارليل لهذا الكتاب)، إقرأ بقية كتاب الفيلسوف توماس كارليل عن سيدنا محمد -صلى الله عليه وسلم-، على هذا الرابط: محمد بن عبد الله -صلى الله عليه وسلم-.

يقول المستشرق الإسباني جان ليك في كتاب (العرب): "لا يمكن أن توصف حياة محمد بأحسن مما وصفها الله بقوله: (وَمَا أَرْسَلْنَاكَ إِلَّا رَحْمَةً لِّلْعَالَمِين) فكان محمدٌ رحمة حقيقية، وإني أصلي عليه بلهفة وشوق".
فَضَّلَ اللهُ مِصْرَ على سائر البُلدان، كما فَضَّلَ بعض الناس على بعض والأيام والليالي بعضها على بعض، والفضلُ على ضربين: في دِينٍ أو دُنْيَا، أو فيهما جميعاً، وقد فَضَّلَ اللهُ مِصْرَ وشَهِدَ لها في كتابهِ بالكَرَمِ وعِظَم المَنزلة وذَكَرَهَا باسمها وخَصَّهَا دُونَ غيرها، وكَرَّرَ ذِكْرَهَا، وأبَانَ فضلها في آياتٍ تُتْلَى من القرآن العظيم.
المهندس حسن فتحي فيلسوف العمارة ومهندس الفقراء: هو معماري مصري بارز، من مواليد مدينة الأسكندرية، وتخرَّجَ من المُهندس خانة بجامعة فؤاد الأول، اشْتُهِرَ بطرازهِ المعماري الفريد الذي استمَدَّ مَصَادِرَهُ مِنَ العِمَارَةِ الريفية النوبية المَبنية بالطوب اللبن، ومن البيوت والقصور بالقاهرة القديمة في العصرين المملوكي والعُثماني.
رُبَّ ضَارَّةٍ نَافِعَةٍ.. فوائدُ فيروس كورونا غير المتوقعة للبشرية أنَّه لم يكن يَخطرُ على بال أحَدِنَا منذ أن ظهر وباء فيروس كورونا المُستجد، أنْ يكونَ لهذه الجائحة فوائدُ وإيجابيات ملموسة أفادَت كوكب الأرض.. فكيف حدث ذلك؟!...
تخليص الإبريز في تلخيص باريز: هو الكتاب الذي ألّفَهُ الشيخ "رفاعة رافع الطهطاوي" رائد التنوير في العصر الحديث كما يُلَقَّب، ويُمَثِّلُ هذا الكتاب علامة بارزة من علامات التاريخ الثقافي المصري والعربي الحديث.
الشيخ علي الجرجاوي (رحمه الله) قَامَ برحلةٍ إلى اليابان العام 1906م لحُضُورِ مؤتمر الأديان بطوكيو، الذي دعا إليه الإمبراطور الياباني عُلَمَاءَ الأديان لعرض عقائد دينهم على الشعب الياباني، وقد أنفق على رحلته الشَّاقَّةِ من مَالِهِ الخاص، وكان رُكُوبُ البحر وسيلته؛ مِمَّا أتَاحَ لَهُ مُشَاهَدَةَ العَدِيدِ مِنَ المُدُنِ السَّاحِلِيَّةِ في أنحاء العالم، ويُعَدُّ أوَّلَ دَاعِيَةٍ للإسلام في بلاد اليابان في العصر الحديث.

أحْـلامٌ مِـنْ أبِـي (باراك أوباما) ***

 

 45 - Suuratul-Jaathiyah

اذهب الى الأسفل 
كاتب الموضوعرسالة
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn
مؤسس ومدير المنتدى
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn


عدد المساهمات : 52644
العمر : 72

45 - Suuratul-Jaathiyah  Empty
مُساهمةموضوع: 45 - Suuratul-Jaathiyah    45 - Suuratul-Jaathiyah  Emptyالأحد 23 يوليو 2023, 6:51 pm

45 - Suuratul-Jaathiyah
Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
(1) Hā mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.
(2) Tírà náà sọ̀kalẹ̀ díẹ̀ díẹ̀¹ láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Isrọ̄’; 17:106.
(3) Dájúdájú nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àwọn àmì wà (nínú wọn) fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
(4) Àwọn àmì wà nínú ìṣẹ̀dá yín àti ohun tí Allāhu ń fọ́nká (sórí ilẹ̀) nínú àwọn n̄ǹkan abẹ̀mí; (àmì wà nínú wọn) fún ìjọ tó ní àmọ̀dájú.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:164.
(5) (Nínú) ìtẹ̀léǹtẹ̀lé òru àti ọ̀sán, àti ohun tí Allāhu ń sọ̀kalẹ̀ ní arísìkí, tí Ó ń fi sọ ilẹ̀ di àyè lẹ́yìn tó ti kú àti ìyípadà atẹ́gùn, àwọn àmì tún wà (nínú wọn) fún ìjọ tó ní làákàyè.
(6) Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Allāhu tí À ń ké (ní kéú) fún ọ pẹ̀lú òdodo. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ wo lẹ́yìn (ọ̀rọ̀) Allāhu àti àwọn àmì Rẹ̀ ni wọn yóò tún gbàgbọ́?
(7) Ègbé ni fún gbogbo ògbólógbòó òpùrọ́, ògbólógbòó ẹlẹ́ṣẹ̀,
(8) tí ó ń gbọ́ àwọn āyah Allāhu, tí wọ́n ń ké e fún un, lẹ́yìn náà, tí ó takú (sórí irọ́) ní ti ìgbéraga bí ẹni pé kò gbọ́ ọ. Fún un ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
(9) Nígbà tí ó bá nímọ̀ nípa kiní kan nínú àwọn āyah Wa (tí òun náà jẹ́rìí sí òdodo rẹ̀), ó máa mú un ní n̄ǹkan yẹ̀yẹ́. Àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá ń bẹ fún.
(10) Iná Jahanamọ wà níwájú wọn. Ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ àti ohun tí wọ́n mú ní alátìlẹ́yìn lẹ́yìn Allāhu kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kan níbi ìyà. Ìyà ńlá sì wà fún wọn.
(11) Èyí ni ìmọ̀nà. Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Olúwa wọn, ìyà ẹlẹ́gbin ẹlẹ́ta-eléro wà fún wọn.
(12) Allāhu ni Ẹni tí Ó rọ agbami odò fún yín nítorí kí àwọn ọkọ̀ ojú-omi lè rìn nínú rẹ̀ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀ àti nítorí kí ẹ tún lè wá nínú oore Rẹ̀ àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Un).
(13) Ó tún rọ ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ pátápátá fún yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní àròjinlẹ̀.
(14) Sọ fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo pé kí wọ́n ṣàmójú kúrò fún àwọn tí kò retí àwọn ọjọ́ (tí) Allāhu (yóò ṣe àrànṣe fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo) nítorí kí Ó lè san ẹ̀san fún ìjọ kan nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
(15) Ẹníkẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ aburú, fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni wọn yóò da yín padà sí.
(16) Dájúdájú A fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl ní Tírà àti ìdájọ́ ṣíṣe àti ipò Ànábì. A sì ṣe arísìkí fún wọn nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. A sì ṣoore àjùlọ fún wọn lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò tiwọn).
(17) A tún fún wọn ní àwọn ẹ̀rí tó yanjú nípa ọ̀rọ̀ náà. Nítorí náà, wọn kò pín sí ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àfi lẹ́yìn tí ìmọ̀ (’Islām) dé bá wọn ní ti ìlara láààrin ara wọn (sí àwọn Ànábì). Dájúdájú Olúwa rẹ l’Ó máa ṣe ìdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa n̄ǹkan tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀.
(18) Lẹ́yìn náà, A fi ọ́ sí ojú ọ̀nà kan nínú ọ̀rọ̀ náà (ẹ̀sìn ’Islām). Nítorí náà, tẹ̀lé e. Kí o sì má ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú àwọn tí kò nímọ̀.
(19) Dájúdájú wọn kò lè rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ kiní kan níbi ìyà ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Àti pé dájúdájú àwọn alábòsí, apá kan wọn lọ̀rẹ́ apá kan. Allāhu sì ni Ọ̀rẹ́ àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).
(20) Èyí ni ìmọ̀ àmọ̀dájú àti ẹ̀rí fún àwọn ènìyàn. Ìmọ̀nà àti ìkẹ́ ni fún ìjọ tó ní àmọ̀dájú.
(21) Tàbí àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ aburú lérò pé A máa ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí (A ti ṣe) àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, kí ìṣẹ́mí ayé wọn àti ikú wọn rí bákan náà? Ohun tí wọ́n ń dá ní ẹjọ́, ó burú.
(22) Allāhu ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo àti nítorí kí Á lè san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san n̄ǹkan tí ó ṣe níṣẹ́. A kò sì níí ṣe àbòsí sí wọn.
(23) Sọ fún mi nípa ẹni tí ó sọ ìfẹ́-inú rẹ̀ di ọlọ́hun rẹ̀, tí Allāhu sì ṣì í lọ́nà pẹ̀lú ìmọ̀¹, tí Ó sì fi èdídí dí ìgbọ́rọ̀ rẹ̀ àti ọkàn rẹ̀, tí Ó tún fi èbìbò bo ojú rẹ̀! Ta ni ó máa fi ọ̀nà mọ̀ ọ́n lẹ́yìn Allāhu? Ṣé ẹ kò níí lo ìrántí ni?
1. Ìmọ̀ nípa ìṣìnà onífẹ̀ẹ́-inú ti wà lọ́dọ̀ Allāhu ṣíwájú ìṣẹ̀dá rẹ̀ pé kò níí tẹ̀lé ìmọ̀nà, kódà kí gbogbo ẹ̀rí tó yanjú dé àrọ́wọ́tó rẹ̀. Ìyẹn ni pé, ìṣìnà olùṣìnà kò bá Allāhu lójijì, kò sì titun sí I. Allāhu - Ọba Alámọ̀tán - kúkú ní ìmọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin ẹ̀dá.
(24) Wọ́n wí pé: “Kò sí ìṣẹ̀mí kan mọ́ bí kò ṣe ìṣẹ̀mí ayé wa yìí; à ń kú, a sì ń ṣẹ̀mí. Àti pé kò sí n̄ǹkan tó ń pa wá bí kò ṣe ìgbà.” Wọn kò sì ní ìmọ̀ kan nípa ìyẹn; wọn kò ṣe kiní kan bí kò ṣe pé wọ́n ń ro èròkérò.
(25) Àti pé nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa tó yanjú fún wọn, àwíjàre wọn kò jẹ́ kiní kan àyàfi kí wọ́n wí pé: “Ẹ mú àwọn bàbá wa wá tí ẹ bá jẹ́ olódodo.” 



45 - Suuratul-Jaathiyah  2013_110
الرجوع الى أعلى الصفحة اذهب الى الأسفل
https://almomenoon1.0wn0.com/
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn
مؤسس ومدير المنتدى
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn


عدد المساهمات : 52644
العمر : 72

45 - Suuratul-Jaathiyah  Empty
مُساهمةموضوع: رد: 45 - Suuratul-Jaathiyah    45 - Suuratul-Jaathiyah  Emptyالأحد 23 يوليو 2023, 6:51 pm


(26) Sọ pé: “Allāhu l’Ó ń sọ yín di alààyè. Lẹ́yìn náà, Ó máa sọ yín di òkú. Lẹ́yìn náà, Ó máa ko yín jọ fún Ọjọ́ Àjíǹde, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kò mọ̀.
(27) Àti pé ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. (Rántí) ọjọ́ tí Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀; ọjọ́ yẹn ni àwọn òpùrọ́ máa ṣòfò.
(28) O sì máa rí gbogbo ìjọ kọ̀ọ̀kan lórí ìkúnlẹ̀. Wọn yó sì máa pe gbogbo ìjọ kọ̀ọ̀kan síbi ìwé iṣẹ́ wọn. Ní òní ni A óò san yín ní ẹ̀san ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
(29) Èyí ni ìwé àkọ́sílẹ̀ Wa, tí ó ń sọ òdodo nípa yín. Dájúdájú Àwa ń ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
(30) Ní ti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, Olúwa wọn yóò fi wọ́n sínú ìkẹ́ Rẹ̀. Ìyẹn ni èrèǹjẹ pọ́nńbélé.
(31) Ní ti àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, (A óò bi wọ́n léèrè pé:) “Ǹjẹ́ wọn kì í ké àwọn āyah Mi fún yín bí?” Ṣùgbọ́n ẹ ṣègbéraga. Ẹ sì jẹ́ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀.
(32) Nígbà tí a bá sọ pé: “Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Àti pé Àkókò náà, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀.” Ẹ̀yin ń wí pé: “Àwa kò mọ ohun tí Àkókò náà jẹ́. Àwa kò sì rò ó sí kiní kan bí kò ṣe èròkérò; àwa kò sì ní àmọ̀dájú (nípa rẹ̀).”
(33) Àwọn aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ sì hàn sí wọn. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà tó yí wọn po.
(34) Wọ́n sì máa sọ (fún wọn) pé: “Ní òní, Àwa yóò gbàgbé yín (sínú Iná) gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ṣe gbàgbé ìpàdé ọjọ́ yín (òní) yìí. Iná sì ni ibùgbé yín. Àti pé kò níí sí àwọn olùrànlọ́wọ́ fún yín.”
(35) Báyẹn ni nítorí pé, ẹ sọ àwọn āyah Allāhu di n̄ǹkan yẹ̀yẹ́. Àti pé ìṣẹ̀mí ayé tàn yín jẹ. Nítorí náà, ní òní wọn kò níí mú wọn jáde kúrò nínú Iná. Wọn kò sì níí fún wọn ní àyè láti ṣe ohun tí wọn yóò fi rí ìyọ́nú Allāhu.
(36) Nítorí náà, gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa àwọn sánmọ̀ àti Olúwa ilẹ̀, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
(37) TiRẹ̀ ni títóbi nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n. 



45 - Suuratul-Jaathiyah  2013_110
الرجوع الى أعلى الصفحة اذهب الى الأسفل
https://almomenoon1.0wn0.com/
 
45 - Suuratul-Jaathiyah
الرجوع الى أعلى الصفحة 
صفحة 1 من اصل 1
 مواضيع مماثلة
-
» Al-Jaathiyah
» CHITSAUKO AL-JAATHIYAH
» 48 - Suuratul-Fat'h
» 6 - Suuratul-An'aam
» 103 - Suuratul-As'r

صلاحيات هذا المنتدى:لاتستطيع الرد على المواضيع في هذا المنتدى
منتديات إنما المؤمنون إخوة (2024 - 2010) The Believers Are Brothers :: (English) :: The Holy Quran is translated :: Yoruba-
انتقل الى: