منتديات إنما المؤمنون إخوة (2024 - 2010) The Believers Are Brothers

(إسلامي.. ثقافي.. اجتماعي.. إعلامي.. علمي.. تاريخي.. دعوي.. تربوي.. طبي.. رياضي.. أدبي..)
 
الرئيسيةالأحداثأحدث الصورالتسجيل
(وما من كاتب إلا سيبلى ** ويبقى الدهر ما كتبت يداه) (فلا تكتب بكفك غير شيء ** يسرك في القيامة أن تراه)

IZHAR UL-HAQ

(Truth Revealed) By: Rahmatullah Kairanvi
قال الفيلسوف توماس كارليل في كتابه الأبطال عن رسول الله -صلى الله عليه وسلم-: "لقد أصبح من أكبر العار على أي فرد مُتمدين من أبناء هذا العصر؛ أن يُصْغِي إلى ما يظن من أنَّ دِينَ الإسلام كَذِبٌ، وأنَّ مُحَمَّداً -صلى الله عليه وسلم- خَدَّاعٌ مُزُوِّرٌ، وآنَ لنا أنْ نُحارب ما يُشَاعُ من مثل هذه الأقوال السَّخيفة المُخْجِلَةِ؛ فإنَّ الرِّسَالة التي أدَّاهَا ذلك الرَّسُولُ ما زالت السِّراج المُنير مُدَّةَ اثني عشر قرناً، لنحو مائتي مليون من الناس أمثالنا، خلقهم اللهُ الذي خلقنا، (وقت كتابة الفيلسوف توماس كارليل لهذا الكتاب)، إقرأ بقية كتاب الفيلسوف توماس كارليل عن سيدنا محمد -صلى الله عليه وسلم-، على هذا الرابط: محمد بن عبد الله -صلى الله عليه وسلم-.

يقول المستشرق الإسباني جان ليك في كتاب (العرب): "لا يمكن أن توصف حياة محمد بأحسن مما وصفها الله بقوله: (وَمَا أَرْسَلْنَاكَ إِلَّا رَحْمَةً لِّلْعَالَمِين) فكان محمدٌ رحمة حقيقية، وإني أصلي عليه بلهفة وشوق".
فَضَّلَ اللهُ مِصْرَ على سائر البُلدان، كما فَضَّلَ بعض الناس على بعض والأيام والليالي بعضها على بعض، والفضلُ على ضربين: في دِينٍ أو دُنْيَا، أو فيهما جميعاً، وقد فَضَّلَ اللهُ مِصْرَ وشَهِدَ لها في كتابهِ بالكَرَمِ وعِظَم المَنزلة وذَكَرَهَا باسمها وخَصَّهَا دُونَ غيرها، وكَرَّرَ ذِكْرَهَا، وأبَانَ فضلها في آياتٍ تُتْلَى من القرآن العظيم.
المهندس حسن فتحي فيلسوف العمارة ومهندس الفقراء: هو معماري مصري بارز، من مواليد مدينة الأسكندرية، وتخرَّجَ من المُهندس خانة بجامعة فؤاد الأول، اشْتُهِرَ بطرازهِ المعماري الفريد الذي استمَدَّ مَصَادِرَهُ مِنَ العِمَارَةِ الريفية النوبية المَبنية بالطوب اللبن، ومن البيوت والقصور بالقاهرة القديمة في العصرين المملوكي والعُثماني.
رُبَّ ضَارَّةٍ نَافِعَةٍ.. فوائدُ فيروس كورونا غير المتوقعة للبشرية أنَّه لم يكن يَخطرُ على بال أحَدِنَا منذ أن ظهر وباء فيروس كورونا المُستجد، أنْ يكونَ لهذه الجائحة فوائدُ وإيجابيات ملموسة أفادَت كوكب الأرض.. فكيف حدث ذلك؟!...
تخليص الإبريز في تلخيص باريز: هو الكتاب الذي ألّفَهُ الشيخ "رفاعة رافع الطهطاوي" رائد التنوير في العصر الحديث كما يُلَقَّب، ويُمَثِّلُ هذا الكتاب علامة بارزة من علامات التاريخ الثقافي المصري والعربي الحديث.
الشيخ علي الجرجاوي (رحمه الله) قَامَ برحلةٍ إلى اليابان العام 1906م لحُضُورِ مؤتمر الأديان بطوكيو، الذي دعا إليه الإمبراطور الياباني عُلَمَاءَ الأديان لعرض عقائد دينهم على الشعب الياباني، وقد أنفق على رحلته الشَّاقَّةِ من مَالِهِ الخاص، وكان رُكُوبُ البحر وسيلته؛ مِمَّا أتَاحَ لَهُ مُشَاهَدَةَ العَدِيدِ مِنَ المُدُنِ السَّاحِلِيَّةِ في أنحاء العالم، ويُعَدُّ أوَّلَ دَاعِيَةٍ للإسلام في بلاد اليابان في العصر الحديث.

أحْـلامٌ مِـنْ أبِـي (باراك أوباما) ***

 

 25 - Suuratul-Fur'qaan

اذهب الى الأسفل 
كاتب الموضوعرسالة
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn
مؤسس ومدير المنتدى
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn


عدد المساهمات : 52644
العمر : 72

25 - Suuratul-Fur'qaan  Empty
مُساهمةموضوع: 25 - Suuratul-Fur'qaan    25 - Suuratul-Fur'qaan  Emptyالسبت 22 يوليو 2023, 12:17 am

25 - Suuratul-Fur'qaan
Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
(1) Ìbùkún ni fún Ẹni tí Ó sọ ọ̀rọ̀-ìpínyà (ohun tó ń ṣe ìpínyà láààrin òdodo àti irọ́) kalẹ̀ fún ẹrúsìn Rẹ̀ nítorí kí ó lè jẹ́ olùkìlọ̀ fún gbogbo ẹ̀dá.
(2) (Òun ni) Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Kò mú ẹnì kan kan ní ọmọ. Kò sí akẹgbẹ́ fún Un nínú ìjọba (Rẹ̀). Ó dá gbogbo n̄ǹkan. Ó sì yan òdíwọ̀n (ìrísí, ìṣẹ̀mí àti àyànmọ́) fún un níwọ̀n-níwọ̀n.
(3) (Àwọn aláìgbàgbọ́) sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu, àwọn tí kò lè dá n̄ǹkan kan, A sì dá wọn ni. Wọn kò sì ní ìkápá ìnira tàbí àǹfààní kan fún ẹ̀mí ara wọn. Àti pé wọn kò ní ìkápá lórí ikú, ìṣẹ̀mí àti àjíǹde.
(4) Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe àdápa irọ́ kan tí ó dá àdápa rẹ̀ (mọ́ Allāhu), tí àwọn ènìyàn mìíràn sì ràn án lọ́wọ́ lórí rẹ̀.” Dájúdájú (àwọn aláìgbàgbọ́) ti gbé àbòsí àti irọ́ dé.
(5) Wọ́n tún wí pé: “Àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́, tí ó ṣàdàkọ rẹ̀ ni. Òhun ni wọ́n ń pè fún un ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́.”
(6) Sọ pé: “Ẹni tí Ó mọ ìkọ̀kọ̀ tí ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ l’Ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀. Dájúdájú Òun ni Ó ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”
(7) Wọ́n tún wí pé: “Kí ló mú Òjíṣẹ́ yìí, tó ń jẹun, tó ń rìn nínú àwọn ọjà? Nítorí kí ni Wọn kò ṣe sọ mọlāika kan kalẹ̀ fún un kí ó lè jẹ́ olùkìlọ̀ pẹ̀lú rẹ̀?
(8) Tàbí (nítorí kí ni) wọn kò ṣe ju àpótí-ọrọ̀ kan sọ́dọ̀ rẹ̀, tàbí kí ó ní ọgbà oko kan tí ó ma máa jẹ nínú rẹ̀?” Àwọn alábòsí sì tún wí pé: “Ta ni ẹ̀ ń tẹ̀lé bí kò ṣe ọkùnrin eléèdì kan.”
(9) Wo bí wọ́n ṣe fún ọ ní àwọn àfiwé (burúkú)! Nítorí náà, wọ́n ti ṣìnà; wọn kò sì lè mọ̀nà.
(10) Ìbùkún ni fún Ẹni tí (ó jẹ́ pé) bí Ó bá fẹ́, Ó máa ṣoore tó dára ju ìyẹn fún ọ. (Ó sì máa jẹ́) àwọn ọgbà tí àwọn odò yóò máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ó sì máa fún ọ ni àwọn ààfin kan.
(11) Ńṣe ni wọ́n pe Àkókò náà nírọ́. A sì ti pèsè Iná tó ń jo sílẹ̀ de ẹnikẹ́ni tí ó bá pe Àkókò náà nírọ́.
(12) Nígbà tí (Iná náà) bá rí wọn láti àyè kan tí ó jìnnà, wọn yó sì máa gbọ́ ohùn ìbínú àti kíkùn (rẹ̀).
(13) Nígbà tí wọ́n bá sì jù wọ́n sí àyè tó há gádígádí nínú (Iná), tí wọ́n de ọwọ́ wọn mọ́ wọn lọ́rùn, wọn yó sì máa kígbe ìparun níbẹ̀.
(14) (A ó sọ pé): “Ẹ má ṣe kígbe ìparun ẹyọ kan, ẹ kígbe ìparun lọ́pọ̀lọ́pọ̀.”
(15) Sọ pé: “Ǹjẹ́ ìyẹn ló lóore jùlọ ni tàbí Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére, èyí tí A ṣe ní àdéhùn fún àwọn olùbẹ̀rù Allāhu. Ó sì jẹ́ ẹ̀san àti ìkángun rere fún wọn.
(16) Ohunkóhun tí wọ́n bá ń fẹ́ wà fún wọn nínú rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n (nínú rẹ̀). (Èyí) jẹ́ àdéhùn tí wọ́n ti tọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Olúwa rẹ.
(17) Àti pé (rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò kó àwọn abọ̀rìṣà àti n̄ǹkan tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu jọ, (Allāhu) yó sì sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin l’ẹ ṣi àwọn ẹrúsìn Mi wọ̀nyí lọ́nà ni tàbí àwọn ni wọ́n ṣìnà (fúnra wọn)?”¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:74.
(18) Wọ́n wí pé: “Mímọ́ ni fún Ọ! Kò tọ́ fún wa láti mú àwọn kan ní alátìlẹ́yìn lẹ́yìn Rẹ. Ṣùgbọ́n Ìwọ l’O fún àwọn àti àwọn bàbá wọn ní ìgbádùn, títí wọ́n fi gbàgbé Ìrántí. Wọ́n sì jẹ́ ẹni ìparun.”
(19) (Allāhu sọ pé): “Dájúdájú àwọn òrìṣà ti pe ẹ̀yin abọ̀rìṣà ní òpùrọ́ nípa ohun tí ẹ̀ ń sọ (pé olùṣìpẹ̀ ni wọ́n). Ní báyìí wọn kò lè gbé ìyà Iná kúrò fún yín, wọn kò sì lè ràn yín lọ́wọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó ṣe àbòsí (ẹbọ ṣíṣe) nínú yín, A sì máa fún un ní ìyà tó tóbi tọ́ wò.”
(20) A kò rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́ rí ṣíwájú rẹ àfi kí wọ́n jẹun, kí wọ́n sì rìn nínú ọjà. A ti fi apá kan yín ṣe àdánwò fún apá kan, ǹjẹ́ ẹ máa ṣe sùúrù bí? Olúwa Rẹ sì ń jẹ́ Olùríran.
(21) Àwọn tí kò retí ìpàdé Wa (ní ọ̀run) wí pé: “Wọn kò ṣe sọ àwọn mọlāika kalẹ̀ fún wa tàbí kí á rí Olúwa wa (ní ojúkojú)? Dájúdájú wọ́n ti ṣègbéraga nínú ẹ̀mí wọn. Wọ́n sì ti tayọ ẹnu-ààlà ní ìtayọ ẹnu-ààlà tó tóbi.
(22) (Rántí) ọjọ́ tí wọ́n yóò rí àwọn mọlāika, kò níí sí ìró ìdùnnú fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọjọ́ yẹn. (Àwọn mọlāika) yó sì sọ pé: “Èèwọ̀, èèwọ̀ (ni ìró ìdùnnú fún ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀).”
(23) Àti pé A máa wá ṣíbi ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́, A sì máa sọ ọ́ di eruku tí wọ́n fẹ́ dànù.
(24) Àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ní ọjọ́ yẹn, (ọgbà wọn) máa lóore jùlọ ní ibùgbé. Ó sì máa dára jùlọ ní ibùsinmi.
(25) Àti pé (rántí) ọjọ́ tí sánmọ̀ yó fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣújò funfun (tí yóò máa tú jáde nínú wọn).¹ A sì máa sọ àwọn mọlāika kalẹ̀ tààrà.
1. Ẹ wo sūrah al-Baƙọrah ; 2:210, sūrah al-’Infitọ̄r; 82:1-2 àti sūrah al-’Inṣiƙọ̄ƙ; 84:1-2. 



25 - Suuratul-Fur'qaan  2013_110
الرجوع الى أعلى الصفحة اذهب الى الأسفل
https://almomenoon1.0wn0.com/
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn
مؤسس ومدير المنتدى
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn


عدد المساهمات : 52644
العمر : 72

25 - Suuratul-Fur'qaan  Empty
مُساهمةموضوع: رد: 25 - Suuratul-Fur'qaan    25 - Suuratul-Fur'qaan  Emptyالسبت 22 يوليو 2023, 12:18 am


(26) Ìjọba òdodo ti ọjọ́ yẹn ń jẹ́ ti Àjọkẹ́-ayé. Ó sì jẹ́ ọjọ́ kan tí ó máa nira fún àwọn aláìgbàgbọ́.
(27) (Rántí) ọjọ́ tí alábòsí yóò jẹ ìka ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì, ó sì máa wí pé: “Yéè! Èmi ìbá ti tọ ọ̀nà kan (náà) pẹ̀lú Òjíṣẹ́ náà.
(28) Ègbé mi o, yéè! Èmi ìbá tí mú lágbájá ní ọ̀rẹ́ àyò.
(29) Dájúdájú ó ti ṣì mí lọ́nà kúrò níbi Ìrántí lẹ́yìn tí ó dé bá mi. Dájúdájú Èṣù ń jẹ́ adáni-dáṣòro fún ọmọnìyàn.”
(30) Òjíṣẹ́ náà sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú àwọn ènìyàn mi ti pa al-Ƙur’ān yìí tì.”
(31) Báyẹn ni A ṣe àwọn kan nínú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọ̀tá fún Ànábì kọ̀ọ̀kan. Olúwa rẹ sì tó ní Afinimọ̀nà àti Alárànṣe.
(32) Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “Wọn kò ṣe sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún un ní àpapọ̀ ní ẹ̀ẹ̀ kan náà?” (A sọ̀ ọ́ kalẹ̀ díẹ̀díẹ̀) báyẹn nítorí kí A lè fi rinlẹ̀ sínú ọkàn rẹ. A sì ké e fún ọ díẹ̀díẹ̀.
(33) Wọn kò níí mú àpẹ̀ẹrẹ kan wá fún ọ (gẹ́gẹ́ bí ìbéèrè láti fi takò ọ́) àfi kí Á mú òdodo (ìyẹn, al-ƙur’ān) àti àlàyé tó dára jùlọ wá fún ọ (lórí rẹ̀).
(34) Àwọn tí A máa kó jọ lọ sínú iná Jahanamọ ní ìdojúbolẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni àyè wọn burú jùlọ. Wọ́n sì ṣìnà jùlọ.
(35) Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. A tún ṣe arákùnrin rẹ̀, Hārūn, ní amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ fún un.
(36) A sì sọ pé: “Ẹ̀yin méjèèjì, ẹ lọ sọ́dọ̀ ìjọ tó pe àwọn āyah Wa nírọ́. A sì pa ìjọ náà run pátápátá.
(37) (Rántí) ìjọ (Ànábì) Nūh. Nígbà tí wọ́n pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́, A tẹ̀ wọ́n rì sínú omi. A sì ṣe wọ́n ní àmì kan fún àwọn ènìyàn. A sì ti pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ de àwọn alábòsí.
(38) (Rántí) àwọn ìjọ ‘Ād, ìjọ Thamūd, ìjọ Rass àti àwọn ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìran mìíràn (tó ń bẹ) láààrin wọn.
(39) Ìkọ̀ọ̀kan wọn ni A fún ní àwọn àpẹ̀ẹrẹ (gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí àti àlàyé ọ̀rọ̀). Ìkọ̀ọ̀kan wọn sì ni A parun pátápátá (torí àìgbàgbọ́ wọn).
(40) Àti pé dájúdájú àwọn náà kọjá ní ìlú tí A rọ òjò burúkú lé lórí. Ṣé wọn kì í rí i ni? Rárá, ńṣe ni wọn kò retí Àjíǹde.
(41) Nígbà tí wọ́n bá sì rí ọ, kò sí ohun tí wọn yóò fi ọ́ ṣe bí kò ṣe yẹ̀yẹ́. (Wọ́n á wí pé): “Ṣé èyí ni ẹni tí Allāhu gbé dìde ní Òjíṣẹ́!?
(42) Ó mà fẹ́ẹ̀ ṣẹ́rí wa kúrò níbi àwọn ọlọ́hun wa, tí kì í bá ṣe pé a takú sorí rẹ̀.” Láìpẹ́ wọn máa mọ ẹni tí ó ṣìnà jùlọ nígbà tí wọ́n bá rí ìyà.
(43) Sọ fún mi nípa ẹni tí ó sọ ìfẹ́-inú rẹ̀ di ọlọ́hun rẹ̀! Nítorí náà, ṣé ìwọ máa jẹ́ aláàbò fún un ni (níbi ìyà)?
(44) Tàbí ìwọ ń rò pé dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ń gbọ́ràn tàbí pé wọ́n ń ṣe làákàyè? Kí ni wọ́n ná, bí kò ṣe bí àgùtàn. Rárá, wọ́n ṣìnà jùlọ.
(45) Ṣé o ò rí (iṣẹ́) Olúwa rẹ ni, bí Ó ṣe fẹ òkùnkùn òwúrọ̀ lójú (sójú sánmọ̀)? Tí Ó bá fẹ́ ni, ìbá dá a dúró síbẹ̀. Lẹ́yìn náà, A fi òòrùn ṣe atọ́ka sí bíbẹ òkùnkùn.
(46) Lẹ́yìn náà, A (fi ìmọ́lẹ̀ òòrùn) mú òkùnkùn (kúrò níta) wá sí ọ̀dọ̀ Wa ní mímú díẹ̀díẹ̀ (kí ojúmọ́ lè mọ́).
(47) Àti pé Òun ni Ẹni tí Ó ṣe òru ní ìbora fún yín. (Ó ṣe) oorun ní ìsinmi (fún yín). Ó tún ṣe ọ̀sán ní àsìkò ìtúsíta (fún wíwá ìjẹ-ìmu).
(48) Òun sì ni Ẹni t’Ó ń rán atẹ́gùn ní ìró-ìdùnnú ṣíwájú ìkẹ́ Rẹ̀. A sì sọ omi mímọ́ kalẹ̀ láti sánmọ̀
(49) nítorí kí A lè fi sọ òkú ilẹ̀ di àyè ilẹ̀ àti nítorí kí A lè fún ẹran-ọ̀sìn àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn nínú àwọn tí A dá ní omi mu.
(50) Dájúdájú À ń darí omi yìí káàkiri láààrin wọn¹ nítorí kí wọ́n lè rántí (ìkẹ́ Olúwa wọn). Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn kọ̀ (láti rántí) àfi àìmoore.
1. A lè rọ̀jọ̀ sí ìlú kan, kí Á mú ọ̀dá òjò wá sí ibò mìíràn. 



25 - Suuratul-Fur'qaan  2013_110
الرجوع الى أعلى الصفحة اذهب الى الأسفل
https://almomenoon1.0wn0.com/
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn
مؤسس ومدير المنتدى
أحمد محمد لبن Ahmad.M.Lbn


عدد المساهمات : 52644
العمر : 72

25 - Suuratul-Fur'qaan  Empty
مُساهمةموضوع: رد: 25 - Suuratul-Fur'qaan    25 - Suuratul-Fur'qaan  Emptyالسبت 22 يوليو 2023, 12:19 am


(51) Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́ ni, A ìbá gbé olùkìlọ̀ kan dìde nínú ìlú kọ̀ọ̀kan.¹
1. Nínú oore àjùlọ tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - ṣe fún Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni pé, kò sí ànábì mìíràn ní ibikíbi ní àsìkò ìṣẹ̀mí rẹ̀ lójú ayé rẹ̀. Èyí ni àgbọ́yé āyah yìí. Àmọ́ ṣíwájú àsìkò tirẹ̀, Allāhu nìkan ló mọ iye ìgbà tí Ó fi iṣẹ́ Rẹ̀ rán Ànábì méjì tàbí mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní àsìkò kan-ùn nínú ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Bí àpẹ̀ẹrẹ, àsìkò kan-ùn ni àsìkò Ànábì ’Ibrọ̄hīm àti Ànábì Lūt, àsìkò kan-ùn ni àsìkò Ànábì Ṣu‘aeb, Ànábì Mūsā àti Ànábì Hārūn - kí ọlà Allāhu máa bá wọn -. Síwájú sí i, oore àjùlọ yìí ló fi jẹ́ pé, gbogbo ayé pátápátá ni Allāhu rán Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - níṣẹ́ sí, = = elédè Lárúbáwá àti elédè mìíràn, ènìyàn àti àlùjọ̀nnú. (sūrah āl-‘Imrọ̄n; 3:110, sūrah al-’An‘ām; 6:19, surah al-Jinn; 72:1 àti sūrah al-’Anbiyā’; 21:107.) Àmọ́ ṣíwájú àsìkò Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ìjọ Ànábì kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ jẹ́ elédè Ànábì rẹ̀ nìkan. Èyí ni ó jẹyọ nínú sūrah ’Ibrọ̄hīm; 14:4. Bákan náà, nínú oore àjùlọ tí Allāhu ṣe fún Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni pé, kò níí sí ànábì mìíràn mọ́ ní ibikíbi lẹ́yìn ikú Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - títí di òpin ayé. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Ahzāb; 33:40.
(52) Nítorí náà, má ṣe tẹ̀lé àwọn aláìgbàgbọ́. Kí o sì fi (al-Ƙur’ān) jà wọ́n ní ogun tó tóbi.
(53) Òun ni Ẹni tí Ó mú àwọn odò méjì ṣàn kiri. Èyí (ni omi) tó dùn gan-an. Èyí sì (ni omi) iyọ̀ tó móró. Ó sì fi gàgá sí ààrin àwọn méjèèjì. (Ó sì) ṣe é ní èèwọ̀ pọ́nńbélé (fún wọn láti kó ìnira bá ẹ̀dá).
(54) Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá abara láti inú omi. Ó ṣe ìbátan ẹbí àti ìbátan àna fún un, Olúwa rẹ sì ń jẹ́ Alágbára.¹
1. Ìṣẹ̀dá ènìyàn wáyé nípasẹ̀ oríṣi ọ̀nà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìkíní; nípasẹ̀ erùpẹ̀. Èyí sì ni Allāhu Ẹlẹ́dàá fi ṣe ẹ̀dá bàbá wa àkọ́kọ́, Ànábì Ādam - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Nítorí náà, ìgbàkígbà tí Allāhu Ẹlẹ́dàá bá ń ki ìṣẹ̀dá wa kan erùpẹ̀ nítorí ti Ànábì Ādam ni - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Ìkejì; nípasẹ̀ ẹfọ́nhà. Èyí sì ni Allāhu Ẹlẹ́dàá fi ṣe ẹ̀dá ìyá wa àkọ́kọ́, Hawā’ - kí Allāhu yọ́nú sí i -. Nítorí náà, ìgbàkígbà tí = = Allāhu Ẹlẹ́dàá bá ń kí ìṣẹ̀dá àwọn obìnrin kan àwa ọkùnrin, nítorí ti Hawā’ ni - kí Allāhu yọ́nú sí i -. Ìkẹta; nípasẹ̀ omi àtọ̀. Èyí si ni Allāhu Ẹlẹ́dàá fi ṣe ẹ̀dá èmi àti ẹ̀yin. Nítorí náà, ìgbàkígbà tí Allāhu Ẹlẹ́dàá bá ń ki ìṣẹ̀dá wa kan omi nítorí ti èmi àti ẹ̀yin ni. Ìkẹrin; nípasẹ̀ atẹ́gùn ẹ̀mí àti gbólóhùn “kunfayakūn” Rẹ̀. Èyí sì ni Allāhu Ẹlẹ́dàá fi ṣe ẹ̀dá ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Kíyè sí i! Àti ìkíní àti ìkejì àti ìkẹta, kò sí ènìyàn kan tí kò ní atẹ́gùn ẹ̀mí lára ṣíwájú kí ó tó di abẹ̀mí. Ṣebí atẹ́gùn ẹ̀mí tí Allāhu ṣẹ̀ṣẹ̀ fi rán mọlāika Jibril - kí ọlà Allāhu máa bá a - sí Mọryam, ìyá Ànábì ‘Īsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - ni Allāhu fúnra Rẹ̀ fẹ́ sínú ọbọrọgidi Ādam - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Èyí kò sì sọ Ànábì Ādam di olúwa àti olùgbàlà. Báwo ni Ànábì ‘Īsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - yó ṣe wá jẹ́ olúwa àti olùgbàlà! Kò sì sí ènìyàn tàbí ẹ̀dá kan tí Allāhu Ẹlẹ́dàá kò ni sọ gbólóhùn “kunfayakūn” fún, ṣíwájú kí ó tó máa bẹ.
(55) Wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu ohun tí kò lè ṣe wọ́n ní àǹfààní, tí kò sì lè kó ìnira bá wọn. Aláìgbàgbọ́ jẹ́ olùrànlọ́wọ́ (fún Èṣù) láti tako Olúwa rẹ̀.
(56) A kò sì rán ọ níṣẹ́ tayọ kí o jẹ́ oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀.
(57) Sọ pé: “Èmi kò bèèrè owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ yín lórí rẹ̀ àfi ẹni tí ó bá fẹ́ mú ọ̀nà (dáadáa) tọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀.”¹
1. Ìyẹn ni pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí Òjíṣẹ́ tàbí Ànábì kan tí ó ń gba owó-ọ̀yà lọ́wọ́ ìjọ rẹ̀ lórí iṣẹ́ tí Allāhu fi rán an níṣẹ́ sí wọn, iṣẹ́ olóore ni fún ẹnikẹ́ni láti máa fún Òjíṣẹ́ tí Allāhu rán sí wọn lọ́rẹ. Ọrẹ sì yàtọ̀ sí owó-ọ̀yà.
(58) Gbáralé Alààyè tí kò níí kú. Ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Un.¹ Allāhu sì tó ní Alámọ̀tán nípa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.
1. Ìyẹn ni pé, ṣe àfọ̀mọ́ Allāhu kúrò níbi gbogbo àdínkù àti àbùkù, kí o sì yìn Ín lógo pé, Ó pé tán pátápátá.
(59) (Òun ni) Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti àwọn n̄ǹkan tó ń bẹ láààrin méjèèjì láààrin ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá. Àjọkẹ́-ayé ni, nítorí náà, bèèrè nípa Rẹ̀ (lọ́dọ̀ Rẹ̀ nítorí pé, Ó jẹ́) Alámọ̀tán.
(60) Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ fún Àjọkẹ́-ayé.” Wọ́n á wí pé: “Kí ni Àjọkẹ-ayé? Ṣé kí á forí kanlẹ̀ fún ohun tí ò ń pa wá láṣẹ rẹ̀ ni?” (Ìpèpè náà) sì mú wọn lékún ní sísá-sẹ́yìn.
(61) Ìbùkún ni fún Ẹni tí Ó ṣe àwọn ibùsọ̀ ìràwọ̀ sínú sánmọ̀. Ó tún ṣe òòrùn àti òṣùpá ní ìmọ́lẹ̀ sínú rẹ̀.
(62) Òun ni Ẹni tí Ó ṣe òru àti ọ̀sán ní ìtẹ̀léǹtẹ̀lé (tí ìkíní yàtọ̀ sí ìkejì) nítorí ẹni tí ó bá gbèrò láti ṣe ìrántí (Allāhu) tàbí tí ó bá gbèrò ìdúpẹ́ (fún Un).
(63) Àwọn ẹrúsìn Àjọkẹ́-ayé ni àwọn tó ń rìn jẹ́ẹ́jẹ́ lórí ilẹ̀. Nígbà tí àwọn òpè bá sì dojú ọ̀rọ̀ kọ wọ́n, wọn yóò sọ ọ̀rọ̀ àlàáfíà.
(64) (Àwọn ni) àwọn tó ń lo òru wọn ní ìforíkanlẹ̀ àti ní ìdúró-kírun fún Olúwa wọn.
(65) (Àwọn ni) àwọn tó ń sọ pé: “Olúwa wa, gbé ìyà iná Jahanamọ kúrò fún wa. Dájúdájú ìyà rẹ̀ jẹ́ ìyà àìnípẹ̀kun.
(66) Dájúdájú ó burú ní ibùgbé àti ibùdúró.
(67) Àwọn tí ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá náwó, wọn kò ná ìná-àpà, wọn kò sì ṣahun; (ìnáwó wọn) wà láààrin ìyẹn ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì.
(68) (Àwọn ni) àwọn tí kò pe ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Wọn kò pa ẹ̀mí tí Allāhu ṣe (pípa rẹ̀) ní èèwọ̀ àfi ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Àti pé wọn kò ṣe zinā. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe (aburú) yẹn, ó máa pàdé (ìyà) ẹ̀ṣẹ̀.
(69) A óò ṣe ìyà ní ìlọ́po fún un ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó sì máa ṣe gbére nínú rẹ̀ ní ẹni yẹpẹrẹ.
(70) Àfi ẹni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu yóò fi iṣẹ́ rere rọ́pò iṣẹ́ aburú wọn (ìyẹn, nípa ìronúpìwàdà wọn). Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
(71) Ẹnikẹ́ni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, (kí ó mọ̀) pé dájúdájú ó ń ronú pìwàdà pátápátá sọ́dọ̀ Allāhu ni.
(72) (Àwọn ni) àwọn tí kò jẹ́rìí èké. Tí wọ́n bá sì kọjá níbi ìbàjẹ́, wọ́n á kọjá pẹ̀lú àpọ́nlé.¹
1. Ìyẹn ni pé, àwọn ẹrúsìn Allāhu ń pọ́nra wọn lé nípa àìjókòó pọ̀ pẹ̀lú àwọn onísọkúsọ. Wọ́n sì ń pọ́nra wọn lé nípa yíyẹra fún ìjókòó tí àwọn aláìmọ̀kan bá ti ń ṣe ìbàjẹ̀ nínú rẹ̀.
(73) (Àwọn ni) àwọn tí ó jẹ́ pé tí wọ́n bá fi àwọn āyah Olúwa wọn ṣèrántí fún wọn, wọn kò dà lulẹ̀ bí adití àti afọ́jú.
(74) (Àwọn ni) àwọn tó ń sọ pé: “Olúwa wa, ta wá ní ọrẹ ìtutù-ojú (ìdùnnú àti ayọ̀) láti ara àwọn ìyàwó wa àti àwọn ọmọ wa. Kí O sì ṣe wá ní aṣíwájú (àwòkọ́ṣe rere) fún àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ).”
(75) Àwọn wọ̀nyẹn, ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì gíga (Ọgbà Ìdẹ̀ra) ni A máa fi san wọ́n ní ẹ̀san nítorí pé, wọ́n ṣe sùúrù. Ìkíni àti sísálámọ̀ ni A óò fi máa pàdé wọn nínú rẹ̀
(76) Olúṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ó dára ní ibùgbé àti ibùdúró.
(77) Sọ pé: “Olúwa mi kò kà yín kún tí kì í bá ṣe àdúà yín (àti ìjọ́sìn yín). Ẹ kúkú ti pe (àwọn āyah Rẹ̀) nírọ́. Láìpẹ́ ó sì máa di ìyà àìnípẹ̀kun (fún yín).” 



25 - Suuratul-Fur'qaan  2013_110
الرجوع الى أعلى الصفحة اذهب الى الأسفل
https://almomenoon1.0wn0.com/
 
25 - Suuratul-Fur'qaan
الرجوع الى أعلى الصفحة 
صفحة 1 من اصل 1
 مواضيع مماثلة
-
» Al-Furqaan
» Al-Furqaan
» AL FURQAAN
» Al-Furqaan
» Al-Furqaan

صلاحيات هذا المنتدى:لاتستطيع الرد على المواضيع في هذا المنتدى
منتديات إنما المؤمنون إخوة (2024 - 2010) The Believers Are Brothers :: (English) :: The Holy Quran is translated :: Yoruba-
انتقل الى: