81 - Suuratut-Takweer
Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.  
(1) Nígbà tí wọ́n bá ká òòrùn kóróbójó dànù,
(2) àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,
(3) àti nígbà tí wọ́n bá mú àwọn àpáta rìn (kúrò ní àyè wọn, tí wọ́n kù wọ́n dànù),
(4) àti nígbà tí wọ́n bá pa àwọn ràkúnmí aboyún tì,
(5) àti nígbà tí wọ́n bá ko àwọn ẹranko jọ,
(6) àti nígbà tí wọ́n bá mú àwọn agbami odò gbiná,
(7) àti nígbà tí wọ́n bá so àwọn ẹ̀mí pọ̀ mọ́ra wọn, (ẹni rere pẹ̀lú ẹni rere, ẹni ibi pẹ̀lú ẹni ibi)
(8) àti nígbà tí ọmọbìnrin tí wọ́n bò mọ́lẹ̀ láàyè bá bèèrè pé
(9) ẹ̀ṣẹ̀ wo ni wọ́n pa òun fún,
(10) àti nígbà tí wọ́n bá ṣí àwọn tákàdá (iṣẹ́ ẹ̀dá) sílẹ̀,
(11) àti nígbà tí wọ́n bá ká sánmọ̀ kúrò lókè,
(12) àti nígbà tí wọ́n bá mú iná Jẹhīm jò fòfò,
(13) àti nígbà tí wọ́n bá sún Ọgbà Ìdẹ̀ra mọ́ (àwọn onígbàgbọ́ òdodo),
(14) (nígbà náà ni) ẹ̀mí (kọ̀ọ̀kan) yóò mọ ohun tí ó mú wá (nínú iṣẹ́ ire àti iṣẹ́ ibi).
(15) Nítorí náà, Èmi (Allāhu) ń fi àwọn ìràwọ̀ tó ń yọ ní alẹ́, tó ń wọ̀ọ̀kùn ní ọ̀sán búra,
(16) (ìyẹn) àwọn ìràwọ̀ tó ń rìn lọ rìn bọ̀, tó ń wọ̀ọ̀kùn sí ibùwọ̀ wọn.
(17) Mo tún fi alẹ́ nígbà tí ó bá lọ búra.¹
1. Ìtúmọ̀ mìíràn: Mo tún fi alẹ́ nígbà tí ó bá wọlé búra.
(18) Mo tún fi òwúrọ̀ nígbà tí ó bá mọ́lẹ̀ búra.
(19) Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán Jibrīl) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé,¹
1. Wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Hāƙƙọh; 69:40.
(20) alágbára, ẹni pàtàkì ní ọ̀dọ̀ Ẹni t’Ó ni Ìtẹ́-ọlá,
(21) ẹni tí wọ́n ń tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ níbẹ̀ yẹn (nínú sánmọ̀), olùfọkàntán.
(22) Àti pé ẹni yín (Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) kì í ṣe wèrè.
(23) Ó kúkú rí i nínú òfurufú kedere.¹
1. Ìyẹn ni pé, Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - fojú ara rẹ̀ rí Mọlāika Jibrīl - kí ọlà Allāhu máa bá a - nínú òfurufú kedere. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah an-Najm; 53:13.
(24) Àti pé kì í ṣe ahun (tàbí ẹni-afurasí) lórí ìró ìkọ̀kọ̀ (tí A fi ránṣẹ́ sí i).
(25) Al-Ƙur’ān kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Èṣù, ẹni ẹ̀kọ̀.
(26) Nítorí náà, ibo l’ẹ̀ ń lọ?
(27) Kí sì ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.
(28) (Ó wà) fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti dúró déédé.
(29) Ẹ̀yin kò sì níí fẹ́ (láti dúró déédé) àyàfi tí Allāhu bá fẹ́, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.