|
| 44 - Suuratud-Dukhaan | |
| | كاتب الموضوع | رسالة |
---|
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: 44 - Suuratud-Dukhaan الأحد 23 يوليو 2023, 6:49 pm | |
| 44 - Suuratud-Dukhaan Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run. (1) Hā mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)¹ 1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1. (2) (Allāhu) fi Tírà tó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá búra. (3) Dájúdájú Àwa sọ̀ ọ́ kalẹ̀ nínú òru ìbùkún.¹ Dájúdájú Àwa ń jẹ́ Olùkìlọ̀. 1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’Isrọ̄’; 17:106. (4) Nínú òru náà ni wọ́n ti máa yanjú gbogbo ọ̀rọ̀ tí kò níí tàsé (lórí ẹ̀dá). (5) Àṣẹ kan ni láti ọ̀dọ̀ Wa. Dájúdájú Àwa l’À ń rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́. (6) Ìkẹ́ kan ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀. (7) Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin méjèèjì tí ẹ̀yin bá jẹ́ alámọ̀dájú. (8) Kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́. (9) Síbẹ̀, wọ́n sì wà nínú iyèméjì, tí wọ́n ń ṣeré. (10) Nítorí náà, máa retí ọjọ́ tí sánmọ̀ yóò mú èéfín pọ́nńbélé wá. (11) Ó máa bo àwọn ènìyàn mọ́lẹ̀. Èyí ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro. (12) (Àwọn ènìyàn yóò wí pé): Olúwa wa, gbé ìyà náà kúrò fún wa, dájúdájú àwa yóò gbàgbọ́ ní òdodo. (13) Báwo ni ìrántí ṣe lè wúlò fún wọn (lásìkò ìyà)? Òjíṣẹ́ pọ́nńbélé kúkú ti dé bá wọn. (14) náà, wọ́n gbúnrí kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. Wọ́n sì wí pé: “Wèrè tí àwọn ènìyàn kan ń kọ́ ní ẹ̀kọ́ ni.” (15) Dájúdájú Àwa máa gbé ìyà náà kúrò fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ẹ̀yin yóò tún padà (sínú àìgbàgbọ́). (16) Ọjọ́ tí A óò gbá (wọn mú) ní ìgbámú tó tóbi jùlọ; dájúdájú Àwa yóò gba ẹ̀san ìyà (lára wọn). (17) Dájúdájú A dán àwọn ènìyàn Fir‘aon wò ṣíwájú wọn. Òjíṣẹ́ alápọ̀n-ọ́nlé sì dé wá bá wọn. (18) (Ó sọ pé): “Ẹ kó àwọn ẹrúsìn Allāhu lé mi lọ́wọ́. Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ olùfọkàntán fún yín. (19) Ẹ má ṣe ṣègbéraga sí Allāhu. Dájúdájú èmi ti mú ẹ̀rí pọ́nńbélé wá ba yín. (20) Dájúdájú Èmi sá di Olúwa mi àti Olúwa yín pé kí ẹ má ṣe sọ mí ní òkò. (21) Tí ẹ kò bá sì gbà mí gbọ́, ẹ fi mí sílẹ̀ jẹ́.” (22) Nítorí náà, ó pe Olúwa rẹ̀ pé dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni ìjọ ẹlẹ́sẹ̀. (23) (Allāhu sọ pé): “Mú àwọn ẹrúsìn Mi rìn ní alẹ́ (nítorí pé) wọn yóò tọ̀ yín lẹ́yìn. (24) Kí o sì fi agbami òkun náà sílẹ̀ (ná) kí ó dákẹ́ rọ́rọ́ láì níí ru (kí ojú ọ̀nà tí ẹ tọ̀ nínú rẹ̀ lè wà bẹ́ẹ̀, kí Fir‘aon àti ọmọ-ogun rẹ̀ lè kó sójú-ọ̀nà náà). Dájúdájú àwọn ni ọmọ ogun tí A máa tẹ̀rì sínú rẹ̀. (25) Mélòó mélòó nínú àwọn ọgbà oko àti odò ìṣẹ́lẹ̀rú tí wọ́n fi sílẹ̀ (lẹ́yìn ìparun wọn). |
| | | أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 44 - Suuratud-Dukhaan الأحد 23 يوليو 2023, 6:50 pm | |
| (26) Àti àwọn irúgbìn pẹ̀lú àyè àpọ́nlé (tí wọ́n fi sílẹ̀). (27) Àti ìdẹ̀ra tí wọ́n ń gbádùn nínú rẹ̀ (ṣíwájú ìparun wọn). (28) Báyẹn (ni ọ̀rọ̀ wọn ṣe rí). A sì jogún (ìlú) wọ́n fún ìjọ ènìyàn mìíràn. (29) Nígbà náà, sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò sunkún wọn. Wọn kò sì fi ìyà wọn falẹ̀. (30) Dájúdájú A gba àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl là nínú ìyà yẹpẹrẹ. (31) (A là wọ́n) lọ́wọ́ Fir‘aon. Dájúdájú ó jẹ́ onígbèéraga. Ó sì wà nínú àwọn alákọyọ. (32) A kúkú ṣà wọ́n lẹ́ṣà lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò tiwọn) pẹ̀lú ìmọ̀ (tí a mọ̀ nípa wọn).¹ 1 “pẹ̀lú ìmọ̀” ní àyè yìí túmọ̀ sí pé, ṣíṣa àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lẹ́ṣà lórí àwọn ẹ̀dá, ó ti wà nínú ìmọ̀ Allāhu - Ọba Alámọ̀tán - nípa wọn ṣíwájú ìṣẹ̀dá wọn. Nítorí náà, àwọn tí Allāhu ṣe ní Ànábì àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nínú wọn, kì í ṣe àṣìmú tàbí àṣìyàn bí kò ṣe àṣàyàn ẹ̀dá. Irú āyah yìí ni ọ̀rọ̀ Allāhu tó sọ pé: “Allāhu ló nímọ̀ jùlọ nípa ibi tí Ó ń fí iṣẹ́-rírán Rẹ̀ sí.” Sūrah al-’Ani‘ām; 6:124 Bákan náà, “lórí àwọn ẹ̀dá” ní àyè yìí túmọ̀ sí àwọn ẹ̀dá ìgbà tiwọn. Àmọ́ lẹ́yìn ìgbédìde Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ìjọ rẹ̀ ni Allāhu tún ṣà lẹ́ṣà lórí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl àti àwọn ènìyàn yòókù pátápátá. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:110. Kíyè sí i, ibikíbi nínú al-Ƙur’ān tí Allāhu bá ti sọ pé, Òun ṣa àwọn ẹ̀dá kan lẹ́ṣà lórí àwọn ẹ̀dá mìíràn, ó dúró fún àwọn ẹ̀dá ìgbà tiwọn nìkan. Ìṣàlẹ́ṣà náà kò sì kan àwọn ará ìgbà mìíràn. Ẹ wo sūrah al-Baƙọrah; 2:47 àti 122, sūrah āli ‘Imrọ̄n; 3:33, sūrah al-’Ani‘ām; 6:86, sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:140 àti sūrah al-Jāthiyah; 45:16. (33) A sì fún wọn ní àwọn àmì tí àdánwò pọ́nńbélé wà nínú rẹ̀. (34) Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ń wí pé: (35) “Kò sí ikú kan àyàfi ikú àkọ́kọ́ (tí ó pa wá nílé ayé). Wọn kò sì níí gbé wa dìde. (36) (Bí bẹ́ẹ̀ kọ́), ẹ mú àwọn bàbá wa wá tí ẹ bá jẹ́ olódodo.” (37) Ṣé àwọn ni wọ́n lóore jùlọ ni tàbí àwọn ènìyàn Tubba‘u àti àwọn tó ṣíwájú wọn? A pa wọ́n rẹ́; dájúdájú wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀. (38) A kò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin méjèèjì pẹ̀lú eré ṣíṣe. (39) A kò dá àwọn méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀. (40) Dájúdájú ọjọ́ òpínyà (ìyẹn, ọjọ́ àjíǹde) ni àkókò àdéhùn fún gbogbo wọn pátápátá. (41) Ní ọjọ́ tí ọ̀rẹ́ kan kò níí fi kiní kan rọ ọ̀rẹ́ kan lọ́rọ̀. A kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́. (42) Àyàfi ẹni tí Allāhu bá kẹ́. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Alágbára, Àṣàkẹ́-ọ̀run. (43) Dájúdájú igi zaƙūm (44) ni oúnjẹ ẹlẹ́ṣẹ̀. (45) Ó dà bí ògéré epo gbígbóná tí ń hó nínú ikùn (46) (tó) dà bí híhó omi tó gbóná gan-an. (47) Ẹ mú un. Kí ẹ wọ́ ọ sáàrin gbùngbùn inú iná Jẹhīm. (48) Lẹ́yìn náà, ẹ rọ́ ìyà olómi gbígbóná lé e lórí. (49) Tọ́ ọ wò (ṣebí) dájúdájú ìwọ ni alágbára, alápọ̀n-ọ́nlé (gẹ́gẹ́ bí ó ṣe pe ara rẹ). (50) Dájúdájú (ìyà) èyí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣeyèméjì nípa rẹ̀!
|
| | | أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn مؤسس ومدير المنتدى
عدد المساهمات : 52644 العمر : 72
| موضوع: رد: 44 - Suuratud-Dukhaan الأحد 23 يوليو 2023, 6:50 pm | |
| (51) Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù Allāhu yóò wà ní àyè ìfàyàbalẹ̀. (52) (Wọn yóò wà) nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra pẹ̀lú àwọn omi ìṣẹ́lẹ̀rú (ní ìsàlẹ̀ rẹ̀). (53) Wọn yóò máa wọ aṣọ àrán fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ àti àrán tó nípọn; wọn yó sì máà kọjú síra wọn (sọ̀rọ̀). (54) Báyẹn (ni ọ̀rọ̀ wọn yó ṣe rí). A sì máa fi àwọn obìnrin ẹlẹ́yinjú-ẹgẹ́ ṣe ìyàwó fún wọn. (55) Wọn yóò máa bèèrè fún gbogbo n̄ǹkan eléso nínú (Ọgbà Ìdẹ̀ra) lẹ́ni ìfàyàbalẹ̀. (56) Wọn kò níí tọ́ ikú wò níbẹ̀ àyàfi ikú àkọ́kọ́ (tí wọ́n ti kú nílé ayé). (Allāhu) sì máa ṣọ́ wọn níbi ìyà iná Jẹhīm. (57) Ó jẹ́ oore àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá. (58) Nítorí náà, dájúdájú A fi èdè abínibí rẹ (èdè Lárúbáwá) ṣe (kíké al-Ƙur’ān àti àgbọ́yé rẹ̀) ní ìrọ̀rùn nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí. (59) Nítorí náà, máa retí¹. Dájúdájú àwọn náà ń retí. 1. Ìyẹn ni pé, máa retí ìparun àwọn agbọ́mágbà.
|
| | | | 44 - Suuratud-Dukhaan | |
|
| صلاحيات هذا المنتدى: | لاتستطيع الرد على المواضيع في هذا المنتدى
| |
| |
| |